وَلِيُمَحِّصَ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَيَمۡحَقَ ٱلۡكَٰفِرِينَ 141
Ati wipe ninu awọn ọgbọn naa ni mimọ awọn olugbagbọ ododo kuro nibi awọn ẹsẹ wọn, ati mimọ afojọ wọn kuro nibi awọn oloju eji, ati wipe ki O le ba pa awọn alaigbagbọ run, ki O si tun le ba pa wọn rẹ.
أَمۡ حَسِبۡتُمۡ أَن تَدۡخُلُواْ ٱلۡجَنَّةَ وَلَمَّا يَعۡلَمِ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ جَٰهَدُواْ مِنكُمۡ وَيَعۡلَمَ ٱلصَّٰبِرِينَ 142
Se ẹ wa nlero - ẹyin olugbagbọ ododo - pe dajudaju ẹyin yoo wọ Ọgba Idẹra lairi adanwo ati suuru, ti awọn olujagun si oju ọna Ọlọhun Ọba Allah ti tootọ ma nse afihan rẹ ati awọn oluse suuru lori adanwo eyiti o ba kan wọn ni ibẹ? !
وَلَقَدۡ كُنتُمۡ تَمَنَّوۡنَ ٱلۡمَوۡتَ مِن قَبۡلِ أَن تَلۡقَوۡهُ فَقَدۡ رَأَيۡتُمُوهُ وَأَنتُمۡ تَنظُرُونَ 143
Ati wipe ni paapaa ẹ jẹ - ẹyin olugbagbọ ododo - ẹniti o nrankan lati pade awọn alaigbagbọ, ki ọwọ yin le baa tẹ kiku si oju ọna Ọlọhun Ọba Allah, gẹgẹ bi ọwọ awọn ọmọ iya yin se tẹ ni Ọjọ Badiri, siwaju ki ẹ to pade awọn okunfa iku ati lile rẹ, ha, ẹ ti ri ni paapaa, ni Ọjọ Uhud ohun ti ẹ rankan, ti ẹyin si nwoo ni oju koroju.
Ati wipe ni igbati o waa fọn kan laarin awọn eniyan ni Ọjọ Uhud wipe dajudaju wọn ti pa Anọbi (ki Ọlọhun se ikẹ ati igẹ fun un) , Ọlọhun Ọba Allah waa sọkalẹ ni Ẹniti nbu awọn ti o joko tẹtẹrẹ ninu awọn olugbagbọ ododo kuro nibi jijagun pẹlu okunfa nkan naa, ni O wa sọ wipe:
وَمَا مُحَمَّدٌ إِلَّا رَسُولٞ قَدۡ خَلَتۡ مِن قَبۡلِهِ ٱلرُّسُلُۚ أَفَإِيْن مَّاتَ أَوۡ قُتِلَ ٱنقَلَبۡتُمۡ عَلَىٰٓ أَعۡقَٰبِكُمۡۚ وَمَن يَنقَلِبۡ عَلَىٰ عَقِبَيۡهِ فَلَن يَضُرَّ ٱللَّهَ شَيۡٔٗاۗ وَسَيَجۡزِي ٱللَّهُ ٱلشَّٰكِرِينَ 144
Muhammad ko jẹ nkankan ju ojisẹ lọ ninu iran awọn ti o siwaju rẹ ninu awọn ojisẹ Ọlọhun Ọba Allah, awọn ti wọn ku tabi wọn pa wọn, se ti o ba waa ku, oun gangan tabi wọn paa, ẹ o pada kuro ninu ẹsin yin ni, ati wipe se ẹ o si tun fi jijagun silẹ, ẹniti o ba kuro ninu yin nibi ẹsin rẹ, ko nii ko inira kankan ba Ọlọhun Ọba Allah nigbati o jẹ wipe Oun ni Alagbara, ti wọn ko lee bori, ati wipe bi ko se wipe ẹniti o pada ni yoo ni ara rẹ lara pẹlu sisẹri rẹ si ofo aye ati ọrun, ati wipe Ọlọhun Ọba Allah yoo pada san awọn oludupẹ fun Un ni ẹsan ti o dara ju pẹlu diduro sinsin wọn lori ẹsin Rẹ ati jijagun wọn si oju ọna Rẹ.
وَمَا كَانَ لِنَفۡسٍ أَن تَمُوتَ إِلَّا بِإِذۡنِ ٱللَّهِ كِتَٰبٗا مُّؤَجَّلٗاۗ وَمَن يُرِدۡ ثَوَابَ ٱلدُّنۡيَا نُؤۡتِهِۦ مِنۡهَا وَمَن يُرِدۡ ثَوَابَ ٱلۡأٓخِرَةِ نُؤۡتِهِۦ مِنۡهَاۚ وَسَنَجۡزِي ٱلشَّٰكِرِينَ 145
Ati wipe ẹmin kankan ko le ku ayaafi pẹlu wiwa si imusẹ kadara Ọlọhun Ọba Allah lẹyin ti o ti lo asiko ẹyiti Ọlọhun Ọba Allah kọ fun pe, ti O si tun se ni asiko fun, ti ko le lekun, ti ko si tun nii din ku, ati wipe ẹniti o ba gbero ẹsan aye pẹlu isẹ rẹ, A o fun pẹlu odiwọn ohun ti A kadara fun un nibẹ, ati wipe ko si ipin kankan fun ni Ọjọ Ikẹyin, ati wipe ẹniti o ba gbero pẹlu isẹ rẹ, ẹsan Ọlọhun Ọba Allah ni ọrun, ni Ọjọ Ikẹyin, A o fun ni ẹsan rẹ ati wipe A o pada san awọn oludupẹ fun Ọlọhun Ọba wọn ni ẹsan ti o tobi.
وَكَأَيِّن مِّن نَّبِيّٖ قَٰتَلَ مَعَهُۥ رِبِّيُّونَ كَثِيرٞ فَمَا وَهَنُواْ لِمَآ أَصَابَهُمۡ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ وَمَا ضَعُفُواْ وَمَا ٱسۡتَكَانُواْۗ وَٱللَّهُ يُحِبُّ ٱلصَّٰبِرِينَ 146
Ati wipe melomelo Anọbi ninu awọn Anọbi Ọlọhun Ọba Allah ni awọn ijọ ti o pọ ninu awọn olutẹle rẹ ti jagun pẹlu rẹ, wọn ko se ojo nipa jijagun, nitori ohun ti o sẹlẹ si wọn ninu pipa ati sisa ni ọgbẹ ni oju ọna Ọlọhun Ọba Allah, ati wipe wọn ko kọlẹ nibi jija ọta ni ogun, wọn si tun tẹriba fun un, bikose wipe wọn se suuru, wọn si tun duro sinsin, ati wipe Ọlọhun Ọba Allah ma nnifẹ awọn onisuuru lor awọn ilekoko ati awọn ohun ti ọkan kọ ni oju ọna Rẹ.
وَمَا كَانَ قَوۡلَهُمۡ إِلَّآ أَن قَالُواْ رَبَّنَا ٱغۡفِرۡ لَنَا ذُنُوبَنَا وَإِسۡرَافَنَا فِيٓ أَمۡرِنَا وَثَبِّتۡ أَقۡدَامَنَا وَٱنصُرۡنَا عَلَى ٱلۡقَوۡمِ ٱلۡكَٰفِرِينَ 147
Ati wipe gbolohun awọn oni suuru yii nigbati adanwo yii sọkalẹ pẹlu wọn, ko jẹ nkankan ju wipe wọn sọ wipe lọ, irẹ Ọlọhun Ọba wa, fi ori awọn ẹsẹ wa jin wa ati kikọja ti a kọja awọn ẹnu aala nibi alamọri wa, ki o si tun ẹsẹ wa rinlẹ nibi ipade pẹlu ọta wa, ki O si tun ran wa se lori awọn ijọ alaigbagbọ pẹlu Rẹ.
فََٔاتَىٰهُمُ ٱللَّهُ ثَوَابَ ٱلدُّنۡيَا وَحُسۡنَ ثَوَابِ ٱلۡأٓخِرَةِۗ وَٱللَّهُ يُحِبُّ ٱلۡمُحۡسِنِينَ 148
Ni Ọlọhun Ọba Allah waa fun wọn ni ẹsan aye pẹlu riran wọn se ati gbigba wọn laaye, ati wipe O tun fun wọn ni ẹsan ti o dara ni Ọjọ Ikẹyin pẹlu yiyọnu si wọn, ati idẹra ti yoo maa bẹ gbere ni inu awọn ọgba Idẹra, ati wipe Ọlọhun Ọba Allah ma nnifẹ awọn oluse daradara nibi awọn ijọsin ọn ati awọn ibasepọ wọn.
Didanniwo jẹ ilana Ọlọhun Ọba Allah ti awọn awọn olujagun, olusọ ododo, oluse suuru fi ma nda yatọ si awọn ti o yatọ si wọn,
O di dandan ki ijagun si oju ọna Ọlọhun Ọba Allah ati pipepe lọsi ọdọ Rẹ, ki o ma ropọ mọ ẹnikankan ninu abara, bi o ti wulẹ iyi rẹ ga to ati ipo rẹ.
Awọn ọjọ ori awọn eniyan ati awọn asiko wọn jẹ ohun ti o rinlẹ ni ọdọ Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) , sise oju kokoro lori aye ko le se alekun rẹ, ati wipe gbigba iwaju ati sise akin ko lee din ku.
Awọn ero awọn eniyan ati awọn adisọkan wọn yatọ si ara wọn, o nbẹ ninu wọn ẹniti o ngbero ẹsan Ọlọhun Ọba Allah, o si tun nbẹ ninu wọn ẹniti o ngbero aye, ati wipe olukuluku ni wọn yoo pada san ni ẹsan lori adisọkan rẹ ati isẹ rẹ.