قَٰتِلُوهُمۡ يُعَذِّبۡهُمُ ٱللَّهُ بِأَيۡدِيكُمۡ وَيُخۡزِهِمۡ وَيَنصُرۡكُمۡ عَلَيۡهِمۡ وَيَشۡفِ صُدُورَ قَوۡمٖ مُّؤۡمِنِينَ 14
ẹ maa baja - ẹyin olugbagbọ ododo - awọn ọlọsẹbọ toripe ti ẹ ba nba wọn ja Ọlọhun Ọba Allah yoo fi iya maa jẹ wọn lati ọwọ yin pẹlu pipa wọn lati ọwọ yin, yoo si yẹpẹrẹ wọn pẹlu ibori ati imulẹru, yoo si ran wọn se le wọn lori pẹlu bibori wọn, yoo si la ijọ mumini kuro nibi arẹ ọkan, awọn ti wọn ko jagun nitori iku ti o sẹlẹ si awọn ọta wọn ati imulẹru ati ibori ati aranse awọn olugbagbọ ododo le wọn lori.
وَيُذۡهِبۡ غَيۡظَ قُلُوبِهِمۡۗ وَيَتُوبُ ٱللَّهُ عَلَىٰ مَن يَشَآءُۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ 15
Yoo si mu ibinu kuro ni ọkan awọn ẹru Rẹ tii se olugbagbọ ododo nitori aranse ti wọn ri lori wọn, Ọlọhun Ọba Allah yoo si gba ironu piwada awọn olorikunkun nigbati wọn ba ronu piwada gẹgẹ bi o se sẹlẹ si awọn ara mekkah ti ọjọ isẹgun, Ọlọhun Ọba Allah jẹ onimimọ pẹlu ododo oluronu piwada ninu wọn, ọjọgbọn nibi sise ẹda Rẹ ati iseto Rẹ ati isofin Rẹ.
أَمۡ حَسِبۡتُمۡ أَن تُتۡرَكُواْ وَلَمَّا يَعۡلَمِ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ جَٰهَدُواْ مِنكُمۡ وَلَمۡ يَتَّخِذُواْ مِن دُونِ ٱللَّهِ وَلَا رَسُولِهِۦ وَلَا ٱلۡمُؤۡمِنِينَ وَلِيجَةٗۚ وَٱللَّهُ خَبِيرُۢ بِمَا تَعۡمَلُونَ 16
Se ẹ lero ni - ẹyin olugbagbọ ododo - pe Ọlọhun Ọba Allah yoo fi yin silẹ laidan yin wo?! Idanniwo jẹ isesi kan ninu isesi Rẹ, wọn yoo dan yin wo titi ti Ọlọhun Ọba Allah yoo fi mọ ni imọ gbangba fun awọn ẹru Rẹ ti o jẹ olusegbiyanju ninu yin pẹlu sise afọmọ fun Allah, awọn ti wọn ko mu alagbara ninu keferi gẹgẹ bi alatilẹyin dipo Allah ati ojisẹ Rẹ atiu olugbagbọ ododo, wọn ko si ri alaayo ti yoo nifẹ wọn ninu awọn eniyan wọnyi, Ọlọhun Ọba Allah jẹ olufunni niro nkan ti ẹ nse nisẹ, nkankan ko pamọ fun Un, yoo si san yin lẹsan lori isẹ yin.
مَا كَانَ لِلۡمُشۡرِكِينَ أَن يَعۡمُرُواْ مَسَٰجِدَ ٱللَّهِ شَٰهِدِينَ عَلَىٰٓ أَنفُسِهِم بِٱلۡكُفۡرِۚ أُوْلَٰٓئِكَ حَبِطَتۡ أَعۡمَٰلُهُمۡ وَفِي ٱلنَّارِ هُمۡ خَٰلِدُونَ 17
Ko tọ fun awọn ọlọsẹbọ ki wọn maa fi ara ro ile Ọlọhun fun ijọsin ati oniranran itẹle asẹ, ti wọn si tun nfin rinlẹ sise keferi wọn, ni ẹniti nse afihan rẹ, awọn wọnyi isẹ wọn ti bajẹ nitori wipe majẹmu ti o le jẹ ki o jẹ atẹwọgba ko si nibẹ, wọn yoo si wọ ina ti wọn yoo maa gbe ibẹ lọ gbere, ayaafi ti wọn ba ronu piwada kuro nibi ẹbọ siwaju iku wọn.
إِنَّمَا يَعۡمُرُ مَسَٰجِدَ ٱللَّهِ مَنۡ ءَامَنَ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ وَأَقَامَ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتَى ٱلزَّكَوٰةَ وَلَمۡ يَخۡشَ إِلَّا ٱللَّهَۖ فَعَسَىٰٓ أُوْلَٰٓئِكَ أَن يَكُونُواْ مِنَ ٱلۡمُهۡتَدِينَ 18
Dajudaju awọn ti wọn ni ẹtọ lati maa fi ara ro ile Ọlọhun, ki wọn si maa se ojuse nibẹ ni awọn ti wọn ba nigbagbọ ninu Ọlọhun Ọba Allah nikan soso, ti wọn ko si se ẹbọ pẹlu Rẹ, wọn si nigbagbọ nipa ọjọ igbende, ti wọn ngberun duro, ti wọn si nyọ saka ninu dukia wọn, wọn ko si paya ẹnikankan yatọ si Allah ti mimọ nbẹ fun, awọn wọnyi ni a nrankan ki wọn jẹ olumọna lọsi oju ọna ti o duro tọ, sugbọn awọn ọlọsẹbọ ni ẹniti yoo jinna tefetefe kuro nibẹ.
۞أَجَعَلۡتُمۡ سِقَايَةَ ٱلۡحَآجِّ وَعِمَارَةَ ٱلۡمَسۡجِدِ ٱلۡحَرَامِ كَمَنۡ ءَامَنَ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ وَجَٰهَدَ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِۚ لَا يَسۡتَوُۥنَ عِندَ ٱللَّهِۗ وَٱللَّهُ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلظَّٰلِمِينَ 19
Se ẹyin yoo - ẹyin ọlọsẹbọ - awọn ti wọn duro lati fun awọn olubẹ ile Ọlọhun wo ni omin mu ati awọn ti nfi ara ro ile Ọlọhun, sọ wọn da gẹgẹ bi olugbagbọ ninu Allah, ti wọn ko si se ẹbọ kankan pẹlu Allah, ti wọn si nigbagbọ ninu ọjọ igbende, ti wọn si tun nse igbiyanju pẹlu ẹmin rẹ ati dukia rẹ ki gbolohun Ọlọhun Ọba Allah le jẹ ohun ti o ga, ki gbollohun awọn keferi le jẹ ohun ti o rẹlẹ, se ẹyin yoo sọ wọn di dọgbandọgba ni ninu ọla ni ọdọ Ọlọhun Ọba Allah?! Wo ko le se dọgbandọgban lailai lọdọ Ọlọhun, Ọlọhun Ọba ko nii fi alabosi se kongẹ ẹbọ, koda wọn kii baa maa se isẹẹre gẹgẹ bi fifun olubẹ ile Ọlọhun Ọba wo ni omin mu.
ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَهَاجَرُواْ وَجَٰهَدُواْ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ بِأَمۡوَٰلِهِمۡ وَأَنفُسِهِمۡ أَعۡظَمُ دَرَجَةً عِندَ ٱللَّهِۚ وَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡفَآئِزُونَ 20
Awọn ti wọn nse akojọpọ laarin igbagbọ ninu Ọlọhun Ọba Allah ati sise irin ajo kuro ni ilu keferi lọ si ilu Islam, ati sise igbiyanju si oju ọna Allah pẹlu awọn dukia ati awọn ẹmin ni ipo ti o tobi ni ọdọ Ọlọhun ju awọn miran ti wọn yatọ si wọn lọ, awọn ni a royin pẹlu iroyin naa, awọn si olujere pẹlu alujannah.
Itọka si ikẹ Ọlọhun Ọba fun awọn ẹru Rẹ ti o jẹ olugbagbọ ododo ati ikọbi ara si isesi wọn wa ninu awọn aayah naa titi ti O fi sọ akojọpọ awọn erongba ofin di iwosan inu ọkan, ati ohun ti yoo mu ibanujẹ yin lọ.
Ọlọhun Ọba Allah se igbiyanju ni ofin ki erongba ti o tobi yii le ba maa sẹlẹ, ohun naa ni lati se adayanri sootọ sootọ ti kii daamu ayaafi fun ẹsin Ọlọhun Ọba yatọ si awọn opurọ ti wọn nlero igbagbọ.
Awọn olufararo ile Ọlọhun tootọ ni awọn ti a royin pẹlu igbagbọ ododo, ti wọn si tun nse isẹẹre eyiti olori rẹẹ se irun kiki ati saka yiyọ, ati ipaya Ọlọhun Ọba Allah eyiti o jẹ ipilẹ gbogbo daadaa.
Igbiyanju ati igbagbọ ninu Ọlọhun Ọba Allah ni ọla ju ẹniti o nfun olubẹ ile Ọlọhun Ọba wo ni omin mu lọ koda ju awọn ti wọn nfi ara ro ile Ọlọhun Abeewọ lọ ni agbega ti o pọ; nitori wipe dajudaju igbagbọ jẹ ipilẹ ẹsin sugbọn igbiyanju si oju ọna Ọlọhun Ọba Allah jẹ rọrọ ijanu ẹsin.