وَأَنَّا مِنَّا ٱلۡمُسۡلِمُونَ وَمِنَّا ٱلۡقَٰسِطُونَۖ فَمَنۡ أَسۡلَمَ فَأُوْلَٰٓئِكَ تَحَرَّوۡاْ رَشَدٗا 14
Atipe dajudaju awa olugbafa ti o tẹriba fun Allah nibi titẹle ti R ẹ wa ninu wa, alabosi kuro nibi oju ọna ti o tọ ati iduro sinsin naa wa ninu wa, ẹniti o ba tẹriba fun Allah pẹlu titẹle ati isẹ rere, awọn wọnyi ni wọn gbero ọnaamọ ati deedee.
وَأَمَّا ٱلۡقَٰسِطُونَ فَكَانُواْ لِجَهَنَّمَ حَطَبٗا 15
Sugbọn awọn ti wọn jẹ alabosi kuro nibi oju ọna ti a gbero ati iduro sinsin, awọn ni wọn yoo jẹ ikiko ina jahannamọ pẹlu awọn apejuwe wọn ninu eniyan.
وَأَلَّوِ ٱسۡتَقَٰمُواْ عَلَى ٱلطَّرِيقَةِ لَأَسۡقَيۡنَٰهُم مَّآءً غَدَقٗا 16
Gẹgẹ bi wọn se fi ransẹ si wipe ikọ kan ninu alujannu tẹti gbọ, bẹẹni wọn tun ransẹ si wipe ti awọn alujannu ati eniyan ba duro tọ ni oju ọna ẹsin ọla, ti wọn si nse ohun ti o wa ninu rẹ, paapaa julọ Allah yoo fun wọn ni omin ti o pọ mu, yoo si mu idẹkun ti o jẹ oniranran gun siwaju.
لِّنَفۡتِنَهُمۡ فِيهِۚ وَمَن يُعۡرِضۡ عَن ذِكۡرِ رَبِّهِۦ يَسۡلُكۡهُ عَذَابٗا صَعَدٗا 17
Paapaa A o dan ọ wo nibẹ, boya wọn yoo dupẹ fun idẹkun Allah tabi wọn yoo se aimoore si i? ẹniti o ba gunri kuro nibi Alukuraani ati awọn isiti ti o wa nibẹ, Ọlọhun rẹ yoo fi wọ sinu iya ti o le, ti ko nii nikapa lati mu mọra.
وَأَنَّ ٱلۡمَسَٰجِدَ لِلَّهِ فَلَا تَدۡعُواْ مَعَ ٱللَّهِ أَحَدٗا 18
Atipe dajudaju awọn mọsalaasi jẹ tiRẹ ti mimọ nbẹ fun kii se fun ẹlomiran, ẹ ko gbọdọ pe ẹnikankan pẹlu Rẹ nibẹ, ki ẹ maa ba da gẹgẹ bi yahuudi ati nasọọra nibi ile ijọsin wọn ati owo wọn.
وَأَنَّهُۥ لَمَّا قَامَ عَبۡدُ ٱللَّهِ يَدۡعُوهُ كَادُواْ يَكُونُونَ عَلَيۡهِ لِبَدٗا 19
Atipe nigbati ẹru Allah tii se Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun naro ti o nsin Ọlọhun rẹ, ni aaye ti a npe ni ‘batinu nakila’ awọn alujannu fẹẹ le maa gun ara wọn le lori nitori lile koko itẹsẹbọsẹ nigbati wọn gbọ kike Alukuraani rẹ.
قُلۡ إِنَّمَآ أَدۡعُواْ رَبِّي وَلَآ أُشۡرِكُ بِهِۦٓ أَحَدٗا 20
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn ẹlẹbọ wọnyi: dajudaju ẹmi npe Ọlọhun mi nikan, nko si nii se ẹbọ pẹlu Rẹ nibi ijọsin fun ẹnikẹni ti ki baa jẹ.
قُلۡ إِنِّي لَآ أَمۡلِكُ لَكُمۡ ضَرّٗا وَلَا رَشَدٗا 21
Sọ fun wọn: dajudaju emi ko nikapa mimu inira ti Allah ba kadara mọ yin kuro, nko si ni ikapa lati mu anfaani ti Allah ba kọ fun yin kuro nibẹ wa.
قُلۡ إِنِّي لَن يُجِيرَنِي مِنَ ٱللَّهِ أَحَدٞ وَلَنۡ أَجِدَ مِن دُونِهِۦ مُلۡتَحَدًا 22
Sọ fun wọn: ẹnikankan ko le la mi kuro lọdọ Allah ti mo ba sẹ Ẹ, nko si le ri ibusalọ si kankan yatọ si ọdọ Rẹ ni ibusasi.
إِلَّا بَلَٰغٗا مِّنَ ٱللَّهِ وَرِسَٰلَٰتِهِۦۚ وَمَن يَعۡصِ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ فَإِنَّ لَهُۥ نَارَ جَهَنَّمَ خَٰلِدِينَ فِيهَآ أَبَدًا 23
Sugbọn eyiti mo nikapa ni ki nfi ohun ti Allah pa mi lasẹ de etigbọ yin ati isẹ riran Rẹ eyiti O gbe mi dide si yin, ẹniti o ba sẹ Allah ati ojisẹ Rẹ, dajudaju ibusẹri si rẹ jẹ ina jahannamọ ti yoo gbebẹ gbere lailai, ko si jade nibẹ kankan.
حَتَّىٰٓ إِذَا رَأَوۡاْ مَا يُوعَدُونَ فَسَيَعۡلَمُونَ مَنۡ أَضۡعَفُ نَاصِرٗا وَأَقَلُّ عَدَدٗا 24
Awọn keferi ko nii yẹ lori keferi wọn titi wọn yoo fi fi oju kan ohun ti wọn se ni adehun fun wọn ni aye ninu iya ni ọjọ igbende, nigba naa wọn yoo wa mọ ẹniti alaranse rẹ lẹ ju, wọn yoo si tun mọ ẹniti oluranlọwọ rẹ kere ju.
قُلۡ إِنۡ أَدۡرِيٓ أَقَرِيبٞ مَّا تُوعَدُونَ أَمۡ يَجۡعَلُ لَهُۥ رَبِّيٓ أَمَدًا 25
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn ẹlẹbọ olutako ajinde yii: emi ko mọ boya ohun ti wọn se ni adehun ninu iya sun mọ tabi o ni asiko ti ẹnikankan ko mọ ayaafi Allah.
عَٰلِمُ ٱلۡغَيۡبِ فَلَا يُظۡهِرُ عَلَىٰ غَيۡبِهِۦٓ أَحَدًا 26
Oun ti mimọ nbẹ fun ni onimimọ kọkọ patapata, nkankan ko pamọ fun Un nibẹ, ẹnikankan ko le riran ri kọkọ Rẹ bikosepe yoo sẹku ni isẹsa pẹlu imọ Rẹ.
إِلَّا مَنِ ٱرۡتَضَىٰ مِن رَّسُولٖ فَإِنَّهُۥ يَسۡلُكُ مِنۢ بَيۡنِ يَدَيۡهِ وَمِنۡ خَلۡفِهِۦ رَصَدٗا 27
Ayaafi ẹniti Oun ti mimọ nbẹ fun ba yọnu si ninu ojisẹ, dajudaju Oun yoo mu u ri ohun ti O ba fẹ, ti yoo si ran oludaabobo ninu awọn Malaika si ojisẹ naa, wọn yoo maa sọ ọ titi ẹniti o yatọ si ojisẹ ko fi ni ri eleyi.
لِّيَعۡلَمَ أَن قَدۡ أَبۡلَغُواْ رِسَٰلَٰتِ رَبِّهِمۡ وَأَحَاطَ بِمَا لَدَيۡهِمۡ وَأَحۡصَىٰ كُلَّ شَيۡءٍ عَدَدَۢا 28
Ni irankan ki ojisẹ naa le mọ wipe dajudaju awọn ojisẹ ti o siwaju rẹ ti mu awọn isẹ Ọlọhun wọn de ogongo eyiti O pa wọn lasẹ mimu de ogongo rẹ nitori irọkirika ikọbi ara si Allah ti o kari rẹ, Allah si tun rọkirika ohun nti o wa ni ọdọ awọn Malaika ati awọn ojisẹ ni imọ, nkankan ko pamọ fun Un ninu eleyi, O si mọ nkan gbogbo nkan, nkankan ko pamọ fun mimọ Rẹ.
Sise abosi jẹ okunfa wiwọ ina.
Pataki iduro sinsin nibi titẹlọwọ ohun ti a ngbero ni daadaa.
Wọn da aabo bo imisi kuro nibi ibasere awọn eesu.