وَمِنَ ٱلَّذِينَ قَالُوٓاْ إِنَّا نَصَٰرَىٰٓ أَخَذۡنَا مِيثَٰقَهُمۡ فَنَسُواْ حَظّٗا مِّمَّا ذُكِّرُواْ بِهِۦ فَأَغۡرَيۡنَا بَيۡنَهُمُ ٱلۡعَدَاوَةَ وَٱلۡبَغۡضَآءَ إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلۡقِيَٰمَةِۚ وَسَوۡفَ يُنَبِّئُهُمُ ٱللَّهُ بِمَا كَانُواْ يَصۡنَعُونَ 14
Gẹgẹbi a se gba adehun ti o yi ni ọdọ awọn yahuudi, gẹgẹ bẹẹ naa ni a se gba adehun ni ọdọ awọn ti wọn nfọ ẹmin ara wọn mọ wipe olutẹle Anọbi Isa ni awọn jẹ, wọn waa gbe isẹ ju silẹ pẹlu apakan nkan ti wọn nsọ, gẹgẹ bi awọn ti wọn ti siwaju wọn ninu awọn yahuudi se, a wa ju ija ati ikorira ti o le koko si aarin wọn titi di ọjọ igbende, bayi ni wọn wa di olubara wọn ja, olujinn si ara wọn, ti apakan wọn npe apakan wọn ni keferi, Ọlọhun Ọba Allah yoo pada fun wọn niro nkan ti wọnn nse ni isẹ, yoo si san wọn lẹsan le lori.
Nigbati Ọlọhun Ọba Allah sọ nipa awọn ti A fun ni tita ati adehun ti o gba ni ọwọ wọn, ati jija adehun naa, O wa pasẹ ki wọn ni igbagbọ si Muhammad ẹniti ikọ ati ọla nbẹ fun, o si sọ wipe:
يَٰٓأَهۡلَ ٱلۡكِتَٰبِ قَدۡ جَآءَكُمۡ رَسُولُنَا يُبَيِّنُ لَكُمۡ كَثِيرٗا مِّمَّا كُنتُمۡ تُخۡفُونَ مِنَ ٱلۡكِتَٰبِ وَيَعۡفُواْ عَن كَثِيرٖۚ قَدۡ جَآءَكُم مِّنَ ٱللَّهِ نُورٞ وَكِتَٰبٞ مُّبِينٞ 15
Ẹyin onitira ninu yahuudi ati awọn oni taoreeta, ati nassara ti a fun ni injiila, paapaa ojisẹ wa Muhammad ti wa ba yin, ti o salaye fun yin ọpọ nkan naa ti ẹ fi pamọ ninu iwe naa ti a sọkalẹ fun yin, o si nse amojukuro nibi ọpọlọpọ rẹ ninu ohun ti ko si anfaani nibẹ bikoseida yẹyẹ yin silẹ, paapaa Alukuraani ti waa ba yin, o si jẹ iwe kan lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, o tun jẹ imọlẹ ti a fi nmọ ọna, bẹẹni o tun jẹ iwe ti o fi oju han fun gbogbo nkan ti ọmọ ẹda eniyan nbukaata si, ninu ọrọ alamọri ọrọ aye ati ọrun.
يَهۡدِي بِهِ ٱللَّهُ مَنِ ٱتَّبَعَ رِضۡوَٰنَهُۥ سُبُلَ ٱلسَّلَٰمِ وَيُخۡرِجُهُم مِّنَ ٱلظُّلُمَٰتِ إِلَى ٱلنُّورِ بِإِذۡنِهِۦ وَيَهۡدِيهِمۡ إِلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ 16
Ọlọhun Ọba Allah yoo fi mọ iwe naa ẹniti o ba tẹle iyọnu Rẹ pẹlu igbagbọ ati isẹẹre lọsi oju ọna alaafia kuro nibi iya Ọl; ọhun Ọba Allah, ohun naa sini ọna ti yoo muni de Alujannah, ti yoo fani yọ kuro ninu okunkun keferi ati ẹsẹ lọsi imọlẹ igbagbọ ati itẹle asẹ pẹlu iyọnda Rẹ, yoo si fi wọn se kongẹ oju ọna ti o duro tọ, tii se oju ọna Islam.
لَّقَدۡ كَفَرَ ٱلَّذِينَ قَالُوٓاْ إِنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلۡمَسِيحُ ٱبۡنُ مَرۡيَمَۚ قُلۡ فَمَن يَمۡلِكُ مِنَ ٱللَّهِ شَيًۡٔا إِنۡ أَرَادَ أَن يُهۡلِكَ ٱلۡمَسِيحَ ٱبۡنَ مَرۡيَمَ وَأُمَّهُۥ وَمَن فِي ٱلۡأَرۡضِ جَمِيعٗاۗ وَلِلَّهِ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا بَيۡنَهُمَاۚ يَخۡلُقُ مَا يَشَآءُۚ وَٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ 17
Paapaa awọn nasaara ti wọn nsọ wipe Ọlọhun Ọba Allah ni isa ọmọ maryam ẹnimimọ ti di keferi, sọ fun wọn - irẹ ojisẹ - : Taani ẹniti o lagbara lati kọ fun Ọlọhun Ọba Allah nibi iparun ẹni mimọ Isa ọmọ Maryam, ti o si tun pa iya rẹ run, ti o si tun pa gbogbo ẹniti o nbẹ lori ilẹ nigbati o ba gbero iparun? ! Ti ẹnikankan ko ba lagbara lati kọ fun nibi eleyi, ntọka si wipe ko si ọba kan ayaafi Allah, ati wipe dajudaju gbogbo wọn: bẹrẹ lori Isa ọmọ Maryam ati iya rẹ ati gbogbo ẹda patapata, wọn jẹ ẹda Ọlọhun Ọba Allah, Ọlọhun Ọba Allah ni O ni ikapa gbogbo sanmọ ati ilẹ, O si ni ikapa ohun ti nbẹ laarin mejeeji, O nda oun ti O wu U, O si nda ẹda ninu oun ti o wu U: Isa ki ọla maa ba, ẹru Rẹ ni o jẹ ati ojisẹ Rẹ, Ọlọhun Ọba Allah si lagbara lori gbogbo nkan.
Gbigbe sise awọn adehun Ọlọhun Ọba Allah ti o yi ju silẹ, o le sọ di ọranyan sisẹlẹ ọta ati kikari ikorira ati sisa fun ara ẹni ati biba ara ẹni ja laarin awọn alatako si asẹ Ọlọhun Ọba Allah.
Ifesi pada fun awọn nasaara, ti wọn nsọ wipe Ọlọhun Ọba Allah ti di abara si inu ẹni mimọ ki ọla maa ba, ati sise alaye keferi wọn ati ọrọ anu wọn.
Ninu ẹri aidara kika Isa kun ẹniti a nsin, oun ni wipe dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ti O ba gbero lati pa ẹni mimọ naa ati iya rẹ ati gbogbo awọn ti nbẹ lori ile run, ẹnikankan ko lagbara lati di lọwọ, eleyi fi rinlẹ jijẹ aaso ninu Ọlọhun Ọba Allah nibi ipasẹ ati wipe ko si ọba kan ayaafi Ohun nikan.
Ninu ẹri aidara kika ẹni mimọ naa kun ẹniti a njọsin fun, ohun ni wipe Ọlọhun Ọba Allah ran wa leti wipe Oun (يَخۡلُقُ مَا يَشَآءُۚ) (ma nda ohun ti o wu U Al-Maaidah: 17) , O da lati ara obi mejeeji, bẹẹ ni o da lati ara iya laisi baba gẹgẹ bi Isa ẹniti ọla nbẹ fun, o si da lati ara nkan ọbọrọgidi gẹgẹ bi ejo Musa ẹniti ọla nbẹ fun, o si da lati ara ọkunrin ti ko si abo gẹgẹ bi Hawau lati ara Aadamọ ẹniti ọla nbẹ fun.