قُل لِّلَّذِينَ ءَامَنُواْ يَغۡفِرُواْ لِلَّذِينَ لَا يَرۡجُونَ أَيَّامَ ٱللَّهِ لِيَجۡزِيَ قَوۡمَۢا بِمَا كَانُواْ يَكۡسِبُونَ 14
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn ti o nigbagbọ ninu Allah ti wọn si pe ojisẹ Rẹ lododo: ẹ se amojukuro fun ẹniti o se aidara si yin ninu awọn keferi, ti wọn ko bikita pẹlu idẹkun Allah ati iya Rẹ, dajudaju Allah yoo san olukaluku inu awọn olugbagbọ ododo onisuuru ati awọn keferi olukọja ẹnu aala lẹsan ohun ti wọn ba ko jọ ni ile aye.
مَنۡ عَمِلَ صَٰلِحٗا فَلِنَفۡسِهِۦۖ وَمَنۡ أَسَآءَ فَعَلَيۡهَاۖ ثُمَّ إِلَىٰ رَبِّكُمۡ تُرۡجَعُونَ 15
Ẹniti o ba sisẹ rere ibuyọrisi isẹ rere rẹ jẹ tirẹ, Allah si jẹ ẹniti o rọrọ kuro nibi isẹ rẹ, ẹniti o ba se aidara, inbuyọrisi isẹ aidara rẹ yoo jẹ ijiya fun un, Allah jẹ ẹniti aburu rẹ ko le ko inira ba, lẹyin naa ọdọ Wa nikan ni ẹ o sẹri si ni ọrun, ki a le san olukaluku lẹsan ohun ti o lẹtọ si.
وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ ٱلۡكِتَٰبَ وَٱلۡحُكۡمَ وَٱلنُّبُوَّةَ وَرَزَقۡنَٰهُم مِّنَ ٱلطَّيِّبَٰتِ وَفَضَّلۡنَٰهُمۡ عَلَى ٱلۡعَٰلَمِينَ 16
Paapaa a ti fun awọn ọmọ isirẹli ti taoreeta ati atunse laarin awọn eniyan pẹlu idajọ rẹ, a si se ọpọ anọbi wọn ninu arọmọdọmọ Ibrahim ẹniti ọla nbẹ fun, a si ran wọn se nibi oniranran ohun ti o mọ, a si gbe ọla fun wọn ni agbanla aye asiko wọn.
وَءَاتَيۡنَٰهُم بَيِّنَٰتٖ مِّنَ ٱلۡأَمۡرِۖ فَمَا ٱخۡتَلَفُوٓاْ إِلَّا مِنۢ بَعۡدِ مَا جَآءَهُمُ ٱلۡعِلۡمُ بَغۡيَۢا بَيۡنَهُمۡۚ إِنَّ رَبَّكَ يَقۡضِي بَيۡنَهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ فِيمَا كَانُواْ فِيهِ يَخۡتَلِفُونَ 17
A si fun wọn ni awọn ẹri ti nsalaye ododo kuro nibi ibajẹ, wọn ko yapa ayaafi lẹyin igbati awọn awijare dide le wọn lori pipe gbigbe anọbi wa Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun dide, bẹẹni nkankan ko mu wọn lọ si ibi iyapa yii ju tẹnbẹlẹkun apakan si apakan lọ ni sise oju kokoro si idari ati iyi, dajudaju Ọlọhun rẹ - irẹ ojisẹ - yoo se atunse laarin wọn ni ọjọ igbende nibi ohun ti wọn nse iyapa nibẹ ni ile aye, ẹniti o nsọ ododo yoo wa han, bakannaa ni onibajẹ.
ثُمَّ جَعَلۡنَٰكَ عَلَىٰ شَرِيعَةٖ مِّنَ ٱلۡأَمۡرِ فَٱتَّبِعۡهَا وَلَا تَتَّبِعۡ أَهۡوَآءَ ٱلَّذِينَ لَا يَعۡلَمُونَ 18
Lẹyin naa a se ọ ni ẹniti o wa ni oju ọna kan ati ikọse kan ati ilana kan ninu asẹ wa eyiti a pa awọn ti o siwaju rẹ ninu awọn ojisẹ wa, ki o maa pepe lọsi ibi igbagbọ ati isẹ rere, ki o ya tẹle ofin yii, mase tẹle ifẹ inu awọn ti ko mọ ododo; nitoripe ifẹẹnu wọn jẹ isini lọna kuro nibi ododo.
إِنَّهُمۡ لَن يُغۡنُواْ عَنكَ مِنَ ٱللَّهِ شَيۡٔٗاۚ وَإِنَّ ٱلظَّٰلِمِينَ بَعۡضُهُمۡ أَوۡلِيَآءُ بَعۡضٖۖ وَٱللَّهُ وَلِيُّ ٱلۡمُتَّقِينَ 19
Dajudaju awọn ti ko mọ ododo ko le mu iya Alah kankan kuro fun ọ ti o ba tẹle ifẹ inu wọn, atipe dajudaju awọn alabosi ni gbogbo ọna ati ojupọnna jẹ ẹniti apakan wọn yoo maa se aranse fun apakan, yoo si maa ran wọn lọwọ lori awọn olugbagbọ ododo, Allah si jẹ alaranse fun awọn ti o nbẹru Rẹ lati ibi mimu awọn asẹ Rẹ ati jijinna si awọn ohun ti O kọ.
هَٰذَا بَصَٰٓئِرُ لِلنَّاسِ وَهُدٗى وَرَحۡمَةٞ لِّقَوۡمٖ يُوقِنُونَ 20
Alukuraani ti a sọkalẹ fun ojisẹ wa jẹ awọn iriran eyiti awọn eniyan yoo maa fi wo ododo kuro nibi ibajẹ ati imọna lọsi ibi ododo, o si jẹ ikẹ fun awọn ijọ ti o mọ amọdaju; nitoripe awọn ni yoo mọna pẹlu rẹ lọsi oju ọna ti o duro tọ, ki Ọlọhun o le yọnu si wọn, ki o si fi wọn wọ ọgba idẹra naa, ki o si mu wọn takete kuro nibi ina.
أَمۡ حَسِبَ ٱلَّذِينَ ٱجۡتَرَحُواْ ٱلسَّئَِّاتِ أَن نَّجۡعَلَهُمۡ كَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ سَوَآءٗ مَّحۡيَاهُمۡ وَمَمَاتُهُمۡۚ سَآءَ مَا يَحۡكُمُونَ 21
Se awọn ti o fi orikerike wọn se keferi ati awọn ese nlero wipe a o se ẹsan wọn gẹgẹ bi awọn ti o nigbagbọ ninu Allah, ti wọn si nse awọn isẹẹre ti wọn yoo fi dọgba ni ile aye ati lọrun bi?! Idajọ wọn yii buru.
وَخَلَقَ ٱللَّهُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ بِٱلۡحَقِّ وَلِتُجۡزَىٰ كُلُّ نَفۡسِۢ بِمَا كَسَبَتۡ وَهُمۡ لَا يُظۡلَمُونَ 22
Allah da gbogbo sanmọ ati ilẹ nitori ọgbọn ti o de ogongo, ko si da wọn ni ere, a ki o le san gbogbo ẹmin kọọkan ni ohun ti o se ni daadaa tabi aburu, Allah ko nii se abosi wọn pẹlu dindin daadaa wọn ku tabi sise alekun awọn asise wọn.
Amojukuro ati ifojurena fun alabosi nigbati ko ba se afihan ibajẹ lorilẹ, ti ko si kọja ẹnu aala Allah; isẹ da ti lọla, ti Allah pasẹ iwa ọla fun awọn olugbagbọ ododo ti igbẹyin daadaa ba bori erongba wọn.
Jijẹ dandan titẹle ofin ati jijinna si titẹle awọn ifẹ inu abara.
Gẹgẹbi awọn olugbagbọ ododo ati awọn keferi ko se papọ nibi iroyin, wọn ko le dọgba nibi ẹsan.
Allah da gbogbo sanmọ ni ibamun si ọgbọn ti o de ogongo, ti awọn yinin yinin olukọja ẹnu aala si fọnu nipa rẹ.