وَقَالُواْ هَٰذِهِۦٓ أَنۡعَٰمٞ وَحَرۡثٌ حِجۡرٞ لَّا يَطۡعَمُهَآ إِلَّا مَن نَّشَآءُ بِزَعۡمِهِمۡ وَأَنۡعَٰمٌ حُرِّمَتۡ ظُهُورُهَا وَأَنۡعَٰمٞ لَّا يَذۡكُرُونَ ٱسۡمَ ٱللَّهِ عَلَيۡهَا ٱفۡتِرَآءً عَلَيۡهِۚ سَيَجۡزِيهِم بِمَا كَانُواْ يَفۡتَرُونَ 138
Awọn ọlọsẹbọ sọ wipe: awọn ẹranko ati ohun ọgbin wọnin jẹ eewọ, ẹnikan ko gbọdọ jẹ nibẹ ayaafi ẹniti wọn ba fẹ, ninu awọn ti wọn nse isẹ sin oosa, ati ẹniti o yatọ si wọn, bẹẹ ni awọn ẹranko yii ẹyin rẹ jẹ eewọ, ẹnikankan ko gbọdọ gun bẹẹ ni wọn ko gbọdọ gbe ẹru le lori, awọn ẹranko naa ni, bahiirọ, saahibah, ati haami, awọn ẹranko wọn kii darukọ Ọlọhun Ọba Allah le lori nigbati wọn ba fẹ du wọn, bikose wipe wọn ma ndu pẹlu orukọ oosa wọn ni; gbogbo eleyi ti wọn nse jẹ adapa irọ mọ Ọlọhun Ọba Allah wipe lati ọdọ Rẹ ni, Ọlọhun Ọba Allah yoo san wọn lẹsan iya nitori irọ ti wọn pa mọ Ọ.
وَقَالُواْ مَا فِي بُطُونِ هَٰذِهِ ٱلۡأَنۡعَٰمِ خَالِصَةٞ لِّذُكُورِنَا وَمُحَرَّمٌ عَلَىٰٓ أَزۡوَٰجِنَاۖ وَإِن يَكُن مَّيۡتَةٗ فَهُمۡ فِيهِ شُرَكَآءُۚ سَيَجۡزِيهِمۡ وَصۡفَهُمۡۚ إِنَّهُۥ حَكِيمٌ عَلِيمٞ 139
Wọn sọ wipe: ohun ti o wa ninu ikun awọn ẹranko yii: saahibah , bahiirọ, nigbati o ba bimọ ni aaye, o jẹ ẹtọ fun awọn ọmọkunrin wa, o si jẹ eewọ fun awọn ọmọbinrin wa, sugbọn ti wọn ba bi ohun ti o wa ninu ikun wọn ni oku, ati akọ ati abo wọn ni yoo lẹtọ sii, Ọlọhun Ọba Allah yoo san wọn lẹsan lori ọrọ wọn yii pẹlu ohun ti wọn ba ni ẹtọ si, O jẹ ọjọgbọn nibi sise ofin Rẹ ati didari eti alamọri awọn ẹda Rẹ, O si tun jẹ Onimimọ nipa wọn.
قَدۡ خَسِرَ ٱلَّذِينَ قَتَلُوٓاْ أَوۡلَٰدَهُمۡ سَفَهَۢا بِغَيۡرِ عِلۡمٖ وَحَرَّمُواْ مَا رَزَقَهُمُ ٱللَّهُ ٱفۡتِرَآءً عَلَى ٱللَّهِۚ قَدۡ ضَلُّواْ وَمَا كَانُواْ مُهۡتَدِينَ 140
Awọn ti wọn pa ọmọ wọn nitori fifuyẹ laakaye wọn ati aimọkan wọn ti parun, wọn si se ohun ti Ọlọhun Ọba Allah se ni ẹtọ fun wọn ni eewọ, ni ẹniti o nse afiti rẹ si ọdọ Ọlọhun Ọba Allah niti irọ, wọn ti jinna si oju ọna ti o duro tọ, wọn kii se olumọna.
۞وَهُوَ ٱلَّذِيٓ أَنشَأَ جَنَّٰتٖ مَّعۡرُوشَٰتٖ وَغَيۡرَ مَعۡرُوشَٰتٖ وَٱلنَّخۡلَ وَٱلزَّرۡعَ مُخۡتَلِفًا أُكُلُهُۥ وَٱلزَّيۡتُونَ وَٱلرُّمَّانَ مُتَشَٰبِهٗا وَغَيۡرَ مُتَشَٰبِهٖۚ كُلُواْ مِن ثَمَرِهِۦٓ إِذَآ أَثۡمَرَ وَءَاتُواْ حَقَّهُۥ يَوۡمَ حَصَادِهِۦۖ وَلَا تُسۡرِفُوٓاْۚ إِنَّهُۥ لَا يُحِبُّ ٱلۡمُسۡرِفِينَ 141
Ọlọhun Ọba ti mimọ nbẹ fun ni O da awọn ọgba ti o tẹ pẹrẹsẹ ni ori ilẹ laisi ohun ti o fun ni omin mu ati eyiti awọn nkan nbẹ ni ori rẹ lati ara omin, Oun ni o da ọpẹ, O da irugbin ni orisirisi eso, ni irisi ati itọwo, Oun ni o da eso ọpọtọ ati mangoro ti ewe wọn yatọ si ara wọn, ti itọwo wọn naa ko si jọra, ẹ maa jẹ -ẹyin eniyan- ninu eso rẹ nigbati o ba yọ ọmọ, ẹ si maa yọ saka rẹ ni ọjọ ti ẹ ba kore rẹ, ẹ ma kọja ẹnu aala ofin Ọlọhun Ọba Allah nibi jijẹ ati nina, Ọlọhun Ọba Allah ko nifẹ si awọn olukọja ẹnu aala Rẹ nibi nkan mejeeji ati ohun ti o yatọ sii, bikose wioe O kirira rẹ, dajudaju ẹniti O da gbogbo eleyi ni o se lẹtọ fun awọn ẹru Rẹ, kii waa se awọn ẹlẹbọ ni yoo se ni eewọ.
وَمِنَ ٱلۡأَنۡعَٰمِ حَمُولَةٗ وَفَرۡشٗاۚ كُلُواْ مِمَّا رَزَقَكُمُ ٱللَّهُ وَلَا تَتَّبِعُواْ خُطُوَٰتِ ٱلشَّيۡطَٰنِۚ إِنَّهُۥ لَكُمۡ عَدُوّٞ مُّبِينٞ 142
Oun ni O da eyiti o wulo lati fun ẹru gbigbe ninu awọn ẹranko gẹgẹ bi rakunmi nla ati eyiti ko wulo fun un gẹgẹ bi eyiti o kere ninu rẹ ati agutan, ẹ maa jẹ -ẹyin eniyan- ninu eyiti Ọlọhun Ọba Allah se ni ẹtọ fun yin, ẹ ma tẹle oju ọna eesu nibi sise lẹts ohun ti Ọlọhun Ọba Allah se ni eewọ, ati sise leewọ nkan ti o se ni ẹtọ gẹgẹ bi awọn ọlọsẹbọ se ma nse, dajudaju esu jẹ -ẹyin eniyan- ọta ti o fi oju han fun yin, nitori wipe o nfẹ ki ẹ sẹ Ọlọhun Ọba Allah latara eleyi.
Eebu Ọlọhun Ọba Allah si awọn keferi pẹlu iroyin meje yii: ofo, omugọ, aisi imọ, ati sise ohun ti Ọlọhun Ọba Allah se ni arisiki fun wọn di eewọ, dida adapa irọ mọ Ọlọhun Ọba, isina, aimọna, awọn nkan meje yii ati ọkọọkan ninu wọn ni o jẹ okunfa ti eebu fi tọ si wọn.
Ifẹ inu jẹ okunfa ti o ma nmuni sọ ohun ti Ọlọhun Ọba Allah se lẹtọ di eewọ, tabi sọ ohun ti Ọlọhun Ọba Allah se leewọ di ẹtọ.
Jijẹdandan yiyọ saka nibi irugbin ati awọn eso nigbati a ba kore rẹ, ti o si tọ ki a jẹ nibẹ siwaju ki a to yọ saka rẹ, wọn ko si nii ka mọ saka.
Gbigbadun pẹlu awọn nkan ti o da laini se ina apa ati ikọja ẹnu aala nibi nkan jijẹ ati nina.