إِنۡ هَٰذَآ إِلَّا خُلُقُ ٱلۡأَوَّلِينَ 137
Eleyi ko jẹ nkankan ju ẹsin awọn ẹni akọkọ lọ ati awọn isesi wọn ati awọn iwa wọn.
وَمَا نَحۡنُ بِمُعَذَّبِينَ 138
Awa kii se ẹniti yoo jiya.
فَكَذَّبُوهُ فَأَهۡلَكۡنَٰهُمۡۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗۖ وَمَا كَانَ أَكۡثَرُهُم مُّؤۡمِنِينَ 139
Wọn tẹsiwaju lori pipe anọbi wọn Huudu nirọ ẹniti ọla nbẹ fun, a si fi atẹgun agan pa wọn nitori irọ wọn, dajudaju ariwoye nbẹ fun awọn oloye nibi iparun yii, bẹẹni ọpọ wọn ko jẹ olugbagbọ ododo.
وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلرَّحِيمُ 140
Dajudaju Ọlọhun Ọba rẹ - irẹ ojisẹ - o jẹ alagbara eyiti o ngba ẹsan lara awọn ọta Rẹ; Onikẹ fun ẹniti o ba ronu piwada ninu awọn ẹru Rẹ.
كَذَّبَتۡ ثَمُودُ ٱلۡمُرۡسَلِينَ 141
Ijọ samudawa pe awọn ojisẹ nirọ nitori pipe anọbi wọn ẹniti ọla nbẹ fun nirọ.
إِذۡ قَالَ لَهُمۡ أَخُوهُمۡ صَٰلِحٌ أَلَا تَتَّقُونَ 142
Nigbati ọmọ iya wọn ninu mọlẹbi sọ fun wọn tii se sọọlihu: se ẹ ko ni paya Allah pẹlu gbigbe sinsin ẹlomiran ju silẹ niti ibẹru Rẹ?!
إِنِّي لَكُمۡ رَسُولٌ أَمِينٞ 143
Dajudaju ojisẹ ni mo jẹ si yin, Allah ran mi si yin, ẹni ifọkantan nibi ohun ti mo mu de etigbọ yin, nko ni se alekun le lori, bẹẹni nko ni din wọn ku.
فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَأَطِيعُونِ 144
Ki ẹ ya paya Allah pẹlu titẹle awọn asẹ Rẹ ati jijinna si awọn nkan ti o kọ, ki ẹ si tẹle mi nibi ohun ti mo ba pa yin lasẹ rẹ, tabi mo kọ fun yin kuro nibẹ.
وَمَآ أَسَۡٔلُكُمۡ عَلَيۡهِ مِنۡ أَجۡرٍۖ إِنۡ أَجۡرِيَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ 145
Nko wa ẹsan ni ọdọ yin nibi ohun ti mo fi nto yin leti lati ọdọ Ọlọhun mi, ẹsan mi ko jẹ lati ibi kankan ayaafi lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah olutọju gbogbo ẹda, ko si ni ọdọ ẹlomiran.
أَتُتۡرَكُونَ فِي مَا هَٰهُنَآ ءَامِنِينَ 146
Se ẹ nrankan ki wọn fi yin silẹ lori daadaa ati idẹkun ti ẹ wa nibẹ ni ẹni ifọkanbalẹ ti ko nii bẹru?!
فِي جَنَّٰتٖ وَعُيُونٖ 147
Ninu awọn oko ati awọn odo ti nsan.
وَزُرُوعٖ وَنَخۡلٖ طَلۡعُهَا هَضِيمٞ 148
Ati awọn irugbin ati ọpẹ ti eso rẹ lẹ, ti o si gbo.
وَتَنۡحِتُونَ مِنَ ٱلۡجِبَالِ بُيُوتٗا فَٰرِهِينَ 149
Wọn si ngbẹ oke ki wọn le kọ ile ti wọn yoo gbe ibẹ, bẹẹni ẹ jẹ ẹniti o jafafa nibi kikọ rẹ.
فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَأَطِيعُونِ 150
Ki ẹ ya paya Allah pẹlu mima tẹle awọn asẹ ati jijinna si awọn nkan ti o kọ, ki ẹ si tẹle mi nibi ohun ti mo ba pa yin lasẹ rẹ ati ohun ti mo ba kọ fun yin kuro nibẹ.
وَلَا تُطِيعُوٓاْ أَمۡرَ ٱلۡمُسۡرِفِينَ 151
Ẹ ma si tẹriba fun asẹ awọn oninan apa lori ara wọn pẹlu gigunle awọn ẹsẹ.
ٱلَّذِينَ يُفۡسِدُونَ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلَا يُصۡلِحُونَ 152
Awọn ti wọn se ibajẹ si ori ilẹ pẹlu ohun ti wọn fanka ninu awọn ẹsẹ, wọn si kii se atunse ẹmin ara wọn pẹlu didunni mọ itẹle ti Allah.
قَالُوٓاْ إِنَّمَآ أَنتَ مِنَ ٱلۡمُسَحَّرِينَ 153
Awọn ijọ rẹ sọ fun wipe: dajudaju o wa ninu ẹniti wọn ti fi idandan lọpọlọpọ titi idan fi bori laakaye wọn, ti o si mu lọ.
مَآ أَنتَ إِلَّا بَشَرٞ مِّثۡلُنَا فَأۡتِ بَِٔايَةٍ إِن كُنتَ مِنَ ٱلصَّٰدِقِينَ 154
Iwọ kii se nkankan ju abara lọ gẹgẹ bii wa, o ko ni ẹsa kankan le wa lori ti o fi le jẹ ojisẹ, mu amin kan wa ti yoo tọka si wipe ojisẹ ni ọ, ti o ba jẹ sootọ sootọ nibi nkan ti o npe apemọra rẹ wipe ojisẹ ni ọ.
قَالَ هَٰذِهِۦ نَاقَةٞ لَّهَا شِرۡبٞ وَلَكُمۡ شِرۡبُ يَوۡمٖ مَّعۡلُومٖ 155
Sọlihu sọ fun wọn - paapaa Ọlọhun Allah ti fun ni amin, ohun si ni rakunmi ti Allah mu jade ni inu apata -: eleyi ni rakunmi ti o see ri, ti o si se fi ọwọ kan, o ni ipin ninu omin naa, bẹẹni ẹyin naa ni ipin ti a mọ, ko ni mu omin ni ọjọ ti o jẹ ipin ti yin, bẹẹ ni ẹyin ko gbọdọ mu omin ni ọjọ ti o jẹ ipin ti rẹ.
وَلَا تَمَسُّوهَا بِسُوٓءٖ فَيَأۡخُذَكُمۡ عَذَابُ يَوۡمٍ عَظِيمٖ 156
Ẹ ko gbọdọ fi aburu kan an gẹgẹ bi gigun tabi lilu u, ki iya lati ọdọ Allah ma baa kan yin, ti yoo pa yin run nitori rẹ ni ọjọ ti o tobi, nitori aluba eyiti yoo sọkalẹ le yin lori nibẹ.
فَعَقَرُوهَا فَأَصۡبَحُواْ نَٰدِمِينَ 157
Wọn si pawọpọ lati gun un, olori buruku ju ninu wọn si gun un, wọn wa di alabamọ lori ohun ti wọn ti siwaju nigbati wọn mọ ijiya ti yoo sọkalẹ le wọn lori laisi ibuyẹ, sugbọn abamọ nigbati iya ti fi oju han ko se anfaani.
فَأَخَذَهُمُ ٱلۡعَذَابُۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗۖ وَمَا كَانَ أَكۡثَرُهُم مُّؤۡمِنِينَ 158
Iya ti wọn se ni adehun fun wọn si gba wọn mu, oun ni ilẹ mimi ati igbe jija, dajudaju nibi eyiti a sọ yii ninu itan Sọlihu ati ijọ rẹ jẹ ariwoye fun awọn oloye, bẹẹ ni ọpọ wọn ko jẹ olugbagbọ ododo.
وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلرَّحِيمُ 159
Ati wipe dajudaju Ọlọhun Ọba rẹ - irẹ ojisẹ - jẹ alagbara eyiti o ngbẹsan lara awọn ọta rẹ; onikẹ fun ẹniti o ba ronu piwada ninu awọn ẹru Rẹ.
Titẹle ra wọn idẹkun pẹlu sise keferi jẹ idẹnilẹkẹ fun iparun.
Riranti idẹkun jẹ ohun ti a nreti igbagbọ nibẹ ati isẹri lati ọdọ ẹru si ọdọ Allah.
Awọn ẹsẹ jẹ okunfa ibajẹ lori ilẹ.