۞يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ كُونُواْ قَوَّٰمِينَ بِٱلۡقِسۡطِ شُهَدَآءَ لِلَّهِ وَلَوۡ عَلَىٰٓ أَنفُسِكُمۡ أَوِ ٱلۡوَٰلِدَيۡنِ وَٱلۡأَقۡرَبِينَۚ إِن يَكُنۡ غَنِيًّا أَوۡ فَقِيرٗا فَٱللَّهُ أَوۡلَىٰ بِهِمَاۖ فَلَا تَتَّبِعُواْ ٱلۡهَوَىٰٓ أَن تَعۡدِلُواْۚ وَإِن تَلۡوُۥٓاْ أَوۡ تُعۡرِضُواْ فَإِنَّ ٱللَّهَ كَانَ بِمَا تَعۡمَلُونَ خَبِيرٗا 135
Ẹyin olugbagbọ ododo si Ọlọhun Ọba Allah, ti ẹ si ntẹle ojisẹ Rẹ, ẹ duro tọ pẹlu deede nibi gbogbo isesi yin ni ẹniti yoo maa jẹri ododo pẹlu ẹnikẹni koda ki baa debi wipe ẹ o fi jẹri lori ẹmin ara yin niti ododo tabi lori awọn obi yin mejeeji tabi awọn ti wọn sun mọ yin, osi ẹnikanakan tabi ọrọ rẹ ko gbọdọ mu yin lati jẹri-kẹri, tabi gbe ju silẹ, Ọlọhun Ọba Allah ni alatilẹyin olosi ati ọlọrọ ninu yin, O si ni imọ nipa nkan ti o jẹ atunse julọ, ẹ mase tẹle ifẹ imnu nibi ijẹri yin, ki ẹ mọ ba fi kuro nibi ododo, ti ẹ ba lọ se adinku ijẹri pẹlu ki ẹ jẹ ni ojupọnna ti ko tọ, tabi ẹ gunri kuro nibi jijẹri; dajudaju Ọlọhun Ọba Allah jẹ olufuni niro nkan ti ẹ nse.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ ءَامِنُواْ بِٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦ وَٱلۡكِتَٰبِ ٱلَّذِي نَزَّلَ عَلَىٰ رَسُولِهِۦ وَٱلۡكِتَٰبِ ٱلَّذِيٓ أَنزَلَ مِن قَبۡلُۚ وَمَن يَكۡفُرۡ بِٱللَّهِ وَمَلَٰٓئِكَتِهِۦ وَكُتُبِهِۦ وَرُسُلِهِۦ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ فَقَدۡ ضَلَّ ضَلَٰلَۢا بَعِيدًا 136
Ẹyin ti ẹ jẹ olugbagbọ ododo, ẹ duro sinsin lori igbagbọ ti ẹ ni si Ọlọhun Ọba Allah ati ojisẹ Rẹ, ati pẹlu awọn iwe Rẹ eyiti o sọkalẹ fun awọn ojisẹ siwaju, ẹniti o ba se aimoore si Ọlọhun Ọba Allah tabi awọn malaika Rẹ tabi awọn iwe Rẹ tabi awọn ojisẹ Rẹ tabi si ọjọ igbende; o ti jinna si oju ọna ti o duro tọọ ni ijina ti o tobi.
إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ثُمَّ كَفَرُواْ ثُمَّ ءَامَنُواْ ثُمَّ كَفَرُواْ ثُمَّ ٱزۡدَادُواْ كُفۡرٗا لَّمۡ يَكُنِ ٱللَّهُ لِيَغۡفِرَ لَهُمۡ وَلَا لِيَهۡدِيَهُمۡ سَبِيلَۢا 137
Dajudaju awọn ti aimoore wọn paara lẹyin igbagbọ, pẹlu wiwọ inu igbagbọ lẹyin ti wọn ti gunri kuro nibẹ, lẹyin igba naa ni wọn tun waa wọ inu rẹ, lẹyin igba naa wọn tun waa gunri kuro, lẹyin igba naa wọn wa taku lori aimoore, wọn si ku le lori; Ọlọhun Ọba Allah ko nii fi ori ẹsẹ wọn jin wọn, bẹẹ ni ko nii tọ wọn si oju ọna ti o duro tọ, ti yoo mu wọn de ọdọ Rẹ.
بَشِّرِ ٱلۡمُنَٰفِقِينَ بِأَنَّ لَهُمۡ عَذَابًا أَلِيمًا 138
Fun niro - ire ojise - awọn sọbẹ-selo ti wọn nse afihan igbagbọ, ti wọn si fi keferi pamọ sinu, wipe dajudaju iya onita nbẹ fun ni ọdọ Ọlọhun Ọba Allah ni ọjọ igbende.
ٱلَّذِينَ يَتَّخِذُونَ ٱلۡكَٰفِرِينَ أَوۡلِيَآءَ مِن دُونِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَۚ أَيَبۡتَغُونَ عِندَهُمُ ٱلۡعِزَّةَ فَإِنَّ ٱلۡعِزَّةَ لِلَّهِ جَمِيعٗا 139
Ijiya yii jẹ titori wipe wọn mu awọn keferi ni alaranse ati oluranlọwọ dipo awọn olugbagbọ ododo, bẹẹni eleyi jẹ nkan eemọ nibi mimu wọn ni alatilẹyin, se nwa agbara ni ọdọ wọn ni, tabi idaabobo ki ẹ le fi di gaga pẹlu rẹ? ! Dajudaju agbara ati idaabobo gbogbo rẹ ti Ọlọhun Ọba Allah.
وَقَدۡ نَزَّلَ عَلَيۡكُمۡ فِي ٱلۡكِتَٰبِ أَنۡ إِذَا سَمِعۡتُمۡ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ يُكۡفَرُ بِهَا وَيُسۡتَهۡزَأُ بِهَا فَلَا تَقۡعُدُواْ مَعَهُمۡ حَتَّىٰ يَخُوضُواْ فِي حَدِيثٍ غَيۡرِهِۦٓ إِنَّكُمۡ إِذٗا مِّثۡلُهُمۡۗ إِنَّ ٱللَّهَ جَامِعُ ٱلۡمُنَٰفِقِينَ وَٱلۡكَٰفِرِينَ فِي جَهَنَّمَ جَمِيعًا 140
Paapaa o ti sọkalẹ fun yin ni ọdọ Ọlọhun -ẹyin olugbagbọ ododo- ninu Alukuraani Alapọnle wipe ti ẹ ba joko ni aaye kan, ti ẹ si ngbọ ẹniti o tako awọn amin Ọlọhun Ọba Allah, ti o si fi nse yẹyẹ; o di dandan fun yin ki ẹ gbe aaye naa ju silẹ, ki ẹ si kuro nibi ibajoko wọn, titi ti wọn yoo fi maa sọ ọrọ ti yatọ si sise keferi si awọn amin Ọlọhun Ọba Allah ati sise yẹyẹ pẹlu rẹ, ti ẹ ba tun waa joko pẹlu wọn lori isesi sise keferi pẹlu awọn amin Ọlọhun Ọba Allah ati sise yẹyẹ pẹlu rẹ, lẹyin igbati ẹ ti gbọ eleyi, dajudaju ẹ ti da gẹgẹ bi wọn nibi iyapa asẹ Ọlọhun Ọba Allah; toripe ẹ yapa Ọlọhun Ọba Allah pẹlu jijoko yin gẹgẹ bẹẹnaa ni awọn naa yapa Ọlọhun Ọba Allah pẹlu sise keferi wọn, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah yoo ko awọn sọbẹselo ti wọn nse afihan Islam, ti wọn si nse afipamọ keferi pọ mọ awọn keferi ni inu ina jahanamọ ni ọjọ igbende.
Jijjẹ dandan deede nibni idajọ laarin awọn eniyan, ati ni igba ijẹri, koda bi ododo naa jẹ lori ara ẹni tabi lori ara alasunmọ.
Dandan ni fun olugbagbọ ododo ki o se igbiyanju lori isẹ ti nyoo se alekun igbagbọ rẹ gẹgẹ bi isẹ ọkan ati orikerike ara, ki o si fi rinlẹ ninu ọkan rẹ.
Titobi ewu awọn sọbẹselu lori Islam ati awọn ẹniirẹ; tori eleyi ni Ọlọhun Ọba Allah fi se adehun ti o le koko ni ọjọ ikẹyin.
Ti ẹnikẹni ninu nolugbagbọ ododo ko ba ni agbara lati tako ẹniti o nfi ẹnu agan kan awọn amin Ọlọhun Ọba Allah ati ofin rẹ, ko tọ ki o joko pẹlu rẹ lori isesi naa.