وَقَالُواْ كُونُواْ هُودًا أَوۡ نَصَٰرَىٰ تَهۡتَدُواْۗ قُلۡ بَلۡ مِلَّةَ إِبۡرَٰهِۧمَ حَنِيفٗاۖ وَمَا كَانَ مِنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ 135
Awọn Yahuudi wa sọ fun awọn ijọ yii: ẹ jẹ Yahuudi, ẹyin yoo tọ oju ọna imọna, awọn Nasaara sọ wipe: ẹ jẹ Nasaara, ẹyin yoo tọ oju ọna imọna. Sọ wipe - irẹ Anọbi - ni ẹniti nda wọn lohun: bikose wipe awa yoo tẹle ẹsin Ibraheem, eyiti o ya kuro nibi awọn ẹsin ibajẹ lọ si ibi ẹsin ododo, ti ko si ninu awọn ti wọn mu orogun kankan pẹlu Ọlọhun Ọba.
قُولُوٓاْ ءَامَنَّا بِٱللَّهِ وَمَآ أُنزِلَ إِلَيۡنَا وَمَآ أُنزِلَ إِلَىٰٓ إِبۡرَٰهِۧمَ وَإِسۡمَٰعِيلَ وَإِسۡحَٰقَ وَيَعۡقُوبَ وَٱلۡأَسۡبَاطِ وَمَآ أُوتِيَ مُوسَىٰ وَعِيسَىٰ وَمَآ أُوتِيَ ٱلنَّبِيُّونَ مِن رَّبِّهِمۡ لَا نُفَرِّقُ بَيۡنَ أَحَدٖ مِّنۡهُمۡ وَنَحۡنُ لَهُۥ مُسۡلِمُونَ 136
Ẹ sọ - ẹyin ti ẹ ni igbagbọ ododo - fun awọn ti wọn npe apemọra ẹni ti o buru yii ninu awọn Yahuudi ati awọn Nasaara, awa gba Ọlọhun Ọba gbọ ati Alukuraani eyiti wọn sọkalẹ fun wa, a si gba ohun ti wọn sọkalẹ fun Ibraheem gbọ ati awọn ọmọ rẹ Isma'eel, Ishaaq ati Yaquub, a si gba ohun ti wọn sọkalẹ fun awọn Anọbi gbọ lati inu awọn ọmọ Yaquub, a si gba Taoreeta gbọ eyiti Ọlọhun Ọba fun Muusa ati Injeel eyiti Ọlọhun Ọba fun Isa, a si nigbagbọ pẹlu awọn tira eyiti Ọlọhun Ọba fun awọn Anọbi lapapọ, a ko nii se opinya laarin ọkankan ninu wọn debi wipe a o waa gba apakan gbọ, ti a ko si nii gba apakan gbọ bikose wipe a o ni igbagbọ pẹlu wọn lapapọ, awa Ọlọhun Ọba ti O mọ nikan ni a o rọ fun, ti a o si tẹriba fun.
فَإِنۡ ءَامَنُواْ بِمِثۡلِ مَآ ءَامَنتُم بِهِۦ فَقَدِ ٱهۡتَدَواْۖ وَّإِن تَوَلَّوۡاْ فَإِنَّمَا هُمۡ فِي شِقَاقٖۖ فَسَيَكۡفِيكَهُمُ ٱللَّهُۚ وَهُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡعَلِيمُ 137
Ti awọn Yahuudi ati awọn Nasaara ati awọn ti wọn yatọ si wọn ninu awọn alaigbagbọ ba ni igbagbọ kan gẹgẹ bi igbagbọ yin a jẹwipe paapaa wọn ti mọna lọ si oju ọna ti o tọ eyiti Ọlọhun Ọba yọnu si, ti wọn ba waa gunri kuro nibi nini igbagbọ pẹlu pe wọn pe gbogbo awọn Anọbi ni irọ tabi apakan wọn dajudaju wọn wa ninu iyapa adehun, mase banujẹ - irẹ Anọbi - dajudaju Ọlọhun Ọba yoo to ọ nibi suta wọn, Yoo si kọ fun ọ nibi aburu wọn, Yoo si ran ọ se le wọn lori, Oun ni ẹniti O gbọ gbogbo gbolohun wọn, ti O si ni imọ pẹlu awọn adisọkan wọn ati awọn isẹẹ wọn.
صِبۡغَةَ ٱللَّهِ وَمَنۡ أَحۡسَنُ مِنَ ٱللَّهِ صِبۡغَةٗۖ وَنَحۡنُ لَهُۥ عَٰبِدُونَ 138
Ẹ duni mọ ẹsin Ọlọhun Ọba eyiti o pilẹ yin lori rẹ, ni gbangba ati ni kọkọ, ko si ẹsin kankan ti o dara ju ẹsin Ọlọhun Ọba lọ, ohun ni o se deede adamọ, ti o si ma nmu awọn daradara wa, ti o si ma nkọ awọn aida, ẹ sọ wipe: awa ni olujọsin fun Ọlọhun Ọba lọkankan soso, a ko si nii mu ẹlomiran lorogun pẹlu Rẹ.
قُلۡ أَتُحَآجُّونَنَا فِي ٱللَّهِ وَهُوَ رَبُّنَا وَرَبُّكُمۡ وَلَنَآ أَعۡمَٰلُنَا وَلَكُمۡ أَعۡمَٰلُكُمۡ وَنَحۡنُ لَهُۥ مُخۡلِصُونَ 139
Sọ - irẹ Anọbi - wipe: se ẹyin yoo maa jawa niyan ni, - ẹyin ti ẹ ni tira - nibi wipe dajudaju ẹyin ni ẹ ni ẹtọ si Ọlọhun Ọba, ati ẹsin Rẹ ju awa lọ; nitoripe ẹsin yin siwaju ti tira yin si gbawaju, nkan naa ko lee se yin ni anfaani, Ọlọhun Ọba ni Ọlọhun Ọba gbogbo lapapọ, ẹyin ko ni ẹsa pẹlu Rẹ, awọn isẹ wa yoo ma jẹ tiwa eyiti wọn ko nii biyin leere nipa rẹ, awọn isẹ yin yoo si maa jẹ ti yin eyiti wọn ko nii bi wa leere nipa rẹ, gbogbo olukuluku ni wọn yoo san lẹsan nipa isẹ rẹ, awa jẹ olusafọmọ fun Ọlọhun Ọba nibi ijọsin ati itẹle, a ko si nii mu orogun kankan pẹlu rẹ.
أَمۡ تَقُولُونَ إِنَّ إِبۡرَٰهِۧمَ وَإِسۡمَٰعِيلَ وَإِسۡحَٰقَ وَيَعۡقُوبَ وَٱلۡأَسۡبَاطَ كَانُواْ هُودًا أَوۡ نَصَٰرَىٰۗ قُلۡ ءَأَنتُمۡ أَعۡلَمُ أَمِ ٱللَّهُۗ وَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّن كَتَمَ شَهَٰدَةً عِندَهُۥ مِنَ ٱللَّهِۗ وَمَا ٱللَّهُ بِغَٰفِلٍ عَمَّا تَعۡمَلُونَ 140
Abi ẹyin yoo maa sọ wipe - ẹyin ti ẹ ni tira - dajudaju Ibraheem, Isma'eel, Ishaaq, Yaquub ati awọn Anọbi lati inu ọmọ Yaquub, wọn nbẹ ni oju ọna Yahuudi tabi Nasaara? Sọ - irẹ Anọbi - ni ẹniti nda wọn lohun wipe se ẹyin ni ẹ ni imọ ju ni tabi Ọlọhun Ọba ?! ti wọn ba lero pe dajudaju awọn wa lori oju ọna wọn paapaa a jẹ wipe wọn ti pa irọ; toripe gbigbe wọn dide ati kiku wọn wa siwaju sisọ Taoraata kalẹ ati Injeel! Wọn waa mọ pẹlu nkan naa, pe dajudaju ohun ti wọn nsọ yii, irọ ni wọn fi pa mọ Ọlọhun Ọba ati ojisẹ Rẹ, ati wipe dajudaju awọn ma npa ododo mọ eyiti wọn sọkalẹ fun wọn, ko si si ẹnikankan ti abosi rẹ lagbara ju ẹniti o pa ijẹri kan ti o fi ẹsẹ rinlẹ ni ọdọ rẹ mọ eyiti o mọ lati ọdọ Ọlọhun Ọba gẹgẹ bi awọn to ni tira se ma nse, Ọlọhun Ọba ko jẹ afọnufọra nipa awọn isẹ yin, yoo si san yin lẹsan le lori.
تِلۡكَ أُمَّةٞ قَدۡ خَلَتۡۖ لَهَا مَا كَسَبَتۡ وَلَكُم مَّا كَسَبۡتُمۡۖ وَلَا تُسَۡٔلُونَ عَمَّا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ 141
Ohun ni ijọ kan ti o ti kọja siwaju yin, o si ti lọọ ba ohun ti o ti siwaju ninu isẹ, yoo gbẹsan ohun ti o se ninu awọn isẹ, yoo si maa bẹ fun yin ohun ti ẹ ba gbese, wọn ko ni bi yin leere nipa awọn isẹ wọn, wọn si ki nii bi awọn naa leere nipa awọn isẹ yin, wọn ko si nii fi ẹsẹ ẹnikankan bi ẹlomiran, ko si nii se anfaani pẹlu isẹ ẹlomiran bikose wipe wọn yoo san olukuluku lẹsan lori ohun ti o ba ti siwaju.
Dajudaju ipe mọ ara ẹni awọn ti a fun ni tira pe dajudaju awọn wa ni ori ododo, ko nii se anfaani fun wọn, wọn jẹ alaigbagbọ si ohun ti Ọlọhun Ọba sọkalẹ fun Anọbi Rẹ Muhammad (ki Ọlọhun Ọba se ikẹ ati igẹ fun un) .
Wọn pe ẹsin ni aró nitori fifi oju han awọn isẹ rẹ ati idanimọ rẹ ni ara Musulumi gẹgẹ bi oripa aro se ma nhan ni ara asọ.
Dajudaju Ọlọhun Ọba (ti ọla Rẹ ga) , O ti fi gunlẹ nibi adamọ ẹda rẹ lapapọ jijẹ ti Ọlọhun Ọba jẹ Olutọju ati jijẹ ọkansoso Rẹ, sugbọn ohun ti o sọ wọn nu nibẹ ni esu ati awọn alaranse rẹ.