فَإِذَا جَآءَتۡهُمُ ٱلۡحَسَنَةُ قَالُواْ لَنَا هَٰذِهِۦۖ وَإِن تُصِبۡهُمۡ سَيِّئَةٞ يَطَّيَّرُواْ بِمُوسَىٰ وَمَن مَّعَهُۥٓۗ أَلَآ إِنَّمَا طَٰٓئِرُهُمۡ عِندَ ٱللَّهِ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ 131
Ti ọpọ nkan ati didara awọn eso tabi ẹdinku iye owo ori nkan ba waa ba awọn ara ile fir'aona wọn yoo sọ pe: wọn fun wa ni eleyi nitori wipe a ni ẹtọ sii, ati jijẹ ẹni ẹsa wa sii, sugbọn ti adanwo ba kan wọn nipa ọda ati ọgbẹlẹ ati ọpọ aarẹ tabi ohun ti o yatọ si ninu awọn nnkan aburu, wọn yoo maa fi aburu naa ti si ọdọ Musa ati awọn ti wọn tẹle ninu awọn ọmọlẹyin rẹ, awọn arọmọdọmọ isirẹla ni, ododo si ni wipe ohun ti o sẹlẹ si wọn jẹ akọsilẹ lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah ti mimọ nbẹ fun, ko si ikapani musa nibẹ ayaafi adua ti musa ba se le wọn lori sugbọn ọpọlọpọ wọn mọ ti wọn fi nse afiti rẹ si ọdọ ohun ti o yatọ si Ọlọhun Ọba Allah.
وَقَالُواْ مَهۡمَا تَأۡتِنَا بِهِۦ مِنۡ ءَايَةٖ لِّتَسۡحَرَنَا بِهَا فَمَا نَحۡنُ لَكَ بِمُؤۡمِنِينَ 132
Ijọ fir'aona sọ fun musa niti isorikunkun si ododo, amin wo tabi itọka wo ni o mu wa ba wa ati wipe ẹri wo ni o duro le lori rẹ ti o ba nkan ti awa nbẹ lori rẹ jẹ lati kuro nibẹ, ti o wa fi gba nkan ti o muwa lododo; a ko le gba ọ lododo.
فَأَرۡسَلۡنَا عَلَيۡهِمُ ٱلطُّوفَانَ وَٱلۡجَرَادَ وَٱلۡقُمَّلَ وَٱلضَّفَادِعَ وَٱلدَّمَ ءَايَٰتٖ مُّفَصَّلَٰتٖ فَٱسۡتَكۡبَرُواْ وَكَانُواْ قَوۡمٗا مُّجۡرِمِينَ 133
Awa ran ọmin ti o pọ ki o le jẹ iya lori irọ pipa wọn ati isorikunkun wọn, awọn irugbọn si ri, awa ran tata si wọn ti o njẹ gbogbo nkan oko wọn, bakanna ni a ran ẹda kekere kan ti wọn npe ni ina ori, ti o nba ọgbin wọn jẹ, tabi ti o nfi suta se ọmọ ẹda eniyan nibi irun ori rẹ, a si ran ọpọlọpọ si wọn ti o kun inu gbogbo apẹ, o si ba gbogbo ounjẹ wọn jẹ, o si tutu gbogbo ibusun wọn, a si ran ẹjẹ si wọn ti gbogbo odo wọn ati isẹlẹru wọn si yi pada si ẹjẹ, a ran gbogbo eleyi ki o le jẹ amin ti o fi oju han, ti o yatọ si ara wọn, ti o si ntẹle ara wọn, sugbọn pẹlu gbogbo ijiya ti o sẹlẹ si wọn yii, wọn ku nigbagbọ si Ọlọhun Ọba Allah, wọn ko si gba ohun ti Musa ẹniti ọla nbẹ fun muwa fun wọn lododo, wọn jẹ ijọ ti o nda ẹsẹ, wọn ko si jawọ kuro nibi ibajẹ, bẹẹ ni wọn ko mọ ọna ododo.
وَلَمَّا وَقَعَ عَلَيۡهِمُ ٱلرِّجۡزُ قَالُواْ يَٰمُوسَى ٱدۡعُ لَنَا رَبَّكَ بِمَا عَهِدَ عِندَكَۖ لَئِن كَشَفۡتَ عَنَّا ٱلرِّجۡزَ لَنُؤۡمِنَنَّ لَكَ وَلَنُرۡسِلَنَّ مَعَكَ بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ 134
Nigbati iya waa ba wọn ni oniranran ọna yii, wọn da oju kọ ọdọ Musa, wọn si sọ fun wipe: irẹ Musa, fi jijẹ anọbi rẹ bẹ Ọlọhun Ọba rẹ fun wa, ati adehun ti O se fun ọ lati gbe iya kuro lẹyin ironu piwada, ki O gbe ijiya ti o sẹlẹ si wa kuro fun wa, ti o ba gbe iya naa kuro fun wa, awa yoo ni igbagbọ sii, a o si ran ojisẹ pẹlu rẹ ninu awọn arọmọdọmọ isirẹla, bẹẹ ni a o gbe wọn ju silẹ.
فَلَمَّا كَشَفۡنَا عَنۡهُمُ ٱلرِّجۡزَ إِلَىٰٓ أَجَلٍ هُم بَٰلِغُوهُ إِذَا هُمۡ يَنكُثُونَ 135
Nigbati a gbe iya kuro fun wọn fun asiko diẹ siwaju ki wọn o to fi riri pa wọn, wọn tun ja adehun eyiti wọn gba lori igbalododo ati riran ojisẹ ninu awọn ọmọ isirẹla, wọn si tun tẹsiwaju lori ẹsin keferi wọn, wọn kọ lati ran ojisẹ ninu arọmọdọmọ isirẹla pẹlu Musa.
فَٱنتَقَمۡنَا مِنۡهُمۡ فَأَغۡرَقۡنَٰهُمۡ فِي ٱلۡيَمِّ بِأَنَّهُمۡ كَذَّبُواْ بَِٔايَٰتِنَا وَكَانُواْ عَنۡهَا غَٰفِلِينَ 136
Nigbati asiko ti a fun wọn to lati pa wọn run, a sọ iya wa kalẹ pẹlu wiọlẹ sinu odo nitori irọ ti wọn npe awọnamin Ọlọhun Ọba, ati igunri wọn kuro nibi ohun ti ododo ntọka si, ti ko si iyemeji nibẹ.
وَأَوۡرَثۡنَا ٱلۡقَوۡمَ ٱلَّذِينَ كَانُواْ يُسۡتَضۡعَفُونَ مَشَٰرِقَ ٱلۡأَرۡضِ وَمَغَٰرِبَهَا ٱلَّتِي بَٰرَكۡنَا فِيهَاۖ وَتَمَّتۡ كَلِمَتُ رَبِّكَ ٱلۡحُسۡنَىٰ عَلَىٰ بَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ بِمَا صَبَرُواْۖ وَدَمَّرۡنَا مَا كَانَ يَصۡنَعُ فِرۡعَوۡنُ وَقَوۡمُهُۥ وَمَا كَانُواْ يَعۡرِشُونَ 137
A jogun ibuyọ oorun ati ibuwọ rẹ fun awọn arọmọdọmọ isirẹla, awọn ti fir'aona yẹpẹrẹ ati awọn ijọ rẹ, ibiti a gbero pẹlu eleyi ni ilẹ ṣamu, ilẹ yii ni Ọlọhun Ọba fi ibukun si pẹlu yiyọ irugbin rẹ jade ati eso rẹ ni ojupọnna ti o pe, gbolohun Ọlọhun Ọba rẹ si di ododo - ire ojise - eyiti o dara ju, ohun ti a darukọ ninu gbolohun Ọlọhun Ọba ti o ga: (وَنُرِيدُ أَن نَّمُنَّ عَلَى ٱلَّذِينَ ٱسۡتُضۡعِفُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَنَجۡعَلَهُمۡ أَئِمَّةٗ وَنَجۡعَلَهُمُ ٱلۡوَٰرِثِينَ) (a gbero lati se idẹkun fun awọn ti wọn lẹ lori ilẹ, ki a si sọ wọn di asiwaju, bakanna ki a sọ wọn di olujogun: kọsọs: 5), Ọlọhun Ọba gba wọn laaye lori ilẹ nitori suuru ti wọn se lori suta ti fir'aona ati ijọ rẹ fi kan wọn, a si pa awọn nkan irugbin ti fir'aona se ati ile wọn run, ati awọn ile nla ti wọn kọ.
Rere ati aburu ati awọn daradara ati aida gbogbo rẹ pẹlu akọsilẹ Ọlọhun Ọba, nkankan ko moribọ kuro nibẹ ninu wọn.
Isesi awọn eniyan ni asiko wahala ati idaamun ni ki wọn sẹri si ọdọ Ọlọhun Ọba Allah pẹlu ki wọn pepe fun igbagbọ ipilẹ.
O tọ fun olugbagbọ ododo ki o ronu nipa awọn amin Ọlọhun Ọba ati isesi Ọlọhun Ọba lori ẹda, ki o si ronu pipa awọn okunfa rẹ ati abajade rẹ.
Agbara awọn eniyan kọọkan ati ilu yoo kọlẹ niwaju agbara Ọlọhun Ọba ti O tobi julọ, igbagbọ si ibusun gbogbo agbara.
Ọlọhun Ọba Allah yoo sẹsan fun awọn ẹru Rẹ ti wọn jẹ olugbagbọ ododo, ti wọn si ni suuru pẹlu wipe ki O gba wọn laaye ni ori ilẹ lẹyin igbati wọn ti jẹ ọlẹ.