أَرَءَيۡتَ إِن كَذَّبَ وَتَوَلَّىٰٓ 13
Iwọ ko ri ti olukọ yii ba pe ohun ti ojisẹ naa muwa nirọ, ti o si gunri kuro nibẹ, se ko nii paya Allah ni?!
أَلَمۡ يَعۡلَم بِأَنَّ ٱللَّهَ يَرَىٰ 14
Se olukọ fun ẹru naa nibi irun ko mọ ni wipe dajudaju Allah ri ohun ti o nse, nkankan ko pamọ fun Un nibẹ?!
كَلَّا لَئِن لَّمۡ يَنتَهِ لَنَسۡفَعَۢا بِٱلنَّاصِيَةِ 15
Ọrọ ko ri bi alaimọkan yii se nyaworan rẹ, ti ko ba ka ọwọ ro kuro nibi fifi suta se ẹru wa ati pipe e nirọ, a o gbamun ni ẹniti a o ti lọsi inu ina pẹlu iwaju ori rẹ niti inira.
نَاصِيَةٖ كَٰذِبَةٍ خَاطِئَةٖ 16
Ẹniti o ni aaso naa jẹ opurọ ninu gbolohun, alasise nibi isẹ.
فَلۡيَدۡعُ نَادِيَهُۥ 17
Nigbati wọn gba ori rẹ mu lọsi inu ina, ki o yaa pe awọn eniyan rẹ ati olubajoko rẹ, ki o wa iranlọwọ pẹlu wọn lati la a kuro nibi iya naa.
سَنَدۡعُ ٱلزَّبَانِيَةَ 18
Awa yoo pe awọn alaabi ina jahannamọ ninu awọn malaika ti o le, awọn ti wọn kii yapa Allah nibi ohun ti O ba pa wọn lasẹ, wọn si ma nse ohun ti O ba pasẹ rẹ, ki o ya wo ipin ti o lagbara ju, ti o si nikapa ju.
كَلَّا لَا تُطِعۡهُ وَٱسۡجُدۡۤ وَٱقۡتَرِب۩ 19
Ọrọ ko ri bi alabosi yii se nlero rẹ nipa ki aburu de ọdọ rẹ, mase tẹle nibi asẹ tabi ẹkọ, ki o fi ori balẹ fun Allah, ki o si sun mọ Ọ pẹlu titẹ le nitoripe yoo mu ọ sun mọ Ọ.
سورة (MAKIYYAH)
Sise alaye titobi oru ipebubu ati ọla rẹ ati ohun ti wọn sọkalẹ nibẹ.
إِنَّآ أَنزَلۡنَٰهُ فِي لَيۡلَةِ ٱلۡقَدۡرِ 1
Awa ni a sọ Alukuraani kalẹ ni apapọ si sanmọ aye gẹgẹ bi a se pilẹ sisọkalẹ rẹ fun anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun ni oru ipebubu ninu osu Ramadan.
وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا لَيۡلَةُ ٱلۡقَدۡرِ 2
Njẹ o mọ - irẹ Anọbi - oore ati ibukun ti o wa ninu oru naa bi?!
لَيۡلَةُ ٱلۡقَدۡرِ خَيۡرٞ مِّنۡ أَلۡفِ شَهۡرٖ 3
Oru yii jẹ oru ti o tobi loore, o si loore ju ẹgbẹrun osu lọ fun ẹniti o ba dide nibẹ pẹlu igbagbọ ati sise isẹ rere.
تَنَزَّلُ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ وَٱلرُّوحُ فِيهَا بِإِذۡنِ رَبِّهِم مِّن كُلِّ أَمۡرٖ 4
Gbogbo Malaika yoo sọkalẹ, bẹẹni Malaika Jibril ẹniti ọla nbẹ fun naa yoo sọkalẹ ninu rẹ pẹlu iyọnda Ọlọhun ti mimọ nbẹ fun pẹlu gbogbo asẹ ti Allah ba kọ ni ọdun naa boya arisiki ni tabi iku tabi ibimọ tabi nkan miran ninu ohun ti Allah ti pebubu rẹ.
سَلَٰمٌ هِيَ حَتَّىٰ مَطۡلَعِ ٱلۡفَجۡرِ 5
Gbogbo oru ibukun yii jẹ oore lati ipilẹ rẹ titi de ipari rẹ titi ti alufajari yoo fi yọ.
سورة (MADANIYYAH)
Sisọ ipo isẹ ojisẹ ti ikẹ ati ọla nbẹ fun ati yiyanju rẹ ati pipe rẹ.
لَمۡ يَكُنِ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ مِنۡ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِ وَٱلۡمُشۡرِكِينَ مُنفَكِّينَ حَتَّىٰ تَأۡتِيَهُمُ ٱلۡبَيِّنَةُ 1
Awọn ti wọn se keferi ninu yahuudi ati nasaara ati awọn ẹlẹbọ, wọn ko jawọ lapapọ wọn ati ipanupọ wọn lori keferi titi awijare ti o fi oju han ati ẹri ti o gbọngbọn fi waa ba wọn.
رَسُولٞ مِّنَ ٱللَّهِ يَتۡلُواْ صُحُفٗا مُّطَهَّرَةٗ 2
Awijare ti o fi oju han yii ati ẹri ti o gbọngbọn yii ni ojisẹ kan lati ọdọ Allah, o gbe e dide ki o maa ka awọn iwe ti o mọ ti ẹnikankan ko le gbamun ayaafi awọn ti a ti mọ.
فِيهَا كُتُبٞ قَيِّمَةٞ 3
Ninu awọn iwe yii, awọn iroyin ti ododo ati awọn idajọ deedee wa nibẹ ti o ntọ awọn eniyan sibi ti anfaani wọn wa ati itọsọna wọn.
وَمَا تَفَرَّقَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ إِلَّا مِنۢ بَعۡدِ مَا جَآءَتۡهُمُ ٱلۡبَيِّنَةُ 4
Awọn yahuudi ti wọn fun ni taoreeta ati awọn nasaara ti wọn fun ni Injiila ko yapa ayaafi lẹyin igbati Allah ti gbe anọbi Rẹ dide si wọn, ẹniti o gbafa wa ninu wọn, ẹniti o si ntẹsiwaju nibi keferi rẹ pẹlu imọ rẹ nipa ododo anọbi Rẹ naa wa ninu wọn.
وَمَآ أُمِرُوٓاْ إِلَّا لِيَعۡبُدُواْ ٱللَّهَ مُخۡلِصِينَ لَهُ ٱلدِّينَ حُنَفَآءَ وَيُقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَيُؤۡتُواْ ٱلزَّكَوٰةَۚ وَذَٰلِكَ دِينُ ٱلۡقَيِّمَةِ 5
Ẹsẹ ati orikunkun yahuudi ati nasaara si han wipe wọn ko pa wọn lasẹ nkankan ninu Alukuraani yii ayaafi iru ohun ti wọn pa wọn lasẹ ninu iwe wọn nipa ijọsin Allah nikan soso ati jijinna si ẹbọ ati gbigbe irun duro ati yiyọ zaka, ohun ti wọn pa wọn lasẹ rẹ gan ni ẹsin ti o duro tọ, ti ko si iwọgun nibẹ.
Ọla ti nbẹ fun oru ipebubu lori gbogbo awọn oru ọdun.
Sise afọmọ nibi ijọsin wa ninu awọn majẹmu itẹwọgba rẹ.
Pipapọ awọn ofin nibi awọn ipilẹ wa ninu ohun ti o peni lọ sibi isẹ riran.