وَأَسِرُّواْ قَوۡلَكُمۡ أَوِ ٱجۡهَرُواْ بِهِۦٓۖ إِنَّهُۥ عَلِيمُۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ 13
Ẹ fi gbolohun wọn pamọ - ẹyin eniyan - tabi ẹ gbe soke, Allah mọ ọ, dajudaju Oun ti mimọ nbẹ fun onimimọ nipa ohun ti nbẹ ninu ọkan awọn ẹru Rẹ, nkankan ko pamọ fun Un ninu eleyi.
أَلَا يَعۡلَمُ مَنۡ خَلَقَ وَهُوَ ٱللَّطِيفُ ٱلۡخَبِيرُ 14
Se ẹniti o da gbogbo ẹda ko wa mọ kọkọ ati nkan ti o pamọ ni kọkọ ni?! Oun ni alaanu si awọn ẹru Rẹ, olufini niro alamọri wọn, nkankan ko pamọ fun Un nibẹ.
هُوَ ٱلَّذِي جَعَلَ لَكُمُ ٱلۡأَرۡضَ ذَلُولٗا فَٱمۡشُواْ فِي مَنَاكِبِهَا وَكُلُواْ مِن رِّزۡقِهِۦۖ وَإِلَيۡهِ ٱلنُّشُورُ 15
Oun ni o se ilẹ ni irọrun fun ibugbe lori rẹ fun yin, ki ẹ rin ni awọn ẹgbẹẹgbẹ rẹ ati eteeti rẹ, ki ẹ si maa jẹ ninu arisiki eyiti o pese fun yin nibẹ, ọdọ rẹ nikan si ni ajinde yin fun isiro ati ẹsan.
ءَأَمِنتُم مَّن فِي ٱلسَّمَآءِ أَن يَخۡسِفَ بِكُمُ ٱلۡأَرۡضَ فَإِذَا هِيَ تَمُورُ 16
Se ẹ fi ọkan balẹ si Allah ti o wa ni sanmọ wipe ko le mu ilẹ san ni abẹ yin gẹgẹ bi o se mu san ni abẹ Qọruna lẹyin igba ti o ti jẹ irọrun, ti o lẹ fun ibugbe le lori, ti yoo wa ma min mọ yin lẹyin igbati o ti rinlẹ?!
أَمۡ أَمِنتُم مَّن فِي ٱلسَّمَآءِ أَن يُرۡسِلَ عَلَيۡكُمۡ حَاصِبٗاۖ فَسَتَعۡلَمُونَ كَيۡفَ نَذِيرِ 17
Tabi ẹ fi aya balẹ si Allah ti o nbẹ ni sanmọ wipe ko le gbe okuta dide le yin lori lati sanmọ gẹgẹ bi o se gbe dide lori ijọ Luuth ni?! ẹ o pada mọ nigbati ẹ ba nfi ara kin iya mi ati ikilọ mi fun yin, sugbọn ẹyin ko le se anfaani pẹlu rẹ lẹyin igbati ẹ ba ti fi oju ri iya naa.
وَلَقَدۡ كَذَّبَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡ فَكَيۡفَ كَانَ نَكِيرِ 18
Paapaa awọn ijọ ti wọn siwaju, awọn ẹlẹbọ yii ti parọ, iya Allah si sọkalẹ le wọn lori nigbati wọn taku lori keferi wọn ati irọ pipa wọn, bawo ni ikorira mi le wọn lori yoo se ri?! Paapaa o jẹ ikorira ti o le.
أَوَ لَمۡ يَرَوۡاْ إِلَى ٱلطَّيۡرِ فَوۡقَهُمۡ صَٰٓفَّٰتٖ وَيَقۡبِضۡنَۚ مَا يُمۡسِكُهُنَّ إِلَّا ٱلرَّحۡمَٰنُۚ إِنَّهُۥ بِكُلِّ شَيۡءِۢ بَصِيرٌ 19
Se awọn opurọ yii ko fi oju ri ẹyẹ ti o wa loke wọn nigbati o nfo, ti o si tẹ iyẹ rẹ ninu atẹgun nigba miran, ti yoo si ka a jọ ni asiko miran, ko si ohun ti o mu wọn duro ti wọn ko fi bọ si ori ilẹ ju Allah lọ, dajudaju O jẹ oluri gbogbo nkan, nkankan ko pamọ fun Un nibẹ.
أَمَّنۡ هَٰذَا ٱلَّذِي هُوَ جُندٞ لَّكُمۡ يَنصُرُكُم مِّن دُونِ ٱلرَّحۡمَٰنِۚ إِنِ ٱلۡكَٰفِرُونَ إِلَّا فِي غُرُورٍ 20
Ko si ọmọ ogun fun yin -ẹyin keferi- ti yoo kọ fun yin kuro nibi iya Allah nigbatgi o ba gbero lati fi iya jẹ yin, awọn keferi ko jẹ nkankan ju ẹni igbatanjẹ lọ, esu tan wọn jẹ, wọn si gba itanjẹ pẹlu rẹ.
أَمَّنۡ هَٰذَا ٱلَّذِي يَرۡزُقُكُمۡ إِنۡ أَمۡسَكَ رِزۡقَهُۥۚ بَل لَّجُّواْ فِي عُتُوّٖ وَنُفُورٍ 21
Ko si ẹnikankan ti yoo se aranse fun yin ti Allah ba kọ aranse lati de ọdọ yin, bikosepe ohun ti o sẹlẹ nipe awọn keferi ntẹsiwaju nibi orikunkun ati igberaga ati kikọ ododo.
أَفَمَن يَمۡشِي مُكِبًّا عَلَىٰ وَجۡهِهِۦٓ أَهۡدَىٰٓ أَمَّن يَمۡشِي سَوِيًّا عَلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ 22
Se ẹniti o nrin ni ọgbun ojupọnna rẹ: ti o si wo mọ - oun si ni ẹlẹbọ - ni o mọna ni tabi olugbagbọ ododo, ti o nrin dọgba lori oju ọna ti o dọgba?
قُلۡ هُوَ ٱلَّذِيٓ أَنشَأَكُمۡ وَجَعَلَ لَكُمُ ٱلسَّمۡعَ وَٱلۡأَبۡصَٰرَ وَٱلۡأَفِۡٔدَةَۚ قَلِيلٗا مَّا تَشۡكُرُونَ 23
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn ẹlẹbọ opurọ wọnyi: Allah Oun ni ẹniti O da yin, O si se awọn igbọran fun yin ti ẹ fi ngbọran ati awọn iriran ti ẹ fi nriran ati awọn ọkan ti ẹ fi nse laakaye pẹlu rẹ, o kere nigbati ẹ ndupẹ lori awọn idẹkun Rẹ eyiti o se fun yin.
قُلۡ هُوَ ٱلَّذِي ذَرَأَكُمۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَإِلَيۡهِ تُحۡشَرُونَ 24
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn ẹlẹbọ opurọ wọnyi: Allah ni ẹniti o nmu yin bẹ ni orilẹ, o si fan yin ka sibẹ, kii se awọn oosa yin ti wọn ko le da nkankan, ọdọ Rẹ nikan ni ẹ o si kojọ si fun isiro ati ẹsan ni ọjọ igbende, kii se ọdọ awọn ẹbọ yin, ki ẹ ya bẹru Rẹ, ki ẹ si maa sin lohun nikan.
وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا ٱلۡوَعۡدُ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ 25
Awọn ti wọn npe ajinde nirọ sọpe: niti titi ajinde jinna siwaju: nigba wo ni adehun yii eyiti o se fun wa - irẹ Muhammad - iwọ ati awọn eniyan rẹ ti o ba jẹ olododo nibi apemọra yin wipe o nbọ?!
قُلۡ إِنَّمَا ٱلۡعِلۡمُ عِندَ ٱللَّهِ وَإِنَّمَآ أَنَا۠ نَذِيرٞ مُّبِينٞ 26
Sọ wipe - irẹ ojisẹ -: dajuidaju imọ asiko ikẹyin wa lọdọ Allah, ẹnikan ko mọ igbati yoo sẹlẹ ayaafi Oun naa atipe dajudaju emi jẹ olusekilọ ti o fi oju han nibi ikilọ mi fun yin.
Riri Allah si ohun ti o pamọ ni agbaaya awọn ẹru Rẹ.
Keferi ati awọn ẹsẹ wa ninu okunfa nini ẹtọ si iya Allah laye ati lọrun.
Sise keferi si Allah jẹ okunkun ati idaamun, nini igbagbọ si I si jẹ imọlẹ ati imọna.