وَأَنَا ٱخۡتَرۡتُكَ فَٱسۡتَمِعۡ لِمَا يُوحَىٰٓ 13
Emi ni mo sa ọ lẹsa - irẹ Musa - ki o le mu isẹ mi de ogongo, ki o tẹti gbọ imisi ti a fi ransẹ si ọ.
إِنَّنِيٓ أَنَا ٱللَّهُ لَآ إِلَٰهَ إِلَّآ أَنَا۠ فَٱعۡبُدۡنِي وَأَقِمِ ٱلصَّلَوٰةَ لِذِكۡرِيٓ 14
Dajudaju Emi ni Allah ko si olujọsin fun niti ododo yatọ si Mi, maa sin Mi ni Emi nikan soso, ki o si maa kirun ni ojupọnna ti o pe, ki o le maa ranti Mi ninu rẹ.
إِنَّ ٱلسَّاعَةَ ءَاتِيَةٌ أَكَادُ أُخۡفِيهَا لِتُجۡزَىٰ كُلُّ نَفۡسِۢ بِمَا تَسۡعَىٰ 15
Dajudaju igbende yoo wa, ko si ibuyẹ bẹẹ ni yoo si sẹlẹ, mo fẹẹ le fi pamọ ti ẹda kankan ko nii le mọ asiko rẹ, sugbọn wọn yoo mọ awọn amin rẹ lati ibi iro awọn anọbi fun wọn; sugbọn wọn yoo san gbogbo ẹmin ni ẹsan ohun ti o ba se, rere ni o jẹ ni tabi aburu.
فَلَا يَصُدَّنَّكَ عَنۡهَا مَن لَّا يُؤۡمِنُ بِهَا وَٱتَّبَعَ هَوَىٰهُ فَتَرۡدَىٰ 16
Ẹniti ko nigbagbọ ninu rẹ ninu awọn keferi ko gbọdọ yi ọ kuro nibi gbigba a lododo ati mimura silẹ nibi isẹẹre, o si tẹle ohun ti ẹmin rẹ nfẹ ninu awọn nkan eewọ, ti yoo wa fi parun pẹlu idi eleyi.
وَمَا تِلۡكَ بِيَمِينِكَ يَٰمُوسَىٰ 17
Ewo ni eyi ti o wa ni ọwọ rẹ ọtun irẹ Musa?
قَالَ هِيَ عَصَايَ أَتَوَكَّؤُاْ عَلَيۡهَا وَأَهُشُّ بِهَا عَلَىٰ غَنَمِي وَلِيَ فِيهَا مََٔارِبُ أُخۡرَىٰ 18
Musa ẹniti ọla nbẹ fun sọpe: ọpa mi ni, mo nrọgbọku le lori nigbati mo ba nrin, mo si fi nlu igi ki ewe rẹ le jabọ fun awọn ẹran mi, bakanna ni anfaani miran nbẹ nibẹ fun mi yatọ si eyiti mo darukọ.
قَالَ أَلۡقِهَا يَٰمُوسَىٰ 19
Ọlọhun Ọba Allah sọpe: ju silẹ irẹ Musa.
فَأَلۡقَىٰهَا فَإِذَا هِيَ حَيَّةٞ تَسۡعَىٰ 20
Musa si juu silẹ, o yi pada si ejo ti nlọ ni yara yara ati ni ipamọ.
قَالَ خُذۡهَا وَلَا تَخَفۡۖ سَنُعِيدُهَا سِيرَتَهَا ٱلۡأُولَىٰ 21
Ọlọhun Allah sọ fun Musa ti ọla nbẹ fun: gba ọpa naa mu, mase paya yiyi pada rẹ si ejo, a o da a pada nigbati o ba gba a mu si issesi rẹ ti o wa ni akọkọ.
وَٱضۡمُمۡ يَدَكَ إِلَىٰ جَنَاحِكَ تَخۡرُجۡ بَيۡضَآءَ مِنۡ غَيۡرِ سُوٓءٍ ءَايَةً أُخۡرَىٰ 22
Fi ọwọ rẹ si ẹgbẹ rẹ, yoo jade ni funfun ti kii se ti ẹtẹ; ni amin keji fun ọ.
لِنُرِيَكَ مِنۡ ءَايَٰتِنَا ٱلۡكُبۡرَى 23
A fi awọn amin mejeeji yii han ọ, ki a le jẹ ki o ri - irẹ Musa - ninu awọn amin wa ti o tobi, ti o si ntọka si agbara wa ati lori jijẹ ojisẹ rẹ lati ọdọ Allah.
ٱذۡهَبۡ إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ إِنَّهُۥ طَغَىٰ 24
Rin lọ si - irẹ Musa - ọdọ fir'aona toripe o kọja ẹnu aala nibi keferi ati isori kunkun si Allah.
قَالَ رَبِّ ٱشۡرَحۡ لِي صَدۡرِي 25
Musa ẹniti ọla nbẹ fun sọpe: Ọlọhun mi, fẹ igbaaya mi ki nle maa gba suta mọ ra.
وَيَسِّرۡ لِيٓ أَمۡرِي 26
Rọ alamọri ọrọ mi fun mi.
وَٱحۡلُلۡ عُقۡدَةٗ مِّن لِّسَانِي 27
Fun mi nikapa ki nle maa sọrọ ni idantọ.
يَفۡقَهُواْ قَوۡلِي 28
Ki wọn le maa gbọ mi ye nigbati mo ba mu isẹ de etigbọ wọn.
وَٱجۡعَل لِّي وَزِيرٗا مِّنۡ أَهۡلِي 29
Se oluranlọwọ fun mi ninu ara ile mi, ti yoo ran mi lọwọ nibi alamọri ọrọ mi.
هَٰرُونَ أَخِي 30
Haruuna ọmọ Imran ọmọ iya mi.
ٱشۡدُدۡ بِهِۦٓ أَزۡرِي 31
Ki o fi fun mi lagbara.
وَأَشۡرِكۡهُ فِيٓ أَمۡرِي 32
Jẹ ki o jẹ akẹgbẹ fun mi nibi isẹ riran naa.
كَيۡ نُسَبِّحَكَ كَثِيرٗا 33
Ki a le maa se afọmọ fun Ọ ni ise afọmọ ti o pọ.
وَنَذۡكُرَكَ كَثِيرًا 34
Ki a si le maa ranti Rẹ ni iranti ti o pọ.
إِنَّكَ كُنتَ بِنَا بَصِيرٗا 35
Dajudaju Iwọ jẹ ẹniti O riran ri wa, nkankan ko pamọ fun Ọ nibi alamọri ọrọ wa.
قَالَ قَدۡ أُوتِيتَ سُؤۡلَكَ يَٰمُوسَىٰ 36
Ọlọhun Ọba Allah sọpe: paapaa a ti fun ọ ni ohun ti o beere irẹ Musa.
وَلَقَدۡ مَنَنَّا عَلَيۡكَ مَرَّةً أُخۡرَىٰٓ 37
Paapaa bẹẹ ni a ti se idẹkun Wa fun ọ ni igba miran.
Jijẹ dandan itẹtigbọ awọn alamọri ti o pataki daadaa eyiti o pataki ju nibẹ ni imisi ti asọkalẹ lati ọdọ Allah.
Akọkọ imisi ko jọ lori Musa nipa ipilẹ meji nibi adisọkan, awọn naa si ni: fifi imọ Ọlọhun Allah lọkan rinlẹ ati nini igbagbọ si ọjọ ikẹyin (igbende) ati lori ọranyan ti o pataki lẹyin igbagbọ ohun si ni irun kiki.
Ikunra ẹni lọwọ laarin awọn olupepe jẹ dandan nitori aseyọri erongba naa; Ọlọhun Allah ti se Haruna tii se ọmọ iya Musa ni anọbi ki o le ba kun lọwọ nibi jijẹ isẹ naa.
Pataki ki olupepe ni ikapa idantọ lati fi agbọye fun ti o npe.