أَمۡ يَقُولُونَ ٱفۡتَرَىٰهُۖ قُلۡ فَأۡتُواْ بِعَشۡرِ سُوَرٖ مِّثۡلِهِۦ مُفۡتَرَيَٰتٖ وَٱدۡعُواْ مَنِ ٱسۡتَطَعۡتُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ 13
Tabi awọn ẹlẹbọ yoo maa sọ wipe: Muhammad hun Alukuraani ni, kii se imisi lati ọdọ Allah, sọ wipe - ire ojise - ni ẹniti o npe wọn nija: ki ẹ mu suura mẹwa ti o se deede Alukuraani yii ti ẹ hun, ti ẹ ko ni so ijẹ ododo rẹ mọ Alukuraani eyiti ẹ nlero wipe nkan ti a hun ni, ki ẹ wa pe ẹniti ẹ ba nikapa lati pe; ki ẹ le wa iranlọwọ pẹlu rẹ lori eleyi ti ẹ ba jẹ sootọ sootọ nibi pipe Alukuraani ni ohun ti a hun.
فَإِلَّمۡ يَسۡتَجِيبُواْ لَكُمۡ فَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّمَآ أُنزِلَ بِعِلۡمِ ٱللَّهِ وَأَن لَّآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۖ فَهَلۡ أَنتُم مُّسۡلِمُونَ 14
Ti ẹ ko ba le mu wa nkan ti ẹ beere lọdọ wọn nitori ailagbara rẹ wọn, ki ẹ yaa lọ mọ - ẹyin olugbagbọ ododo - imọ amọdaju wipe Alukuraani Ọlọhun Ọba ni O sọ kalẹ pẹlu imọ Rẹ fun ojisẹ Rẹ kii se nkan ti a da, ki ẹ si mọ wipe ko si ẹniti ijọsin tọsi lododo yatọ si Allah, njẹ ẹyin yoo tẹriba fun Un lẹyin awọn awijare ti o mun yii?
مَن كَانَ يُرِيدُ ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا وَزِينَتَهَا نُوَفِّ إِلَيۡهِمۡ أَعۡمَٰلَهُمۡ فِيهَا وَهُمۡ فِيهَا لَا يُبۡخَسُونَ 15
Ẹniti o ba ngbero nibi isẹ rẹ, isẹmin aye ati igbadun ti yoo tan, ti ko si gbero ọrun pẹlu rẹ, a o fun wọn ni ẹsan isẹ wọn laye, alaafia ati ifọkanbalẹ ati gbigbaaye arisiki, wọn ko ni din nkankan ku nibi ẹsan isẹ wọn rara.
أُوْلَٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ لَيۡسَ لَهُمۡ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ إِلَّا ٱلنَّارُۖ وَحَبِطَ مَا صَنَعُواْ فِيهَا وَبَٰطِلٞ مَّا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ 16
Awọn ni a royin pẹlu erongba eebu yii, ko si ẹsan kankan fun wọn ni ọjọ igbende ayaafi ina ti wọn yoo wọ, ẹsan isẹ wọn yoo bọ mọ wọn lọwọ, bẹẹ ni awọn isẹ wọn yoo si bajẹ; toripe wọn ko fi igbagbọ siwaju rẹ ati erongba ti o dara, wọn ko fi wa oju rere Ọlọhun ati ile ọrun.
أَفَمَن كَانَ عَلَىٰ بَيِّنَةٖ مِّن رَّبِّهِۦ وَيَتۡلُوهُ شَاهِدٞ مِّنۡهُ وَمِن قَبۡلِهِۦ كِتَٰبُ مُوسَىٰٓ إِمَامٗا وَرَحۡمَةًۚ أُوْلَٰٓئِكَ يُؤۡمِنُونَ بِهِۦۚ وَمَن يَكۡفُرۡ بِهِۦ مِنَ ٱلۡأَحۡزَابِ فَٱلنَّارُ مَوۡعِدُهُۥۚ فَلَا تَكُ فِي مِرۡيَةٖ مِّنۡهُۚ إِنَّهُ ٱلۡحَقُّ مِن رَّبِّكَ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يُؤۡمِنُونَ 17
A ko le fi anọbi Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, ti o si ni awijare lati ọdọ Ọlọhun Ọba rẹ ti O ga, ti olujẹri si tun tẹle lati ọdọ Ọlọhun Ọba rẹ tii se Jibirilu, ti taoreeta si jẹri gbe e siwaju jijẹ anọbi rẹ eyiti wọn sọkalẹ fun Musa ẹniti alaafia nbẹ fun ti o jẹ awokọse fun awọn eniyan ati ikẹ wọn, a ko le fi we ati ẹniti o nigbagbọ pẹlu rẹ awọn keferi ti o ntẹsẹ bọsẹ ni ọna anu, awọn wọnyi ni wọn nigbagbọ si Alukuraani ati Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, ti a sọ alukuraani kalẹ fun, bẹẹ ni ẹniti o ba se keferi pẹlu rẹ ninu awọn ẹni oju opo miran, ina ni adehun rẹ ni ọjọ igbende, mase jẹ -ire ojise- ẹniti yoo wa inu iyemeji nipa Alukuraani ati si adehun wọn ohun ni ododo ti ko si iyemeji nibẹ sugbọn ọpọ awọn eniyan wọn ko nigbagbọ pẹlu pipọ awọn ẹri ti o fi oju han ati awọn awijare ti o gbọngbọn.
وَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّنِ ٱفۡتَرَىٰ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبًاۚ أُوْلَٰٓئِكَ يُعۡرَضُونَ عَلَىٰ رَبِّهِمۡ وَيَقُولُ ٱلۡأَشۡهَٰدُ هَٰٓؤُلَآءِ ٱلَّذِينَ كَذَبُواْ عَلَىٰ رَبِّهِمۡۚ أَلَا لَعۡنَةُ ٱللَّهِ عَلَى ٱلظَّٰلِمِينَ 18
Ko si ẹniti o se abosi to ẹniti o hun irọ mọ Ọlọhun Ọba Allah nibi sise afiti orogun tabi ọmọ ti si I, awọn wọnyi ni wọn hun irọ jọ mọ Ọlọhun Ọba, wọn yoo sẹri wọn si ọdọ Ọlọhun Ọba wọn ni ọjọ igbende ki O le bi wọn leere isẹẹ wọn, awọn malaika ati awọn ojisẹ yoo maa sọrọ ni ẹlẹri le wọn lori: awọn wọnyi ni ẹniti o parọ mọ Ọlọhun Ọba Allah nitori orogun ati ọmọ ti wọn fi ti si I lọdọ, se Ọlọhun Ọba Allah ko waa ni le wọn kuro nibi ikẹ Rẹ, awọn ti wọn jẹ alabosi si ẹmin ara wọn latara irọ ti wọn pa mọ Ọlọhun Ọba Allah.
ٱلَّذِينَ يَصُدُّونَ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ وَيَبۡغُونَهَا عِوَجٗا وَهُم بِٱلۡأٓخِرَةِ هُمۡ كَٰفِرُونَ 19
Awọn ti wọn kọ fun awọn eniyan kuro ni oju ọna Allah ti o duro tọ, ti wọn si nwa iwọgun fun oju ọna Rẹ kuro nibi idurotọ, ti ẹnikankan ko fi ni le tọ ọ, wọn jẹ ẹniti o se keferi si igbende lẹyin iku, wọn si nja a niyan.
Ọlọhun Ọba Allah ti o ga pe awọn ẹlẹbọ nija pe ki wọn mu ọgba ọrọ mẹwa ti o jọ Alukuraani wa, O si se alaye ikagara wọn lati mu wa.
Ti wọn ba fun keferi ni ohun ti o nfẹ laye ko si nkankan fun mọ ni ọrun ju ina lọ.
Titobi abosi ẹniti o da adapa irọ mọ Ọlọhun Ọba Allah ati titobi ijiya rẹ ni ọjọ igbende.