وَإِنِ ٱمۡرَأَةٌ خَافَتۡ مِنۢ بَعۡلِهَا نُشُوزًا أَوۡ إِعۡرَاضٗا فَلَا جُنَاحَ عَلَيۡهِمَآ أَن يُصۡلِحَا بَيۡنَهُمَا صُلۡحٗاۚ وَٱلصُّلۡحُ خَيۡرٞۗ وَأُحۡضِرَتِ ٱلۡأَنفُسُ ٱلشُّحَّۚ وَإِن تُحۡسِنُواْ وَتَتَّقُواْ فَإِنَّ ٱللَّهَ كَانَ بِمَا تَعۡمَلُونَ خَبِيرٗا 128
Ti obinrin ba npaya isorikunkun ọkọ rẹ ati aini ifokan sii mọ, ko si ẹsẹ fun awọn mejeeji ki wọn se atunse pẹlu apakan wọn sọkalẹ nibi ẹtọ ti o jẹ ọranyan fun un, gẹgẹ bi ẹtọ inawo ati ibusun, sugbọn atunse nibiyi ni o loore ju ikọra ẹni silẹ lọ, paapaa a ti da ojukokoro ati ahun mọ ẹmin, ti ko nii nifẹ si sisọkalẹ kuro nibi ẹtọ ti o tọ sii, o wa tọ fun lọkọ-laya wiwa iwosan fun ẹda naa pẹlu rire ẹmin lori isamojukuro ati daadaa sise. Ti ẹ ba nse daradara nibi gbogbo alamọri ọrọ yin tabi ẹ npaya Ọlọhun Ọba Allah pẹlu titẹle awọn asẹ Rẹ ati jijina si ohun ti O kọ, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah jẹ olufunniro nkan ti ẹ nse, nkankan ko pamọ fun Un, bẹẹni Yoo si san yin lẹsan le lori.
وَلَن تَسۡتَطِيعُوٓاْ أَن تَعۡدِلُواْ بَيۡنَ ٱلنِّسَآءِ وَلَوۡ حَرَصۡتُمۡۖ فَلَا تَمِيلُواْ كُلَّ ٱلۡمَيۡلِ فَتَذَرُوهَا كَٱلۡمُعَلَّقَةِۚ وَإِن تُصۡلِحُواْ وَتَتَّقُواْ فَإِنَّ ٱللَّهَ كَانَ غَفُورٗا رَّحِيمٗا 129
Ẹ ko lee se - ẹyin ọkọ iyawo - lati le se deede ti o pe pẹlu awọn iyawo naa nibi fifi si ọkan, koda biu ẹ se oju kokoro sii; pẹlu okunfa ti o le wa lẹyin erongba yin, ẹ ko gbọdọ fi niti fifi kuro ni ọdọ ẹniti ẹ ko nifẹ sii, ti ẹ yoo fi wa gbe ju silẹ gẹgẹ bi ẹniti a pa ti, ko nii lọkọ ti yoo mojuto ẹtọ rẹ, ko si nii wa ni ẹniti ko ni ọkọ, ti yoo le maa nagasi nini ọkọ, ti ẹ ba se atunse ohun ti nbẹ laarin yin pẹlu ki mu ọkan lati le se ẹtọ obinrin eyiti ọkan yin ko nifẹ si, ki ẹ bẹru ỌLọhun Ọba Allah nipa rẹ, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah jẹ oluforijin, olukẹni si yin.
وَإِن يَتَفَرَّقَا يُغۡنِ ٱللَّهُ كُلّٗا مِّن سَعَتِهِۦۚ وَكَانَ ٱللَّهُ وَٰسِعًا حَكِيمٗا 130
Ti ọkọ ati iyawo ba pin ya pẹlu ikọra ẹni silẹ tabi iyawo ni o nyọ ara rẹ, Ọlọhun Ọba Allah yoo to ikini-keji wọn ninu ọla Rẹ ti o gbaaye, Ọlọhun Ọba Allah jẹ olugbaaye ni ọla ati ikẹ, ọjọgbọn nibi idari ati ipebubu Rẹ.
وَلِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۗ وَلَقَدۡ وَصَّيۡنَا ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ مِن قَبۡلِكُمۡ وَإِيَّاكُمۡ أَنِ ٱتَّقُواْ ٱللَّهَۚ وَإِن تَكۡفُرُواْ فَإِنَّ لِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۚ وَكَانَ ٱللَّهُ غَنِيًّا حَمِيدٗا 131
Ọlọhun Ọba Allah nikan ni o ni ikapa ohun ti nbẹ ni sanmọ ati ilẹ, O si tun ni ikapa ohun ti nbẹ laarin mejeeji, paapaa ati gba adehun ni ọdọ awọn onitira bii yahuudi ati nasaara, a si gba adehun ni ọdọ ti yin pẹlu titẹle awọn asẹ Allah ati jijina si awọn nkan ti O kọ, ti ẹ ba se aimoore si adehun naa, ko le ko inira ba ẹnikankan ju ẹmin yin lọ, Ọlọhun Ọba Allah rọrọ ju itẹle asẹ yin lọ, Oun ni O ni ikapa ohun ti nbẹ ni sanmọ ati ilẹ, Oun ni O si rọrọ ju gbogbo awọn ẹda Rẹ lọ, Oun ni ẹniti ọpẹ tọ si lori gbogbo iroyin Rẹ ati isẹ Rẹ.
وَلِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۚ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ وَكِيلًا 132
Ọlọhun Ọba Allah nikan ni o ni ọla gbogbo ohun ti nbẹ ni sanmọ ati ilẹ, Oun ni O si tọ lati tẹle, Ọlọhun Ọba Allah to ni alatilẹyin nibi didari gbogbo alamọri ọrọ ẹda Rẹ.
إِن يَشَأۡ يُذۡهِبۡكُمۡ أَيُّهَا ٱلنَّاسُ وَيَأۡتِ بَِٔاخَرِينَۚ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلَىٰ ذَٰلِكَ قَدِيرٗا 133
Ti O ba fẹ, O le pa yin run - ẹyin eniyan -, Yoo si mu ẹlomiran wa ti o yatọ si yin, ti yoo maa tẹle asẹ Rẹ, ti ko nii yapa Rẹ, Ọlọhun Ọba Allah jẹ alagbara lori eleyi.
مَّن كَانَ يُرِيدُ ثَوَابَ ٱلدُّنۡيَا فَعِندَ ٱللَّهِ ثَوَابُ ٱلدُّنۡيَا وَٱلۡأٓخِرَةِۚ وَكَانَ ٱللَّهُ سَمِيعَۢا بَصِيرٗا 134
Ẹnikẹni ninu yin ti o ba jẹ wipe - ẹyin eniyan - o gbero ẹsan aye nikan pẹlu isẹ rẹ, ki o mọ wipe dajudaju ẹsan aye ati ọrun nbẹ ni ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, ki o le ba wa ẹsan mejeeji ni ọdọ Rẹ, Ọlọhun Ọba Allah jẹ olugbọ gbogbo ọrọ yin, oluri gbogbo isẹ yin, yoo si san yin ni ẹsan le lori.
Ninifẹ si sise atunse laarin lọkọ-laya ni igba ifanfa ati gbigbe ọla fun atunse pẹlu sisọkalẹ kuro nibi apakan ẹtọ nitori itẹsiwaju koko lọkọ-laya.
Ọlọhun Ọba Allah se deede ni dandan laarin lọkọ-laya pataki julọ nibi awọn alamọri nkan nina eyiti o wa ni ikapa awọn ọkọ ati sise lofin amoju kuro nigbati deede nibi awọn nkan ti ko se fi oju ri ba kọlẹ gẹgẹ bi ifẹ, fifi ọkan.
Ko si laifi laarin lọkọ-laya lati pinya nigbati ibasepọ ko ba gunmọ laarin wọn.
Asọtẹlẹ alakotan fun gbogbo ẹda, akọkọ inu wọn ati ẹnikẹyin wọn, ohun ni alamọri ipaya Ọlọhun Ọba Allah pẹlu titẹle awọn asẹ ati jijina si ohun ti O kọ.