فَكَذَّبُوهُ فَإِنَّهُمۡ لَمُحۡضَرُونَ 127
Nkankan ko wa lati ọdọ awọn ijọ rẹ ayaafi ki wọn pe e nirọ nitori pipe wọn nirọ wọn yoo si pesẹ ninu iya naa.
إِلَّا عِبَادَ ٱللَّهِ ٱلۡمُخۡلَصِينَ 128
Ayaafi ẹniti o ba jẹ olugbagbọ ododo alafọmọ fun Allah nibi awọn ijọsin rẹ ninu awọn ijọ rẹ; dajudaju oun ni ẹniti yoo la nibi pipeju si inu iya naa.
وَتَرَكۡنَا عَلَيۡهِ فِي ٱلۡأٓخِرِينَ 129
A si sẹ ẹyin ti o dara ku fun un ati iranti o dun ninu awọn ijọ ti o tẹle e.
سَلَٰمٌ عَلَىٰٓ إِلۡ يَاسِينَ 130
Ikini lati ọdọ Allah ati ẹyin fun Iliyaas.
إِنَّا كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ 131
Dajudaju Awa gẹgẹbi a se san iliyaas lẹsan daadaa yii, a o maa sẹsan fun awọn oluse daadaa ti wọn jẹ olugbagbọ ododo.
إِنَّهُۥ مِنۡ عِبَادِنَا ٱلۡمُؤۡمِنِينَ 132
Dajudaju iliyaas wa ninu awọn ẹru Wa olugbagbọ ododo tootọ, awọn sootọ sootọ nibi igbagbọ wọn si Ọlọhun Ọba wọn.
وَإِنَّ لُوطٗا لَّمِنَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ 133
Atipe dajudaju Luuth wa ninu awọn ojisẹ Allah ati ti Allah ran si ijọ wọn ni ilufunniro idunnu ati olukilọ fun ni.
إِذۡ نَجَّيۡنَٰهُ وَأَهۡلَهُۥٓ أَجۡمَعِينَ 134
Tun ranti nigbati a la a ati gbogbo awọn ara ile rẹ kuro nibi iya eyiti a ran si awọn ijọ rẹ.
إِلَّا عَجُوزٗا فِي ٱلۡغَٰبِرِينَ 135
Ayaafi iyawo rẹ paapaa o jẹ obinrin ti iya awọn ijọ rẹ naa ko sinu; nitori o jẹ keferi gẹgẹ bi wọn.
ثُمَّ دَمَّرۡنَا ٱلۡأٓخَرِينَ 136
Lẹyin naa a tun pa awọn ti o sẹku ninu awọn ijọ rẹ run ninu awọn ti wọn pe e nirọ, ti wọn ko si gba ohun ti o mu wa lododo.
وَإِنَّكُمۡ لَتَمُرُّونَ عَلَيۡهِم مُّصۡبِحِينَ 137
Dajudaju ẹyin - ara Mẹkkah - ẹ o maa re kọja nibi awọn ibugbe wọn nibi irin ajo yin lọsi Saamu ni asiko aarọ.
وَبِٱلَّيۡلِۚ أَفَلَا تَعۡقِلُونَ 138
Bẹẹni ẹ o maa re kọja nibẹ bakkanaa ni alẹ se ẹ ko se laakaye ni, ki ẹ si gba isiti ohun ti ọrọ wọn pada sẹri si lẹyin pipe wọn nirọ ati sise keferi wọn ati sise ibajẹ wọn ti ẹnikankan ko tii gbawaju lọsi ibẹ?!
وَإِنَّ يُونُسَ لَمِنَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ 139
Dajudaju ẹru wa yuunus wa ninu awọn ojisẹ Allah awọn ti a ransẹ si awọn ijọ wọn ni olufunni ni iro idunnu ati olukilọ.
إِذۡ أَبَقَ إِلَى ٱلۡفُلۡكِ ٱلۡمَشۡحُونِ 140
Nigbati a sa kuro ni ọdọ awọn ijọ rẹ laigba iyọnda ni ọdọ Ọlọhun Ọba rẹ, ti o si gun ọkọ oju omin ti o kun fun ero ati dukia.
فَسَاهَمَ فَكَانَ مِنَ ٱلۡمُدۡحَضِينَ 141
Ọkọ oju omin naa fẹẹ ri nitori kikun rẹ, awọn ti o gun un wa mu imọran jiju apakan wọn nu; niti ipaya kuro nibi riri ọkọ oju omin naa nitori pipọ ero, yuunus si wa ninu awọn ti ọwọ tẹ, wọn si ju u sinu odo.
فَٱلۡتَقَمَهُ ٱلۡحُوتُ وَهُوَ مُلِيمٞ 142
Nigbati wọn ju u sinu odo, ọja si gbe e, o si mi in, o si wa pẹlu ohun ti wọn bu le lori; nitoripe o lọ si inu omin laigba iyọnda Ọlọhun Ọba rẹ.
فَلَوۡلَآ أَنَّهُۥ كَانَ مِنَ ٱلۡمُسَبِّحِينَ 143
Ti kii ba sepe Yuunus wa ninu awọn oluranti Allah ni ọpọlọpọ siwaju ohun ti o sẹlẹ si i ati wipe ti kii ba se afọmọ rẹ ninu ẹja.
لَلَبِثَ فِي بَطۡنِهِۦٓ إِلَىٰ يَوۡمِ يُبۡعَثُونَ 144
Ki baa maa wa ninu ẹja naa titi di ọjọ igbende.
۞فَنَبَذۡنَٰهُ بِٱلۡعَرَآءِ وَهُوَ سَقِيمٞ 145
A ju u lati inu ẹja si ori ilẹ ti o pa lofo kuro nibi igi ati ile ni ẹniti ara rẹ ti lẹ nitori lilo asiko kan ninu ẹja.
وَأَنۢبَتۡنَا عَلَيۡهِ شَجَرَةٗ مِّن يَقۡطِينٖ 146
A si mu igi ti o pa lofo kuro nibi eso ti a le ri iboji tabi jẹ nibẹ ni ori ilẹ naa jade ni ori ilẹ naa.
وَأَرۡسَلۡنَٰهُ إِلَىٰ مِاْئَةِ أَلۡفٍ أَوۡ يَزِيدُونَ 147
A si ran si awọn ijọ rẹ, onka wọn si ni ọgọrun ni ọna ẹgbẹrun, koda wọn si lekun.
فََٔامَنُواْ فَمَتَّعۡنَٰهُمۡ إِلَىٰ حِينٖ 148
Wọn nigbagbọ, wọn si gba ohun ti o mu wa lododo, Allah si mu idẹkun ba wọn ni isẹmin aye wọn titi di igbati asiko ti wọn se ni aala fun wọn tan.
فَٱسۡتَفۡتِهِمۡ أَلِرَبِّكَ ٱلۡبَنَاتُ وَلَهُمُ ٱلۡبَنُونَ 149
Ki o ya beere - irẹ Muhammad - lọwọ awọn ẹlẹbọ ni ibeere ikorira: se ẹ o maa fi ọmọbinrin ẹyiti ẹyin korira ti si ọdọ Allah ni, ti ẹ o si maa fi awọn ọmọkunrin ti ẹ nifẹ si ti si ọdọ ara yin bi?! Iru ipin ewo ni eleyi?!
أَمۡ خَلَقۡنَا ٱلۡمَلَٰٓئِكَةَ إِنَٰثٗا وَهُمۡ شَٰهِدُونَ 150
Bawo ni wọn se lero wipe awọn Malaaika jẹ ọmọkunrin, ti wọn ko si le mu ẹda ti wọn wa ati ohun ti wọn nri?!
أَلَآ إِنَّهُم مِّنۡ إِفۡكِهِمۡ لَيَقُولُونَ 151
ẹ tẹti gbọ dajudaju awọn ẹlẹbọ nibi irọ wọn ti wọn pa mọ Allah ati adapa irọ wọn.
وَلَدَ ٱللَّهُ وَإِنَّهُمۡ لَكَٰذِبُونَ 152
Wọn nse afiti ọmọkunrin si ọdọ Rẹ, dajudaju opurọ si ni wọn nibi ohun ti wọn npe apemọra rẹ yii.
أَصۡطَفَى ٱلۡبَنَاتِ عَلَى ٱلۡبَنِينَ 153
Se Allah ni o sa awọn ọmọbinrin lẹsa eyiti ẹ nkorira rẹ lori awọn ọmọkunrin eyiti ẹ nifẹ si bi?! ọrọ ko ri bẹẹ.
Isesi Allah eyiti kii parada, ti kii si yi: ohun ni lila awọn olugbagbọ ododo ati pipa awọn keferi run.
Jijẹ dandan isiti ati wiwoye pẹlu ibudarisi awọn ti wọn ba pe awọn ojisẹ nirọ, ki iru ohun ti o sẹlẹ si ẹlomiran ma baa sẹlẹ si wọn.
Titọ mimuje ninu ofin ẹsin nitori gbolohun Rẹ ti O ga: (فَسَاهَمَ فَكَانَ مِنَ ٱلۡمُدۡحَضِينَ) (o nipin nibẹ, o si wa ninu awọn ẹni ijakulẹ).