وَإِذۡ يَرۡفَعُ إِبۡرَٰهِۧمُ ٱلۡقَوَاعِدَ مِنَ ٱلۡبَيۡتِ وَإِسۡمَٰعِيلُ رَبَّنَا تَقَبَّلۡ مِنَّآۖ إِنَّكَ أَنتَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡعَلِيمُ 127
Ranti - irẹ Anọbi - nigbati Ibraheem ati Isma'eel gbe awọn ipilẹ Kaaba soke, ti awọn mejeeji si sọ wipe - ni itẹriba ati irẹra ẹni nilẹ-: Irẹ Ọlọhun Ọba wa gba awọn isẹ wa lọwọ wa - ninu rẹ naa ni mimọ ile yii- dajudaju iwọ ni ẹniti O le gba adua wa, ẹniti O ni imọ pẹlu awọn adisọkan wa ati awọn isẹ wa.
رَبَّنَا وَٱجۡعَلۡنَا مُسۡلِمَيۡنِ لَكَ وَمِن ذُرِّيَّتِنَآ أُمَّةٗ مُّسۡلِمَةٗ لَّكَ وَأَرِنَا مَنَاسِكَنَا وَتُبۡ عَلَيۡنَآۖ إِنَّكَ أَنتَ ٱلتَّوَّابُ ٱلرَّحِيمُ 128
Irẹ Ọlọhun Ọba wa se awa mejeeji ni olugbafa fun asẹ Rẹ, olutẹriba fun Ọ ti a ko si nii wa orogun kankan pẹlu Rẹ, ki O si se ninu awọn ọmọ wa ni ijọ ti yoo juwọọlẹ fun Ọ, ki O si jẹ ki a mọ ijọsin Rẹ biotiyẹ ki o wa, ki O si se amojukuro nibi asise wa ati awọn aseeto wa nibi itẹle tiRẹ; dajudaju Iwọ ni Ẹniti O ma ngba tituuba ẹniti o ba tuuba ninu awọn ẹru Rẹ, ti O si jẹ onikẹ fun wọn.
رَبَّنَا وَٱبۡعَثۡ فِيهِمۡ رَسُولٗا مِّنۡهُمۡ يَتۡلُواْ عَلَيۡهِمۡ ءَايَٰتِكَ وَيُعَلِّمُهُمُ ٱلۡكِتَٰبَ وَٱلۡحِكۡمَةَ وَيُزَكِّيهِمۡۖ إِنَّكَ أَنتَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ 129
Irẹ Ọlọhun Ọba wa, waa gbe dide si aarin wọn ojisẹ kan laarin wọn ninu arọmọdọmọ Isma'eel, ti yoo maa ka fun wọn awọn aayah Rẹ ti o sọkalẹ, ti yoo si maa kọ wọn ni Alukuraani ati Sunnah, ti yoo si maa mọ wọn kuro nibi ẹbọ ati awọn iwa idọti, Irẹ ni Alagbara ti O ma nbori, Ọjọgbọn ninu awọn isẹ Rẹ ati awọn idajọ Rẹ.
وَمَن يَرۡغَبُ عَن مِّلَّةِ إِبۡرَٰهِۧمَ إِلَّا مَن سَفِهَ نَفۡسَهُۥۚ وَلَقَدِ ٱصۡطَفَيۡنَٰهُ فِي ٱلدُّنۡيَاۖ وَإِنَّهُۥ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ لَمِنَ ٱلصَّٰلِحِينَ 130
Ẹnikankan ko nii gunri kuro nibi ẹsin Ibraheem (ki ọla maa jẹ tirẹ) lọ si ibi eyiti o yatọ si ninu awọn ẹsin ayaafi ẹniti o se abosi ẹmi ara rẹ pẹlu sisọ di omugọ ati irori rẹ ti ko dara pẹlu fifi ododo silẹ lọ si bi anu, ti o si yọnu si pẹlu iyẹpẹrẹ. Paapaa A ti se ẹsa rẹ ni aye nbi, ni ojisẹ ati ọrẹ aayo dajudaju oun ni Ọjọ Ikẹyin yoo wa ninu awọn ẹniire, awọn ti wọn mu ohun ti Ọlọhun Ọba se ni dandan le wọn lori wa, ni ọwọ wọn fi waa tẹ eyiti o ga ninu ipo.
إِذۡ قَالَ لَهُۥ رَبُّهُۥٓ أَسۡلِمۡۖ قَالَ أَسۡلَمۡتُ لِرَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ 131
Ọlọhun Ọba se ẹsa rẹ nitoripe o tete juwọ silẹ nigbati Ọlọhun Ọba rẹ sọ fun wipe: se afọmọ ijọsin fun Mi, ki o si tẹriba fun asẹ Mi, o waa sọ ni ẹniti o nda Ọlọhun Ọba rẹ lohun wipe: mo gba fun Ọlọhun Ọba ti o da awọn ẹru, ti O si nse arisiki fun wọn, ti o si ndari alamọri wọn.
وَوَصَّىٰ بِهَآ إِبۡرَٰهِۧمُ بَنِيهِ وَيَعۡقُوبُ يَٰبَنِيَّ إِنَّ ٱللَّهَ ٱصۡطَفَىٰ لَكُمُ ٱلدِّينَ فَلَا تَمُوتُنَّ إِلَّا وَأَنتُم مُّسۡلِمُونَ 132
Ibraheem waa se isiti fun awọn ọmọ rẹ pẹlu gbolohun yii: (أَسۡلَمۡتُ لِرَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ) (mo gbafa fun Ọlọhun Ọba ti ntọju gbogbo ẹda) , bakanna ni Yaquub se isiti fun awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ, awọn mejeeji waa sọ ni ẹniti npe awọn ọmọ awọn mejeeji: dajudaju Ọlọhun Ọba se ẹsa islam fun yin ni ẹsa, ẹ gbamu sinsin titi ti iku yoo fi waa ba yin, ti ẹyin yoo si jẹ ẹniti yoo gbafa fun Ọlọhun Ọba ni gbangba ati ni kọkọ.
أَمۡ كُنتُمۡ شُهَدَآءَ إِذۡ حَضَرَ يَعۡقُوبَ ٱلۡمَوۡتُ إِذۡ قَالَ لِبَنِيهِ مَا تَعۡبُدُونَ مِنۢ بَعۡدِيۖ قَالُواْ نَعۡبُدُ إِلَٰهَكَ وَإِلَٰهَ ءَابَآئِكَ إِبۡرَٰهِۧمَ وَإِسۡمَٰعِيلَ وَإِسۡحَٰقَ إِلَٰهٗا وَٰحِدٗا وَنَحۡنُ لَهُۥ مُسۡلِمُونَ 133
Njẹ ẹyin wa nibi iro Yaquub nigbati iku waa de ba, nigbati o sọ fun awọn ọmọ rẹ ni ẹniti nbi wọn leere wipe: kinni ẹ yoo maa sin lẹyin iku mi? Wọn waa sọ ni ẹniti o ndahun ibeere rẹ wipe: a o maa sin Ọlọhun Ọba rẹ ati Ọlọhun Ọba awọn baba rẹ, Ibraheem, Isma'eel ati Ishaaq, Ọlọhun Ọba ọkan soso, ti ko si orogun fun Un, Oun nikan soso ni awa yoo juwọ silẹ fun Un, ti a o si rọ fun Un.
تِلۡكَ أُمَّةٞ قَدۡ خَلَتۡۖ لَهَا مَا كَسَبَتۡ وَلَكُم مَّا كَسَبۡتُمۡۖ وَلَا تُسَۡٔلُونَ عَمَّا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ 134
Ohun ni ijọ kan ti o ti kọja ninu awọn ijọ ti o ti siwaju yin, o si ti lọọ ba ohun ti o ti siwaju ninu isẹ, yoo gbẹsan ohun ti o se nisẹ ninu daadaa tabi aida, yoo si maa bẹ fun ohun ti ẹ ba gbese, wọn ko ni bi yin leere nipa isẹ wọn, wọn si ki nii bi awọn naa leere nipa isẹ yin, wọn ko si nii fi ẹsẹ ẹnikankan bi ẹlomiran bikose wipe wọn yoo san gbogbo ẹnikọọkan ni ẹsan ohun ti o ba ti siwaju, ko si gbọdọ ko airoju ba yin, isẹ awọn ti o siwaju yin nipa wiwo isẹ ti yin, toripe dajudaju ẹnikankan ko nii se ni anfaani lẹyin ikẹ Ọlọhun Ọba ju isẹẹre rẹ lọ.
Olugbagbọ ti o jẹ olupaya Ọlọhun Ọba ko nii gba itanjẹ pẹlu awọn isẹẹre rẹ bikose wipe yoo maa bẹru ki wọn da pada fun un, ti wọn ko si nii gba lọwọ rẹ, tori idi eleyi, ni o fi gbọdọ pọ ni ibeere ni ọwọ Ọlọhun Ọba gbigbaa rẹ.
Alubarika adua baba awọn Anọbi tii se Ibraheem (ki ọla maa jẹ tirẹ) ni aaye ti Ọlọhun Ọba ti gba adua rẹ, ti O waa se olukẹyin awọn Anọbi Rẹ ati ẹniti o ni ọla julọ ninu awọn ojisẹ Rẹ lati inu awọn ara Mẹkka.
Ẹsin Ibraheem (ki ọla o maa jẹ tirẹ) ni oju ọna ti o mọ kanga, ti o se deede adamọ, ko nii gbẹmi kuro nibẹ, ko si nii sa kuro nibẹ ayaafi alaimọkan, ẹniti o ti yapa adamọ rẹ.
Sise mima se isiti fun awọn arọmọdọmọ ni ofin lati maa tẹle oju ọnaamọ, ati mima gba adehun lọwọ wọn nipa gbigba ododo mu ati diduro sinsin lori rẹ.