قَالَ كَذَٰلِكَ أَتَتۡكَ ءَايَٰتُنَا فَنَسِيتَهَاۖ وَكَذَٰلِكَ ٱلۡيَوۡمَ تُنسَىٰ 126
Ọlọhun Allah fesi ni ẹniti o da ọrọ pada si lọdọ: iru eleyi ti o se ni ile aye, paapa awọn amin wa ti wa, o si gunri kuro nibẹ, bakanna ni iwọ naa yoo di ẹni igbejusilẹ loni si inu iya.
وَكَذَٰلِكَ نَجۡزِي مَنۡ أَسۡرَفَ وَلَمۡ يُؤۡمِنۢ بَِٔايَٰتِ رَبِّهِۦۚ وَلَعَذَابُ ٱلۡأٓخِرَةِ أَشَدُّ وَأَبۡقَىٰٓ 127
Ati gẹgẹ bi apejuwe ẹsan yii ni a o san fun ẹniti o ba tẹri si inu adun ti a se leewọ, ti o si gunri kuro nibi igbagbọ pẹlu awọn ẹri ti o fi oju han lati ọdọ ỌLọhun Ọba rẹ, paapa julọ iya Ọlọhun Allah ni ọrun gbona, o si lagbara ju isẹmin inira lọ ni ile aye ati agede meji aye, yoo si tun maa wa lọ bẹẹ.
أَفَلَمۡ يَهۡدِ لَهُمۡ كَمۡ أَهۡلَكۡنَا قَبۡلَهُم مِّنَ ٱلۡقُرُونِ يَمۡشُونَ فِي مَسَٰكِنِهِمۡۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّأُوْلِي ٱلنُّهَىٰ 128
Se ko hande fun awọn ẹlẹbọ ni pipọ awọn ijọ ti a parun siwaju wọn, ti wọn nrin ninu awọn ile ijọ ti a pa run, ti wọn si fi ara kin awọn oripa ohun ti o sẹlẹ si wọn? Dajudaju nibi ohun ti o sẹlẹ si awọn ijọ ti o pọ yii nibi iparun ati titan jẹ ariwoye fun awọn ti o ni laakaye.
وَلَوۡلَا كَلِمَةٞ سَبَقَتۡ مِن رَّبِّكَ لَكَانَ لِزَامٗا وَأَجَلٞ مُّسَمّٗى 129
Ti kii ba se gbolohun ti o siwaju ni ọdọ Ọlọhun Ọba rẹ - ire ojise - wipe dajudaju ko ni fi iya jẹ ẹnikẹni siwaju ki o to gbe awijare le lori, ti ki ba se asiko ti a ti pebubu ni ọdọ Rẹ fun wọn, ki ba kanju iya fun wọn; nitori lilẹtọ si wọn ti wọn lẹtọ si i.
فَٱصۡبِرۡ عَلَىٰ مَا يَقُولُونَ وَسَبِّحۡ بِحَمۡدِ رَبِّكَ قَبۡلَ طُلُوعِ ٱلشَّمۡسِ وَقَبۡلَ غُرُوبِهَاۖ وَمِنۡ ءَانَآيِٕ ٱلَّيۡلِ فَسَبِّحۡ وَأَطۡرَافَ ٱلنَّهَارِ لَعَلَّكَ تَرۡضَىٰ 130
Ki o si se suuru - ire ojise - lori ohun ti awọn opurọ nsọ nibi awọn iroyin ibajẹ, ki o si se afọmọ pẹlu Ọlọhun Ọba rẹ ni irun idaji siwaju ki oorun too yọ ati nibi irun irọlẹ siwaju ki o to wọ ati nibi irun asalẹ ati alẹ ninu awọn asiko oru, ati nibi irun ọsan nigbati oorun ba yẹ atari lẹyin igbati abala akọkọ ninu ọsan ba tan, ati nibi irun asalẹ lẹyin igbati abala ẹkeji ninu rẹ ba tan; ni ireti ki wọn le ri ẹsan ni ọdọ Allah eyiti yoo yọ wọn ninu.
وَلَا تَمُدَّنَّ عَيۡنَيۡكَ إِلَىٰ مَا مَتَّعۡنَا بِهِۦٓ أَزۡوَٰجٗا مِّنۡهُمۡ زَهۡرَةَ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا لِنَفۡتِنَهُمۡ فِيهِۚ وَرِزۡقُ رَبِّكَ خَيۡرٞ وَأَبۡقَىٰ 131
Mase woye si ohun ti a se fun awọn ijọ kan ninu awọn opurọ ninu idẹkun, wọn yoo maa gbadun rẹ ninu yodo yindin aye isẹmin aye ki a le dan wọn wo, dajudaju ohun ti a se fun wọn yii, ohun ti yoo yẹ kuro ni, bẹẹ ni ẹsan Ọlọhun rẹ eyiti o se adehun rẹ fun ọ titi ti iwọ yoo fi yọnu, o loore ju ohun ti a se fun wọn ni ile aye ninu awọn idẹkun ti yoo yẹ kuro, yoo si tun pẹ ju lọ; nitoripe ohun ko nii tan.
وَأۡمُرۡ أَهۡلَكَ بِٱلصَّلَوٰةِ وَٱصۡطَبِرۡ عَلَيۡهَاۖ لَا نَسَۡٔلُكَ رِزۡقٗاۖ نَّحۡنُ نَرۡزُقُكَۗ وَٱلۡعَٰقِبَةُ لِلتَّقۡوَىٰ 132
Pa awọn ara ile rẹ lasẹ irun kiki - ire ojise - ki o si se suuru lori mimu wa rẹ, a ko nii beere arisiki fun ara rẹ ati fun ẹlomiran ti o yatọ si ọ, awa ni a la arisiki rẹ bọrun, bẹẹ ni igbẹyin ọpẹ ni ile aye ati ni ọrun jẹ ti awọn olupaya, awọn ti wọn nbẹru Allah, ti wọn si ntẹle awọn asẹ Rẹ, wọn si tun jinna si awọn nkan ti O kọ.
وَقَالُواْ لَوۡلَا يَأۡتِينَا بَِٔايَةٖ مِّن رَّبِّهِۦٓۚ أَوَ لَمۡ تَأۡتِهِم بَيِّنَةُ مَا فِي ٱلصُّحُفِ ٱلۡأُولَىٰ 133
Awọn keferi ti wọn npe Anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun nirọ yii si sọpe: se Muhammad ko le mu amin kan wa lati ọdọ Ọlọhun Ọba rẹ ti yoo tọka si otitọ rẹ ati wipe dajudaju ojisẹ ni, se kii wa sepe Alukuraani eyiti o npe awọn tira sanmọ ni ododo ti o siwaju rẹ ti waa ba awọn opurọ yi ni?!
وَلَوۡ أَنَّآ أَهۡلَكۡنَٰهُم بِعَذَابٖ مِّن قَبۡلِهِۦ لَقَالُواْ رَبَّنَا لَوۡلَآ أَرۡسَلۡتَ إِلَيۡنَا رَسُولٗا فَنَتَّبِعَ ءَايَٰتِكَ مِن قَبۡلِ أَن نَّذِلَّ وَنَخۡزَىٰ 134
Ti a ba pa awọn ti npe anọbi ti ẹni ati ọla nbẹ fun nirọ run lati ibi sisọ iya kalẹ le wọn lori lati ibi keferi wọn ati orikunkun wọn siwaju ki a to ran ojisẹ si wọn, ti a si tun sọ eyi kalẹ fun wọn, wọn ko ba wi ni ọjọ igbende ni ẹniti o nwi awijare nipa keferi wọn: se ko yẹ ki O ran ojisẹ si wa ni ile aye ni –irẹ Ọlọhun wa- ti a ko ba gba a gbọ, ki a si tun tẹle awọn amin ti o mu siwaju, siwaju ki iyẹpẹrẹ ati itiju too sẹlẹ si wa nitori ijiya Rẹ?!
قُلۡ كُلّٞ مُّتَرَبِّصٞ فَتَرَبَّصُواْۖ فَسَتَعۡلَمُونَ مَنۡ أَصۡحَٰبُ ٱلصِّرَٰطِ ٱلسَّوِيِّ وَمَنِ ٱهۡتَدَىٰ 135
Sọ fun awọn opurẹ yii - irẹ ojisẹ -: ẹnikọọkan ninu wa ati ninu yin nreti ohun ti Allah yoo fi nsan lẹsan, ki ẹyin naa yaa ma reti, ẹyin yoo pada mọ - tiko si ibuyẹ - ẹniti o jẹ ẹni ọna ti o duro tọ ati awọn ti wọn mọ ọna: awa tabi ẹyin?
Ninu awọn okunfa ti o ma nranni lọwọ lati le gba suta awọn olugunri mọra ni lilo awọn asiko ti o lọla si bi sise afọmọ idupẹ fun Allah.
Dandan ni fun ẹru ki o wọn ọsọ aye ti o yẹ ati ọsọ ọrun ti yoo wa gbere si ara wọn nigbati o ba ri oju kokoro rẹ lọ si ibi ọsọ aye ati kikọbi ara si i.
Dandan ni fun ẹru ki o gbe irun duro ni paapa gbigbe duro, nigbati alamọri kan ba kun ninu ki o ki irun, ki o si pa ara ile rẹ lasẹ irun kiki, ki o si se suuru le wọn lori ni kikọse ojisẹ naa ti ikẹ ati ọla nbẹ fun.
Igbẹyin ti o rẹwa, ti o si jẹ ọpẹ ni ile idẹra fun awọn olupaya.