يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ قَٰتِلُواْ ٱلَّذِينَ يَلُونَكُم مِّنَ ٱلۡكُفَّارِ وَلۡيَجِدُواْ فِيكُمۡ غِلۡظَةٗۚ وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ مَعَ ٱلۡمُتَّقِينَ 123
Ọlọhun Ọba Allah pasẹ fun awọn olugbagbọ ododo lati maa ba awọn keferi ti wọn wa ni ayika wọn ja; nitori ewu ti wọn le se fun awọn olugbagbọ ododo latara sisun mọ wọn, bakanna ni o pa wọn lasẹ lati maa se afihan agbara ati ile koko nitori ki wọn le maa da ẹru ba wọn ati titi aburu wọn danu, Ọlọhun Ọba Allah wa pẹlu awọn olugbagbọ ododo ti wọn wa pẹlu Rẹ niti iranlọwọ ati ikunlọwọ Rẹ.
وَإِذَا مَآ أُنزِلَتۡ سُورَةٞ فَمِنۡهُم مَّن يَقُولُ أَيُّكُمۡ زَادَتۡهُ هَٰذِهِۦٓ إِيمَٰنٗاۚ فَأَمَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ فَزَادَتۡهُمۡ إِيمَٰنٗا وَهُمۡ يَسۡتَبۡشِرُونَ 124
Ti Ọlọhun Ọba Allah ba sọ suura kan kalẹ fun ojisẹ Rẹ ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, o wa ninu awọn sọbẹ sele ti yoo maa beere ibeere niti ise yẹyẹ: taani suura ti o sọkalẹ yii lekun igbagbọ rẹ ninu yin si ohun ti Muhammad mu wa? Sugbọn awọn ti wọn nigbagbọ ninu Allah, ti wọn si pe ojisẹ Rẹ lododo, paapaa julọ sisọkalẹ suura naa ti se alekun igbagbọ lori igbagbo wọn ti wọn ni siwaju, wọn jẹ ẹniti o ndunnu si ohun ti o sọkalẹ ninu imisi; nitori anfaani aye ati ti ọrun ti o wa nibẹ.
وَأَمَّا ٱلَّذِينَ فِي قُلُوبِهِم مَّرَضٞ فَزَادَتۡهُمۡ رِجۡسًا إِلَىٰ رِجۡسِهِمۡ وَمَاتُواْ وَهُمۡ كَٰفِرُونَ 125
Sugbọn awọn sọbẹ selu, dajudaju sisọkalẹ Alukuraani pẹlu awọn idajọ ati awọn itan ti o wa nibẹ yoo se alekun aarẹ ati ẹgbin fun wọn nitori wipe wọn npe ohun ti o sọkalẹ nirọ, bi sisọkalẹ Alukuraani ba se nlekun ni aarẹ ọkan wọn yoo se maa lekun, tori wipe ti ohun ki hun ba ti sọkalẹ ni wọn ma nse iyemeji si, ti wọn si ku leori keferi.
أَوَلَا يَرَوۡنَ أَنَّهُمۡ يُفۡتَنُونَ فِي كُلِّ عَامٖ مَّرَّةً أَوۡ مَرَّتَيۡنِ ثُمَّ لَا يَتُوبُونَ وَلَا هُمۡ يَذَّكَّرُونَ 126
Akọkọ, awọn sọbẹ selu nwoye ni ẹniti o nkọgbọn latar adanwo ọla ti O se fun wọn nitori wipe O tu asiri isesi wọn, O si yẹpẹrẹ wọn pẹlu isọbẹ selu wọn ni gboogbo ọdun lẹẹkan tabi lẹẹmeji?! Pẹlu wipe wọn mọ wipe Ọlọhun Ọba Allah ti o ga Oun ni O nse eleyi, wọn kii wa aforijin lọ si ọdọ Rẹ nibi keferi wọn, wọn kii wu sọbẹ selu wọn tegbo tegbo, wọn si kii ranti ohun ti o sẹlẹ si wọn wipe dajudaju ọdọ Ọlọhun Ọba Allah ni o ti wa!
وَإِذَا مَآ أُنزِلَتۡ سُورَةٞ نَّظَرَ بَعۡضُهُمۡ إِلَىٰ بَعۡضٍ هَلۡ يَرَىٰكُم مِّنۡ أَحَدٖ ثُمَّ ٱنصَرَفُواْۚ صَرَفَ ٱللَّهُ قُلُوبَهُم بِأَنَّهُمۡ قَوۡمٞ لَّا يَفۡقَهُونَ 127
Ti Ọlọhun Ọba Allah ba sọ suura kan kalẹ fun ojisẹ Rẹ ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, ti ọrọ nipa awọn sọbẹ selu si wa nibẹ, awọn sọbẹ selu kan yoo maa wo awọn miran ni ẹniti yoo maa sọ bayi wipe: se ẹnikankan ri yin bi? Ti ẹnikankan ko ba ri wọn, wọn yoo kuro ni aaye naa, ẹ tẹti ẹ gbọ, Ọlọhun Ọba Allah ti yi ọkan wọn kuro nibi imọna ati rere, O si dagunla si wọn nitori wipe wọn jẹ ẹniti ko lagbọye.
لَقَدۡ جَآءَكُمۡ رَسُولٞ مِّنۡ أَنفُسِكُمۡ عَزِيزٌ عَلَيۡهِ مَا عَنِتُّمۡ حَرِيصٌ عَلَيۡكُم بِٱلۡمُؤۡمِنِينَ رَءُوفٞ رَّحِيمٞ 128
Paapaa o ti waa ba yin - ẹyin akojọpọ larubawa - ojisẹ kan ninu iran yin, o si jẹ larubawa gẹgẹ bii yin, o nsoro fun un nkan ti o nsoro fun ẹyin naa, o si ni oju kokoro ti o le koko nibi imọna yin ati ikọbi ara si yin, o si jẹ ẹniti aanu rẹ pọ ati ikẹ rẹ pataki julọ si awọn olugbagbọ ododo.
فَإِن تَوَلَّوۡاْ فَقُلۡ حَسۡبِيَ ٱللَّهُ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۖ عَلَيۡهِ تَوَكَّلۡتُۖ وَهُوَ رَبُّ ٱلۡعَرۡشِ ٱلۡعَظِيمِ 129
Ti wọn ba gunri kuro ni ọdọ rẹ, ti wọn ko si nigbagbọ si ohun ti o mu wa, ki o wa sọ fun wọn wipe –ire ojise- Ọlọhun Ọba Allah ti ko si ẹniti a njọsi fun nitootọ ju Oun nikan lọ, Oun nikan ni mo gbara le, Oun ni ọba mimọ ti o ni aga alaarasi ti o tobi julọ.
Jijẹ dandan bibẹrẹ biba awọn keferi ti o sunmọ ni ja nigbati Islam ba ga, ti bukaata si pepe fun.
Sise alaye isesi awọn sọbẹ selu nigbati Alukuraani ba sọkalẹ fun wọn, o si jẹ isewadi ati ruke rudo.
Sise alaye ikẹ Anọbi ti ikọ ati ọla nbẹ fun si awọn olugbagbọ ododo ati oju kokoro rẹ le wọn lori.
Ẹri lori wipe igbagbọ ma nlekun, Oo si ma ndin ku wa ninu awọn aayah naa, ati wipe o tọ fun olugbagbọ ododo wipe igbagbọ oun le lọ, ti oun si gbọdọ maa kiye si i, ti yoo wa maa sọ di dandan, ti yoo si maa re e; ki o le ba maa wa nigbogbo igba nibi giga.