Nigbati Ọlọhun Ọba Allah darukọ ẹsan awọn olutẹle esu, O tun darukọ ẹsan awọn olutẹle ojisẹ naa; O wa sọ wipe:
وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ سَنُدۡخِلُهُمۡ جَنَّٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَآ أَبَدٗاۖ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقّٗاۚ وَمَنۡ أَصۡدَقُ مِنَ ٱللَّهِ قِيلٗا 122
Awọn ni wọn nigbagbọ ninu Ọlọhun Ọba Allah, ti wọn si nse awọn isẹẹre eyiti yoo mu wọn sun mọ Ọ, a o fi wọn wọ sinu awọn Alujannah, ti awọn awọn akere mọdo nsan ni abẹ awọn orule rẹ, wọn yoo maa wa nibẹ lọ gbere lọ lailai, eleyi jẹ adehun lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, bẹẹni adehun Rẹ ti o ga jẹ ododo, Oun kii yapa adehun, ko si si ẹniti o sọ ootọ to Ọlọhun Ọba Allah.
لَّيۡسَ بِأَمَانِيِّكُمۡ وَلَآ أَمَانِيِّ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِۗ مَن يَعۡمَلۡ سُوٓءٗا يُجۡزَ بِهِۦ وَلَا يَجِدۡ لَهُۥ مِن دُونِ ٱللَّهِ وَلِيّٗا وَلَا نَصِيرٗا 123
Kii se alamọri ọla ati erenjẹ ni ohun ti tẹle nkan ti ẹ nrankan - ẹyin olugbagbọ ododo -, tabi ti o tẹle ohun ti awọn onitira nrankan, bikose wipe alamọri naa tẹle isẹ ni, ẹniti o ba se isẹ kan, ti ko dara, wọn yoo san lẹsan ni ọjọ igbende, ko si nii alatilẹyin miran yatọ si Ọlọhun Ọba Allah, ti yoo se ni anfaani, bẹẹni ko nii si alaranse ti yoo mu aburu kuro fun un.
وَمَن يَعۡمَلۡ مِنَ ٱلصَّٰلِحَٰتِ مِن ذَكَرٍ أَوۡ أُنثَىٰ وَهُوَ مُؤۡمِنٞ فَأُوْلَٰٓئِكَ يَدۡخُلُونَ ٱلۡجَنَّةَ وَلَا يُظۡلَمُونَ نَقِيرٗا 124
Ẹniti o ba se isẹ ninu awọn isẹẹre, biya ọkunrin tabi obinrin, ti o si jẹ olugbagbọ ododo si Ọlọhun Ọba Allah tootọ, awọn wọnyi ni wọn ko igbagbọ ododo ati isẹ papọ, wọn yoo wọ Alujannah, wọn ko nii din nkankan ku ninu awọn isẹẹ wọn, koda ki baa jẹ nkan kekere, ni odiwọn oku eyiti onbẹ ni ẹyin eso tamuru.
وَمَنۡ أَحۡسَنُ دِينٗا مِّمَّنۡ أَسۡلَمَ وَجۡهَهُۥ لِلَّهِ وَهُوَ مُحۡسِنٞ وَٱتَّبَعَ مِلَّةَ إِبۡرَٰهِيمَ حَنِيفٗاۗ وَٱتَّخَذَ ٱللَّهُ إِبۡرَٰهِيمَ خَلِيلٗا 125
Ko si ẹniti o fi ndara ni ẹsin fun ẹniti o jupa jusẹ fun Ọlọhun Ọba Allah niti ode ati inu, ti o si se afọmọ adisọkan rẹ fun un, ti o se daradara nibi isẹ rẹ pẹlu ohun ti wọn se ni ofin, ti o si tẹle ẹsin Anọbi Ibraheem eyiti o jẹ ipilẹ ẹsin Anọbi Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, eyiti o yẹ kuro nibi ẹbọ ati keferi si ọkansoso Ọlọhun Ọba Allah ati igbagbọ, Ọlọhun Ọba Allah si se afọmọ Anọbi Rẹ Ibraheem ki ikẹ ati igẹ maa ba, pẹlu ifẹ ti o pe ninu awọn ẹda Rẹ.
وَلِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۚ وَكَانَ ٱللَّهُ بِكُلِّ شَيۡءٖ مُّحِيطٗا 126
Ọlọhun Ọba Allah nikan ni O ni gbogbo ohun ti o wa ninu sanmọ mejeeje ati ilẹ, Ọlọhun Ọba Allah jẹ ẹniti imọ rẹ rọkirikọ gbogbo nkan niti imọ ati agbara ati idari.
وَيَسۡتَفۡتُونَكَ فِي ٱلنِّسَآءِۖ قُلِ ٱللَّهُ يُفۡتِيكُمۡ فِيهِنَّ وَمَا يُتۡلَىٰ عَلَيۡكُمۡ فِي ٱلۡكِتَٰبِ فِي يَتَٰمَى ٱلنِّسَآءِ ٱلَّٰتِي لَا تُؤۡتُونَهُنَّ مَا كُتِبَ لَهُنَّ وَتَرۡغَبُونَ أَن تَنكِحُوهُنَّ وَٱلۡمُسۡتَضۡعَفِينَ مِنَ ٱلۡوِلۡدَٰنِ وَأَن تَقُومُواْ لِلۡيَتَٰمَىٰ بِٱلۡقِسۡطِۚ وَمَا تَفۡعَلُواْ مِنۡ خَيۡرٖ فَإِنَّ ٱللَّهَ كَانَ بِهِۦ عَلِيمٗا 127
Wọn yoo bi ọ leere - ire ojise - nipa alamọri ọrọ awọn obninrin, ohun ti o di dandan le fun wọn ati le wọn lori, sọpe: Ọlọhun Ọba Allah yoo se alaye fun yin nipa ohun ti ẹ beere nipa rẹ, yoo si se alaye fun yin nkan ti wọn fun yin ninu Alukuraani, ninu ọrọ awọn ọmọ orukan ninu awọn obinrin ti o wa ni abẹ idari yin, ti ẹ ko fun wọn ni ohun ti Ọlọhun Ọba Allah se ni ọranyan ninu owo ori ati ogun, o ko si gbọdọ se oju kokoro sibi fifẹ wọn, bẹẹni ẹ ko gbọdọ kọ fun wọn lati lọkọ niti irankan sibi dukia wọn, Ọlọhun Ọba Allah se alaye fun yin nipa awọn ọlẹ ninu awọn ọmọ keekeeke, nibi fifun wọn ni ẹtọ wọn ninu ogun, ti ẹ ko si gbọdọ se abosi si wọn pẹlu jijẹ gaga lori awọn dukia wọn, Ọlọhun Ọba Allah nse alaye fun yin jijẹ dandan mimujuto awọn ọmọ orukan pẹlu deedee, nibi ohun ti yoo tun isẹmi wọn se ni ile aye ati ni ọrun, ohunkohun ti ẹ ba se fun awọn ọmọ orukan tabi ẹniti o yatọ si wọn, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah jẹ Onimọ nipa, Yoo si san yin lẹsan le lori.
Ọwọ ko le tẹ ohun ti o wa ni ọdọ Ọlọhun Ọba Allah ninu ẹsan pẹlu irankan lasan ati pipe apemọra bikose wipe dandan ni igbagbọ ati isẹẹre.
Ẹsan wa pẹlu iran isẹ, ẹniti o ba se aburu, wọn yoo san ni ẹsan rẹ, bẹẹni ẹniti o ba se rere, wọn yoo san ni ẹsan ti o dara ju lọ.
Sise afọmọ ati itẹle mejeeji ni osunwọn gbigba isẹ ni ọdọ Ọlọhun Ọba Allah ti ọla Rẹ ga.
Islam pataki iwọ awọn apakan ninu awọn obinrin ti wọn jẹ ọlẹ ati awọn ọmọ keekeeke, o si se ikọja ẹnu aala si wọn ni eewọ, o si se mima se atunse wọn ni ibamun si ofin Ọlọhun Ọba Allah ni ọranyan.