إِذۡ هَمَّت طَّآئِفَتَانِ مِنكُمۡ أَن تَفۡشَلَا وَٱللَّهُ وَلِيُّهُمَاۗ وَعَلَى ٱللَّهِ فَلۡيَتَوَكَّلِ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ 122
Ranti - irẹ Anọbi - ohun ti o sẹlẹ si awọn ikọ meji kan ninu awọn olugbagbọ ododo, ninu awọn Bani Salamọ ati Bani Haritha nigbati wọn kọlẹ, ti wọn si tun gbero lati sẹri pada nigbati awọn oloju-eji nsẹri pada, ati wipe Ọlọhun Ọba Allah ni Alaranse awọn wọnyi pẹlu fifi ẹsẹ wọn rinlẹ lori ijagun ati yiyi wọn kuro lori ohun ti wọn gba lero, ati wipe Ọlọhun Ọba Allah nikan soso ni ki awọn olugbagbọ ododo maa fi ara ti nibi gbogbo awọn isesi wọn.
وَلَقَدۡ نَصَرَكُمُ ٱللَّهُ بِبَدۡرٖ وَأَنتُمۡ أَذِلَّةٞۖ فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ لَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ 123
Ati wipe paapaa Ọlọhun Ọba Allah ti ran yin se lori awọn ọsẹbọ nibi ogun Badiri, ti ẹyin si jẹ ọlẹ, ati wipe nkan naa jẹ pẹlu kikere onka yin ati nkan ija yin, ki ẹ ya paya Ọlọhun Ọba Allah, ki ẹ le baa jẹ ẹniti yoo maa dupẹ awọn idẹra Rẹ lori yin.
إِذۡ تَقُولُ لِلۡمُؤۡمِنِينَ أَلَن يَكۡفِيَكُمۡ أَن يُمِدَّكُمۡ رَبُّكُم بِثَلَٰثَةِ ءَالَٰفٖ مِّنَ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةِ مُنزَلِينَ 124
Ranti - irẹ Anọbi - nigbati o sọ fun awọn olugbagbọ ododo ni ẹniti nfi ẹsẹ wọn rinlẹ nibi Ogun Badiri lẹyin igbati wọn ti gbọ aranse kan ti nbọ fun awọn ọsẹbọ wipe: se ko wa to yin ni, ki Ọlọhun Ọba Allah ran yin lọwọ pẹlu ẹgbẹrun mẹta ninu awọn Malaika, ti wọn yoo maa sọkalẹ lati ọdọ Rẹ, mimọ fun Un, lati le ba royin lagbara nibi ijagun yin? !
بَلَىٰٓۚ إِن تَصۡبِرُواْ وَتَتَّقُواْ وَيَأۡتُوكُم مِّن فَوۡرِهِمۡ هَٰذَا يُمۡدِدۡكُمۡ رَبُّكُم بِخَمۡسَةِ ءَالَٰفٖ مِّنَ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةِ مُسَوِّمِينَ 125
Bẹẹni, dajudaju nkan naa yoo to yin, o si nbẹ fun yin iro idunnu pẹlu aranse miran lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, ti ẹ ba se suuru lori ogun jija, ti ẹ si paya Ọlọhun Ọba Allah, ti ikunlọwọwaa de fun awọn ọta yin ni asiko wọn, ni ẹniti o nyara bọ wa si ọdọ yin, ti nkan naa ba sẹlẹ, dajudaju Ọlọhun Ọba yin Yoo ran yin lọwọ pẹlu ẹgbẹrun maarun ninu awọn Malaika, ti wọn yoo maa da ara wọn mọ, ati ẹsin wọn pẹlu amin ti o fi oju han.
وَمَا جَعَلَهُ ٱللَّهُ إِلَّا بُشۡرَىٰ لَكُمۡ وَلِتَطۡمَئِنَّ قُلُوبُكُم بِهِۦۗ وَمَا ٱلنَّصۡرُ إِلَّا مِنۡ عِندِ ٱللَّهِ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡحَكِيمِ 126
Ọlọhun Ọba Allah ko se iranlọwọ yii ati ikunlọwọ yii pẹlu awọn Malaika ayaafi iro idunnu fun yin, ti ọkan yin yoo balẹ pẹlu rẹ, ati wipe ti ko ba ri bẹ dajudaju aranse ni ododo kii jẹ pẹlu awọn okunfa ti o fi oju han lasan, ati wipe dajudaju aranse ododo ma nwa lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, Ọba Alagbara Ẹniti ẹnikankan ko le bori Rẹ, Ọjọgbọ si ni nibi ipebubu Rẹ ati isofin Rẹ.
لِيَقۡطَعَ طَرَفٗا مِّنَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ أَوۡ يَكۡبِتَهُمۡ فَيَنقَلِبُواْ خَآئِبِينَ 127
Aranse yii eyiti o sẹlẹ ni ododo fun yin ninu Ogun Badiri, Ọlọhun Ọba Allah gbero pẹlu rẹ lati pa ikọ kan ninu awọn alaigbagbọ run pẹlu pipa, ati ki o yẹpẹrẹ ikọ miran, Yoo si ko ibinu ba wọn pẹlu bibori wọn, wọn yoo waa sẹri pẹlu pipadanu ati iyẹpẹrẹ.
لَيۡسَ لَكَ مِنَ ٱلۡأَمۡرِ شَيۡءٌ أَوۡ يَتُوبَ عَلَيۡهِمۡ أَوۡ يُعَذِّبَهُمۡ فَإِنَّهُمۡ ظَٰلِمُونَ 128
Nigbati ojisẹ sẹ epe le awọn adari awọn ọsẹbọ pẹlu iparun lẹyin ohun ti o sẹlẹ lati ọdọ wọn nibi ogun Uhud; Ọlọhun Ọba Allah sọ fun wipe: ko si nkankan fun ọ ninu alamọri wọn. , bikose wipe alamọri, ti Ọlọhun Ọba Allah ni, ki o yaa lọọ se suuru titi ti Ọlọhun Ọba Allah yoo fi dajọ laarin yin tabi ki O fi wọn mọ ọna lọsi ibi ironu piwada, ti wọn yoo waa gba Islam, tabi ki wọn maa lọ lori aigbagbọ wọn, ti Yoo fi waa fi iwa jẹ wọn, toripe dajudaju awọn ni alabosi, awọn ti wọn ni ẹtọ si iya naa.
وَلِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۚ يَغۡفِرُ لِمَن يَشَآءُ وَيُعَذِّبُ مَن يَشَآءُۚ وَٱللَّهُ غَفُورٞ رَّحِيمٞ 129
Ati wipe ti Ọlọhun Ọba Allah niise ohun ti nbẹ ninu awọn sanmọ ati ohun ti o nbẹ ni ilẹ ni ẹda ati idari, o ma nfi ori awọn ẹsẹ jin ẹniti O ba fẹ ninu awọn ẹru Rẹ pẹlu ikẹ Rẹ ati wipe O si ma njẹ ẹniti O ba fẹ niya pẹlu deede Rẹ, ati wipe Ọlọhun Ọba ni Olufi ori jin ẹniti o ba ronu piwada ninu awọn ẹru Rẹ, Onikẹ wọn si ni.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَأۡكُلُواْ ٱلرِّبَوٰٓاْ أَضۡعَٰفٗا مُّضَٰعَفَةٗۖ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ لَعَلَّكُمۡ تُفۡلِحُونَ 130
Ẹyin ti ẹ ni igbagbọ pẹlu Ọlọhun Ọba Allah, ti wọn si tẹle ojisẹ Rẹ, ẹ jinna si gbigba riba, ni aleekun aladipele lori awọn ipilẹ awọn owo yin, eyiti ti ẹ fi dogo gẹgẹ bi awọn ara igba aimọkan se ma nse, ati wipe ki ẹ paya Ọlọhun Ọba Allah pẹlu mima mu awọn asẹ Rẹ wa si imusẹ ati jijina si awọn ohun ti O kọ, ki ẹ le baa jẹ ẹniti owo rẹ yoo tẹ ikẹ ni aye ati ọrun.
وَٱتَّقُواْ ٱلنَّارَ ٱلَّتِيٓ أُعِدَّتۡ لِلۡكَٰفِرِينَ 131
Ẹ waa laarin yin ati laarin ina, eyiti Ọlọhun Ọba Allah pese rẹ fun awọn alaigbagbọ pẹlu Rẹ, gaga kan, nkan naa yoo maa jẹ pẹlu isẹ oloore ati fif awọn nkan eewọ silẹ.
وَأَطِيعُواْ ٱللَّهَ وَٱلرَّسُولَ لَعَلَّكُمۡ تُرۡحَمُونَ 132
Ati wipe ki ẹ tẹle Ọlọhun Ọba Allah ati ojisẹ Rẹ pẹlu mimu awọn asẹ wa si imusẹ ati jijina si awọn ẹkọ, ki ọwọ yin le baa tẹ ikẹ ni aye ati ọrun.
Sise iranti pẹlu idẹra ati iya eyiti o ma nsọkalẹ pẹlu awọn eniyan titi ti ọmọniyan yoo fi se ariwoye pẹlu rẹ lofin.
Ninu awọn okunfa ti o tobi, ti o ma nmu aranse Ọlọhun Ọba Allah sọkalẹ lori ẹru ati ikẹ Rẹ ati aanu Rẹ pẹlu wọn ni didunni mọ ipaya Ọlọhun ati sise suuru lori awọn ilekoko ogun.
Alamọri, gbogbo rẹ patapata ti Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) niise, ni O fi ma nse ofin ohun ti O ba fẹ, ti O si ma ndajọ ohun ti O ba gba lero, ati wipe olugbagbọ ododo yoo jọwọ alamọri rẹ silẹ fun Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) , ati wipe yoo si tẹriba fun idajọ Rẹ,
Awọn ẹsẹ - ninu rẹ ni owo ele - ninu awọn okunfa iyẹpẹrẹ ẹru ti o tobi ni, paapaa julọ ni awọn asiko ti o lagbara, ti o si le.
Wiwa ti kikọ wa kuro nibi riba laarin awọn aayah ogun Uhud, o nse afihan kikun ti Islam kun nibi awọn ofin rẹ ati asopọ rẹ nibi ti o ti ntọka si awọn apakan rẹ laarin ọrọ nipa apakan.