وَلَن تَرۡضَىٰ عَنكَ ٱلۡيَهُودُ وَلَا ٱلنَّصَٰرَىٰ حَتَّىٰ تَتَّبِعَ مِلَّتَهُمۡۗ قُلۡ إِنَّ هُدَى ٱللَّهِ هُوَ ٱلۡهُدَىٰۗ وَلَئِنِ ٱتَّبَعۡتَ أَهۡوَآءَهُم بَعۡدَ ٱلَّذِي جَآءَكَ مِنَ ٱلۡعِلۡمِ مَا لَكَ مِنَ ٱللَّهِ مِن وَلِيّٖ وَلَا نَصِيرٍ 120
Ọlọhun Ọba nba Anọbi Rẹ sọrọ ni ẹniti O ntọsọna ti O si nse ikilọ, ni Ẹni ti O sọ fun wipe: awọn Yahuudi ati Nasaara ko le yọnu si ọ lailai titi ti iwọ yoo fi fi Islam silọ, ti o si maa tẹle oun ti wọn wa lori rẹ, sope: tira Olohun ati alaye oun ni onanmo ododo, koki nse nkan ti won wa lori re ninu ibaje, ti itelewon ba waye lati ọdọ rẹ tabi lati ikan ninu awọn ti o ntẹle ọ, lẹyin ounti o ti waa ba ọ ninu ododo ti o fi oju han, o ko nii ri aranse tabi iranlọwọ lati odo Ọlọhun Ọba, eleyi wa ninu ojupọnna sise alaye ewu ti o nbẹ ninu fifi ododo silẹ ati sisunmọ awọn alaida.
ٱلَّذِينَ ءَاتَيۡنَٰهُمُ ٱلۡكِتَٰبَ يَتۡلُونَهُۥ حَقَّ تِلَاوَتِهِۦٓ أُوْلَٰٓئِكَ يُؤۡمِنُونَ بِهِۦۗ وَمَن يَكۡفُرۡ بِهِۦ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡخَٰسِرُونَ 121
Alukuraani Alapọnle nsọrọ nipa awọn ikọ kan ninu awọn ti a fun ni tira, ti wọn mọ ohun ti nbẹ lọwọ wọn ninu tira ti wọn sọkalẹ, ti wọn si ntẹle, ni itẹle ododo, awọn wọnyi yoo maa ri ninu awọn tira yii, awọn amin eyi ti o ntọka sisọ ododo Anọbi Muhammad (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ ko maa ba) , tori idi eyi, ni wọn fi sare lọ si ibi nini igbagbọ pẹlu rẹ, awọn ikọ miran sise orikunkun lori aini igbagbọ rẹ, ni ofo fi jẹ ti wọn.
يَٰبَنِيٓ إِسۡرَٰٓءِيلَ ٱذۡكُرُواْ نِعۡمَتِيَ ٱلَّتِيٓ أَنۡعَمۡتُ عَلَيۡكُمۡ وَأَنِّي فَضَّلۡتُكُمۡ عَلَى ٱلۡعَٰلَمِينَ 122
Ẹyiin ọmọ Isirẹli, ẹ ranti idẹra Mi ti ẹsin ati ti aye eyiti Mo pe leyin lori, ki ẹ si ranti wipe dajudaju Emi ni Mo fun yin ni ajulọ lori awọn ti ẹ jọ logba pẹlu ijẹ anọbi ati nini ọla.
وَٱتَّقُواْ يَوۡمٗا لَّا تَجۡزِي نَفۡسٌ عَن نَّفۡسٖ شَيۡٔٗا وَلَا يُقۡبَلُ مِنۡهَا عَدۡلٞ وَلَا تَنفَعُهَا شَفَٰعَةٞ وَلَا هُمۡ يُنصَرُونَ 123
Ẹ fi gaga kan si aarin yin ati laarin iya ọjọ igbende; pẹlu titẹle awon asẹ Ọlọhun Ọba ati jijinna si awọn nkan ti O kọ, toripe ko nii rọrọ - ni ọjọ naa - ẹmi kankan fun ẹmi miran, wọn ko si nii gba ninu rẹ fun un irapada kankan biotiwulẹ ki o tobi too, ko si nii s’anfaani fun un nibẹ isipẹ lati ọdọ ẹnikankan biotiwulẹ ki ipo rẹ ga to, ko si nii si fun alaranse kankan ti yoo ranse yatọ si Ọlọhun Ọba.
۞وَإِذِ ٱبۡتَلَىٰٓ إِبۡرَٰهِۧمَ رَبُّهُۥ بِكَلِمَٰتٖ فَأَتَمَّهُنَّۖ قَالَ إِنِّي جَاعِلُكَ لِلنَّاسِ إِمَامٗاۖ قَالَ وَمِن ذُرِّيَّتِيۖ قَالَ لَا يَنَالُ عَهۡدِي ٱلظَّٰلِمِينَ 124
Ẹ ranti igbati Ọlọhun Ọba dan Ibraheem wo (ki ọla maa bẹẹ fu un) pẹlu ohun ti O pa lasẹ rẹ ninu awọn idajọ ati awọn ti o jẹ dandan lati se, ti o si gbe duro, ti o si pe mimu wa si imusẹ lori ojupọnna ti o pe, Ọlọhun Ọba sọ fun Anọbi Rẹ Ibraheem: dajudaju Emi se o fun awọn eniyan ni arikọse kan, ti wọn yoo maa kọse pẹlu rẹ nibi awọn isẹẹ rẹ ati awọn iwa rẹ, Ibraheem si sọpe: waa se - irẹ Ọlọhun Ọba mi - ninu awọn arọmọdọmọ mi bakanna ni awọn asiwaju ti awọn eniyan yoo maa kọse pẹlu wọn, Ọlọhun Ọba sọpe ni Ẹniti ndalohun: ọwọ rẹ ko nii tẹ adehun Mi fun ọ pẹlu ijẹ asiwaju ninu ẹsin awọn alabosi ninu awọn arọmọdọmọ rẹ.
وَإِذۡ جَعَلۡنَا ٱلۡبَيۡتَ مَثَابَةٗ لِّلنَّاسِ وَأَمۡنٗا وَٱتَّخِذُواْ مِن مَّقَامِ إِبۡرَٰهِۧمَ مُصَلّٗىۖ وَعَهِدۡنَآ إِلَىٰٓ إِبۡرَٰهِۧمَ وَإِسۡمَٰعِيلَ أَن طَهِّرَا بَيۡتِيَ لِلطَّآئِفِينَ وَٱلۡعَٰكِفِينَ وَٱلرُّكَّعِ ٱلسُّجُودِ 125
Ki ẹ si se iranti nigbati Ọlọhun Ọba se ile ọwọ nni, ni ibusẹrisi awọn eniyan, ti awọn ọkan wọn yoo si maa rọ mọ, ni gbogbo igbati wọn ba se irin-ajo kuro nibẹ, wọn yoo pada si ibẹ, O si se ni ifọkanbalẹ fun wọn, ti ẹnikankan ko lee gbẹru gbọnri si wọn nibẹ, O si waa sọ fun awọn eniyan: Ẹ mu ninu okuta - eyiti Ibraheem ma nduro lori rẹ o si wa laarin ‘Kaaba’- aaye kan fun irun kiki. A waa sọ asọtẹlẹ fun Ibraheem ati ọmọ rẹ Isma'eel pẹlu mima mọ ile ọwọ naa kuro nibi awọn ẹgbin ati awọn oosa ati ki wọn si maa pese rẹ silẹ fun ẹniti o baa fẹ se ijọsin nibẹ pẹlu rirọkirika ati kikoraduro ati kiki irun ati awọn nkan ti o yatọ sii.
وَإِذۡ قَالَ إِبۡرَٰهِۧمُ رَبِّ ٱجۡعَلۡ هَٰذَا بَلَدًا ءَامِنٗا وَٱرۡزُقۡ أَهۡلَهُۥ مِنَ ٱلثَّمَرَٰتِ مَنۡ ءَامَنَ مِنۡهُم بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِۚ قَالَ وَمَن كَفَرَ فَأُمَتِّعُهُۥ قَلِيلٗا ثُمَّ أَضۡطَرُّهُۥٓ إِلَىٰ عَذَابِ ٱلنَّارِۖ وَبِئۡسَ ٱلۡمَصِيرُ 126
Waa ranti - irẹ Anọbi - nigbati Ibraheem sọ ni ẹniti npe Ọlọhun Ọba rẹ wipe: Irẹ Ọlọhun Ọba mi, se Mẹkka ni ilu kan ti o fọkanbalẹ, ti ẹnikankan ko nii le fi aburu kan, ki O si se arisiki fun awọn to ngbe ibẹ ninu oniranran eso ni arisiki kan, ti yoo wa fun awọn ti o gba Ọ lododo nikan ati ọjọ ikẹyin, Ọlọhun Ọba si sọ wipe: ẹniti o ba se aigbagbọ ninu wọn dajudaju Emi yoo fun ni igbadun pẹlu ohun ti Mo se fun un ni arisiki ni aye ni igbadun kan ti o kere, lẹyinnaa, ti o ba di ọjọ ikẹyin Maa dari rẹ ni ifipamuni lọsi ibi iya ina, siọ ibudesi eyiti o sẹri sibẹ ni Ọjọ Igbende.
Dajudaju awọn Musulumi, biotiwulẹ ki wọn se daadaa to fun awọn Yahuudi ati awọn Nasaara, wọn ko nii yọnu lailai titi wọn yoo fi yọ wọn kuro ninu ẹsin wọn, ti wọn yoo si maa tẹle wọn lori anu wọn,
Jijẹ asiwaju ninu ẹsin ko nii jẹ ohun ti ọwọ yoo tẹ ayaafi pẹlu amọdaju ti o ni alaafia ati mima se suuru lori mima mu asẹ Ọlọhun Ọba (ti ọla Rẹ ga) wa.
Alubarika adua Ibraheem (ki ọla maa jẹ tirẹ) fun ilu ọwọ nni, nigbati Ọlọhun Ọba se ni aaye kan, ti o ni ifọkanbalẹ fun awọn eniyan, ti o si se ọla fun awọn ti wọn ngbe ibẹ pẹlu oniranran arisiki.