قَالَ مَا مَنَعَكَ أَلَّا تَسۡجُدَ إِذۡ أَمَرۡتُكَۖ قَالَ أَنَا۠ خَيۡرٞ مِّنۡهُ خَلَقۡتَنِي مِن نَّارٖ وَخَلَقۡتَهُۥ مِن طِينٖ 12
Ọlọhun Ọba Allah sọ fun esu niti iruju: ki ni yoo kọ fun ọ lati mase tẹle asẹ ti Mo pa ọ wipe ki o fi ori balẹ fun Aadamọ? Esu fesi fun Ọlọhun Ọba rẹ: lilọjuu lọ ni o kọ fun mi, O dami lati inu ina, O si daa lati inu amọ, ina si niyi ju amọ lọ.
قَالَ فَٱهۡبِطۡ مِنۡهَا فَمَا يَكُونُ لَكَ أَن تَتَكَبَّرَ فِيهَا فَٱخۡرُجۡ إِنَّكَ مِنَ ٱلصَّٰغِرِينَ 13
Ọlọhun Ọba Allah sọ fun un, kuro ninu alujannah, ko si aaye fun ọ ki o se igberaga nibẹ; toripe o jẹ ile awọn ẹniire, ẹni mimọ, ko tọ ki o mọ wa nibẹ dajudaju iwọ jẹ - irẹ ibilisu - ninu awọn ẹni ilẹ, ẹni yẹpẹrẹ, ko da bi o ba wo ara rẹ pe o niyi ju Aadamọ lọ.
قَالَ أَنظِرۡنِيٓ إِلَىٰ يَوۡمِ يُبۡعَثُونَ 14
Esu sọ wipe: irẹ Ọlọhun Ọba mi, lọ mi lara titi di ọjọ igbende ki nle si lọna ẹniti o ba wu mi lati si lọna ninu awọn eniyan.
قَالَ إِنَّكَ مِنَ ٱلۡمُنظَرِينَ 15
Ọlọhun Ọba Allah sọ fun un pe, dajudaju - irẹ ibilisu - ninu awọn ti maa lọ lara ni iwọ yoo wa, awọn ti mo ba kọ iku mọ ni ọjọ ifanfere akọkọ nigba ti gbogbo ẹda ba ku lapapọ, yoo sẹku adẹda wọn nikan soso.
قَالَ فَبِمَآ أَغۡوَيۡتَنِي لَأَقۡعُدَنَّ لَهُمۡ صِرَٰطَكَ ٱلۡمُسۡتَقِيمَ 16
Ibilisu sọpe: nitori sisọ mi nu titi ti mo fi gbe asẹ Rẹ ju silẹ lati fi ori balẹ fun Aadamọ, baa joko de awọn arọmọdọmọ Aadamọ ni oju ọna Rẹ ti o duro tọ; ki nle kọ di wọn, ati sọ wọn nu kuro nibẹ gẹgẹ bi emi naa se sọnu kuro nibi iforikanlẹ fun baba wọn Aadamọ.
ثُمَّ لَأٓتِيَنَّهُم مِّنۢ بَيۡنِ أَيۡدِيهِمۡ وَمِنۡ خَلۡفِهِمۡ وَعَنۡ أَيۡمَٰنِهِمۡ وَعَن شَمَآئِلِهِمۡۖ وَلَا تَجِدُ أَكۡثَرَهُمۡ شَٰكِرِينَ 17
Lẹyin igba naa, maa waa ba wọn ni gbogbo ọna ti wọn ko fi nii fẹ ọrun, ti wọn yoo si maa se oju kokoro si ile aye, ti maa si fi iruju ti o pọ silẹ, emi yoo maa se awọn adun lọsọ, iwọ ko nii ri - irẹ Ọlọhun Ọba mi - ọpọ wọn ni ẹniti yoo dupẹ fun Ọ latara keferi ti maa ti pe si wọn lẹnu.
قَالَ ٱخۡرُجۡ مِنۡهَا مَذۡءُومٗا مَّدۡحُورٗاۖ لَّمَن تَبِعَكَ مِنۡهُمۡ لَأَمۡلَأَنَّ جَهَنَّمَ مِنكُمۡ أَجۡمَعِينَ 18
Ọlọhun Ọba Allah sọ fun: jade - irẹ ibilisu - kuro ninu Alujannah ni ẹni eebu, ẹniti a le kuro nibi ikẹ Ọlọhun Ọba Allah, Emi yoo fi iwọ ati ẹniti o ba tẹle ọ tabi o tẹle asẹ Rẹ ti o si yapa asẹ Ọlọhun Ọba rẹ kun ina jahanamọ ni ọjọ igbende.
وَيَٰٓـَٔادَمُ ٱسۡكُنۡ أَنتَ وَزَوۡجُكَ ٱلۡجَنَّةَ فَكُلَا مِنۡ حَيۡثُ شِئۡتُمَا وَلَا تَقۡرَبَا هَٰذِهِ ٱلشَّجَرَةَ فَتَكُونَا مِنَ ٱلظَّٰلِمِينَ 19
Ọlọhun Ọba Allah sọ fun Aadamọ - irẹ Aadamọ - maa gbe iwọn ati iyawo rẹ , Hawahu, ninu Alujanna, ki ẹyin mejeeji si maa jẹ ninu ohun ti o mọ, ti o wu yin nibẹ, ẹ mase jẹ nibi igi yii (igi ti Ọlọhun Ọba se adayanri rẹ fun wọn) tori wipe ẹyin mejjeji ti ẹ ba jẹ nibẹ lẹyin igbati a ti kọ fun yin, ẹyin mejeeji yoo di ẹniti o kọja ẹnu aala Ọlọhun Ọba Allah.
فَوَسۡوَسَ لَهُمَا ٱلشَّيۡطَٰنُ لِيُبۡدِيَ لَهُمَا مَا وُۥرِيَ عَنۡهُمَا مِن سَوۡءَٰتِهِمَا وَقَالَ مَا نَهَىٰكُمَا رَبُّكُمَا عَنۡ هَٰذِهِ ٱلشَّجَرَةِ إِلَّآ أَن تَكُونَا مَلَكَيۡنِ أَوۡ تَكُونَا مِنَ ٱلۡخَٰلِدِينَ 20
Esu pe ọrọ kẹlẹkẹlẹ si wọn; lati se afihan ohun ti wọn fi bo wọn lara kuro nibi ihoho, o wa sọ fun awọn mejeeji, ki ni ohun ti o kọ fun yin lati le jẹ ninu igi yii, bikose wipe kikọ ki ẹ mọ baa di Malaika meji ni, tabi kikọ ki ẹ mọ baa di ẹniti yoo maa gbe ninu alujannah gbere.
وَقَاسَمَهُمَآ إِنِّي لَكُمَا لَمِنَ ٱلنَّٰصِحِينَ 21
O si fi Ọlọhun Ọba Allah bura fun wọn: dajudaju mo jẹ fun yin - irẹ Aadamọ ati Hawahu - oluse isiti nibi nkan ti mo ntọka rẹ fun yin ni.
فَدَلَّىٰهُمَا بِغُرُورٖۚ فَلَمَّا ذَاقَا ٱلشَّجَرَةَ بَدَتۡ لَهُمَا سَوۡءَٰتُهُمَا وَطَفِقَا يَخۡصِفَانِ عَلَيۡهِمَا مِن وَرَقِ ٱلۡجَنَّةِۖ وَنَادَىٰهُمَا رَبُّهُمَآ أَلَمۡ أَنۡهَكُمَا عَن تِلۡكُمَا ٱلشَّجَرَةِ وَأَقُل لَّكُمَآ إِنَّ ٱلشَّيۡطَٰنَ لَكُمَا عَدُوّٞ مُّبِينٞ 22
O mu wọn sọkalẹ kuro ni aaye ti awọn mejeeji wa pẹlu ete ati kitanjẹ lati ọdọ rẹ nigbati awọn mejeeji jẹ ninu igi ti wọn kọ fun wọn, ihoho ti wọn wa si han si wọn. Wọn bẹrẹ sini wa ewe ninu alujannah lati fi bora; ki awọn mejeeji fi le bo ihoho wọn, Ọlọhun Ọba wọn waa pe wọn ni ẹniti o sọ bayi wipe, se kii se wipe ko kọ fun yin ni kuro nibi jijẹ igi yii, Mo si nsọ fun ẹyin mejeeji ni ẹniti nse ikilọ: dajudaju esu jẹ ọta fun ẹyin mejeeji, ni ọta ti o fi oju han? !
Awọn amin yii tọka lori wipe ẹniti o ba sẹ olowo rẹ ti di ẹni yẹpẹrẹ.
Esu kede jijẹ ọta rẹ fun ọmọ Aadamọ, O si se adehun wipe oun yoo di wọn ni oju ọna ti o duro tọ pẹlu gbogbo oniranran itẹgun ati okunfa.
Ewu ẹsẹ ati wipe dajudaju ohun ni okunfa awọn iya Ọlọhun Ọba Allah ni ile aye ati ni ọrun.