يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِذَا نَٰجَيۡتُمُ ٱلرَّسُولَ فَقَدِّمُواْ بَيۡنَ يَدَيۡ نَجۡوَىٰكُمۡ صَدَقَةٗۚ ذَٰلِكَ خَيۡرٞ لَّكُمۡ وَأَطۡهَرُۚ فَإِن لَّمۡ تَجِدُواْ فَإِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٌ 12
Nigbati awọn ọmọlẹyin anọbi pọ ni pipe anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun; Allah sọpe: mo pe ẹyin ti ẹ nigbagbọ, nigbati ẹ ba gbero lati ba ojisẹ naa sọrọ ni kẹlẹkẹlẹ yin, ki ẹ yaa ti ọrẹnta siwaju, titi ọrẹnta siwaju naa jẹ oore fun yin ati mimọ julọ; nitori titẹle ti Allah ti o wa nibẹ, ti yoo fọ awọn ẹmin mọ, ti ẹ ko ba ri ohun ti ẹ o fi se ọrẹnta, ko si wahala fun yin nibi biba sọrọ kẹlẹkẹlẹ, dajudaju Allah jẹ oluforijin awọn ẹsẹ awọn ẹru Rẹ, Onikẹ si wọn nitoripe ko la bọ wọn lọrun ju ohun ti wọn lagbara lọ.
ءَأَشۡفَقۡتُمۡ أَن تُقَدِّمُواْ بَيۡنَ يَدَيۡ نَجۡوَىٰكُمۡ صَدَقَٰتٖۚ فَإِذۡ لَمۡ تَفۡعَلُواْ وَتَابَ ٱللَّهُ عَلَيۡكُمۡ فَأَقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتُواْ ٱلزَّكَوٰةَ وَأَطِيعُواْ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥۚ وَٱللَّهُ خَبِيرُۢ بِمَا تَعۡمَلُونَ 13
Se ẹ nbẹru osi ni nitori titi ọrẹnta siwaju nigbati ojisẹ ba pe yin?! Ti ẹ ko ba se ohun ti Allah pasẹ rẹ, ti o si gba ironu piwada yin nitori sise ni fifuyẹ fun yin nibi gbigbe e ju silẹ, ki ẹ yaa ki irun ni ojupọnna pipe, ki ẹ si yọ afọmọ awọn dukia yin, ki ẹ si tẹle Allah ati ojisẹ Rẹ, Allah jẹ olufuni niro ohun ti ẹ nse nisẹ, nkankan ko pamọ fun Un ninu isẹ yin, yoo si san yin lẹsan le lori.
۞أَلَمۡ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ تَوَلَّوۡاْ قَوۡمًا غَضِبَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِم مَّا هُم مِّنكُمۡ وَلَا مِنۡهُمۡ وَيَحۡلِفُونَ عَلَى ٱلۡكَذِبِ وَهُمۡ يَعۡلَمُونَ 14
Se o ko ri ni - irẹ ojisẹ - awọn sọbẹ selo ti wọn se atilẹyin fun awọn yahuudi, awọn ti Allah ti binu si nitori keferi wọn ati asise wọn, awọn sọbẹ selu yii wọn kii se ara awọn onigbagbọ, bẹẹni wọn kii se ara yahuudi bikosepe wọn jẹ oloju eji, wọn ko si pẹlu awọn eniyan yii, wọn ko si si pẹlu awọn eniyan naa, wọn yoo si maa bura pe olugbafa ni awọn, atipe awọn ko gbe iro awọn olugbafa fun awọn yahuudi, wọn si jẹ opurọ nibi ibura wọn.
أَعَدَّ ٱللَّهُ لَهُمۡ عَذَابٗا شَدِيدًاۖ إِنَّهُمۡ سَآءَ مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ 15
Allah ti pese iya ti o le koko fun wọn ni ọrun nitoripe yoo ki wọn bọ ipele isalẹ ninu ina, dajudaju awọn isẹ keferi ti wọn wa ninu rẹ ni ile aye buru.
ٱتَّخَذُوٓاْ أَيۡمَٰنَهُمۡ جُنَّةٗ فَصَدُّواْ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ فَلَهُمۡ عَذَابٞ مُّهِينٞ 16
Wọn mu awọn ibura wọn eyiti wọn nbu yii ni idaabobo kuro nibi ipani nitori keferi nitoripe wọn se afihan ẹsin alaafia lati fi sọ ẹjẹ wọn ati awọn dukia wọn, wọn si yi awọn eniyan kuro nibi ododo nitori irẹwẹsi ati iduro sinsin fun awọn olugbafa ti wọn wa nibẹ, iya iyẹpẹrẹ ti yoo yẹpẹrẹ wọn ti yoo si doju ti wọn nbẹ fun wọn.
لَّن تُغۡنِيَ عَنۡهُمۡ أَمۡوَٰلُهُمۡ وَلَآ أَوۡلَٰدُهُم مِّنَ ٱللَّهِ شَيًۡٔاۚ أُوْلَٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِۖ هُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ 17
Awọn dukia wọn ko le rọ wọn lọrọ, bẹẹni awọn ọmọ wọn naa ko le rọ wọn lọrọ kankan ni ọdọ Allah, awọn wọnyi ni ẹni ina ti wọn yoo wọ inu ina gbere, ti iya ko nii ja kuro fun wọn lailai.
يَوۡمَ يَبۡعَثُهُمُ ٱللَّهُ جَمِيعٗا فَيَحۡلِفُونَ لَهُۥ كَمَا يَحۡلِفُونَ لَكُمۡ وَيَحۡسَبُونَ أَنَّهُمۡ عَلَىٰ شَيۡءٍۚ أَلَآ إِنَّهُمۡ هُمُ ٱلۡكَٰذِبُونَ 18
Ọjọ ti Allah yoo gbe wọn dide ni apapọ, ti ko nii sẹku ẹnikankan ninu wọn ayaafi ki o le gbe dide fun ẹsan, wọn yoo wa maa bura fun Allah wipe wọn ko si lori keferi ati sọbẹ selu bikosepe wọn jẹ olugbagbọ ti o se ohun ti yoo yọ Allah ninu, wọn yoo maa bura fun Un ni ọrun gẹgẹ bi wọn se nbura fun yin - ẹyin olugbagbọ ododo - ni aye wipe awọn jẹ olugbafa, wọn yoo si maa lero wipe ibura ti awọn nbu yii fun Allah lori nkankan kna wa ninu ohun ti o le mu anfaani wa fun tabi mu inira kuro fun wọn, tẹti gbọ dajudaju olupurọ tootọ ni wọn jẹ nibi awọn ibura wọn ni ile aye ati awọn ibura wọn ni ọrun.
ٱسۡتَحۡوَذَ عَلَيۡهِمُ ٱلشَّيۡطَٰنُ فَأَنسَىٰهُمۡ ذِكۡرَ ٱللَّهِۚ أُوْلَٰٓئِكَ حِزۡبُ ٱلشَّيۡطَٰنِۚ أَلَآ إِنَّ حِزۡبَ ٱلشَّيۡطَٰنِ هُمُ ٱلۡخَٰسِرُونَ 19
Esu ti jẹ gaba le wọn lori, o si mu wọn gbagbe iranti Allah nitori royiroyi rẹ, wọn ko se ohun ti yoo yọ ninu bikosepe wọn se ẹohun ti yoo bi ninu ni, awọn wọnyi ni ẹniti a fi awọn iroyin yii royin, awọn ni awọn ọmọ ogun esu ati awọn olutẹle rẹ, tẹti gbọ dajudaju awọn ọmọ ogun esu ati awọn olutẹle rẹ ni ẹni ofo ni aye ati ni ọrun, wọn ti ta ọnaamọ fi ra anu ati alujanna fi ra ina.
إِنَّ ٱلَّذِينَ يُحَآدُّونَ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥٓ أُوْلَٰٓئِكَ فِي ٱلۡأَذَلِّينَ 20
Dajudaju awọn ti wọn nba Allah se ọta, ti wọn si nba ojisẹ Rẹ naa se ọta, awọn wọnyi ni akojọ ẹniti Allah yoo yẹpẹrẹ wọn ni aye ati ni ọrun, yoo si doju ti wọn ninu awọn ijọ alaimoore.
كَتَبَ ٱللَّهُ لَأَغۡلِبَنَّ أَنَا۠ وَرُسُلِيٓۚ إِنَّ ٱللَّهَ قَوِيٌّ عَزِيزٞ 21
Allah ti dajọ nibi imọ Rẹ ti o gbawaju wipe dajudaju emi ati awọn ojisẹ mi ni yoo ri aranse lori awọn ọta wa pẹlu awijare ati agbara, dajudaju Allah jẹ alagbara lori sise aranse fun awọn ojisẹ Rẹ, oniyi ti yoo gbẹsan lara awọn ọta wọn.
Aanu Allah fun anọbi rẹ ti ikẹ ati ọla nbẹ fun; nitoripe o kọ awọn ọmọlẹyin anọbi lẹkọ pẹlu ki o ma jẹ wahala fun un nibi pipe pupọ.
Isedari awọn yahuudi wa ninu isesi awọn sọbẹ selu.
Ofo awọn keferi ati ibori awọn onigbagbọ jẹ isesi Ọlọhun ti o le lọra sugbọn ko le rọpo.