يَوۡمَ تَرَى ٱلۡمُؤۡمِنِينَ وَٱلۡمُؤۡمِنَٰتِ يَسۡعَىٰ نُورُهُم بَيۡنَ أَيۡدِيهِمۡ وَبِأَيۡمَٰنِهِمۖ بُشۡرَىٰكُمُ ٱلۡيَوۡمَ جَنَّٰتٞ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَاۚ ذَٰلِكَ هُوَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡعَظِيمُ 12
Ọjọ ti iwọ yoo ri awọn olugbagbọ ododo lọkunrin ati lobinrin ti imọlẹ wọn yoo gbawaju wọn ati ni ẹgbẹ ọtun wọn, wọn yoo wa sọ fun wọn ni ọjọ yii pe: ẹ ku idunnu oni pẹlu ọgba idẹra ti awọn akeremọdo nsan ni abẹ awọn orulẹ ibẹ ati awọn igi ibẹ, ti ẹ o maa gbe ibẹ lọ gbere, ẹsan yii ni erenjẹ ti o tobi, ti erenjẹ kankan ko sun mọ ọ. Nigbati Allah sọ isesi awọn olugbagbọ ododo ni ọjọ yii, O tun sọ isesi awọn sọbẹ selu, O wa sọpe:
Nigbati Allah sọ isesi awọn olugbagbọ ododo ni ọjọ yii, O tun sọ isesi awọn sọbẹ selu, O wa sọpe:
يَوۡمَ يَقُولُ ٱلۡمُنَٰفِقُونَ وَٱلۡمُنَٰفِقَٰتُ لِلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱنظُرُونَا نَقۡتَبِسۡ مِن نُّورِكُمۡ قِيلَ ٱرۡجِعُواْ وَرَآءَكُمۡ فَٱلۡتَمِسُواْ نُورٗاۖ فَضُرِبَ بَيۡنَهُم بِسُورٖ لَّهُۥ بَابُۢ بَاطِنُهُۥ فِيهِ ٱلرَّحۡمَةُ وَظَٰهِرُهُۥ مِن قِبَلِهِ ٱلۡعَذَابُ 13
Ọjọ ti awọn sọbẹ selu lọkunrin ati awọn sọbẹ selu lobinrin yoo sọ fun awọn olugbagbọ ododo wipe: ẹ ni suuru fun wa ki a le mu ninu imọlẹ yin eyiti yoo ran wa lọwọ lati kọja lori afara siraati, wọn yoo si maa sọ fun awọn sọbẹ selu niti fifi wọn se yẹyẹ: ẹ pada si ẹyin yin, ki ẹ maa wa imọlẹ ti ẹ o fi riran, wọn yoo wa fi awọn odi si aarin wọn, ti ẹnu ọna nbẹ fun odi naa, ikẹ ti yoo bẹ fun awọn olugbagbọ ododo nbẹ ni inu rẹ, iya ti yoo bẹ fun awọn sọbẹ selu wa ni ode rẹ.
يُنَادُونَهُمۡ أَلَمۡ نَكُن مَّعَكُمۡۖ قَالُواْ بَلَىٰ وَلَٰكِنَّكُمۡ فَتَنتُمۡ أَنفُسَكُمۡ وَتَرَبَّصۡتُمۡ وَٱرۡتَبۡتُمۡ وَغَرَّتۡكُمُ ٱلۡأَمَانِيُّ حَتَّىٰ جَآءَ أَمۡرُ ٱللَّهِ وَغَرَّكُم بِٱللَّهِ ٱلۡغَرُورُ 14
Awọn sọbẹ selu yoo maa pe awọn olugbagbọ ododo ni ẹniti o sọ bayi wipe: kii wa sepe a wa pẹlu yin lori ẹsin alaafia ni ati itẹle asẹ?! Awọn olugbafa yoo sọ fun wọn: bẹẹni, ẹ wa pẹlu wa sugbọn ẹ daamun ẹmin ara yin pẹlu sise sọbẹ selu, ẹ si mu iparun ba a, ẹ si ndẹdẹ awọn olugbagbọ ododo lati bori wọn, ki ẹ le kede sise keferi yin, ẹ si se iyemeji si aranse Allah fun awọn olugbagbọ ododo ati ajinde lẹyin iku, ẹ si mu itanjẹ ba awọn wọbia opurọ titi iku fi waa ba yin, ẹ si wa lori eleyi ti esu fi tan yin jẹ nipa Allah.
فَٱلۡيَوۡمَ لَا يُؤۡخَذُ مِنكُمۡ فِدۡيَةٞ وَلَا مِنَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْۚ مَأۡوَىٰكُمُ ٱلنَّارُۖ هِيَ مَوۡلَىٰكُمۡۖ وَبِئۡسَ ٱلۡمَصِيرُ 15
Ni oni wọn ko nii gba lọwọ yin -ẹyin sọbẹ selu- ifidi kuro nibi iya Allah, bẹẹni wọn ko nii gba ifidi lọwọ awọn ti wọn se keferi si Allah ni gbangba, ibusẹri si yin ati ibusẹrisi awọn keferi si jẹ ina, ohun ni o lẹtọ fun yin ju, ẹyin ni ẹ si lẹtọ si i ju, o si buru ni ibusẹrisi.
۞أَلَمۡ يَأۡنِ لِلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ أَن تَخۡشَعَ قُلُوبُهُمۡ لِذِكۡرِ ٱللَّهِ وَمَا نَزَلَ مِنَ ٱلۡحَقِّ وَلَا يَكُونُواْ كَٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ مِن قَبۡلُ فَطَالَ عَلَيۡهِمُ ٱلۡأَمَدُ فَقَسَتۡ قُلُوبُهُمۡۖ وَكَثِيرٞ مِّنۡهُمۡ فَٰسِقُونَ 16
Se ko to asiko fun awọn ti wọn nigbagbọ ninu Allah ati si ojisẹ Rẹ ni ki ọkan wọn rọ, ki o si tun balẹ fun iranti Allah ti mimọ nbẹ fun ati ohun ti o sọkalẹ ninu Alukuraani gẹgẹ bi adehun daadaa ati adehun iya, ki ma da gẹgẹ bi awọn ti wọn fun taoreeta ninu awọn yahuudi ati awọn ti wọn fun ni injiila ninu awọn nasaarọ nibi lile koko ọkan, asiko gun laarin wọn ati asiko ti wọn gbe awọn anọbi wọn dide, eleyi ni o fa lile koko ọkan wọn, ọpọ wọn si jade kuro nibi itẹle ti Allah nibi yiyapa Rẹ?!
ٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ يُحۡيِ ٱلۡأَرۡضَ بَعۡدَ مَوۡتِهَاۚ قَدۡ بَيَّنَّا لَكُمُ ٱلۡأٓيَٰتِ لَعَلَّكُمۡ تَعۡقِلُونَ 17
Ki ẹ mọ wipe dajudaju Allah ni ẹniti o nji ilẹ pẹlu mimu hu lẹyin ọgbẹlẹ rẹ, paapaa a ti se alaye fun yin -ẹyin eniyan- awọn ẹri ati awọn awijare lori agbara Allah ati awọn ijọkan soso Rẹ ni ireti ki ẹ le se laakaye pẹlu rẹ; ki nẹ si le mọ wipe dajudaju ẹniti o nta ilẹ ji lẹyin iku rẹ jẹ alagbara lati ta yin ji lẹyin iku yin, O si lagbara lati sọ ọkan yin di rirọ lẹyin lile koko rẹ.
إِنَّ ٱلۡمُصَّدِّقِينَ وَٱلۡمُصَّدِّقَٰتِ وَأَقۡرَضُواْ ٱللَّهَ قَرۡضًا حَسَنٗا يُضَٰعَفُ لَهُمۡ وَلَهُمۡ أَجۡرٞ كَرِيمٞ 18
Dajudaju awọn ti wọn nna apakan dukia wọn lọkunrin ati awọn ti wọn nna apakan dukia wọn lobinrin, awọn ti o nna pẹlu ẹmin ti o dara ti kii se ti iregun tabi suta, wọn yoo se adipele awọn isẹ wọn fun wọn: daadaa yoo maa jẹ mẹwa apejuwe rẹ ni ẹsan titi di ọgọrun meje adipele titi di awọn adipele ti o pọ, pẹlu eleyi naa ẹsan ti o lapọnle nbẹ fun wọn lọdọ Allah, ohun si ni ọgba idẹra naa.
Sise idẹkun Allah lori awọn olugbagbọ ododo pẹlu fifun wọn ni imọlẹ kan ti yoo maa bẹ ni iwaju wọn ati ni abala ọtun wọn.
Awọn ẹsẹ ati sọbẹ selu jẹ okunfa okunkun ati iparun ni ọjọ igbende.
Mimọa dẹ awọn olugbagbọ ododo lẹkẹ ati sise iyemeji si igbende ati gbigba itanjẹ pẹlu awọn erongba ati gbigba itanjẹ pẹlu esu: wa ninu awọn iroyin sọbẹ selu.
Ewu ifọnu ti o ma nmu ki awọn ọkan le koko.