فَقَضَىٰهُنَّ سَبۡعَ سَمَٰوَاتٖ فِي يَوۡمَيۡنِ وَأَوۡحَىٰ فِي كُلِّ سَمَآءٍ أَمۡرَهَاۚ وَزَيَّنَّا ٱلسَّمَآءَ ٱلدُّنۡيَا بِمَصَٰبِيحَ وَحِفۡظٗاۚ ذَٰلِكَ تَقۡدِيرُ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡعَلِيمِ 12
Allah si pe isẹda gbogbo sanmọ ni ọjọ meji: ọjọbọ ati ọjọ ẹti, pẹlu mejeeji yii ni isẹda gbogbo sanmọ ati ilẹ se jẹ ijọ mẹfa, Allah si ransẹ si gbogbo sanmọ pẹlu gbogbo ohun ti O pebubu sibẹ ati ohun ti O pa lasẹ nipa itẹle ati ijọsin, a si se ọsọ si sanmọ aye pẹlu awọn irawọ, bẹẹni a si nfi daabobo jiji ọrọ gbọ awọn esu ninu sanmọ, gbogbo eleyi ti a sọ yii jẹ ipebubu alagbara eyiti ẹnikankan ko le bori, Onimimọ nipa ẹda Rẹ.
فَإِنۡ أَعۡرَضُواْ فَقُلۡ أَنذَرۡتُكُمۡ صَٰعِقَةٗ مِّثۡلَ صَٰعِقَةِ عَادٖ وَثَمُودَ 13
Ti awọn wọnyi ba gunri kuro nibi igbagbọ si ohun ti o mu wa, ki o ya sọ fun wọn - irẹ ojisẹ -: mo nfi iya ti yoo sẹlẹ le yin lori dẹruba yin, apejuwe iru iya eyiti o sẹlẹ si hadi ijọ Hud ati samuud ijọ Sọlihu nigbati wọn pe awọn mejeeji nirọ.
إِذۡ جَآءَتۡهُمُ ٱلرُّسُلُ مِنۢ بَيۡنِ أَيۡدِيهِمۡ وَمِنۡ خَلۡفِهِمۡ أَلَّا تَعۡبُدُوٓاْ إِلَّا ٱللَّهَۖ قَالُواْ لَوۡ شَآءَ رَبُّنَا لَأَنزَلَ مَلَٰٓئِكَةٗ فَإِنَّا بِمَآ أُرۡسِلۡتُم بِهِۦ كَٰفِرُونَ 14
Nigbati awọn ojisẹ wọn wa ba wọn, apakan wọn tẹle apakan pẹlu ipepe kan soso ti wọn pa wọn lasẹ rẹ pe wọn ko gbọdọ sin nkankan ayaafi Allah nikan soso, awọn keferi ninu wọn sọpe: ti Ọlọhun wa ba fẹ sọ awọn Malaaika kalẹ fun wa ni ojisẹ ki ba sọ wọn kalẹ, dajudaju awa jẹ keferi si ohun ti wọn fi ran yin; nitoripe ẹyin jẹ abara bii ti wa.
فَأَمَّا عَادٞ فَٱسۡتَكۡبَرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ بِغَيۡرِ ٱلۡحَقِّ وَقَالُواْ مَنۡ أَشَدُّ مِنَّا قُوَّةًۖ أَوَ لَمۡ يَرَوۡاْ أَنَّ ٱللَّهَ ٱلَّذِي خَلَقَهُمۡ هُوَ أَشَدُّ مِنۡهُمۡ قُوَّةٗۖ وَكَانُواْ بَِٔايَٰتِنَا يَجۡحَدُونَ 15
Sugbọn 'Aadu tii se ijọ Hudu, pẹlu sise keferi wọn si Allah, wọn se igberaga lorilẹ ni ọna ti ko tọ, wọn si se abosi awọn ti o rokirika wọn, wọn si sọpe ni ẹniti wọn ti gba itanjẹ pẹlu agbara wọn: taani o lagbara ju wa lọ?! Ko si ẹnikankan ti o lagbara ju wọn lọ ninu erongba wọn, Allah wa da pada si wọn: se awọn wọnyi ko wa mọ ni, bẹẹni se wọn ko ri wipe dajudaju Allah ti o da wọn, ti o si fun wọn lagbara ti o nmu wọn kọja ẹnu aala yii, Oun ni ẹniti O lagbara ju wọn lọ?! Wọn si jẹ ẹniti o nse aimoore si awọn amin Allah eyiti Hudu mu wa - ẹniti ọla nbẹ fun -.
فَأَرۡسَلۡنَا عَلَيۡهِمۡ رِيحٗا صَرۡصَرٗا فِيٓ أَيَّامٖ نَّحِسَاتٖ لِّنُذِيقَهُمۡ عَذَابَ ٱلۡخِزۡيِ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۖ وَلَعَذَابُ ٱلۡأٓخِرَةِ أَخۡزَىٰۖ وَهُمۡ لَا يُنصَرُونَ 16
A si gbe atẹgun kan ti o mu ni ohun ibẹru ni awọn ọjọ buruku le wọn lori nitori iya ti o wa nibẹ; ki a le fun wọn ni iya iyẹpẹrẹ ati idoju tini tọ wo ni isẹmin aye, bẹẹni iya ọrun eyiti o nreti wọn lagbara ni iyẹpẹrẹ ju, wọn ko si nii ri ẹniti yoo ran wọn se lati yọ wọn kuro ninu iya naa.
وَأَمَّا ثَمُودُ فَهَدَيۡنَٰهُمۡ فَٱسۡتَحَبُّواْ ٱلۡعَمَىٰ عَلَى ٱلۡهُدَىٰ فَأَخَذَتۡهُمۡ صَٰعِقَةُ ٱلۡعَذَابِ ٱلۡهُونِ بِمَا كَانُواْ يَكۡسِبُونَ 17
Sugbọn Thamuudu tii se ijọ Sọlihu, paapaa a ti fi wọn mọ ọna pẹlu sise adayanri ọna ododo fun wọn, wọn wa gbe ọla fun anu lori imọna lọsi ibi ododo, iya iyẹpẹrẹ wa gba wọn mu nitori keferi ati awọn ẹsẹ ti wọn se nisẹ.
وَنَجَّيۡنَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَكَانُواْ يَتَّقُونَ 18
A si la awọn ti o nigbagbọ ninu Allah ati awọn ojisẹ Rẹ, wọn jẹ ẹniti o npaya Allah nipa mimu awọn asẹ Rẹ sẹ ati jijinna si awọn nkan ti o kọ, a la wọn kuro ninu iya eyiti o sẹlẹ si awọn ijọ wọn.
وَيَوۡمَ يُحۡشَرُ أَعۡدَآءُ ٱللَّهِ إِلَى ٱلنَّارِ فَهُمۡ يُوزَعُونَ 19
Ati ni ọjọ ti Allah yoo ko awọn ọta Rẹ jọ sinu ina, ti awọn oludaabobo ina yoo maa da akọkọ wọn pada si ẹni ikẹyin wọn, wọn ko nii nikapa lati sa kuro ninu ina.
حَتَّىٰٓ إِذَا مَا جَآءُوهَا شَهِدَ عَلَيۡهِمۡ سَمۡعُهُمۡ وَأَبۡصَٰرُهُمۡ وَجُلُودُهُم بِمَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ 20
Titi ti wọn yoo fi de ibi ina eyiti wọn nda wọn lọ si ibẹ, wọn yoo wa se alaimọ si nkan ti wọn se ni ile aye, awọn etigbọ wọn yoo maa gbẹri le wọn lori ati awọn iriran wọn ati awọn awọ wọn nipa ohun ti wọn se ni ile aye nipa keferi ati awọn ẹsẹ.
Igunri kuro nibi ododo jẹ okunfa iparun ni ile aye ati lọrun.
Igberaga ati gbigba itanjẹ pẹlu agbara, mejeeji jẹ ohun ti nkọ fun ni kuro nibi titẹriba fun ododo.
Awọn keferi jẹ ẹniti wọn ko iya aye ati ti ọrun papọ fun.
Ijẹri awọn orikerika ara lori awọn ẹni rẹ ni ọjọ igbende.