۞وَلَكُمۡ نِصۡفُ مَا تَرَكَ أَزۡوَٰجُكُمۡ إِن لَّمۡ يَكُن لَّهُنَّ وَلَدٞۚ فَإِن كَانَ لَهُنَّ وَلَدٞ فَلَكُمُ ٱلرُّبُعُ مِمَّا تَرَكۡنَۚ مِنۢ بَعۡدِ وَصِيَّةٖ يُوصِينَ بِهَآ أَوۡ دَيۡنٖۚ وَلَهُنَّ ٱلرُّبُعُ مِمَّا تَرَكۡتُمۡ إِن لَّمۡ يَكُن لَّكُمۡ وَلَدٞۚ فَإِن كَانَ لَكُمۡ وَلَدٞ فَلَهُنَّ ٱلثُّمُنُ مِمَّا تَرَكۡتُمۚ مِّنۢ بَعۡدِ وَصِيَّةٖ تُوصُونَ بِهَآ أَوۡ دَيۡنٖۗ وَإِن كَانَ رَجُلٞ يُورَثُ كَلَٰلَةً أَوِ ٱمۡرَأَةٞ وَلَهُۥٓ أَخٌ أَوۡ أُخۡتٞ فَلِكُلِّ وَٰحِدٖ مِّنۡهُمَا ٱلسُّدُسُۚ فَإِن كَانُوٓاْ أَكۡثَرَ مِن ذَٰلِكَ فَهُمۡ شُرَكَآءُ فِي ٱلثُّلُثِۚ مِنۢ بَعۡدِ وَصِيَّةٖ يُوصَىٰ بِهَآ أَوۡ دَيۡنٍ غَيۡرَ مُضَآرّٖۚ وَصِيَّةٗ مِّنَ ٱللَّهِۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَلِيمٞ 12
Ati wipe yoo maa bẹ fun yin ẹyin ọkọ ilaji ohun ti awọn iyawo yin ba fi silẹ; ti ko ba si ọmọ fun wọn, - o jẹ ọkunrin ni tabi obirin -, lati ọdọ yin tabi lati ọdọ ẹniti o yatọ si yin, ti o ba waa jẹ wipe ọmọ nbẹ fun wọn, - ọkunrin ni o jẹ ni tabi obirin -, yoo maa bẹ fun yin ida kan ninu ida mẹrin ninu ohun ti o ba fi silẹ, wọn yoo maa pin nkan naa fun yin lẹyin mimu asọtẹlẹ wọn sẹ, ati sisan ohun ti o wa fun wọn ninu gbese, ati wipe yoo maa bẹ fun awọn iyawo ida kan ninu idamẹrin ohun ti ẹ ba fi silẹ - ẹyin ọkọ -, ti ko ba si ọmọ fun yin, - o jẹ ọkunrin ni tabi obirin - lati ọdọ wọn tabi lati ọdọ ẹniti o yatọ si wọn, ti o ba wa jẹ wipe ọmọ wa fun yin, - ọkunrin ni o jẹ tabi obirin -, yoo maa jẹ ti wọn ida kan ninu idamẹjọ ninu ohun ti ẹ ba fi silẹ, wọn yoo maa pin nkan naa fun wọn lẹyin mimu asọtẹlẹ yin sẹ, ati sisan ohun ti o wa lori yin ninu gbese, ati wipe ti ọkunrin kan ba ku, ti ko si baba fun un ati ọmọ, tabi obirin kan ni o ba ku, ti ko si baba fun un ati ọmọ, ati wipe ti o wa nbẹ fun ẹniti o ku ninu awọn mejeeji ọmọ iya l’ọkunrin tabi ọmọ iya l’obirin; yoo maa bẹ fun ọkọọkan ninu awọn ọmọ iya rẹ lọkunrin, tii se ti iya rẹ tabi ọmọ iya rẹ l’obirin tii se ti iya rẹ, ida kan ninu idamẹfa ni ọranyan, ti o ba wa jẹ wipe ọmọ iya l’ọkunrin naa ti o jẹ ti iya, tabi awọn ọmọ iya l’obirin naati o jẹ ti iya, ba pọ ju ẹyọkan lọ; yoo maa bẹ fun gbogbo wọn ida kan ninu idamẹta ni ọranyan, ti wọn yoo ko ẹgbẹ de ibẹ, ti ọkunrin wọn ati obirin wọn yoo se deedee nibi nkan naa, ati wipe dajudaju wọn yoo maa gba ipin wọn yii lẹyin mimu asọtẹlẹ oku sẹ, ati sisan ohun ti o wa lori rẹ ninu gbese pẹlu majẹmu wipe ki asọtẹlẹ rẹ ma mu inira wa fun awọn to yoo jogun naa; gẹgẹ bi ki asọtẹlẹ rẹ jẹ ohun ti o pọ ju idamẹta owo rẹ lọ, idajọ yii ẹyiti aayah naa ko sinu ni adehun lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah si ọdọ yin, ti O si se ni dandan fun yin ati wipe Ọlọhun Ọba Allah ni onimimọ nipa ohun ti o le se atunse awọn ẹru RẸ ni ile aye ati ni ọrun, Onisuuru si ni, ti kii kanju ifiyajẹ ẹlẹsẹ.
تِلۡكَ حُدُودُ ٱللَّهِۚ وَمَن يُطِعِ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ يُدۡخِلۡهُ جَنَّٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَاۚ وَذَٰلِكَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡعَظِيمُ 13
Awọn idajọ naa ti o jẹ sisọ nibi alamọri awọn ọmọ orukan ati awọn ti o yatọ si wọn jẹ awọn ofin Ọlọhun Ọba Allah, eyiti O se ni ofin fun awọn ẹrusin RẸ, ki wọn le baa mọ Ọ, ati wipe ẹniti o ba tẹle Ọlọhun Ọba Allah ati ojisẹ Rẹ pẹlu mimu awọn asẹ Rẹ wa si imusẹ ati jijinna si ohun ti O kọ, Ọlọhun Ọba Allah yoo mu wọ awọn Ọgba Idẹra, ti awọn akeremọdu nsan ni abẹ awọn aafin rẹ, ti wọn yoo maa bẹ nibẹ lọ gbere, ti titan ko si nii le wọn ba, ati wipe ẹsan Ọlọhun Ọba naa, ohun ni erenjẹ ti o tobi, eyiti ẹrenjẹ kankan ko lee jọ.
وَمَن يَعۡصِ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ وَيَتَعَدَّ حُدُودَهُۥ يُدۡخِلۡهُ نَارًا خَٰلِدٗا فِيهَا وَلَهُۥ عَذَابٞ مُّهِينٞ 14
Ẹniti o ba yapa Ọlọhun Ọba Allah ati ojisẹ Rẹ pẹlu yiyi awọn idajọ Rẹ loju po, ati gbigbe sise isẹ pẹlu rẹ ju silẹ, tabi sise iyemeji nibẹ, ati wipe ti o wa nkọja ẹnu aala ohun ti o se lofin, yoo mu wọ ina kan, ti yoo maa bẹ nibẹ lọ gbere, o si nbẹ nibẹ fun un iya ti o ma nyẹpẹrẹ eniyan.
Wọn ko nii pin awọn dukia laarin awọn ti wọn fẹ jogun, titi ti wọn yoo fi san ohun ti o wa fun oku ninu gbese, ti wọn yoo si tun mu asọtẹlẹ rẹ jade nibẹ, eyiti ko lẹtọ lati kọja idamẹta ninu dukia rẹ.
Kikilọ fun ni nibi sise atẹtẹrẹ nibi pinpin awọn ogun; toripe dajudaju ohun jẹ adehun Ọlọhun Ọba Allah ati asọtẹlẹ Rẹ fun awọn ẹrusin Rẹ, olugbagbọ ododo, ko waa lẹtọ lati gbe ju silẹ tabi lati se atẹtẹrẹ nibẹ.
Ninu awọn apẹrẹ igbagbọ ni mima mu awọn asẹ Ọlọhun Ọba Allah wa si imusẹ, ati gbigbe awọn ohun ti O kọ tobi, ati kikora duro ni awọn ẹnu aala Rẹ.
Ninu deede Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) ati oye Rẹ ni wipe dajudaju ẹniti o ba tẹle, O se adehun ẹsan ti o tobi fun un, ati wipe ẹniti o ba yapa Rẹ, ti o si tun kọja ẹnu aala Rẹ, O se adehun iya ti o tobi fun un.