يَٰيَحۡيَىٰ خُذِ ٱلۡكِتَٰبَ بِقُوَّةٖۖ وَءَاتَيۡنَٰهُ ٱلۡحُكۡمَ صَبِيّٗا 12
Wọn si bi yahya fun un nigbati o de ọjọ ori ti wọn le ba a sọrọ, a si sọ wipe: irẹ Yahya, gba taoreeta mu pẹlu igbamun gidi ati igbiyanju, a si fun ni agbọye, imọ ati igbiyanju ati ipinnu nigbati o wa ni ọjọ ori ọmọde.
وَحَنَانٗا مِّن لَّدُنَّا وَزَكَوٰةٗۖ وَكَانَ تَقِيّٗا 13
A kẹ ninu ikẹ lati ọdọ Wa, a sọ fọ ọ mọ kuro nibi awọn ẹsẹ, o si jẹ olupaya ti o ma nse awọn asẹ Allah, ti o si njinna si awọn nkan ti O kọ.
وَبَرَّۢا بِوَٰلِدَيۡهِ وَلَمۡ يَكُن جَبَّارًا عَصِيّٗا 14
O jẹ ọmọọre si awọn eniyan ati alanu si awọn mejeeji, oluse daadaa si wọn, ko jẹ onigberaga si itẹle asẹ Ọlọhun Ọba rẹ tabi itẹle awọn obi rẹ mejeeji, ko si jẹ ẹlẹsẹ si Ọlọhun rẹ tabi si awọn obi rẹ mejeeji.
وَسَلَٰمٌ عَلَيۡهِ يَوۡمَ وُلِدَ وَيَوۡمَ يَمُوتُ وَيَوۡمَ يُبۡعَثُ حَيّٗا 15
Alaafia lati ọdọ Allah ki o maa bẹ fun un ati ifọkanbalẹ lati ọdọ Rẹ ni ọjọ ti wọn bi ati ọjọ ti yoo ku, ti yoo si jade kuro ninu isẹmin yii ati ọjọ ti wọn yoo gbe dide ni aaye ni igbende, awọn aaye mẹta wọnyi ni aaye ipaayun ju ti ọmọniyan yoo re kọja nibẹ, ti o ba ri ifakanbalẹ nibẹ, ko si ipaya fun mọ nibi ohun ti o yatọ si i.
وَٱذۡكُرۡ فِي ٱلۡكِتَٰبِ مَرۡيَمَ إِذِ ٱنتَبَذَتۡ مِنۡ أَهۡلِهَا مَكَانٗا شَرۡقِيّٗا 16
Tun ranti - irẹ ojisẹ - ninu Alukuraani ti a sọkalẹ fun ọ iro nipa Marayam ẹniti ọla nbẹ fun nigbati o jinna si awọn ara ile rẹ, ti o da wa ni aaye kan ni abala ibuyọ oorun.
فَٱتَّخَذَتۡ مِن دُونِهِمۡ حِجَابٗا فَأَرۡسَلۡنَآ إِلَيۡهَا رُوحَنَا فَتَمَثَّلَ لَهَا بَشَرٗا سَوِيّٗا 17
O si fi gaga bo ara rẹ kọdi awọn ijọ rẹ, ti yoo daabobo ti wọn ko fi ni le ri nigbati o ba nsin Ọlọhun Ọba rẹ, a si gbe Jibril ẹniti ọla nbẹ fun dide si i, o si hande si i gẹgẹ bi aworan eniyan ti o dọgba ni ẹda, o bẹru wipe boya o gbero aburu pẹlu rẹ ni.
قَالَتۡ إِنِّيٓ أَعُوذُ بِٱلرَّحۡمَٰنِ مِنكَ إِن كُنتَ تَقِيّٗا 18
Nigbati o ri ni aworan eniyan ti o dọgba, o da oju kọ ọ o si sọpe: dajudaju emi fi Ọba Ajọkẹ aye wa isọ kuro ni ọdọ rẹ ki aburu maa ba kan mi lati ọdọ rẹ -irẹ eleyi - ti o ba jẹ olupaya ti nbẹru Allah.
قَالَ إِنَّمَآ أَنَا۠ رَسُولُ رَبِّكِ لِأَهَبَ لَكِ غُلَٰمٗا زَكِيّٗا 19
Jibril ẹniti ọla nbẹ fun sọpe: emi kii se abara, emi kan jẹ ojisẹ lati ọdọ Ọlọhun Ọba rẹ, o si ransẹ si ọ ki nle ta ọ ni ọrẹ ọmọ ti o dara, ti o si mọ.
قَالَتۡ أَنَّىٰ يَكُونُ لِي غُلَٰمٞ وَلَمۡ يَمۡسَسۡنِي بَشَرٞ وَلَمۡ أَكُ بَغِيّٗا 20
Maryam sọ ni ẹniti o se eemọ: bawo ni ọmọ se fẹ wa fun mi ti ọkunrin kankan ko sun mọ mi tabi ẹlomiran, emi kii si se alagbere ti maa fi waa bi ọmọ?!
قَالَ كَذَٰلِكِ قَالَ رَبُّكِ هُوَ عَلَيَّ هَيِّنٞۖ وَلِنَجۡعَلَهُۥٓ ءَايَةٗ لِّلنَّاسِ وَرَحۡمَةٗ مِّنَّاۚ وَكَانَ أَمۡرٗا مَّقۡضِيّٗا 21
Jibril sọ fun: bi ọrọ se ri ni o se sọ wipe ọkunrin kankan ko fi ọwọ kan ọ tabi ẹniti o yatọ si i, bẹẹni iwọ ko si jẹ alagbere, sugbọn Ọlọhun Ọba rẹ ti mimọ nbẹ fun sọpe: dida ọmọ laisi baba rọrun fun mi, ki ọmọ ti A fẹ ta ọ lọrẹ le jẹ amin fun awọn eniyan lori agbara Allah ati ikẹ lọdọ wa fun ọ ati fun ẹniti o gba A gbọ, bẹẹni dida ọmọ rẹ yii jẹ eto lati ọdọ Allah ti O lagbara, o si jẹ ohun ti a kọ silẹ ninu ọpọn ti a daabobo.
۞فَحَمَلَتۡهُ فَٱنتَبَذَتۡ بِهِۦ مَكَانٗا قَصِيّٗا 22
O si loyun pẹlu rẹ lẹyin imisi Malaika, o si mu u takete si aaye kan ti o jinna si awọn eniyan.
فَأَجَآءَهَا ٱلۡمَخَاضُ إِلَىٰ جِذۡعِ ٱلنَّخۡلَةِ قَالَتۡ يَٰلَيۡتَنِي مِتُّ قَبۡلَ هَٰذَا وَكُنتُ نَسۡيٗا مَّنسِيّٗا 23
Ibimọ mu u, o si mu simin si ojugun igi ọpẹ, Maryam ẹniti ọla nbẹ fun sọpe: o mase fun mi ti emi ko ku siwaju ọjọ oni, ki nwaa jẹ ohun ti wọn ko ni maa sọ nipa rẹ, ti ko fi ni wa maa ro ohun ti ko dara pẹlu mi.
فَنَادَىٰهَا مِن تَحۡتِهَآ أَلَّا تَحۡزَنِي قَدۡ جَعَلَ رَبُّكِ تَحۡتَكِ سَرِيّٗا 24
Isa pe e ni abẹ gigisẹ rẹ: mase banujẹ paapaa Ọlọhun Ọba rẹ ti se kagawa omi si abẹ rẹ ti iwọ yoo mu ninu rẹ.
وَهُزِّيٓ إِلَيۡكِ بِجِذۡعِ ٱلنَّخۡلَةِ تُسَٰقِطۡ عَلَيۡكِ رُطَبٗا جَنِيّٗا 25
ki o gba egbo ọpẹ mu, ki o min in, awọn nkan tutu yoo maa jabọ le ọ lori, ti yoo si maa gbo ni asiko naa.
Suuru lori sise awọn nkan ti ofin ẹsin se ni dandan jẹ ohun ti a fẹ.
Giga ipo oore sise si awọn obi ati aaye ti o wa ni ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, Ọlọhun Ọba fi kun didupẹ fun Un.
Pẹlu pipe agbara Ọlọhun Ọba ninu awọn amin Rẹ ti o gbọngbọn eyiti o se afihan fun Maryam bikosepe o kan fẹ ki o se itẹgun lasan ki eso ọpẹ le de ọdọ rẹ ni.