وَعَلَى ٱلثَّلَٰثَةِ ٱلَّذِينَ خُلِّفُواْ حَتَّىٰٓ إِذَا ضَاقَتۡ عَلَيۡهِمُ ٱلۡأَرۡضُ بِمَا رَحُبَتۡ وَضَاقَتۡ عَلَيۡهِمۡ أَنفُسُهُمۡ وَظَنُّوٓاْ أَن لَّا مَلۡجَأَ مِنَ ٱللَّهِ إِلَّآ إِلَيۡهِ ثُمَّ تَابَ عَلَيۡهِمۡ لِيَتُوبُوٓاْۚ إِنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلتَّوَّابُ ٱلرَّحِيمُ 118
Paapaa Ọlọhun Ọba Allah ti gba ironu piwada awọn eniyan mẹta naa, awọn ni: Ka’b ọmọ malik, Murọọrọ ọmọ rọbi’i ati Hilaalu ọmọ humayah; awọn ti wọn yapa kuro nibi ironu piwada, wọn nfi gbigba ironu piwada wọn sẹyin lẹyin igbati wọn ti yapa lati jade pẹlu ojisẹ Allah ti ikẹ ati ọla nbẹ fun lọ si Taabuuki, Anọbi ti ikẹ ati ọla nbẹ fun waa pasẹ fun awọn eniyan lati yan wọn lodi, ibanujẹ ati ironu waa sẹlẹ si wọn lori eleyi titi ti ilẹ fi fun mọ wọn pẹlu bi o se fẹ to, ọkan wọn naa si fun pinpin nitori idawa ti o sẹlẹ si wọn, wọn waa mọ wipe ko si ibusẹrisi kankan fun awọn ju ki wọn o sẹri si ọdọ Allah nikan soso lọ, ki o le fi kongẹ rẹ kẹ wọn lati gba ironu piwada lẹyin igba naa Ọlọhun Ọba Allah si gba ironu piwada wọn nitori wipe o jẹ olugba ironu piwada awọn ẹru Rẹ, onikẹ si wọn.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَكُونُواْ مَعَ ٱلصَّٰدِقِينَ 119
Ẹyin ti ẹ nigbagbọ ninu Allah ti ẹ si tẹle ojisẹ Rẹ, ti ẹ si nse awọn ofin Rẹ, ẹ paya Allah pẹlu ki ẹ maa tẹle awọn asẹ Rẹ ati jijinna si awọn ohun ti O kọ, ki ẹ si maa wa pẹlu awọn sootọ sootọ nibi ọrọ wọn ati awọn isẹ wọn, ko si ibula fun yin ayaafi nibi ododo.
مَا كَانَ لِأَهۡلِ ٱلۡمَدِينَةِ وَمَنۡ حَوۡلَهُم مِّنَ ٱلۡأَعۡرَابِ أَن يَتَخَلَّفُواْ عَن رَّسُولِ ٱللَّهِ وَلَا يَرۡغَبُواْ بِأَنفُسِهِمۡ عَن نَّفۡسِهِۦۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ لَا يُصِيبُهُمۡ ظَمَأٞ وَلَا نَصَبٞ وَلَا مَخۡمَصَةٞ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ وَلَا يَطَُٔونَ مَوۡطِئٗا يَغِيظُ ٱلۡكُفَّارَ وَلَا يَنَالُونَ مِنۡ عَدُوّٖ نَّيۡلًا إِلَّا كُتِبَ لَهُم بِهِۦ عَمَلٞ صَٰلِحٌۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُضِيعُ أَجۡرَ ٱلۡمُحۡسِنِينَ 120
Ko tọ fun awọn ara Mẹdinah tabi fun awọn ara agbegbe rẹ ninu awọn ti wọn ngbe loko ki wọn o yapa ojisẹ nigbati o ba jade lati gbiyanju fun ara rẹ, ko si tọ fun wọn ki wọn o se ahun ara wọn, ki wọn o maa sọ ẹmin wọn kuro lọdọ rẹ, ohun ti o jẹ dandan fun wọn niki wọn o na ẹmin wọn nitori ẹmin tirẹ; eleyi nitori wipe ongbẹ ko le gbẹ wọn bẹẹ ni ko le rẹ wọn, ko si nii si ibi ni oju ọna Allah, bẹẹ ni wọn ko nii le sọkalẹ si aaye ti yoo bi awọn keferi ninu, ti wọn ko si ni ri iku lati ọdọ ọta tabi imuni lẹru tabi ikọrọ tabi ibori –ayaafi ki Ọlọhun Ọbna Allah kọ ẹsan isẹẹre fun wọn, ti yoo tẹwọgba lọwọ wọn, dajudaju Allah ko nii ra ẹsan awọn oluse daadaa lare bikose wipe Yoo fi wọn se kongẹ Rẹ ni pipe, Yoo si se alekun fun wọn nibẹ.
وَلَا يُنفِقُونَ نَفَقَةٗ صَغِيرَةٗ وَلَا كَبِيرَةٗ وَلَا يَقۡطَعُونَ وَادِيًا إِلَّا كُتِبَ لَهُمۡ لِيَجۡزِيَهُمُ ٱللَّهُ أَحۡسَنَ مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ 121
Wọn ko nii na dukia kan o kere ni tabi o pọ, bẹẹ ni wọn ko niire kọja ninu ọgbun kan ayaafi ki o kọ ohun ti wọn se yii silẹ boya nkan nina ni tabi irin ajo, ki Ọlọhun Ọba Allah le fun wọn lẹsan, yoo wa fun wọn ni ẹsan ohun ti dara ju ohun ti wọn se lọ ni ọrun.
۞وَمَا كَانَ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ لِيَنفِرُواْ كَآفَّةٗۚ فَلَوۡلَا نَفَرَ مِن كُلِّ فِرۡقَةٖ مِّنۡهُمۡ طَآئِفَةٞ لِّيَتَفَقَّهُواْ فِي ٱلدِّينِ وَلِيُنذِرُواْ قَوۡمَهُمۡ إِذَا رَجَعُوٓاْ إِلَيۡهِمۡ لَعَلَّهُمۡ يَحۡذَرُونَ 122
Ko tọ fun awọn olugbagbọ ododo ki wọn jade lati lọ jagun lapapọ ki ọta maa ba pa wọn patapata, kilo de ti ipin ko jade fun igbiyanju ninu wọn, ki awọn ipin miran si maa wa pẹlu ojisẹ Allah ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, ki wọn o maa kọ ẹkọ ẹsin ti wọn ngbọ ni ọdọ rẹ ninu Alukuraani ati awọn idajọ ofin, ki wọn si le maa se ikilọ fun awọn ijọ wọn nigbati wọn ba sẹri lọ si ọdọ wọn pẹlu nkan ti wọn ti kọ; ki wọn le ba sọ ra kuro nibi iya Ọlọhun Ọba, ki wọn le maa tẹle asẹ Rẹ, ki wọn si maa jinna si awọn ohun ti O kọ, eleyi jẹ nibi awọn ogun ipamọ eyiti ojisẹ Allah gbe dide lọsi awọn aaye kan, o si se awọn abala kan ninu awọn ọmọlẹyin rẹ lẹsa fun un.
Jijẹ ọranyan ipaya Ọlọhun Ọba ati ododo, ati wipe awọn mejeeji jẹ okunfa ọla kuro nibi iparun.
Titobi ọla ti nbẹ fun mima na nkan si oju ọna Ọlọhun Ọba Allah.
Jijẹ dandan nina ohun ti a ni sibi ẹsin, iru rẹ naa ni igbiyanju naa ati wipe ẹsin ko le duro ayaafi pẹlu mejeeji lapapọ.