وَلَوۡ شَآءَ رَبُّكَ لَجَعَلَ ٱلنَّاسَ أُمَّةٗ وَٰحِدَةٗۖ وَلَا يَزَالُونَ مُخۡتَلِفِينَ 118
Ti Ọlọhun Ọba rẹ ba fẹ ni - irẹ ojisẹ - lati sọ gbogbo awọn eniyan di ijọ kan lori ododo ki ba se e, sugbọn ko fẹ eleyi, wọn ko nii yẹ ni ẹniti yoo maa yapa si ara wọn nitori titẹle ifẹ inu ati tẹnbẹlẹkun.
إِلَّا مَن رَّحِمَ رَبُّكَۚ وَلِذَٰلِكَ خَلَقَهُمۡۗ وَتَمَّتۡ كَلِمَةُ رَبِّكَ لَأَمۡلَأَنَّ جَهَنَّمَ مِنَ ٱلۡجِنَّةِ وَٱلنَّاسِ أَجۡمَعِينَ 119
Ayaafi awọn ti Ọlọhun Ọba ba fi kongẹ Rẹ kẹ lati ri imọna, dajudaju awọn wọnyi ko nii yapa nibi mimu Ọlọhun Ọba lọkan soso ti mimọ nbẹ fun nitori idanwo yii lori yiyapa ni Ọlọhun Ọba se da wọn, o nbẹ ninu wọn oloriibu ati oloriire, gbolohun ọba rẹ si ti pari - ire ojise - pe eyiti o ti kọsilẹ ni ibẹrẹ pẹpẹ lati fi awọn ti ntẹle esu ati alujannah kun jahanamọ.
وَكُلّٗا نَّقُصُّ عَلَيۡكَ مِنۡ أَنۢبَآءِ ٱلرُّسُلِ مَا نُثَبِّتُ بِهِۦ فُؤَادَكَۚ وَجَآءَكَ فِي هَٰذِهِ ٱلۡحَقُّ وَمَوۡعِظَةٞ وَذِكۡرَىٰ لِلۡمُؤۡمِنِينَ 120
Gbogbo iro ti a ba sọ fun ọ - ire ojise - ninu iroyin awọn ojisẹ ti wọn ti siwaju rẹ, a sọ iroyin yii nitori fifi ọkan rẹ rinlẹ lori ododo ati fifun un lagbara, paapaa ododo ti ko si iyemeji ti waa ba ọ ninu suura yii, bẹẹ ni isiti fun awọn keferi ti waa ba ọ nibẹ ati iranti fun awọn olugbagbọ ododo ti wọn yoo se anfaani pẹlu iranti.
وَقُل لِّلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ ٱعۡمَلُواْ عَلَىٰ مَكَانَتِكُمۡ إِنَّا عَٰمِلُونَ 121
Tun sọ: - irẹ ojisẹ - fun awọn ti ko nigbagbọ ninu Allah, ti wọn ko si mu lọkan soso: ẹ maa sisẹ lojupọna yin nipa gigunri kuro nibi ododo ati kikọ di i, dajudaju awa naa yoo maa sisẹ ni oju ọna tiwa nibi diduro sinsin le lori ati pipepe sibẹ ati sise suuru le lori.
وَٱنتَظِرُوٓاْ إِنَّا مُنتَظِرُونَ 122
Ẹ maa sọ nkan ti wọn sọkalẹ fun wa, dajudaju awa naa yoo maa sọ nkan ti wọn sọkalẹ fun yin.
وَلِلَّهِ غَيۡبُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَإِلَيۡهِ يُرۡجَعُ ٱلۡأَمۡرُ كُلُّهُۥ فَٱعۡبُدۡهُ وَتَوَكَّلۡ عَلَيۡهِۚ وَمَا رَبُّكَ بِغَٰفِلٍ عَمَّا تَعۡمَلُونَ 123
Ti Ọlọhun Ọba nikan ni imọ nkan ti o pamọ ninu sanmọ ati ohun ti o pamọ si inu ilẹ, nkankan ko pamọ fun un, ọdọ Rẹ si nikan ni alamọri gbogbo nkan yoo sẹri si ni ọjọ igbende, maa sin In - irẹ ojisẹ - ni Oun nikan soso, ki o si gbe ara le nibi gbogbo alamọri rẹ, Ọlọhun Ọba rẹ kii se ẹniti o fọnu nipa gbogbo nkan ti ẹ nse nisẹ, bikose wipe o jẹ onimimọ nipa rẹ, yoo si san gbogbo ẹnikẹni lẹsan ohun ti o se.
سورة (MAKIYYAH)
Wiwoye si pẹlẹpẹlẹ ti Allah fi ngbe ọrọ awọn aayo rẹ yẹwo ati gbigba wọn laaye, ati bi igbẹyin wọn se dara.
الٓرۚ تِلۡكَ ءَايَٰتُ ٱلۡكِتَٰبِ ٱلۡمُبِينِ 1
(الٓر) (Alif, Lam, Rọ) ọrọ ti gbawaju lori rẹ ati iru iran rẹ ni ibẹrẹ ọgba ọrọ bakọrah, awọn aayah yii ti o sọkalẹ ninu suurah yii ninu awọn aayah alukuraani ti nkan ti o ko sinu fi oju han.
إِنَّآ أَنزَلۡنَٰهُ قُرۡءَٰنًا عَرَبِيّٗا لَّعَلَّكُمۡ تَعۡقِلُونَ 2
Dajudaju awa ni a sọ alukuraani kalẹ ni ede larubawa ki ẹ le ba - ẹyin larubawa - gbagbọye awọn itumọ rẹ.
نَحۡنُ نَقُصُّ عَلَيۡكَ أَحۡسَنَ ٱلۡقَصَصِ بِمَآ أَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡكَ هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانَ وَإِن كُنتَ مِن قَبۡلِهِۦ لَمِنَ ٱلۡغَٰفِلِينَ 3
Awa ni a nsọ ọ fun ọ - irẹ ojisẹ - itan ti o dara ju nitori jijẹ ododo rẹ ati lila awọn gbolohun rẹ ati ọrọ ijinlẹ rẹ pẹlu sisọ ti a sọ alukuraani kalẹ fun ọ, dajudaju o jẹ ẹniti o fọnu nipa rẹ siwaju ki a to sọ ọ kalẹ fun ọ, iwọ ko nimọ nipa rẹ.
إِذۡ قَالَ يُوسُفُ لِأَبِيهِ يَٰٓأَبَتِ إِنِّي رَأَيۡتُ أَحَدَ عَشَرَ كَوۡكَبٗا وَٱلشَّمۡسَ وَٱلۡقَمَرَ رَأَيۡتُهُمۡ لِي سَٰجِدِينَ 4
A nfun ọ niro - irẹ ojisẹ - nigbati yusuf sọ fun baba rẹ Ya'quub: irẹ baba mi, dajudaju mo ri irawọ mọkanla lojuran, mo si tun ri oorun ati osupa, mo ri gbogbo wọn ni ẹniti o nfi ori balẹ fun mi, ala yii jẹ iro idunnu ikanju fun yuusuf ẹniti ọla nbẹ fun.
Sise alaye ọgbọn ti nbẹ nibi awọn itan inu alukuraani, ohun si ni fifi ọkan anọbi rinlẹ ati isiti fun awọn olugbagbọ ododo.
Jijẹ aaso fun Ọlọhun Ọba nibi imọ kọkọ ti ẹnikẹni ko ba kẹgbẹ nibẹ.
Ọgbọn ti o wa nibi sisọ alukuraani kalẹ ni ede larubawa ni ki larubawa le se laakaye pẹlu rẹ, ki o le ba mu de etigbọ ẹlomiran ti o yatọ si i.
Kikun alukuraani fun awọn itan eyiti o dara.