إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَن تُغۡنِيَ عَنۡهُمۡ أَمۡوَٰلُهُمۡ وَلَآ أَوۡلَٰدُهُم مِّنَ ٱللَّهِ شَيۡٔٗاۖ وَأُوْلَٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِۖ هُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ 116
Dajudaju awọn ti wọn se aigbagbọ pẹlu Ọlọhun Ọba Allah ati awọn ojisẹ Rẹ, awọn dukia wọn ati awọn ọmọ wọn ko nii da aabo kankan bo wọn kuro ni ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, ko nii da iya pada Rẹ pada kuro ni ọdọ wọn, ati wipe ko nii fa ikẹ Rẹ fun wọn, bikose wipe yoo pada le wọn kun ni iya ati ofo, awọn naa ni awọn ijọ ina, ti wọn yoo maa dunni mọọ.
مَثَلُ مَا يُنفِقُونَ فِي هَٰذِهِ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا كَمَثَلِ رِيحٖ فِيهَا صِرٌّ أَصَابَتۡ حَرۡثَ قَوۡمٖ ظَلَمُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ فَأَهۡلَكَتۡهُۚ وَمَا ظَلَمَهُمُ ٱللَّهُ وَلَٰكِنۡ أَنفُسَهُمۡ يَظۡلِمُونَ 117
Apẹrẹ ohun ti awọn alaigbagbọ yii nna si oju ọna daadaa ati ohun ti wọn nreti ninu ẹsan rẹ, da gẹgẹ bi apẹrẹ atẹgun kan ti otutu ti o lagbara nbẹ nibẹ, ti o waa fi ọwọ ba ọgbin ijọ kan ti wọn se abosi ẹmi ara wọn pẹlu awọn iyapa ati ohun ti o yatọ sii, ni o ba run ọgbin wọn, ati wipe paapaa wọn nrankan oore ti o pọ nibẹ, gẹgẹ bi atẹgun yii se run nkan ọgbin naa, ti wọn ko waa se anfaani pẹlu rẹ, bakanna ni aigbagbọ yoo ba ẹsan awọn isẹ wọn eyiti wọn nrankan rẹ jẹ, ati wipe Ọlọhun Ọba Allah ko se abosi wọn - (ti ọla Rẹ ga) kuro nibi nkan naa -, ati wipe bikose wipe wọn se abosi ẹmin ara wọn ni pẹlu okunfa aigbagbọ wọn pẹlu rẹ ati bi wọn se pe awọn ojisẹ Rẹ ni onirọ.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَتَّخِذُواْ بِطَانَةٗ مِّن دُونِكُمۡ لَا يَأۡلُونَكُمۡ خَبَالٗا وَدُّواْ مَا عَنِتُّمۡ قَدۡ بَدَتِ ٱلۡبَغۡضَآءُ مِنۡ أَفۡوَٰهِهِمۡ وَمَا تُخۡفِي صُدُورُهُمۡ أَكۡبَرُۚ قَدۡ بَيَّنَّا لَكُمُ ٱلۡأٓيَٰتِۖ إِن كُنتُمۡ تَعۡقِلُونَ 118
Ẹyin ti ẹ ni igbagbọ pẹlu Ọlọhun Ọba Allah, ti wọn si tẹle ojisẹ Rẹ, ẹ mase mu awọn ọrẹ ati awọn aayo ninu awọn ti kii se olugbagbọ ododo, ti ẹ o maa jẹ ki wọn ri awọn kọkọ yin ati awọn ẹsa awọn isesi yin, toripe awọn ko nii tẹti nibi ohun ti yoo ko inira ba yin ati ibajẹ isesi yin, wọn yoo maa rankan sisẹlẹ ohun ti yoo niyin lara ati eyi ti yoo le koko fun yin, paapaa ikorira ti fi oju han ati isẹta lori awọn ahọn wọn pẹlu fifi ẹnu ẹgan kan ẹsin yin ati dida ogun silẹ laarin yin ati fifan awọn kọkọ yin ka, ohun ti awọn igbaaya wọn pamọ ninu ikorira si tobi pupọ, paapaa A ti se alaye fun yin -ẹyin olugbagbọ ododo- awọn awijare ti o fi oju han lori ohun ti daadaa yin nbẹ nibẹ ni aye ati ọrun, ti ẹ ba jẹ ẹniti o se laakaye nipa Ọlọhun Ọba yin si ohun ti O sọkalẹ fun yin.
هَٰٓأَنتُمۡ أُوْلَآءِ تُحِبُّونَهُمۡ وَلَا يُحِبُّونَكُمۡ وَتُؤۡمِنُونَ بِٱلۡكِتَٰبِ كُلِّهِۦ وَإِذَا لَقُوكُمۡ قَالُوٓاْ ءَامَنَّا وَإِذَا خَلَوۡاْ عَضُّواْ عَلَيۡكُمُ ٱلۡأَنَامِلَ مِنَ ٱلۡغَيۡظِۚ قُلۡ مُوتُواْ بِغَيۡظِكُمۡۗ إِنَّ ٱللَّهَ عَلِيمُۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ 119
Ha, ẹyin - olugbagbọ ododo yii - ni ẹ nfẹran awọn ijọ naa, ti ẹ si nrankan oore fun wọn, ti o si jẹ wipe awọn ko nifẹ yin, ati wipe wọn ko rankan oore fun yin, bikose wipe wọn ma nkorira yin, ti ẹyin si jẹ ẹniti o ni igbagbọ pẹlu awọn tira lapapọ, ati wipe o nbẹ nibẹẹ awọn tira wọn, ti o si jẹ wipe awọn ko ni igbagbọ pẹlu tira eyiti Ọlọhun Ọba Allah sọkalẹ fun Anọbi yin, ati wipe ti wọn ba pade yin, wọn yoo sọ pẹlu awọn ahọn wọn wipe: a gba ni ododo, ati wipe ti apakan wọn ba waa dawa pẹlu apakan, wọn yoo maa jẹ eteeti awọn ọmọnika wọn niti ibanujẹ ati ibinu si oun ti ẹ wa lori rẹ ninu ijọkan soso ati ipapọ gbolohun, ati iyi Islam, ati fun oun ti wọn wa lori rẹ ninu iyẹpẹrẹ. Sọ - irẹ Anọbi - fun awọn ijọ naa, ẹ maa sẹku si ori oun ti ẹ wa lori rẹ titi ẹ o fi ku niti ibanujẹ ati ibinu, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ni Olumọ oun ti nbẹ ninu awọn igbaaya ninu igbagbọ ati aini igbagbọ, ati oore ati aburu.
إِن تَمۡسَسۡكُمۡ حَسَنَةٞ تَسُؤۡهُمۡ وَإِن تُصِبۡكُمۡ سَيِّئَةٞ يَفۡرَحُواْ بِهَاۖ وَإِن تَصۡبِرُواْ وَتَتَّقُواْ لَا يَضُرُّكُمۡ كَيۡدُهُمۡ شَيًۡٔاۗ إِنَّ ٱللَّهَ بِمَا يَعۡمَلُونَ مُحِيطٞ 120
Ti o ba sẹlẹ si yin - ẹyin olugbagbọ ododo - idẹra kan ninu aranse lori ọta tabi alekun kan nibi owo ati ọmọ, ẹdun ọkan ati ibanujẹ yoo ba wọn, ti o ba sẹlẹ si yin adanwo kan ninu aranse ọta tabi adinku nibi owo ati ọmọ, wọn yoo maa yọ pẹlu nkan naa, wọn yoo si maa mu eebu wa pẹlu yin, ati wipe ti ẹ ba se suuru lori awọn asẹ Rẹ ati awọn kadara Rẹ, ti ẹ si paya ibinu Rẹ leyin lori, ete wọn ati suta wọn ko nii ko aburu ba yin, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ni Olurọkirika oun ti wọn nse ninu ete, ati wipe Yoo si da wọn pada ni ẹniti o pofo.
وَإِذۡ غَدَوۡتَ مِنۡ أَهۡلِكَ تُبَوِّئُ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ مَقَٰعِدَ لِلۡقِتَالِۗ وَٱللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ 121
Ati wipe ki o ranti –irẹ Anọbi- nigbati o jade ni akọkọ ọsan lati Mẹdinah lati lọọ ba awọn ọsẹbọ ja ni Huud, nibi ti o ti bẹrẹ ni ẹniti nsọ awọn olugbagbọ ododo kalẹ si awọn aaye wọn nibi ijagun naa, ti o si se alaye fun gbogbo ẹnikọọkan ipo rẹ, ati wipe Ọlọhun Ọba Allah ni nOLugbọ awọn gbolohun yii, Onimimọ nipa awọn isẹ yin.
Kikọ fun awọn olugbagbọ ododo kuro nibi mima mu awọn alaigbagbọ ni alagbọrọdun ati sisọ wọn di awọn ọrẹ ati awọn aayo, ti wọn yoo maa tu awọn isesi awọn olugbagbọ ododo fun ati awọn ikọkọ wọn.
Ninu aworan isọta awọn alaigbagbọ si awọn onigbagbọ ni yiyọ wọn pẹlu ohun ti o ba sẹlẹ si awọn olugbagbọ ododo ninu adanwo ati adinku, ati ibinu wọn nigbati oore ba kan wọn.
Isọra nibi idọgban awọn alaigbagbọ ati idete wọn yoo maa jẹ pẹlu suuru ati aise afihan ibẹru, lẹyin naa ni ipaya Ọlọhun Ọba Allah ati mimu awọn okunfa agbara ati aranse.