قَالَ عِيسَى ٱبۡنُ مَرۡيَمَ ٱللَّهُمَّ رَبَّنَآ أَنزِلۡ عَلَيۡنَا مَآئِدَةٗ مِّنَ ٱلسَّمَآءِ تَكُونُ لَنَا عِيدٗا لِّأَوَّلِنَا وَءَاخِرِنَا وَءَايَةٗ مِّنكَۖ وَٱرۡزُقۡنَا وَأَنتَ خَيۡرُ ٱلرَّٰزِقِينَ 114
Isa dahun ibeere wọn, o si pe Ọlọhun Ọba Allah ni ẹniti nsọ bayi wipe: iwọ Ọlọhun Ọba wa o, sọ tabili ounje kan kalẹ, ti a o sọ ọjọ ti o sọkalẹ di ọjọ ọdun, niti idupẹ fun Ọ, fun awon olusemi ninu wa loni, ati awon ti nbo leyin wa, ti yoo si jẹ amin ati awijare lori ijọkan soso Rẹ, ati jijẹ ododo nkan ti wọn gbe mi dide nitori rẹ, ki o si ran wa se ni aranse ti yoo ranwa lowo lori ijọsin Rẹ, iwọ - Ọlọhun Oba wa - ni o loore ju ni oluse arisiki.
قَالَ ٱللَّهُ إِنِّي مُنَزِّلُهَا عَلَيۡكُمۡۖ فَمَن يَكۡفُرۡ بَعۡدُ مِنكُمۡ فَإِنِّيٓ أُعَذِّبُهُۥ عَذَابٗا لَّآ أُعَذِّبُهُۥٓ أَحَدٗا مِّنَ ٱلۡعَٰلَمِينَ 115
Ọlọhun Ọba Allah se jẹ pe Anọbi Isa ẹniti ọla nbẹ fun, o wa sọ wipe: emi yoo sọ tabili ti ẹ beere fun kalẹ fun yin, ẹniti o ba se aimoore lẹyin sisọkalẹ, ko gbọdọ bu ẹnikankan ayaafi ẹmin ara rẹ, maa si fi iya ti o le koko jẹ, eyiti nko fi jẹ ẹnikankan ri, tori wipe o fi oju ri amin ti o han, sise aimoore si I jẹ isori kunkun, Ọlọhun Ọba Allah si pe adehun Rẹ, O si sọọ kalẹ le wọn lori.
وَإِذۡ قَالَ ٱللَّهُ يَٰعِيسَى ٱبۡنَ مَرۡيَمَ ءَأَنتَ قُلۡتَ لِلنَّاسِ ٱتَّخِذُونِي وَأُمِّيَ إِلَٰهَيۡنِ مِن دُونِ ٱللَّهِۖ قَالَ سُبۡحَٰنَكَ مَا يَكُونُ لِيٓ أَنۡ أَقُولَ مَا لَيۡسَ لِي بِحَقٍّۚ إِن كُنتُ قُلۡتُهُۥ فَقَدۡ عَلِمۡتَهُۥۚ تَعۡلَمُ مَا فِي نَفۡسِي وَلَآ أَعۡلَمُ مَا فِي نَفۡسِكَۚ إِنَّكَ أَنتَ عَلَّٰمُ ٱلۡغُيُوبِ 116
Ranti nigbati Ọlọhun Ọba Allah yoo maa sọ ni ọjọ igbende alukiyaamọ ni ẹniti nda oju kọ Isa ọmọ Maryam, ẹniti alaafia nbẹ fun; irẹ Isa ọmọ Maryam, njẹ o sọ fun awọn eniyan: wipe ẹ sọ emi ati mama mi di ẹniti ẹ yoo maa sin yatọ si Ọlọhun Ọba Allah? Isa fesi ni ẹniti nse afọmọ Ọlọhun Ọba rẹ, ko tọ fun mi, ki nsọ nkankan fun wọn ju ododo lọ, ti mo ba sọ nkankan fun wọn, paapaa julọ O ti mọ ọ nitori wipe nkankan ko pamọ fun ọ, O mọ ohun ti o pamọ si inu ọkan mi, emi ko mọ nkan ti o pamọ si inu ọkan Rẹ, iwọ nikan ni o mọ gbogbo kọkọ ati gbogbo ohun ti o pamọ, bẹẹ ni gbogbo nkan ti o han.
مَا قُلۡتُ لَهُمۡ إِلَّا مَآ أَمَرۡتَنِي بِهِۦٓ أَنِ ٱعۡبُدُواْ ٱللَّهَ رَبِّي وَرَبَّكُمۡۚ وَكُنتُ عَلَيۡهِمۡ شَهِيدٗا مَّا دُمۡتُ فِيهِمۡۖ فَلَمَّا تَوَفَّيۡتَنِي كُنتَ أَنتَ ٱلرَّقِيبَ عَلَيۡهِمۡۚ وَأَنتَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ شَهِيدٌ 117
Isa sọ fun Ọlọhun Ọba rẹ: emi ko sọ nkankan fun awọn eniyan ju nkan ti o pa mi lasẹ lọ, gẹgẹ bi wipe ki wọn o mu lọkan nibi ijọsin, mo si jẹ ẹniti nkiye si wọn lori nkan ti wọn nsọ, ni asiko ti mo fi wa laarin wọn, sugbọn nigbati mo lo asiko mi pẹlu wọn tan, pẹlu gbigbe mi lọ si oke san mọ ni aaye, Iwọ ni o jẹ - Iwọ Ọlọhun Ọba - olusọ gbogbo isẹ wọn, O si jẹ ẹlẹri lori gbogbo nkan, nkankan ko pamọ fun Ọ, bẹẹ ni nkankan ko pamọ fun Ọ ninu ohun ti mo sọ fun wọn, ati ohun ti wọn sọ lẹyin mi.
إِن تُعَذِّبۡهُمۡ فَإِنَّهُمۡ عِبَادُكَۖ وَإِن تَغۡفِرۡ لَهُمۡ فَإِنَّكَ أَنتَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ 118
Ti O ba fi iya jẹ wọn - irẹ Ọlọhun - ẹru Rẹ ni wọn nse, O le se ohun ti o wu Ọ pẹlu wọn, ti O ba se idẹkun le awọn ti o nigbagbọ ninu wọn lori pẹlu ki o se aforijin fun wọn, ko si ẹniti o le ta ko Ọ nibi eleyi, Irẹ ni alagbara ti ẹnikankan ko le bori rẹ, ati ọjọgbọn nibi eti idari Rẹ.
قَالَ ٱللَّهُ هَٰذَا يَوۡمُ يَنفَعُ ٱلصَّٰدِقِينَ صِدۡقُهُمۡۚ لَهُمۡ جَنَّٰتٞ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَآ أَبَدٗاۖ رَّضِيَ ٱللَّهُ عَنۡهُمۡ وَرَضُواْ عَنۡهُۚ ذَٰلِكَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡعَظِيمُ 119
Ọlọhun Ọba Allah sọ fun Isa ẹniti alaafia nbẹ fun: ootọ awọn ti adisọkan wọn dara nibi ootọ sisọ ati isẹẹre ati ọrọọre yoo se wọn ni anfaani, alujannah ti akeremọdo nsan ni abẹ awọn orule rẹ ati igi rẹ nbẹ fun wọn, wọn yoo maa gbe ibẹ lọ gbere, iku ko lee pa wọn, Ọlọhun Ọba Allah yoo yọnu si wọn, ko nii binu si wọn lailai, awọn naa yoo yọnu siI pẹlu ohun ti O ba se fun wọn ninu idẹkun gbere, eleyi ni ẹsan naa ati iyọnu si wọn, ohun ni erenjẹ ti o tobi, ko si erenjẹ ti o sun mọ ọ.
لِلَّهِ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا فِيهِنَّۚ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرُۢ 120
ikapa sanmọ mejeeje ati ilẹ ti Allah nikan ni, Oun ni O da wọn, ti O si ndari awọn alamọri rẹ, Oun ni O ni ikapa ohun ti o wa ninu wọn ninu gbogbo ẹda, O si lagbara lori gbogbo nkan, nkankan ko le ka lagara.
Ọlọhun Ọba Allah se adehun iya fun gbogbo ẹniti o ba se aimoore, ti o si se ori kunkun lẹyin igbati awijare ti o han ba ti wa fun un.
Bibọpa bọsẹ ẹni mimọ naa kuro nibi pipe apemọra ti awọn nasaara pe apimọra pe oun ni o mimọ ju, ati wipe oun ni ọlọhun tabi oun ni ọmọ ọlọhun, tabi oun ni ntọju gbogbo ẹda, ati ẹniti ijọsin tọsi.
Dajudaju Ọlọhun Ọba ti ọla Rẹ ga yoo beere ibeere lọwọ awọn eniyan pataki ati awọn ẹni iyi ninu awọn ojisẹ ni ọjọ igbende, bawo waa nki ti ẹniti ipo rẹ ko to wọn? !
Giga ipo ododo sisọ ati ẹyin Ọlọhun Ọba Allah fun awọn ẹni ootọ ati alaye anfaani ti o wa fun awọn ẹni ododo ni ọjọ igbende.