۞لَّا خَيۡرَ فِي كَثِيرٖ مِّن نَّجۡوَىٰهُمۡ إِلَّا مَنۡ أَمَرَ بِصَدَقَةٍ أَوۡ مَعۡرُوفٍ أَوۡ إِصۡلَٰحِۢ بَيۡنَ ٱلنَّاسِۚ وَمَن يَفۡعَلۡ ذَٰلِكَ ٱبۡتِغَآءَ مَرۡضَاتِ ٱللَّهِ فَسَوۡفَ نُؤۡتِيهِ أَجۡرًا عَظِيمٗا 114
Ko sii oore nibi ọpọlọpọ ọrọ ti nse afipamọ fun awọn eniyan, bẹẹni ko si anfaani nibẹ ayaafi ti o ba jẹ ọrọ ipani lasẹ sise saara, tabi daradara eyiti ofin mu wa bẹẹ ni ti laakaye si tọka sii, tabi pipe sibi atunse laarin olufanfa meji, ẹniti o ba se eleyi ni ẹniti o fi nwa iyọnu Ọlọhun Ọba Allah, A o pada fun ni ẹsan ti o tobi.
وَمَن يُشَاقِقِ ٱلرَّسُولَ مِنۢ بَعۡدِ مَا تَبَيَّنَ لَهُ ٱلۡهُدَىٰ وَيَتَّبِعۡ غَيۡرَ سَبِيلِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ نُوَلِّهِۦ مَا تَوَلَّىٰ وَنُصۡلِهِۦ جَهَنَّمَۖ وَسَآءَتۡ مَصِيرًا 115
Ẹniti o ba tako ojisẹ naa, ti o si yapa si ohun ti o muwa, lẹyin igbati o ododo ti han sii, ti o wa tẹle oju ọna ti o yatọ si oju ọna awọn olugbagbọ ododo, a o gbeju silẹ ati nkan ti o yan fun ẹmin rara rẹ, a o ni fi se kongẹ ododo nitori igunri kuro rẹ niti imọọmọ, a o ki wọ inu ina jahanamọ, yoo fi ara kin ooru rẹ, o si buru ni ibusẹri si fun awọn ẹni rẹ.
إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَغۡفِرُ أَن يُشۡرَكَ بِهِۦ وَيَغۡفِرُ مَا دُونَ ذَٰلِكَ لِمَن يَشَآءُۚ وَمَن يُشۡرِكۡ بِٱللَّهِ فَقَدۡ ضَلَّ ضَلَٰلَۢا بَعِيدًا 116
Dajudaju Ọlọhun Ọba Allah ko nii fi ori jin ẹniti o ba se ẹbọ pẹlu Rẹ, bikose wipe yoo jẹ ki ọsẹbọ ra si inu ina, Yoo si fi ori jin ohun ti ko to ẹbọ ninu ẹsẹ fun ẹniti o ba fẹ pẹlu ikẹ Rẹ ati ọla Rẹ, ẹniti o ba mu ẹnikẹni pẹlu Ọba Allah niti ẹbọ, o ti sọnu kuro nibi ododo, o si takete sii niti takete ti o pọ; toripe o se dọgba laarin adẹda ati ẹniti a da.
إِن يَدۡعُونَ مِن دُونِهِۦٓ إِلَّآ إِنَٰثٗا وَإِن يَدۡعُونَ إِلَّا شَيۡطَٰنٗا مَّرِيدٗا 117
Awọn ọsẹbọ yii, ti wọn npe nkan miran mọ Ọlọhun Ọba Allah, wọn ko sin ju oosa lọ, niti ohun ti wọn sọ wọn ni awọn orukọ abo gẹgẹ bi ‘laata’ ati ‘usa’, ko si anfaani fun un tabi inira, ohun ti wọn nsin nitootọ, ko jẹ ohunkohun ju eesu lọ, ti o jade kuro nibi itẹle Ọlọhun Ọba Allah, ti ko si oore nibẹ; toripe oun ni o pa wọn lasẹ sinsin oosa.
لَّعَنَهُ ٱللَّهُۘ وَقَالَ لَأَتَّخِذَنَّ مِنۡ عِبَادِكَ نَصِيبٗا مَّفۡرُوضٗا 118
Toribẹ ni Ọlọhun Ọba Allah fi le wọn kuro nibi ikẹẹ Rẹ, bẹẹni eesu sọ fun Ọlọhun Ọba rẹ ni ẹniti o nbura: maa mu ninu ẹru Rẹ ipin kan pato, maa sọ wọn nu kuro nibi ododo.
وَلَأُضِلَّنَّهُمۡ وَلَأُمَنِّيَنَّهُمۡ وَلَأٓمُرَنَّهُمۡ فَلَيُبَتِّكُنَّ ءَاذَانَ ٱلۡأَنۡعَٰمِ وَلَأٓمُرَنَّهُمۡ فَلَيُغَيِّرُنَّ خَلۡقَ ٱللَّهِۚ وَمَن يَتَّخِذِ ٱلشَّيۡطَٰنَ وَلِيّٗا مِّن دُونِ ٱللَّهِ فَقَدۡ خَسِرَ خُسۡرَانٗا مُّبِينٗا 119
Maa sẹri wọn kuro nibi oju ọna Rẹ ti o duro tọ, maa si fi wọn lọkan le awọn adehun irọ eyiti yoo se isẹnu wọn lọsọ fun wọn, maa si pa wọn lasẹ gige eti awọn ẹranko wọn lati le se ohun ti Ọlọhun Ọba Allah se ni ẹtọ di eewọ, maa si pa wọn lasẹ yiyi ẹda Ọlọhun Ọba pada ati isẹda rẹ, ẹniti o ba mu esu ni alatilẹyin yoo tẹwọ gbaa, yoo maa tẹle, paapaa o ti se ofo ni ofo ti o fi oju han pẹlu mimu esu ẹni ẹkọ ni alaayo.
يَعِدُهُمۡ وَيُمَنِّيهِمۡۖ وَمَا يَعِدُهُمُ ٱلشَّيۡطَٰنُ إِلَّا غُرُورًا 120
Esu nse adehun irọ fun wọn, o si nfi awọn ireti ibajẹ le wọn lọkan, ko si ohun ti o nse ni adehun fun ni tootọ ju ibajẹ lọ, ti ko si ododo fun un.
أُوْلَٰٓئِكَ مَأۡوَىٰهُمۡ جَهَنَّمُ وَلَا يَجِدُونَ عَنۡهَا مَحِيصٗا 121
Awọn wọnyi ni olutẹle ojupọnna esu ati ohun ti o npe fun wọn, kibusẹri si wọn ina jahanamọ, wọn ko nii ri ibusalọ kuro nibẹ lati sẹri sii.
Ọpọ ọrọ kẹlẹkẹlẹ awọn eniyan ko si oore nibẹ bikose wipe o seese ki ẹsẹ wa nibẹ, o kere ninu ọrọ wọn, ti o nsẹlẹ laarin wọn, ti rere ati daradara pamọ si ninu.
Isorikunkun si ojisẹ naa ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, ati yiyapa si oju ọna awọn olugbagbọ ododo, igbẹyin rẹ ijina si Ọlọhun Ọba Allah ati wiwọ ina.
Gbogbo ẹsẹ pata ni o wa ni abẹ fifẹ Ọlọhun Ọba Allah, paapa O le fi ori jin ẹnii Rẹ, ayaafi ẹbọ, Ọlọhun Ọba Allah ko nii fi orijin lailai, ti elese ko ba tuba, ti o si ku si ori re.
Ogogngo esu ni lati sẹri awọn eniyan kuro nibi ijọsin Ọlọhun Ọba Allah ti ọla Rẹ ga, ninu ojupọnna rẹ ti o tobi ju, ohun ni sise ibajẹ ni ọsọ pẹlu erongba itanjẹ ati awọn adehun irọ.