فَتَعَٰلَى ٱللَّهُ ٱلۡمَلِكُ ٱلۡحَقُّۗ وَلَا تَعۡجَلۡ بِٱلۡقُرۡءَانِ مِن قَبۡلِ أَن يُقۡضَىٰٓ إِلَيۡكَ وَحۡيُهُۥۖ وَقُل رَّبِّ زِدۡنِي عِلۡمٗا 114
Giga Ọlọhun Allah ati mimọ Rẹ ati gbigbọngbọn, Ọlọla eyiti o ni gbogbo nkan, ẹniti O jẹ ododo, ti gbolohun Rẹ naa si jẹ otitọ, O ga kọja iroyin ti awọn ẹlẹbọ fi nroyin Rẹ, ki o mase yara - ire ojise - nibi Alukuraani pẹlu Malaika Jibril, ki imude ogongo rẹ too de ọdọ rẹ, ki o si waa sọpe: Ọlọhun mi, lekun imọ mi lọsi ibi ohun ti o fi mọ mi.
Nigbati Ọlọhun Allah sọ itan Musa ati ohun ti o ko sinu ninu igunri fir'aona ati ifọnu awọn ọmọ isirẹli, O tun sọ itan Aadamọ ẹniti ọla nbẹ fun ni ẹniti o nse oju kokoro si sisẹri ẹniti o gbagbe lọsi ibi titẹle ti Allah, o wa sọpe:
وَلَقَدۡ عَهِدۡنَآ إِلَىٰٓ ءَادَمَ مِن قَبۡلُ فَنَسِيَ وَلَمۡ نَجِدۡ لَهُۥ عَزۡمٗا 115
Paapaa a ti sọ asọtẹlẹ fun Aadamọ siwaju wipe ki o ma jẹ ninu igi naa, A si kọ fun kuro nibi eleyi, bẹẹni A sọ igbẹyin rẹ fun un, o wa gbagbe asọtẹlẹ, o si jẹ ninu igi naa, ko si se suuru kuro nibẹ, A ko ri ipinu ẹmin ti o lagbara lori sisọ ohun ti a sọ asọtẹlẹ rẹ.
وَإِذۡ قُلۡنَا لِلۡمَلَٰٓئِكَةِ ٱسۡجُدُواْ لِأٓدَمَ فَسَجَدُوٓاْ إِلَّآ إِبۡلِيسَ أَبَىٰ 116
Ki o tun ranti - ire ojise - nigbati a sọ fun awọn Malaika wipe: ẹ furi balẹ fun Aadamọ ni iforibalẹ ikini, gbogbo wọn si fi ori balẹ ayaafi ibilisu - eyiti o wa pẹlu wọn sugbọn ti kii se ara wọn - o taku lati fi ori balẹ niti igberaga.
فَقُلۡنَا يَٰٓـَٔادَمُ إِنَّ هَٰذَا عَدُوّٞ لَّكَ وَلِزَوۡجِكَ فَلَا يُخۡرِجَنَّكُمَا مِنَ ٱلۡجَنَّةِ فَتَشۡقَىٰٓ 117
A si sọ wipe: irẹ Aadamọ dajudaju ibilisu jẹ ọta fun ọ ati ọta fun iyawo rẹ, ko gbọdọ mu ọ jade iwọ ati iyawo rẹ ninu ọgba idẹra pẹlu titẹle asẹ rẹ nibi ohun ti o ba nse royiroyi rẹ, ki o ma ba ru ẹru wahala rẹ ati nkan ikorira rẹ.
إِنَّ لَكَ أَلَّا تَجُوعَ فِيهَا وَلَا تَعۡرَىٰ 118
Dajudaju dandan ni fun ọba Allah ki o fun ọ ni ijẹ imu ninu ọgba idẹra ti ebi ko gbọdọ pa ọ, ki o si fi asọ bu ọ, o ko gbọdọ wa ni hoho.
وَأَنَّكَ لَا تَظۡمَؤُاْ فِيهَا وَلَا تَضۡحَىٰ 119
Ati ki o fun ọ ni ohun mimu, ongbẹ ko gbọdọ gbẹ ọ, ki O si sẹ iji bo ọ, ooru oorun tabi igbina oorun ko gbọdọ sẹlẹ si ọ.
فَوَسۡوَسَ إِلَيۡهِ ٱلشَّيۡطَٰنُ قَالَ يَٰٓـَٔادَمُ هَلۡ أَدُلُّكَ عَلَىٰ شَجَرَةِ ٱلۡخُلۡدِ وَمُلۡكٖ لَّا يَبۡلَىٰ 120
Esu si ko royiroyi ba Aadamọ, o wa sọ fun: se ki njuwe igi kan fun ọ ti ẹniti o ba jẹ nibẹ ko nii ku lailai, bikosepe yoo sẹku ni alaaye lailai, yoo si tun ni ọla kan ti yoo maa tẹsiwaju, ti ko nii ja, bẹẹni ko nii tan?!
فَأَكَلَا مِنۡهَا فَبَدَتۡ لَهُمَا سَوۡءَٰتُهُمَا وَطَفِقَا يَخۡصِفَانِ عَلَيۡهِمَا مِن وَرَقِ ٱلۡجَنَّةِۚ وَعَصَىٰٓ ءَادَمُ رَبَّهُۥ فَغَوَىٰ 121
Aadamọ ati hawawu si jẹ ninu igi naa eyiti wọn kọ fun wọn, ihoho wọn si han si wọn lẹyin igbati wọn ti wa ni ẹniti a ti bo ni asiri, wọn si bẹrẹ si ni ja ninu awọn ewe awọn igi ọgba idẹra naa, wọn wa nfi bo ihoho wọn, Aadamọ yapa asẹ Ọlọhun Ọba Rẹ nitoripe ko tẹle asẹ Rẹ lori jijinna si jijẹ igi naa, o kọja ẹnu aala lọsi ibi ohun ti ko tọ fun.
ثُمَّ ٱجۡتَبَٰهُ رَبُّهُۥ فَتَابَ عَلَيۡهِ وَهَدَىٰ 122
Lẹyin naa Ọlọhun Ọba rẹ si sa a lẹsa, O si gba ironu piwada rẹ, O wa fi se kongẹ lọsi ibi itọsọna.
قَالَ ٱهۡبِطَا مِنۡهَا جَمِيعَۢاۖ بَعۡضُكُمۡ لِبَعۡضٍ عَدُوّٞۖ فَإِمَّا يَأۡتِيَنَّكُم مِّنِّي هُدٗى فَمَنِ ٱتَّبَعَ هُدَايَ فَلَا يَضِلُّ وَلَا يَشۡقَىٰ 123
Ọlọhun Allah sọ fun Aadamọ ati hawawu: ẹ sọ kalẹ kuro ninu ọgba idẹra ẹyin mejeeji ati ibilisu, o jẹ ọta fun ẹyin mejeeji, ẹyin mejeeji naa si jẹ ọta fun un, ti alaye kan ba wa lati ọdọ Mi fun oju ọna Mi: ẹnikẹni ti o ba tẹle alaye oju ọna mi ninu yin ti o si siẹ pẹlu rẹ, ti ko si yẹ kuro nibẹ, ko nii sọnu kuro nibi ododo, bẹẹ ni ko nii se ori buruku ni ọrun pẹlu iya bikosepe Allah yoo fi wọ Alujannah.
وَمَنۡ أَعۡرَضَ عَن ذِكۡرِي فَإِنَّ لَهُۥ مَعِيشَةٗ ضَنكٗا وَنَحۡشُرُهُۥ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ أَعۡمَىٰ 124
Ẹniti o ba si gunri kuro nibi iranti mi ti ko tẹwọ gba a, ti ko si jẹ ipe rẹ dajudaju isẹmin ti o fun yoo maa bẹ fun ni ile aye ati agedegbe meji, a o si tun dari rẹ lọsi ibi akojọ ni ọjọ igbende ti yoo padanu iriran ati awijare.
قَالَ رَبِّ لِمَ حَشَرۡتَنِيٓ أَعۡمَىٰ وَقَدۡ كُنتُ بَصِيرٗا 125
Olugunri yii yoo sọ nipa iranti: irẹ Ọlọhun mi, kilode ti O fi gbe mi dide ni afọju loni, paapa mo si ti jẹ oluriran ni ile aye.
Ẹkọ wa nibi gbigba imọ ati wipe dajudaju olutẹti gbọ imọ lẹtọ ki o se pẹlu, ki o si se suuru titi ti ẹniti o npe e fun un ati olukọ yoo fi pari ọrọ rẹ eyiti apakan rẹ ni asepọ mọ apakan.
Adamọ gbagbe bẹẹni arọmọdọmọ rẹ naa gbagbe, ko si duro lori ipinnu ti a kan pa mọ, bẹẹ ni awọn naa se wa, o si yara ronu piwada Ọlọhun Ọba Allah si fi ori jin in, ẹniti o ba jọ baba rẹ ko se abosi.
Ọla ti nbẹ fun ironu piwada; nitoripe dajudaju Adamọ ẹniti ọla nbẹ fun jẹ ẹniti o dara ju bi o se wa siwaju ironu piwada lọ.
Isẹmin ti o nira wa ni ile aye ati ni agedegbe meji sugbọn o wa fun awọn ẹniti keferi ati anu ni ile ikẹyin.