وَقَالَتِ ٱلۡيَهُودُ لَيۡسَتِ ٱلنَّصَٰرَىٰ عَلَىٰ شَيۡءٖ وَقَالَتِ ٱلنَّصَٰرَىٰ لَيۡسَتِ ٱلۡيَهُودُ عَلَىٰ شَيۡءٖ وَهُمۡ يَتۡلُونَ ٱلۡكِتَٰبَۗ كَذَٰلِكَ قَالَ ٱلَّذِينَ لَا يَعۡلَمُونَ مِثۡلَ قَوۡلِهِمۡۚ فَٱللَّهُ يَحۡكُمُ بَيۡنَهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ فِيمَا كَانُواْ فِيهِ يَخۡتَلِفُونَ 113
Awọn Yahuudi sọ wipe: Awọn Nasaara ko si lori ẹsin ti o ni alaafia, awọn Nasaara naa sọ wipe: Awon Yahuudi ko si lori ẹsin ti o ni alaafia, gbogbo wọn ni wọn si nka ounti o ba aigbagbo re mu ninu tira re ati pipasẹ ini igbagbọ si gbogbo awọn Anọbi laini se iyato, afijo awọn wọnyi ninu isẹ ti wọn se yii jọ gbolohun awọn ti ko ni imọ ninu awọn ọsẹbọ; nigbati wọn pe gbogbo awọn ojise ni irọ ati awọn nkan ti wọn sọkalẹ fun wọn ninu tira, tori idi eleyi, Ọlọhun Ọba yoo dajọ laarin awọn ti wọn ntako ara wọn ni apapọ ni Ọjọ Igbende, pẹlu idajọ Rẹ ti o jẹ deede eyiti O ti fun awọn erusin Rẹ niro nipa rẹ: pe dajudaju ko si erenjẹ kankan ayaafi pẹlu nini igbagbọ pẹlu gbogbo oun ti Ọlọhun Ọba (ti ọla Rẹ ga) sọkalẹ.
وَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّن مَّنَعَ مَسَٰجِدَ ٱللَّهِ أَن يُذۡكَرَ فِيهَا ٱسۡمُهُۥ وَسَعَىٰ فِي خَرَابِهَآۚ أُوْلَٰٓئِكَ مَا كَانَ لَهُمۡ أَن يَدۡخُلُوهَآ إِلَّا خَآئِفِينَۚ لَهُمۡ فِي ٱلدُّنۡيَا خِزۡيٞ وَلَهُمۡ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ عَذَابٌ عَظِيمٞ 114
Ko si ẹnikankan ti abosi rẹ lagbara ju ẹniti o kọ ki wọn maa darukọ Ọlọhun Ọba ninu awọn ile ijọsin rẹ, o kọ irun ati mima se iranti ati mima ka Alukuraani nibẹ, o si wa npọsẹsẹ ni ẹni to ngbiyanju lati jẹ ẹniti yoo se okunfa didawo ati bibaa jẹ; pẹlu wiwo tabi kikọ nipa mima se ijọsin nibẹ, awọn eleyi ti wọn nse ipọsẹsẹ nipa wiwo, ko lẹtọ fun wọn lati maa wọ inu awọn ile ijọsin Ọlọhun Ọba ayaafi ni ẹniti yoo maa bẹru, ti ọkan rẹ yoo si maa gbọn; nititori ohun ti wọn wa lori rẹ ninu aigbagbọ ati mima kọdi awọn ile ijọsin Ọlọhun Ọba, o nbẹ fun wọn ninu isẹmi aye iyẹpẹrẹ ati ailasunsi lati ọwọ awọn olugbagbọ ododo, o si nbẹ fun wọn ni ọjọ ikẹyin, iya ti o tobi lori bi wọn se nkọ fun awọn eniyan nibi awọn ile ijọsin Ọlọhun Ọba.
وَلِلَّهِ ٱلۡمَشۡرِقُ وَٱلۡمَغۡرِبُۚ فَأَيۡنَمَا تُوَلُّواْ فَثَمَّ وَجۡهُ ٱللَّهِۚ إِنَّ ٱللَّهَ وَٰسِعٌ عَلِيمٞ 115
Ti Ọlọhun Ọba nii se, ọla ibuyọ oorun ati ibuwọ rẹ ati ohun ti nbẹ laarin mejeeji, O si ma npa awọn ẹru Rẹ lasẹ ohun ti o ba wu U, gbogbo ibikibi ti ẹ ba dojukọ, dajudaju ẹyin dojukọ Ọlọhun Ọba (ti ọla Rẹ ga) ni, ti O ba payin lasẹ lati dojukọ ‘Baytul - Maqdisi’ tabi Kaa'ba tabi ti ẹ ba se asise nibi idojukọ ‘Qibla’ tabi o ba le fun yin lati da oju kọọ, ko si inira kankan fun yin; toripe awọn agbegbe, gbogbo rẹ ti Ọlọhun Ọba (ti ọla Rẹ ga) nii se, dajudaju Ọlọhun Ọba jẹ Ẹniti o gbaaye, ti O si ma ngba awọn ẹda Rẹ laaye ikẹ Rẹ ati irọrun Rẹ, O si ni imọ pẹlu awọn adisọkan wọn awọn isẹ wọn.
وَقَالُواْ ٱتَّخَذَ ٱللَّهُ وَلَدٗاۗ سُبۡحَٰنَهُۥۖ بَل لَّهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ كُلّٞ لَّهُۥ قَٰنِتُونَ 116
Awọn Yahuudi, Nasaara ati awọn ọsẹbọ sọ wipe: Ọlọhun Ọba mu ọmọ kan fun ara Rẹ! O bọpa-bọsẹ, O si mọọ kuro nibi nkan naa, ohun ni ẹniti O rọrọ kuro ni ọdọ awọn ẹda Rẹ, dajudaju ẹniti o ma nmu ọmọ ni ẹniti o ba ni bukaata sii, bikose wipe tirẹ nii se, mimọ fun Un, ti ọla Rẹ si ga, ikapa ohun ti nbẹ ni sanmọ ati ilẹ, gbogbo awọn ẹda, ẹru ni wọn jẹ fun Un, mimọ fun Un, ni ẹni to ntẹriba fun Un, ti O si ma nse bi O se wu U laarin wọn.
بَدِيعُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ وَإِذَا قَضَىٰٓ أَمۡرٗا فَإِنَّمَا يَقُولُ لَهُۥ كُن فَيَكُونُ 117
Ọlọhun Ọba, mimọ fun Un, ni Ẹniti o da awọn sanmọ ati ilẹ ati ohun ti nbẹ ninu mejeeji laini afiwe to siwaju, nigbati O ba pebubu alamọri kan, ti O si gbero rẹ, ohun ti Yoo sọ fun alamọri naa ni, (كُن) (kun) ; maa bẹ, yoo si maa bẹ lori bi Ọlọhun Ọba se gba ero wiwabẹẹ, ko si si ẹni ti yoo da alamọri Rẹ pada ati ohun ti O ba fẹ ki O sẹlẹ.
وَقَالَ ٱلَّذِينَ لَا يَعۡلَمُونَ لَوۡلَا يُكَلِّمُنَا ٱللَّهُ أَوۡ تَأۡتِينَآ ءَايَةٞۗ كَذَٰلِكَ قَالَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِم مِّثۡلَ قَوۡلِهِمۡۘ تَشَٰبَهَتۡ قُلُوبُهُمۡۗ قَدۡ بَيَّنَّا ٱلۡأٓيَٰتِ لِقَوۡمٖ يُوقِنُونَ 118
Awọn ti ko ni imọ ninu awon ti A fun ni tira ati awọn ọsẹbọ sọ wipe niti kikọ ododo: kilode ti Ọlọhun Ọba ko fi bawa sọrọ laini alagata, tabi ki O mu wa fun wa amin ti a le fi oju ri, ti yoo wa fun awa nikan, iru gbolohun wọn yii, ni awọn ijọ ti o parọ siwaju sọ fun awọn ojisẹ wọn, bi o ti ẹ jẹ wipe asiko wọn yatọ si ara wọn ati aaye wọn, okan awon won yi ati awon ti o siwaju won jo arawon nibi aigbagbo ati gigunri ati sise ori kunkun, paapaa, atise afihan awọn aayah fun awọn ijọ ti wọn ni amọdaju pẹlu ododo nigbati o ba han si wọn, ti wọn ko si nii ni iyemeji lori rẹ, ti igbẹrugbọnri ko si nii kọ fun wọn.
إِنَّآ أَرۡسَلۡنَٰكَ بِٱلۡحَقِّ بَشِيرٗا وَنَذِيرٗاۖ وَلَا تُسَۡٔلُ عَنۡ أَصۡحَٰبِ ٱلۡجَحِيمِ 119
Dajudaju Awa ni a ran ọ nisẹ - irẹ Anọbi - pẹlu ẹsin ododo, eyiti ko si irọ nibẹ; ki o le baa maa fun awọn onigbagbọ ododo ni iro ọgba idẹra, ki o si lee maa se ikilọ fun alaigbagbọ pẹlu ina, ko si ohun ti o jẹ dandan fun ọ ju mimu ọrọ de ogbongo ti o fi oju han, Ọlọhun Ọba ko si nii bi ọ leere nipa awọn ti ko ni igbagbọ pẹlu rẹ ninu awọn eri ina ‘Jaheem’.
Aini igbagbọ, oju ọna kan ni koda bi awọn oniranran wọn ba yatọ ati awọn aaye wọn, wọn jọ ara wọn nibi aini igbagbọ wọn ati gbolohun wọn ti wọn sọ si Ọlọhun Ọba laini imọ kankan.
Ẹniti ibajẹ rẹ tobi ju ninu awọn eniyan, ti ẹsẹ rẹ si lagbara ni ẹniti o nkọdi oju ọna Ọlọhun Ọba, ti o si nkọ fun ẹniti o ba fẹẹ se daradara.
Ọlọhun Ọba (ti ọla Rẹ ga) bọpa-bọsẹ kuro nibi nini iyawo ati ọmọ, Oun ni mimọ nbẹ fun Un, ko ni bukaata si ẹda Rẹ.