ٱلتَّٰٓئِبُونَ ٱلۡعَٰبِدُونَ ٱلۡحَٰمِدُونَ ٱلسَّٰٓئِحُونَ ٱلرَّٰكِعُونَ ٱلسَّٰجِدُونَ ٱلۡأٓمِرُونَ بِٱلۡمَعۡرُوفِ وَٱلنَّاهُونَ عَنِ ٱلۡمُنكَرِ وَٱلۡحَٰفِظُونَ لِحُدُودِ ٱللَّهِۗ وَبَشِّرِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ 112
Awọn ti wọn lẹtọ si ẹsan yii ni awọn ti wọn sẹri kuro nibi ohun ti Ọlọhun Ọba korira, ti O si binu si lọsi ibi nkan ti O nifẹ si, ti O si yọnu si, awọn ti wọn yẹpẹrẹ ara wọn nitori ipaya Allah ati itẹriba, ti wọn si se igbiyanju sibi titẹle asẹ Rẹ, awọn ti ndupẹ fun Ọlọhun Ọba wọn lori gbogbo isesi, awọn ti ngba aawẹ, awọn olukirun, awọn olupasẹ ohun ti Ọlọhun Ọba pa lasẹ tabi ohun ti ojisẹ Rẹ pa lasẹ, awọn ti wọn nkọ ohun ti Ọlọhun Ọba Allah kọ ati ojisẹ Rẹ, awọn ti wọn nsọ awọn asẹ Ọlọhun pẹlu titẹle ati awọn ohun ti O kọ pẹlu jijinna si, si fun niro - ire ojise - awọn olugbagbọ ododo ti a fi iroyin yii royin, nkan ti yoo dun mọ wọn ninu ni ile aye ati lọrun.
مَا كَانَ لِلنَّبِيِّ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ أَن يَسۡتَغۡفِرُواْ لِلۡمُشۡرِكِينَ وَلَوۡ كَانُوٓاْ أُوْلِي قُرۡبَىٰ مِنۢ بَعۡدِ مَا تَبَيَّنَ لَهُمۡ أَنَّهُمۡ أَصۡحَٰبُ ٱلۡجَحِيمِ 113
Ko tọ fun Anọbi, bẹẹ ni ko tọ fun awọn olugbagbọ ododo ki wọn maa wa aforijin ni ọdọ Ọlọhun Ọba Allah fun awọn ẹlẹbọ koda ki wọn jẹ alasunmọ wọn lẹyin igbati o ba ti han wipe ẹni ina ni wọn nitori wipe wọn ku lori ẹbọ.
وَمَا كَانَ ٱسۡتِغۡفَارُ إِبۡرَٰهِيمَ لِأَبِيهِ إِلَّا عَن مَّوۡعِدَةٖ وَعَدَهَآ إِيَّاهُ فَلَمَّا تَبَيَّنَ لَهُۥٓ أَنَّهُۥ عَدُوّٞ لِّلَّهِ تَبَرَّأَ مِنۡهُۚ إِنَّ إِبۡرَٰهِيمَ لَأَوَّٰهٌ حَلِيمٞ 114
Aforijin ti Anọbi Ibrahim nwa fun baba rẹ ko jẹ nkankan ju adehun rẹ wipe oun yoo beere fun lọ; ni ireti ki o le gba ifa, sugbọn nigbati o han si Ibrahim wipe baba oun jẹ ọta Ọlọhun nitori aise anfaani isiti rẹ fun, tabi nitori imisi ti o mọ wipe yoo ku si keferi, o si jawọ nibẹ, iwaforijin rẹ kan jẹ igbiyanju lati ọdọ rẹ fun ni kii se lati yapa ofin imisi Ọlọhun si i, dajudaju Ibrahim ẹniti ikẹ nbẹ fun jẹ ẹniti o ma nrawọ rasẹ lọpọ si ọdọ Allah, o si jẹ ọlọpọ amọkan kuro ati amoju kuro fun awọn ijọ rẹ ti wọn jẹ alabosi.
وَمَا كَانَ ٱللَّهُ لِيُضِلَّ قَوۡمَۢا بَعۡدَ إِذۡ هَدَىٰهُمۡ حَتَّىٰ يُبَيِّنَ لَهُم مَّا يَتَّقُونَۚ إِنَّ ٱللَّهَ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٌ 115
Kii se wipe Ọlọhun Ọba gbero lati dajọ anu lori awọn ijọ bikose wipe lati fi wọn se kongẹ imọna titi ti ohun ti o jẹ eewọ yoo fi han si wọn eyiti o di dandan ki wọn jinna si, ti wọn ba se nkan ti o jẹ eewọ lẹyin alaye sise ni eewọ rẹ, wọn yoo dajọ anu le wọn lori, dajudaju Ọlọhun Ọba jẹ onimimọ nipa gbogbo nkan, nkankan ko pamọ fun Un, paapaa O ti mọ yin nkan ti ẹ ko mọ.
إِنَّ ٱللَّهَ لَهُۥ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ يُحۡيِۦ وَيُمِيتُۚ وَمَا لَكُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ مِن وَلِيّٖ وَلَا نَصِيرٖ 116
Dajudaju Allah ni O ni ikapa gbogbo sanmọ ati ilẹ, ko si orogun fun Un nibi mejeeji, nkankan ko pamọ fun Un nibi mejeeji, O ma nji ẹniti O ba fẹ jiji fun, O si ma npa ẹniti o ba fẹ iku fun, ko si fun yin - ẹyin ẹniyan - yatọ si Allah ni alatilẹyin ti yoo la ọrọ yin bọrun, bẹẹ ni ko si fun yin alaranse ti yoo ti aburu kuro, ti yoo si ran yin se lori ọta yin.
لَّقَد تَّابَ ٱللَّهُ عَلَى ٱلنَّبِيِّ وَٱلۡمُهَٰجِرِينَ وَٱلۡأَنصَارِ ٱلَّذِينَ ٱتَّبَعُوهُ فِي سَاعَةِ ٱلۡعُسۡرَةِ مِنۢ بَعۡدِ مَا كَادَ يَزِيغُ قُلُوبُ فَرِيقٖ مِّنۡهُمۡ ثُمَّ تَابَ عَلَيۡهِمۡۚ إِنَّهُۥ بِهِمۡ رَءُوفٞ رَّحِيمٞ 117
Paapaa Ọlọhun Ọba Allah ti gba ironu piwada Anọbi Muhammad ki ikẹ ati ọla maa ba nitori iyọnda rẹ fun awọn sọbẹ selu lati yapa kuro nibi ogun tabuuki, bẹẹ ni o ti gba ironu piwada awọn oluse irin ajo ati awọn alaranse ti wọn ko yapa kuro nibẹ, bikose wipe wọn tẹle nibi ogun tabuuki pẹlu lile ooru ati kikere ikunlọwọ ati agbara awọn ọta lẹyin igbati ọkan awọn eniyan kan ninu wọn ti fi sibi gbigbero pipa ogun ti; nitori ilekoko ti o tobi ti wọn wa nibẹ, lẹyin igba naa ni Ọlọhun Ọba fi wọn se kongẹ iduro sinsin ati jijade fun ogun, O si gba ironu piwada wọn, dajudaju O jẹ alaanu, onikẹ si wọn, ninu ikẹ Rẹ ni fifi wọn se kongẹ ironu piwada ati gbigba a lọwọ wọn.
Jijẹ aidara iwawijare lori titọ wiwa aforijin fun awọn ẹlẹbọ lati ara isẹ Anọbi Ibrahim ẹniti ike nbẹ fun.
Dajudaju awọn ẹsẹ ati asise jẹ okunfa awọn adanwo ati idagunlasi ati sise afẹku kongẹ.
Dajudaju Allah ni olukapa gbogbo ọla, Oun ni alatilẹyin wa, ko si si alatilẹyin, alaranse fun wa yatọ si I.
Sise alaye ọla awọn ọmọlẹyin Anọbi lori gbogbo awọn eniyan.