قَالَ وَمَا عِلۡمِي بِمَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ 112
Nuhu - ẹniti ọla nbẹ fun - sọ fun wọn: imọ mi mo si nibi nkan ti awọn olugbagbọ yii ma nse? Wọn kii se olusọ le wọn lori, ti wọn yoo maa ki ye si isẹ wọn.
إِنۡ حِسَابُهُمۡ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّيۖ لَوۡ تَشۡعُرُونَ 113
Isiro isẹ wọn ko jẹ lori ẹnikẹni ju Allah ti O mọ kọkọ wọn ati gbangba wọn lọ, kii se si ọdọ mi; ti ẹ ba fura ọm ohun ti ẹ nsọ, ẹ ko nii sọ ọ.
وَمَآ أَنَا۠ بِطَارِدِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ 114
Emi kii se olule awọn olugbagbọ ododo kuro nibi aaye mi niti jijẹpe ibeere yin ki ẹ le baa gbagbọ.
إِنۡ أَنَا۠ إِلَّا نَذِيرٞ مُّبِينٞ 115
Wọn ko jẹ ohun kihun ju olukilọ ti o fi ojuhan ninu ikilọ lọ, mo nkilọ iya Allah fun yin.
قَالُواْ لَئِن لَّمۡ تَنتَهِ يَٰنُوحُ لَتَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡمَرۡجُومِينَ 116
Awọn ijọ rẹ sọ fun: ti o ko ba jawọ kuro nibi ohun ti o npe wa si, iwọ yoo wa ninu ẹni eebu ati ẹni ijuko mọ lọ.
قَالَ رَبِّ إِنَّ قَوۡمِي كَذَّبُونِ 117
Nuhu sọ ni ẹniti o npe Ọlọhun Ọba rẹ: Ọlọhun mi dajudaju awọn ijọ mi npe mi nirọ, wọn ko si gbami lododo nibi ohun ti mo mu wa lati ọdọ Rẹ.
فَٱفۡتَحۡ بَيۡنِي وَبَيۡنَهُمۡ فَتۡحٗا وَنَجِّنِي وَمَن مَّعِيَ مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ 118
Ki O ya se idajọ laarin emi ati wọn, ni idajọ ti yoo pa wọn ru nitori wiwo mọ ibajẹ wọn, ki o si la mi ati ẹniti o ba wa pẹlu mi ninu awọn olugbagbọ ododo nibi ohun ti o fi pa awọn keferi ninu ijọ mi run.
فَأَنجَيۡنَٰهُ وَمَن مَّعَهُۥ فِي ٱلۡفُلۡكِ ٱلۡمَشۡحُونِ 119
A si jẹpe adera rẹ, bẹẹni a la a ati ẹniti o wa pẹlu rẹ ninu awọn olugbagbọ ododo nibi ọkọ oju omin ti o kun fun awọn eniyan ati ẹranko.
ثُمَّ أَغۡرَقۡنَا بَعۡدُ ٱلۡبَاقِينَ 120
Lẹyin naa, a tun tẹ awọn ti o sẹku ri lẹyin wọn, awọn naa ni ijọ Nuhu.
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗۖ وَمَا كَانَ أَكۡثَرُهُم مُّؤۡمِنِينَ 121
Dajudaju nibi itan Nuha ati ijọ rẹ ti a sọ yii ati lila Nuha ati awọn ti wọn bẹ pẹlu rẹ ninu awọn olugbagbọ ododo, ati iparun awọn keferi inu ijọ rẹ jẹ ariwoye fun awọn oluwoye sugbọn ọpọlọpọ wọn kii se ẹolugbagbọ ododo.
وَإِنَّ رَبَّكَ لَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلرَّحِيمُ 122
Ati wipe dajudaju Ọlọhun Ọba rẹ - irẹ ojisẹ - Oun ni Alagbara eyiti o ngbẹsan lara awọn ọta rẹ; olukọ fun ẹniti o ba ronu piwada ninu wọn.
كَذَّبَتۡ عَادٌ ٱلۡمُرۡسَلِينَ 123
Ijọ Hadi pe awọn ojisẹ nirọ nigbati wọn npe ojisẹ wọn Huudu ẹniti ọla nbẹ fun nirọ.
إِذۡ قَالَ لَهُمۡ أَخُوهُمۡ هُودٌ أَلَا تَتَّقُونَ 124
Ranti nigbati ọmọ iyawọn ninu mọlebi Huudu sọ fun wọn: se ẹ ko paya Allah pẹlu gbigbe sinsin ẹlomiran ti o yatọ si I ju silẹ niti ibẹru Rẹ ni?!
إِنِّي لَكُمۡ رَسُولٌ أَمِينٞ 125
Dajudaju emi jẹ ojisẹ ti Allah ran si yin, ẹni ifọkantan, nko nii se alekun lori ohun ti Allah pa mi lasẹ mimudopin rẹ, bẹẹni nko nii din ku.
فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَأَطِيعُونِ 126
Ki ẹ yaa bẹru Allah; pẹlu titẹle awọn asẹ Rẹ ati jijiina si ohun ti o kọ, ki ẹ si tẹle mi nibi ohun ti mo ba pa yin la sẹ rẹ ati ohun ti mo ba kọ fun yin kuro nibẹ.
وَمَآ أَسَۡٔلُكُمۡ عَلَيۡهِ مِنۡ أَجۡرٍۖ إِنۡ أَجۡرِيَ إِلَّا عَلَىٰ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ 127
Bẹẹni nko wa ẹsan ni ọdọ yin lori ounti mo nfun yin niro rẹ ni ọdọ Ọlọhun Ọba mi, ẹsan mi ko jẹ lati ọdọ ẹnikẹni ayaafi lati ọdọ Allah Olutọju gbogbo ẹda, ko si lọdọ ẹlomiran.
أَتَبۡنُونَ بِكُلِّ رِيعٍ ءَايَةٗ تَعۡبَثُونَ 128
Se ẹ nmọ aaye iyi ti o ga kan si gbogbo aaye ni, ti o si jẹ amin ere ti ko nii se anfaani kankan fun yin ni ile aye yin ati ni ọrun yin?!
وَتَتَّخِذُونَ مَصَانِعَ لَعَلَّكُمۡ تَخۡلُدُونَ 129
Ẹ si tun mu idaabobo ati ile gogoro gẹgẹbi wipe ẹ o maa gbe ile aye gbere, ẹ ko nii sipo pada kuro nibẹ ni?!
وَإِذَا بَطَشۡتُم بَطَشۡتُمۡ جَبَّارِينَ 130
Nigbati wọn ba fi ipani tabi lilu jẹ gaba le yin lori tabi wọn fi awọn alagbara ti ko nii aanu tabi ikẹ jẹ gaba le yin lori.
فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَأَطِيعُونِ 131
Ki ẹ ya paya Allah pẹlu mima tẹle awọn asẹ ẹ ati jijinna si awọn ohun ti O kọ, ki ẹ si maa tẹle mi nibi ohun ti mo npayin lasẹ rẹ, ati ohun ti mo nkọ fun yin kuro nibẹ.
وَٱتَّقُواْ ٱلَّذِيٓ أَمَدَّكُم بِمَا تَعۡلَمُونَ 132
Ki ẹ paya ibbinu Allah eyiti o nfun yin ni awọn idẹkun eyiti ẹ mọ.
أَمَدَّكُم بِأَنۡعَٰمٖ وَبَنِينَ 133
O fun yin ni awọn ẹran ọsin, bẹẹni O si fun yin ni awọn ọmọ.
وَجَنَّٰتٖ وَعُيُونٍ 134
O fun yin ni awọn oko ati awọn odo ti o nsan.
إِنِّيٓ أَخَافُ عَلَيۡكُمۡ عَذَابَ يَوۡمٍ عَظِيمٖ 135
Dajudaju emi npaya le yin lori - ẹyin ijọ mi - iya ọjọ ti o tobi, ohun si ni ọjọ igbende.
قَالُواْ سَوَآءٌ عَلَيۡنَآ أَوَعَظۡتَ أَمۡ لَمۡ تَكُن مِّنَ ٱلۡوَٰعِظِينَ 136
Awọn ijọ rẹ sọ fun: ikilọ rẹ ati aikilọ rẹ jẹ dọgba lọdọ rẹ, a ko le gba ọ gbọ, bẹẹni a ko si le sẹri kuro nibi nkan ti a wa.
Ọla ti nbẹ fun awọn ti wọn ti gbawju ninu igbagbọ, koda bi wọn alaini ati ọlẹ.
Pipa awọn alabosi run ati lila awọn olugbagbọ jẹ isesi Allah.
Ewu ti o wa nibi ifayabalẹ si aye
Sise ẹyamẹya awọn onibajẹ ati titaku wọn le lori.