يُرۡسِلِ ٱلسَّمَآءَ عَلَيۡكُم مِّدۡرَارٗا 11
Dajudaju ti ẹ ba se eleyi, Allah yoo sọ oju kalẹ fun yin ni titẹle ra wọn ni gbogbo igba ti ẹ ba bukaata si i, ọda ko nii sẹlẹ si yin.
وَيُمۡدِدۡكُم بِأَمۡوَٰلٖ وَبَنِينَ وَيَجۡعَل لَّكُمۡ جَنَّٰتٖ وَيَجۡعَل لَّكُمۡ أَنۡهَٰرٗا 12
Yoo si fun yin ni ọpọ dukia ati awọn ọmọ, yoo si se awọn ọgba ti ẹ o maa jẹ awọn eso nibẹ fun yin, yoo si awọn omin ti ẹ o maa mun nibẹ, ti ẹ o si maaa fun awọn ọgbin yin ati awọn ẹranko yin lomin mu nibẹ.
مَّا لَكُمۡ لَا تَرۡجُونَ لِلَّهِ وَقَارٗا 13
Kinni o se yin - ẹyin ijọ mi - ti ẹ ko bẹru titobi Allah, ti ẹ nsẹ Ẹ laibikita?!
وَقَدۡ خَلَقَكُمۡ أَطۡوَارًا 14
O si da yin ni ipele lẹyin ipele lati inu ikun, o di ẹjẹ kiki, o di baasi ẹran.
أَلَمۡ تَرَوۡاْ كَيۡفَ خَلَقَ ٱللَّهُ سَبۡعَ سَمَٰوَٰتٖ طِبَاقٗا 15
Se ẹ ko ri bi Allah se sẹda sanmọ mejeeje, sanmọ kan wa lori ikan?!
وَجَعَلَ ٱلۡقَمَرَ فِيهِنَّ نُورٗا وَجَعَلَ ٱلشَّمۡسَ سِرَاجٗا 16
O si se osupa si inu sanmọ aye, ninu rẹ ni imọlẹ wa fun awọn ara ilẹ, o si se oorun ni ohun ti o ntan imọlẹ.
وَٱللَّهُ أَنۢبَتَكُم مِّنَ ٱلۡأَرۡضِ نَبَاتٗا 17
Allah si da yin lati inu ilẹ pẹlu dida baba yin Adamọ lati ninu yerupẹ, lẹyin naa ẹ njẹ ninu ohun ti o nwu jade fun yin.
ثُمَّ يُعِيدُكُمۡ فِيهَا وَيُخۡرِجُكُمۡ إِخۡرَاجٗا 18
Lẹyin naa, yoo sẹri yin pada si inu rẹ lẹyin iku yin, lẹyin naa yoo mu yin jade fun ajinde kuro nibẹ niti mimu jade.
وَٱللَّهُ جَعَلَ لَكُمُ ٱلۡأَرۡضَ بِسَاطٗا 19
Allah si se ilẹ fun yin ni pẹrẹsẹ, ti o wa ni ipese fun olugbe.
لِّتَسۡلُكُواْ مِنۡهَا سُبُلٗا فِجَاجٗا 20
Ni irankan ki ẹ le maa rin awọn oju ọna ti o gbaaye nibẹ, ni irin lati ko ẹtọ jọ.
قَالَ نُوحٞ رَّبِّ إِنَّهُمۡ عَصَوۡنِي وَٱتَّبَعُواْ مَن لَّمۡ يَزِدۡهُ مَالُهُۥ وَوَلَدُهُۥٓ إِلَّا خَسَارٗا 21
Nuuh sọpe: irẹ Ọlọhun mi dajudaju awọn ijọ mi sẹ mi nibi ohun ti mo pa wọn lasẹ rẹ nipa mimu Ọ lọkan ati jiọsin fun Ọ niWọ nikan, awọn ẹni ilẹ wọn si tẹle awọn olori wọn, awọn ti O se idẹkun dukia ati ọmọ fun, idẹkun ti O se fun wọn ko le nkankan kun ju anu lọ.
وَمَكَرُواْ مَكۡرٗا كُبَّارٗا 22
Awọn agbalagba inu wọn si da ete ni ete ti o tobi pẹlu didẹ awọn ẹni ilẹ wọn si Nuuh.
وَقَالُواْ لَا تَذَرُنَّ ءَالِهَتَكُمۡ وَلَا تَذَرُنَّ وَدّٗا وَلَا سُوَاعٗا وَلَا يَغُوثَ وَيَعُوقَ وَنَسۡرٗا 23
Wọn si sọ fun awọn ti o tẹle wọn; ẹ mase gbe ijọsin awọn ọlọhun yin ju silẹ; ki ẹ si mase gbe ijọsin awọn oosa yin tii se Wadda ati Suwaa’a ati yaguutha ati Ya’uuku ati Nasirọ ju silẹ.
وَقَدۡ أَضَلُّواْ كَثِيرٗاۖ وَلَا تَزِدِ ٱلظَّٰلِمِينَ إِلَّا ضَلَٰلٗا 24
Paapaa wọn ti fi awọn oosa wọn sọ ọpọ ninu awọn eniyan nu, awọn ti wọn se abosi si ẹmin ara wọn - irẹ Ọlọhun mi - ko nii lekun nkankan kan ju anu kuro nibi ododo lọ.
مِّمَّا خَطِيٓـَٰٔتِهِمۡ أُغۡرِقُواْ فَأُدۡخِلُواْ نَارٗا فَلَمۡ يَجِدُواْ لَهُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ أَنصَارٗا 25
Wọn yoo tẹ wọn ri pẹlu okun tuufanu ni ile aye nitori awọn asise wọn eyiti wọn se, wọn yoo si mu wọn wọ ina lẹyin iku wọn lẹsẹkẹsẹ, wọn ko si nii ri alaranse ti yoo la wọn kuro nibi itẹri ati ina yatọ si Allah.
وَقَالَ نُوحٞ رَّبِّ لَا تَذَرۡ عَلَى ٱلۡأَرۡضِ مِنَ ٱلۡكَٰفِرِينَ دَيَّارًا 26
Nuuh sọ nigbati Allah fun niro wipe ẹnikankan ko nii nigbagbọ ninu ijọ rẹ ayaafi ẹniti o ti gbagbọ: Ọlọhun mi, mase sẹ ẹnikankan ku ti o nlọ, ti o nbọ tabi o ngbepa gbesẹ lori ilẹ ninu awọn keferi.
إِنَّكَ إِن تَذَرۡهُمۡ يُضِلُّواْ عِبَادَكَ وَلَا يَلِدُوٓاْ إِلَّا فَاجِرٗا كَفَّارٗا 27
Dajudaju iwọ - Ọlọhun wa - ti O ba fi wọn silẹ, ti O si lọ wọn lara, wọn yoo sọ awọn ẹru Rẹ olugbagbọ ododo nu, wọn ko si nii bi ju ẹlẹsẹ ti ko nii tẹle Ọ lọ, ti keferi rẹ le, ti ko nii dupẹ fun ọ lori idẹkun Rẹ.
رَّبِّ ٱغۡفِرۡ لِي وَلِوَٰلِدَيَّ وَلِمَن دَخَلَ بَيۡتِيَ مُؤۡمِنٗا وَلِلۡمُؤۡمِنِينَ وَٱلۡمُؤۡمِنَٰتِۖ وَلَا تَزِدِ ٱلظَّٰلِمِينَ إِلَّا تَبَارَۢا 28
Ọlọhun mi, fi ori awọn ẹsẹ mi jin mi, ki o si fi ori jin awọn obi mi, ki O si fi ori jin ẹniti o ba wọ inu ile mi ni olugbagbọ ododo, ki O si fi ori jin awọn olugbagbọ ododo lọkunrin ati lobinrin, awọn oluse abosi ẹmin ara wọn pẹlu sise keferi ati awọn ẹsẹ ko nii lekun nkankan ayaafi iparun ati ofo.
Wiwa aforijin jẹ okunfa sisọkalẹ ojo ati pipọ awọn dukia ati awọn ọmọ.
Ipo awọn agbalagba nibi sisọ awọn ọmọ keekeeke nu han ni ohun ti o se fi oju ri.
Awọn ẹsẹ jẹ okunfa iparun ni ile aye ati iya ni ọrun.