يُبَصَّرُونَهُمۡۚ يَوَدُّ ٱلۡمُجۡرِمُ لَوۡ يَفۡتَدِي مِنۡ عَذَابِ يَوۡمِئِذِۢ بِبَنِيهِ 11
Gbogbo ọmọniyan ni yoo ri alasunmọ rẹ, ti ko nii pamọ fun un pẹlu eleyi naa ẹnikankan ko nii le bi ẹnikan leere ibeere nitori ipaya iduro naa, ẹniti o lẹtọ si ina yoo nifẹ si ki o ti awọn ọmọ rẹ sibi iya dipo ara rẹ.
وَصَٰحِبَتِهِۦ وَأَخِيهِ 12
Yoo fi iyawo rẹ ati ọmọ iya rẹ di i.
وَفَصِيلَتِهِ ٱلَّتِي تُٔۡوِيهِ 13
Yoo fi mọlẹbi rẹ ti wọn sun mọ di i, awọn ti wọn duro pẹlu rẹ ni igba ilekoko.
وَمَن فِي ٱلۡأَرۡضِ جَمِيعٗا ثُمَّ يُنجِيهِ 14
Yoo si fi gbogbo ẹniti o nbẹ lori ilẹ ninu eniyan tabi alujannu ati ẹniti o yatọ si wọn di i, lẹyin naa, wọn yoo ju u silẹ nibi ifidi yii, yoo si ju u sinu iya naa.
كَلَّآۖ إِنَّهَا لَظَىٰ 15
Ọrọ ko ri bi ẹlẹsẹ yii se lero, dajudaju ina ọrun ti o njoni berebere, ti o si njo ni.
نَزَّاعَةٗ لِّلشَّوَىٰ 16
Ti yoo maa si awọ ori ni sisi ti o le nitori lile koko igbona rẹ ati jijo rẹ.
تَدۡعُواْ مَنۡ أَدۡبَرَ وَتَوَلَّىٰ 17
yoo maa pe gbogbo ẹniti o gunri kuro nibi ododo, ti o si ta kete si i, ti ko gba a gbọ, ti ko si fi sisẹ.
وَجَمَعَ فَأَوۡعَىٰٓ 18
Ti o ko dukia jọ, ti o si se ahun pẹlu nina ninu rẹ si oju ọna Allah.
۞إِنَّ ٱلۡإِنسَٰنَ خُلِقَ هَلُوعًا 19
Dajudaju ọmọniyan jẹ ẹniti a da ni oloju kokoro ti o le.
إِذَا مَسَّهُ ٱلشَّرُّ جَزُوعٗا 20
Ti inira ba kan an gẹgẹ bi aarẹ tabi osi, yoo jẹ onisuuru kekere.
وَإِذَا مَسَّهُ ٱلۡخَيۡرُ مَنُوعًا 21
Ti o ti o ndun un ninu ba sẹlẹ si gẹgẹ bi ikere tabi ọrọ, yoo pọ ni atako lati na an si oju ọna Allah.
إِلَّا ٱلۡمُصَلِّينَ 22
Ayaafi awọn olukirun, awọn ni ẹniti yoo la kuro nibi iroyin abuku yii.
ٱلَّذِينَ هُمۡ عَلَىٰ صَلَاتِهِمۡ دَآئِمُونَ 23
Awọn ti wọn nmojuto irun wọn, wọn kii ko airoju kuro nibẹ, wọn si nki ni asiko rẹ ti a se ni aala fun un.
وَٱلَّذِينَ فِيٓ أَمۡوَٰلِهِمۡ حَقّٞ مَّعۡلُومٞ 24
Awọn ti wọn nmu ipin ti o ni onidiwọn ti a se ni ọranyan ninu awọn dukia wọn.
لِّلسَّآئِلِ وَٱلۡمَحۡرُومِ 25
Wọn nna fun ẹniti o nbeere lọwọ wọn ati fun ẹniti ko bi wọn leere ninu awọn ti wọn se arisiki leewọ fun nitori eyikeyi okunfa.
وَٱلَّذِينَ يُصَدِّقُونَ بِيَوۡمِ ٱلدِّينِ 26
Awọn ti wọn npe ọjọ igbende ni ododo, ọjọ ti Allah yoo sẹsan fun olukuluku pẹlu ohun ti o lẹtọ si.
وَٱلَّذِينَ هُم مِّنۡ عَذَابِ رَبِّهِم مُّشۡفِقُونَ 27
Awọn ti wọn jẹ olupaya nibi iya Ọlọhun wọn pẹlu ohun ti wọn ti ti siwaju ninu awọn isẹ rere wọn.
إِنَّ عَذَابَ رَبِّهِمۡ غَيۡرُ مَأۡمُونٖ 28
Dajudaju iya Ọlọhun wọn jẹ nkan ibẹru ti onilaakaye ko le fi ọkan balẹ si.
وَٱلَّذِينَ هُمۡ لِفُرُوجِهِمۡ حَٰفِظُونَ 29
Awọn ti wọn jẹ oludaabobo abẹ wọn pẹlu bibo o lasiri ati mimu jinna si awọn ibajẹ.
إِلَّا عَلَىٰٓ أَزۡوَٰجِهِمۡ أَوۡ مَا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُهُمۡ فَإِنَّهُمۡ غَيۡرُ مَلُومِينَ 30
Ayaafi lọdọ awọn iyawo wọn tabi awọn ẹru ti nikapa, dajudaju wọn kii se ẹni eebu nibi gbigbadun ibalopọ lọkọlaya pẹlu wọn ati ohun ti o kere si i.
فَمَنِ ٱبۡتَغَىٰ وَرَآءَ ذَٰلِكَ فَأُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡعَادُونَ 31
Ẹniti o ba beere fun wiwa igbadun pẹlu ohun ti o yatọ si awọn ohun ti wọn darukọ gẹgẹ bi iyawo ati awọn ẹru, awọn wọnyi ni olukọja ẹnu aala Allah.
وَٱلَّذِينَ هُمۡ لِأَمَٰنَٰتِهِمۡ وَعَهۡدِهِمۡ رَٰعُونَ 32
Awọn ti wọn jẹ alamojuto ohun ti wọn fi ọkan balẹ le wọn lori ninu awọn dukia ati awọn asiri ati ohun ti o yatọ si mejeeji ati awọn adehun eyiti wọn se pẹlu awọn eniyan, wọn kii jamba afọkantan wọn, wọn kii si ja adehun wọn.
وَٱلَّذِينَ هُم بِشَهَٰدَٰتِهِمۡ قَآئِمُونَ 33
Awọn ti wọn duro pẹlu ẹri wọn loju pọnna ti a fẹ, ti asunmọ tabi ọta kii lapa nibẹ.
وَٱلَّذِينَ هُمۡ عَلَىٰ صَلَاتِهِمۡ يُحَافِظُونَ 34
Awọn ti wọn mojuto irun wọn; pẹlu kiki i ni asiko rẹ ati pẹlu imọra ati ifọkanbalẹ, airoju kan kii di wọn lọwọ.
أُوْلَٰٓئِكَ فِي جَنَّٰتٖ مُّكۡرَمُونَ 35
Awọn ti a royin pẹlu awọn iroyin wọnyii yoo maa wa ninu awọn ọgba idẹra ni ẹni apọnle; nitori idẹkun gbere ti wọn yoo ba pade ati riri adojukọ Allah ti o ni apọnle.
فَمَالِ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ قِبَلَكَ مُهۡطِعِينَ 36
Kinni ohun ti o mu awọn ẹlẹbọ wọnyi ninu ijọ rẹ - irẹ ojisẹ - ti wọn wa lẹgbẹ rẹ ni ẹniti o yara lati pe ọ nirọ na?!
عَنِ ٱلۡيَمِينِ وَعَنِ ٱلشِّمَالِ عِزِينَ 37
Awọn ijọ ijọ yoo yipo rẹ lọtun rẹ ati ni osi rẹ.
أَيَطۡمَعُ كُلُّ ٱمۡرِيٕٖ مِّنۡهُمۡ أَن يُدۡخَلَ جَنَّةَ نَعِيمٖ 38
Se ikọọkan ninu wọn ngbero ki Allah mu wọ ọgba idẹra onidẹkun, ki o mu gbadun idẹkun gbere, ki o si tun sẹku lori keferi rẹ ni?!
كَلَّآۖ إِنَّا خَلَقۡنَٰهُم مِّمَّا يَعۡلَمُونَ 39
Ọrọ ko ri bi wọn se nlero rẹ, awa ni a dan wọn nibi ohun ti wọn mọ, paapaa a da wọn lati ibi omin yẹpẹrẹ, wọn jẹ ọlẹ ti wọn ko nikapa anfaani tabi inira fun ẹmin ara wọn, wọn se wa nse igberaga?!
فَلَآ أُقۡسِمُ بِرَبِّ ٱلۡمَشَٰرِقِ وَٱلۡمَغَٰرِبِ إِنَّا لَقَٰدِرُونَ 40
Allah bura pẹlu araarẹ, Oun ni Ọlọhun ibuyọ ati ibuwọ oorun ati osupa ati awọn gbogbo irawọ, dajudaju Awa ni olunikapa.
Lile koko iya ina nigbati awọn ẹni ina ba nfẹ lila kuro nibẹ pẹlu gbogbo atẹgun eyiti wọn nimọ si ninu awọn atẹgun ile aye.
Irun jẹ ohun ti o tobi ju ninu awọn ohun ti o npa asesi rẹ ni ile aye, ti a si fi nwa isọ kuro nibi ina ọrun.
Ipaya kuro nibi iya Allah ma nti ni lọsi ibi isẹ rere.