وَٱلَّذِي نَزَّلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءَۢ بِقَدَرٖ فَأَنشَرۡنَا بِهِۦ بَلۡدَةٗ مَّيۡتٗاۚ كَذَٰلِكَ تُخۡرَجُونَ 11
Ati ẹniti o sọ omin kalẹ pẹlu odiwọn ti yoo to yin lati sanmọ, ti yoo si to awọn ẹran yin ati awọn irugbin yin, ti a fi nta ilu ti o ti sa ji, ti ko si irugbin nibẹ, gẹgẹ bi Allah se waa ta ilẹ ti o ti sa ji pẹlu awọn irugbin ni yoo ta ẹyin naa ji fun ajinde.
وَٱلَّذِي خَلَقَ ٱلۡأَزۡوَٰجَ كُلَّهَا وَجَعَلَ لَكُم مِّنَ ٱلۡفُلۡكِ وَٱلۡأَنۡعَٰمِ مَا تَرۡكَبُونَ 12
Ẹniti O da oniranran nkan lapapọ gẹgẹ bi oru ati ọsan ati akọ ati abo ati ohun ti o yatọ si wọn, o tun se nkan ti ẹ o maa gun ni awọn irin ajo yin fun yin lati ibi awọn ọkọ oju omin ati awọn ẹranko, ti ẹ o maa gun awọn ọkọ oju omin ni ori omin, ẹ o si maa gun awọn ẹranko yin ni ori ilẹ.
لِتَسۡتَوُۥاْ عَلَىٰ ظُهُورِهِۦ ثُمَّ تَذۡكُرُواْ نِعۡمَةَ رَبِّكُمۡ إِذَا ٱسۡتَوَيۡتُمۡ عَلَيۡهِ وَتَقُولُواْ سُبۡحَٰنَ ٱلَّذِي سَخَّرَ لَنَا هَٰذَا وَمَا كُنَّا لَهُۥ مُقۡرِنِينَ 13
O se gbogbo eleyi fun yin; ni ireti ki ẹ le rinlẹ lori ẹyin awọn nkan ti ẹ ngun lori irin ajo yin, lẹyin naa ki ẹ le ranti idẹkun Ọlọhun yin nibi rirọ ọ fun yin nigbati ẹ ba simin si ori awọn ẹyin rẹ, ki ẹ wa maa sọ pẹlu ahọn yin: o mọ, O si nmọ kanga ẹniti o pese, ti o si rọ awọn nkan igun fun wa, ti awa nse bi o se wu wa nibẹ, a ko ni agbara rẹ ti kii ba se pe Allah rọ fun wa.
وَإِنَّآ إِلَىٰ رَبِّنَا لَمُنقَلِبُونَ 14
Dajudaju Awa yoo sẹri lọ si ọdọ Ọlọhun Ọba wa lohun nikan lẹyiin iku wa fun isiro ati ẹsan.
وَجَعَلُواْ لَهُۥ مِنۡ عِبَادِهِۦ جُزۡءًاۚ إِنَّ ٱلۡإِنسَٰنَ لَكَفُورٞ مُّبِينٌ 15
Awọn ẹlẹbọ lero wipe apakan awọn ẹda jẹ ohun ti Asọda bi ti mimọ nbẹ fun bi nigbati wọn sọpe: awọn Malaaika jẹ ọmọbinrin Allah, dajudaju ọmọniyan ti o sọ iru eleyi jẹ alaimoore, ti keferi rẹ ati ọna anu rẹ si hande.
أَمِ ٱتَّخَذَ مِمَّا يَخۡلُقُ بَنَاتٖ وَأَصۡفَىٰكُم بِٱلۡبَنِينَ 16
Se ẹyin yoo sọ wipe - ẹyin ẹlẹbọ - Allah mu ọmọbinrin fun Rẹ ninu ohun ti O da, o si sa yin lẹsa ọmọkunrin ninu awọn ọmọ naa?! Iru ipin wo ni ipin eleyi ti ẹ nro?!
وَإِذَا بُشِّرَ أَحَدُهُم بِمَا ضَرَبَ لِلرَّحۡمَٰنِ مَثَلٗا ظَلَّ وَجۡهُهُۥ مُسۡوَدّٗا وَهُوَ كَظِيمٌ 17
Ti wọn ba fun ẹnikan ninu wọn ni iro idunnu ọmọbinrin eyiti o nfi nti si ọdọ Ọlọhun rẹ, oju rẹ yoo di dudu nitori lilekoko ibanujẹ ati aidunnu ti o nbẹ fun, yoo si kun fun ibinu, bawo ni o se wa fi ti si ọdọ Ọlọhun rẹ ohun ti nko ibanujẹ ba a nigbati wọn ba fun ni iro idunnu rẹ?
أَوَ مَن يُنَشَّؤُاْ فِي ٱلۡحِلۡيَةِ وَهُوَ فِي ٱلۡخِصَامِ غَيۡرُ مُبِينٖ 18
Se wọn se wa nfi ẹniti wọn nre pẹlu ọsọ ti si ọdọ Ọlọhun wọn, ti o si jẹpe ko dantọ lọrọ nibi iyan nitori jijẹ abo rẹ?!
وَجَعَلُواْ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةَ ٱلَّذِينَ هُمۡ عِبَٰدُ ٱلرَّحۡمَٰنِ إِنَٰثًاۚ أَشَهِدُواْ خَلۡقَهُمۡۚ سَتُكۡتَبُ شَهَٰدَتُهُمۡ وَيُسَۡٔلُونَ 19
Wọn npe awọn Malaaika ti wọn jẹ awọn ẹru Ọba Ajọkẹ aye ti mimọ nbẹ fun ni: abo, se pesẹ nigbati Allah da wọn ni, ti o fi wa han si wọn wipe dajudaju abo ni wọn?! Awọn Malaaika yoo kọ ijẹri wọn yoo silẹ, wọn yoo si bi wọn leere ni ọjọ igbende, wọn tun fi iya jẹ wọn nitori irọ pipa wọn le lori.
وَقَالُواْ لَوۡ شَآءَ ٱلرَّحۡمَٰنُ مَا عَبَدۡنَٰهُمۗ مَّا لَهُم بِذَٰلِكَ مِنۡ عِلۡمٍۖ إِنۡ هُمۡ إِلَّا يَخۡرُصُونَ 20
Wọn sọ ni ẹniti o nwa awijare pẹlu akọsilẹ: ti Allah ba fẹ ki a ma sin awọn Malaaika, awa ko nii sin wọn nitoripe o fẹ eleyi ni ọdọ wa, o ti tọka iyọnu si Rẹ, ko si imọ fun wọn pẹlu gbolohun wọn yii bikosepe wọn jẹ opurọ.
أَمۡ ءَاتَيۡنَٰهُمۡ كِتَٰبٗا مِّن قَبۡلِهِۦ فَهُم بِهِۦ مُسۡتَمۡسِكُونَ 21
Tabi a fun awọn ẹlẹbọ yii ni iwe siwaju Alukuraani ti o se sinsin ohun ti o yatọ si llah lẹtọ fun wọn?! Ti wọn fi wa gba iwe na mu, ti wọn si fi nse ẹri.
بَلۡ قَالُوٓاْ إِنَّا وَجَدۡنَآ ءَابَآءَنَا عَلَىٰٓ أُمَّةٖ وَإِنَّا عَلَىٰٓ ءَاثَٰرِهِم مُّهۡتَدُونَ 22
Rara, eleyi ko sẹlẹ bikosepe wọn sọ ọrọ ni ẹniti o nwi awijare awokọse: dajudaju a ri awọn baba wa siwaju lori ẹsin kan ati oju ọna kan, paapaa wọn si ti jẹ ẹniti o nsin awọn oosa, dajudaju awa yoo tẹsiwaju lori oripa wọn nibi ijọsin rẹ.
Gbogbo idẹkun ni o ni bukaata si ọpẹ.
Abosi awọn ẹlẹbọ nibi irori wọn nipa Ọlọhun wọn nigbati wọn se afiti abo si ọdọ Rẹ, wọn si korira rẹ fun ẹmin ara ti wọn.
Jijẹ ibajẹ fifi kadara se awijare lori awọn ẹsẹ.
Ifoju ganni jẹ ọkan ninu ipilẹ fifi awọn ododo rinlẹ.