فَاطِرُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ جَعَلَ لَكُم مِّنۡ أَنفُسِكُمۡ أَزۡوَٰجٗا وَمِنَ ٱلۡأَنۡعَٰمِ أَزۡوَٰجٗا يَذۡرَؤُكُمۡ فِيهِۚ لَيۡسَ كَمِثۡلِهِۦ شَيۡءٞۖ وَهُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡبَصِيرُ 11
Allah ni asẹda gbogbo sanmọ ati ilẹ lori apejuwe ti ko si tẹlẹ, o se takọ tabo fun yin lati ara yin, O si se takọ tabo fun yin lati ara rakunmi, maalu ati agutan ti wọn fi npọ nitori ti yin, O si nda yin lati ara takọ tabo pẹlu fifẹ ara ẹni, O si mu yin sẹmin lati ara awọn ẹran yin pẹlu ẹran ekiri rẹ ati awọn wara rẹ ti nkankan ko jọ ọ ninu awọn ẹda Rẹ, Oun ni olugbọ ọrọ awọn ẹru Rẹ, oluriran ri awọn isẹ wọn, nkankan ko le bọ mọ lọwọ, yoo si san yin lẹsan lori awọn isẹ yin; ti o ba jẹ rere, yoo san yin lẹsan rere, ti o ba jẹ aburu, yoo san yin lẹsan aburu,
لَهُۥ مَقَالِيدُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ يَبۡسُطُ ٱلرِّزۡقَ لِمَن يَشَآءُ وَيَقۡدِرُۚ إِنَّهُۥ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٞ 12
Ti Rẹ nikan ni awọn kọkọrọ gbogbo sanmọ ati ilẹ, O ma ngbaaye arisiki fun ẹniti o ba wu U ninu awọn ẹru Rẹ; ni idanwo fun un boya yoo dupẹ tabi yoo se aimoore? O si ma nfun mọ ẹniti o ba wu U; ki o le dan wo boya yoo se suuru tabi yoo binu si kadara Allah? O jẹ onimimọ nipa gbogbo nkan, nkankan ko pamọ fun nipa ohun ti o le jẹ anfaani fun awọn ẹru Rẹ.
۞شَرَعَ لَكُم مِّنَ ٱلدِّينِ مَا وَصَّىٰ بِهِۦ نُوحٗا وَٱلَّذِيٓ أَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡكَ وَمَا وَصَّيۡنَا بِهِۦٓ إِبۡرَٰهِيمَ وَمُوسَىٰ وَعِيسَىٰٓۖ أَنۡ أَقِيمُواْ ٱلدِّينَ وَلَا تَتَفَرَّقُواْ فِيهِۚ كَبُرَ عَلَى ٱلۡمُشۡرِكِينَ مَا تَدۡعُوهُمۡ إِلَيۡهِۚ ٱللَّهُ يَجۡتَبِيٓ إِلَيۡهِ مَن يَشَآءُ وَيَهۡدِيٓ إِلَيۡهِ مَن يُنِيبُ 13
Wọn se lofin fun yin ninu ẹsin iru ohun ti a pa Nuha lasẹ wipe ki o mu de etigbọ, ki o si siẹ pẹlu rẹ eyiti a fi ransẹ si ọ - irẹ ojisẹ - ti a si se lofin fun yin gẹgẹ bi eyiti a pa Ibrahim ati Musa ati Isa lasẹ rẹ pẹlu imudopin rẹ ati sisisẹ pẹlu rẹ, soki rẹ si ni: ki ẹ gbe ẹsin duro, ki ẹ si gbe yiyapa ninu rẹ ju silẹ, o tobi lara awọn ẹlẹbọ nkan ti ẹ npe wọn sibẹ ninu mimu Allah lọkan ati gbigbe ijọsin ẹniti o yatọ si I ju silẹ, Allah ma nsẹsa ẹniti o ba wu U ninu awọn ẹru Rẹ ti yoo wa fi wa se kongẹ ijọsin Rẹ tabi itẹle tiRẹ, O si ma nfi ẹiti o ba sẹri si ọdọ Rẹ mọna ninu wọn pẹlu ironu piwada kuro nibi awọn ẹsẹ rẹ.
وَمَا تَفَرَّقُوٓاْ إِلَّا مِنۢ بَعۡدِ مَا جَآءَهُمُ ٱلۡعِلۡمُ بَغۡيَۢا بَيۡنَهُمۡۚ وَلَوۡلَا كَلِمَةٞ سَبَقَتۡ مِن رَّبِّكَ إِلَىٰٓ أَجَلٖ مُّسَمّٗى لَّقُضِيَ بَيۡنَهُمۡۚ وَإِنَّ ٱلَّذِينَ أُورِثُواْ ٱلۡكِتَٰبَ مِنۢ بَعۡدِهِمۡ لَفِي شَكّٖ مِّنۡهُ مُرِيبٖ 14
Awọn keferi ati awọn ẹlẹbọ ko yapa ayaafi lẹyin igbati awijare wa le wọn lori pẹlu gbigbe Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun dide si wọn, yiyapa wọn yii ko sadede sẹlẹ ayaafi tori tẹnbẹlẹkun ati abosi, ti kii ba se imọ Allah ti o ti gbawaju wipe Oun yoo lọra iya fun wọn titi di asiko kan ti a fi aala si ninu imọ Rẹ, Ohun ni ọjọ igbende fun idajọ Allah laarin wọn, o wa kanju iya fun wọn nitori keferi wọn si Allah ati pipe awọn ojisẹ Rẹ nirọ, atiwpe dajudaju awọn ti o jogun taoreeta ninu awọn yahuudi ati injiila ninu awọn nassarọ lẹyin awọn asiwaju wọn ati lẹyin awọn ẹlẹbọ wọnyi, paapaa wọn wa ninu iyemeji nipa Alukuraani yii eyiti Muhammad ti ikọ ati ọla nbẹ fun mu wa, wọn si pe e nirọ.
فَلِذَٰلِكَ فَٱدۡعُۖ وَٱسۡتَقِمۡ كَمَآ أُمِرۡتَۖ وَلَا تَتَّبِعۡ أَهۡوَآءَهُمۡۖ وَقُلۡ ءَامَنتُ بِمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ مِن كِتَٰبٖۖ وَأُمِرۡتُ لِأَعۡدِلَ بَيۡنَكُمُۖ ٱللَّهُ رَبُّنَا وَرَبُّكُمۡۖ لَنَآ أَعۡمَٰلُنَا وَلَكُمۡ أَعۡمَٰلُكُمۡۖ لَا حُجَّةَ بَيۡنَنَا وَبَيۡنَكُمُۖ ٱللَّهُ يَجۡمَعُ بَيۡنَنَاۖ وَإِلَيۡهِ ٱلۡمَصِيرُ 15
Pepe si ẹsin ti o duro tọ yii, duro sinsin nibẹ ni ibamun si ohun ti Allah pa ọ lasẹ, mase tẹle awọn ifẹ inu wọn ti o jẹ ibajẹ, ki o maa sọ nigbati o ba nba wọn se ifanfa: mo nigbagbọ si Allah ati awọn iwe eyiti Allah sọkalẹ fun awọn ojisẹ Rẹ, Allah si pa mi lasẹ ki nse idajọ laarin yin pẹlu deedee, Allah eyiti mo nsin jẹ Ọlọhun wa ati Ọlọhun yin lapapọ, ti wa ni awọn isẹ wa yoo jẹ ti o ba jẹ rere ni tabi aburu, ti yin ni awọn isẹ yin yoo jẹ ti o ba jẹ rere ni tabi aburu, ko si iyan laarin wa ati ẹyin lẹyin igbati awijare ti fi oju han, ti ohun ti a jiyan le lori si ti han, Allah yoo ko wa papọ lapapọ, ọdọ Rẹ si ni ibusẹri si ni ọjọ igbende, yoo si san onikaluku lẹsan ninu wa pẹlu ohun ti o ba lẹtọ si i, nigba yii ni olododo yoo hande kuro ninu onirọ, ẹniti ti o lẹtọ yoo si han kuro ninu anibajẹ.
Ẹsin awọn anọbi ninu ipilẹ rẹ jẹ ẹsin kan soso.
Pataki isọkan gbolohun ati ewu yiyapa nibẹ.
Ninu awọn ti o gbe aseyọri ipepe si ọdọ Allah duro: nini alaafia ipilẹ ati iduro sinsin le lori ati ijina si itẹle awọn ifẹẹnu ati deedee sise ati mimujuto ajọsepọ ati gbigbe iyan ti ko ni asunsi ninu ju silẹ ati riranileti nipa ibudarisi ajọsepọ.