وَكَمۡ قَصَمۡنَا مِن قَرۡيَةٖ كَانَتۡ ظَالِمَةٗ وَأَنشَأۡنَا بَعۡدَهَا قَوۡمًا ءَاخَرِينَ 11
Kinni o fi npọ to awọn ijọ ti a parun nitori sise abosi wọn pẹlu sise keferi, a si da awọn ijọ miran lẹyin wọn!
فَلَمَّآ أَحَسُّواْ بَأۡسَنَآ إِذَا هُم مِّنۡهَا يَرۡكُضُونَ 12
Nigbati awọn ti a parun fi oju kan ijiya Wa tan yanyan, lojiji ni wọn sa kuro nibi iparun ninu abole wọn.
لَا تَرۡكُضُواْ وَٱرۡجِعُوٓاْ إِلَىٰ مَآ أُتۡرِفۡتُمۡ فِيهِ وَمَسَٰكِنِكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تُسَۡٔلُونَ 13
Wọn wa nbẹrẹ sini pe wọn ni ojupọnna ifini se yẹyẹ: ẹ mase sa, ẹ pada si ibi igbadun ti ẹ wa nibẹ tẹlẹ, ati si awọn inu ile yin; o seese ki wọn bi yin leere nkankan nipa ile yin.
قَالُواْ يَٰوَيۡلَنَآ إِنَّا كُنَّا ظَٰلِمِينَ 14
Awọn alabosi wọnyi nsọrọ niti jijẹwọ ẹsẹ wọn: irẹ iparun wa o, ofo wa o, paapa julọ a ti jẹ alabosi nitori sise keferi wa si Allah.
فَمَا زَالَت تِّلۡكَ دَعۡوَىٰهُمۡ حَتَّىٰ جَعَلۡنَٰهُمۡ حَصِيدًا خَٰمِدِينَ 15
Jijẹwọ ẹsẹ wọn koyẹ kogbo ati sisepe le ara wọn lori iparun eyiti wọn npaara rẹ titi ti a fi sọ wọn di apejuwe irugbin eyiti a kore rẹ, ti wọn ti ku, ti ko le yira pada mọ.
وَمَا خَلَقۡنَا ٱلسَّمَآءَ وَٱلۡأَرۡضَ وَمَا بَيۡنَهُمَا لَٰعِبِينَ 16
Awa ko da sanmọ ati ile ati ohun ti nbẹ laarin awọn mejeeji ni ere ati asan bikosepe a da awọn mejeeji ki o le tọka si agbara Wa.
لَوۡ أَرَدۡنَآ أَن نَّتَّخِذَ لَهۡوٗا لَّٱتَّخَذۡنَٰهُ مِن لَّدُنَّآ إِن كُنَّا فَٰعِلِينَ 17
Ti a ba gbero lati ni ọrẹ tabi ọmọ, a ba mu u ni ọdọ Wa, sugbọn Awa ko ni se eleyi nitoripe A mọ kanga kuro nibẹ.
بَلۡ نَقۡذِفُ بِٱلۡحَقِّ عَلَى ٱلۡبَٰطِلِ فَيَدۡمَغُهُۥ فَإِذَا هُوَ زَاهِقٞۚ وَلَكُمُ ٱلۡوَيۡلُ مِمَّا تَصِفُونَ 18
Bikosepe a nju ododo eyiti a se imisi rẹ si ojisẹ Wa lori ibajẹ awọn keferi ti o si sọọdi iyẹpẹrẹ, ni ojiji ni ibajẹ wọn si lọ, o wa fun yin - ẹyin ti ẹ nsọ nipa mimu ni ọrẹ ati ọmọ Rẹ - iparun nitorpe ẹ nroyin Rẹ pẹlu ohun ti ko lẹtọ si I.
Nigbati mimu ọrẹ ati ọmọ jẹ ohun ti o jade lati ibi aini; O salaye ẹniti mimọ nbẹ fun wipe Oun ni olukapa aye yii, ti O si sọpe:
وَلَهُۥ مَن فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ وَمَنۡ عِندَهُۥ لَا يَسۡتَكۡبِرُونَ عَنۡ عِبَادَتِهِۦ وَلَا يَسۡتَحۡسِرُونَ 19
Oun nikan ti mimọ nbẹ fun ni aaso ti o ni sanmọ, ti O si ni ilẹ, lati ọdọ Rẹ ni awọn Malaika ti wọn kii se orikunkun si ijọsin Rẹ, kii si rẹ wọn lori rẹ.
يُسَبِّحُونَ ٱلَّيۡلَ وَٱلنَّهَارَ لَا يَفۡتُرُونَ 20
Wọn ma npesẹ lori sise afọmọ fun Ọlọhun Ọba ni gbogbo igba, ti wọn kii ko susu.
أَمِ ٱتَّخَذُوٓاْ ءَالِهَةٗ مِّنَ ٱلۡأَرۡضِ هُمۡ يُنشِرُونَ 21
Bikosepe awọn ẹlẹbọ mu Ọlọhun Ọba miran yatọ si Allah, wọn ko ji oku, bawo ni wọn se wa nsin ẹniti o kagara nibi eleyi?!
لَوۡ كَانَ فِيهِمَآ ءَالِهَةٌ إِلَّا ٱللَّهُ لَفَسَدَتَاۚ فَسُبۡحَٰنَ ٱللَّهِ رَبِّ ٱلۡعَرۡشِ عَمَّا يَصِفُونَ 22
Ti o ba jẹsi wipe ẹniti a tun le jọsin fun miran wa jatọ si Ọlọhun Ọba Allah ni sanmọ ati ilẹ, mejeeji ki ba ti bajẹ latara ifanfa ẹni a njọsin fun nibi ọla, eyiti o sẹlẹ ni ohun ti o yatọ si eleyi, Allah mọ kanga, Ọba ti o ni Alaarasi kuro nibi ohun ti awọn ẹlẹbọ fi nroyin Rẹ niti irọ nibi wipe O ni akẹgbẹ.
لَا يُسَۡٔلُ عَمَّا يَفۡعَلُ وَهُمۡ يُسَۡٔلُونَ 23
Ọlọhun Ọba Allah nikan ni aaso nibi ọla Rẹ ati idajọ Rẹ, ẹnikankan ko le bi leere nibi ohun ti o ba pebubu tabi se idajọ rẹ, sugbọn Oun yoo bi awọn ẹru Rẹ leere nipa isẹ wọn, yoo si san wọn lẹsan le lori.
أَمِ ٱتَّخَذُواْ مِن دُونِهِۦٓ ءَالِهَةٗۖ قُلۡ هَاتُواْ بُرۡهَٰنَكُمۡۖ هَٰذَا ذِكۡرُ مَن مَّعِيَ وَذِكۡرُ مَن قَبۡلِيۚ بَلۡ أَكۡثَرُهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ ٱلۡحَقَّۖ فَهُم مُّعۡرِضُونَ 24
Bikosepe wọn mu olujọsin miran yatọ si Allah, sọpe - ire ojise - fun awọn ẹlẹbọ yii: ẹ mu awijare yin wa lori lilẹtọ si ijọsin wọn, iwe yii ti asọkalẹ fun mi ati awọn iwe ti a sọkalẹ fun awọn ojisẹ, ko si awijare fun yin ninu rẹ, bikosepe ọpọ ninu awọn ẹlẹbọ wọn ko ni ifarati kankan ju aimọkan ati awokọse lọ, wọn jẹ ẹniti o gunri kuro nibi gbigba ododo.
Abosi jẹ okunfa iparun lori ipo ẹnikọọkan ati akojọpọ.
Ọlọhun Allah ko da nkankan lasan; nitoripe dajudaju Oun ti mimọ nbẹ fun mọ kanga kuro nibi ere.
Bibori ododo ati rirẹlẹ ibajẹ jẹ isesi Ọlọhun.
Biba adisọkan ẹbọ jẹ pẹlu ẹri aipemeji.