وَلِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۚ وَإِلَى ٱللَّهِ تُرۡجَعُ ٱلۡأُمُورُ 109
Ti Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) ni Oun nikan, ni ọla ohun ti nbẹ ni awọn sanmọ ati ohun ti nbẹ ni ilẹ se, ni dida ẹda ati pipa asẹ, ọdọ Rẹ (ti ọla Rẹ ga) ni ibupadasi gbogbo alamọri ẹda Rẹ, Yoo si san olukuluku ninu wọn ni ẹsan lori odiwọn ohun ti o lẹtọ si.
كُنتُمۡ خَيۡرَ أُمَّةٍ أُخۡرِجَتۡ لِلنَّاسِ تَأۡمُرُونَ بِٱلۡمَعۡرُوفِ وَتَنۡهَوۡنَ عَنِ ٱلۡمُنكَرِ وَتُؤۡمِنُونَ بِٱللَّهِۗ وَلَوۡ ءَامَنَ أَهۡلُ ٱلۡكِتَٰبِ لَكَانَ خَيۡرٗا لَّهُمۚ مِّنۡهُمُ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ وَأَكۡثَرُهُمُ ٱلۡفَٰسِقُونَ 110
Ẹ jẹ - ẹyin ijọ Muhammad (ki Ọlọhun se ikẹ ati igẹ fun un) - ijọ ti o loore ju, eyiti Ọlọhun Ọba Allah mu jade fun awọn eniyan, nibi igbagbọ yin ati isẹ yin, ati eniyan ti o ni anfaani ju fun awọn eniyan, ti ẹ yoo maa pasẹ daadaa, eyiti Ṣẹria tọka si, ti laakaye si se ni ohun ti o dara, ti ẹ o si maa kọ nibi ohun ti ọkan kọ, eyiti Ṣhẹria kọ, ti laakaye naa si pe ni ohun ti ko dara, ti ẹ yoo si maa ni igbagbọ pẹlu Ọlọhun Ọba Allah, ni igbagbọ ti o dantọ, ti isẹ yoo maa sọ di ododo, ti o ba jẹ wipe o gbagbọ awọn ti wọn ni tira ninu awọn Yahuudi ati awọn Nasaara pẹlu Muhammad (ki Ọlọhun Ọba se ikẹ ati igẹ fun un) , nkan naa ko ba ni oore fun wọn ninu aye wọn ati Ọjọ Ikẹyin, o nbẹ ninu awọn ti o ni tira, awọn diẹ ti wọn gba ohun ti Muhammad (ki Ọlọhun Ọba se ikẹ ati igẹ fun un) mu wa gbọ, ati wipe ọpọlọpọ wọn ni awọn ti wọn jade kuro ninu ẹsin Ọlọhun Ọba Allah ati ofin Rẹ,
لَن يَضُرُّوكُمۡ إِلَّآ أَذٗىۖ وَإِن يُقَٰتِلُوكُمۡ يُوَلُّوكُمُ ٱلۡأَدۡبَارَ ثُمَّ لَا يُنصَرُونَ 111
Biotiwulẹ ki isọta wa ni aarin wọn to, wọn ko le niyin lara -ẹyin olugbagbọ ododo - nibi ẹsin yin tabi ninu awọn ẹmin yin, Ayaafi suta pẹlu ahọn wọn nibi sisọ ọrọ odi si ẹsin, ati mima se yẹyẹ pẹlu yin ati ohun ti o jọ nkan naa, ati wipe ti wọn ba waa ba yin ja, wọn yoo sa lọ ni ẹniti o ja kulẹ niwaju yin, wọn ko ni ran wọn se leyin lori lailai.
ضُرِبَتۡ عَلَيۡهِمُ ٱلذِّلَّةُ أَيۡنَ مَا ثُقِفُوٓاْ إِلَّا بِحَبۡلٖ مِّنَ ٱللَّهِ وَحَبۡلٖ مِّنَ ٱلنَّاسِ وَبَآءُو بِغَضَبٖ مِّنَ ٱللَّهِ وَضُرِبَتۡ عَلَيۡهِمُ ٱلۡمَسۡكَنَةُۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ كَانُواْ يَكۡفُرُونَ بَِٔايَٰتِ ٱللَّهِ وَيَقۡتُلُونَ ٱلۡأَنۢبِيَآءَ بِغَيۡرِ حَقّٖۚ ذَٰلِكَ بِمَا عَصَواْ وَّكَانُواْ يَعۡتَدُونَ 112
Wọn se iyẹpẹrẹ ati kikere ni ohun ti rọkirika awọn Yahuudi, ti yoo si maa wa pẹlu wọn nibi gbogbo ibi ti wọn ba ti ri wọn, wọn ko si nii ni ifọkanbalẹ ayaafi pẹlu adehun kan tabi ifayabalẹ lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) , tabi ni ọdọ awọn eniyan, ati wipe wọn si sẹri pẹlu ibinu lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah, wọn si gbe bukaata le wọn lori ati osi, ni ohun ti o rọkirika wọn, ohun ti wọn gbe le wọn lori naa jẹ pẹlu okunfa sise aigbagbọ wọn si awọn aayah Ọlọhun Ọba Allah, ati pipa awọn Anọbi Rẹ niti abosi, nkan naa - bakanna - jẹ pẹlu okunfa gbigbẹrugbọnri wọn ati kikọja aala wọn si awọn ẹnu aala Ọlọhun Ọba Allah.
Ati wipe nigbati Ọlọhun Ọba Allah salaye isesi ọpọlọpọ awọn ti wọn ni tira, O waa salaye isesi awọn ikọ kan ninu wọn, ti wọn duro deede lori ododo, ni ẹniti o duro pẹlu rẹ, ni O wa sọ wipe:
۞لَيۡسُواْ سَوَآءٗۗ مِّنۡ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِ أُمَّةٞ قَآئِمَةٞ يَتۡلُونَ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ ءَانَآءَ ٱلَّيۡلِ وَهُمۡ يَسۡجُدُونَ 113
Awọn ti A fun ni tira ko ri bakanna nibi isesi wọn, bikose wipe o nbẹ ninu wọn ikọ kan, ti o duro lori ẹsin Ọlọhun Ọba Allah, ni ẹniti o duro pẹlu asẹ Ọlọhun Ọba Allah ati ohun ti O kọ, wọn ma nka awọn aayah Ọlọhun Ọba Allah, ni awọn wakati oru, ni ẹniti nkirun fun Ọlọhun Ọba Allah, awọn ikọ yii nbẹ siwaju gbigbe Anọbi Muhammad (ki Ọlọhun Ọba se ikẹ ati igẹ fun un) dide ni ojisẹ, ẹniti o ba ba igbenidide ni ojisẹ ninu wọn, yoo gba Islam.
يُؤۡمِنُونَ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ وَيَأۡمُرُونَ بِٱلۡمَعۡرُوفِ وَيَنۡهَوۡنَ عَنِ ٱلۡمُنكَرِ وَيُسَٰرِعُونَ فِي ٱلۡخَيۡرَٰتِۖ وَأُوْلَٰٓئِكَ مِنَ ٱلصَّٰلِحِينَ 114
Wọn ma ngba Ọlọhun Ọba Allah ati Ọjọ Ikẹyin gbọ ni igbagbọ ti o dantọ, wọn si ma npasẹ daada ati oore, wọn si tun ma nkọ kuro nibi ohun ti ọkan kọ ati aburu, wọn si tete ma nlọ si ibi awọn isẹ oloore, wọn si tete ma nlo awọn asiko awọn ijọsin, awọn ti wọn ni iroyin yii lara, wa ninu awọn ẹrusin Ọlọhun Ọba Allah, awọn ti adisọkan wọn dara ati awọn isẹ wọn.
وَمَا يَفۡعَلُواْ مِنۡ خَيۡرٖ فَلَن يُكۡفَرُوهُۗ وَٱللَّهُ عَلِيمُۢ بِٱلۡمُتَّقِينَ 115
Ohun ti awọn wọnyi ba se ninu oore, o kere ni tabi o pọ, ẹsan rẹ ko nii sọnu fun wọn, ẹsan rẹ ko si nii dinku, Ọlọhun Ọba Allah ni Ẹniti O ni imọ nipa awọn olupaya Ọlọhun, awn ti wọn nmu awọn asẹ Rẹ sẹ, ti wọn si njinna si awọn ti O kọ, nkankan ko pamọ fun Un ninu awọn isẹ wọn, ati wipe Yoo si pada san wọn lẹsan le lori.
Ohun ti o tobi, ti o se iyatọ awọn ijọ yii, ti o si jẹ wipe ohun naa ni wọn fi ni oore - lẹyin nini igbagbọ pẹlu Ọlọhun Ọba Allah - ni mima pasẹ daadaa ati mima kọ ohun ti ọkan kọ.
Ọlọhun Ọba Allah (ti ọla Rẹ ga) dajọ iyẹpẹ lori awọn ti o ni tira, nitori sise oju-eji wọn, ati gigunri wọn kuro nibi ẹsin Ọlọhun Ọba Allah, ati aipe adehun wọn pẹlu eyiti ti wọn gba lọwọ wọn ninu adehun.
Awọn ti A fun ni tira, ko wa lori isesi ẹyọ kan, o nbẹ ninu wọn ẹniti o duro pẹlu asẹ Ọlọhun Ọba Allah, ti o si ntẹle ẹsin Rẹ, ti o si duro nibi awọn aala Rẹ, awọn wọnyi o nbẹ fun wọn ere ati ẹsan ti o tobi, eleyi siwaju gbigbe Anọbi Muhammad (ki Ọlọhun Ọba se ikẹ ati igẹ fun un) dide ni ojisẹ ni.