فَلَا تَكُ فِي مِرۡيَةٖ مِّمَّا يَعۡبُدُ هَٰٓؤُلَآءِۚ مَا يَعۡبُدُونَ إِلَّا كَمَا يَعۡبُدُ ءَابَآؤُهُم مِّن قَبۡلُۚ وَإِنَّا لَمُوَفُّوهُمۡ نَصِيبَهُمۡ غَيۡرَ مَنقُوصٖ 109
Mase wa - irẹ ojisẹ - ninu oniye meji tabi roiroi lori bibajẹ ohun ti awọn ẹlẹbọ nsin, ko si awijare laakaye tabi ti ofin ẹsin ti o ni alaafia lori rẹ, ohun ti o gbe wọn lọ si ibi mima jọsin fun ohun ti o yatọ si Allah ju ikọse awọn baba wọn lọ, dajudaju Awa Ọlọhun yoo pe ipin iya wọn fun wọn ti ko nii din rara.
وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا مُوسَى ٱلۡكِتَٰبَ فَٱخۡتُلِفَ فِيهِۚ وَلَوۡلَا كَلِمَةٞ سَبَقَتۡ مِن رَّبِّكَ لَقُضِيَ بَيۡنَهُمۡۚ وَإِنَّهُمۡ لَفِي شَكّٖ مِّنۡهُ مُرِيبٖ 110
Paapaa ati fun Musa ti taoreeta, awọn eniyan se iyapa le lori, apakan ninu wọn gbaagbọ bẹẹ ni apakan wọn se keferi si i, ti kii baa se akọsilẹ Ọlọhun Ọba Allah ti o ti gbawaju wipe Oun ko nii kanju ifiyajẹni bikose wipe Oun yoo lọ lara di ọjọ igbende nitori ọgbọn kan, ohun ti wọn lẹtọ si ninu iya aye ki ba sọkalẹ le wọn lori, dajudaju awọn keferi yahuudi ati awọn ẹlẹbọ wa ninu iyemeji si alukuraani, wọn si ti ko sinu roiroi.
وَإِنَّ كُلّٗا لَّمَّا لَيُوَفِّيَنَّهُمۡ رَبُّكَ أَعۡمَٰلَهُمۡۚ إِنَّهُۥ بِمَا يَعۡمَلُونَ خَبِيرٞ 111
Dajudaju gbogbo awon ti adarukọ ninu awọn oluyapa yii ni Ọlọhun Ọba rẹ yoo se pipe - irẹ ojisẹ - ẹsan isẹ wọn, eyiti o ba jẹ daadaa ẹsan rẹ yoo jẹ rere, bẹẹ ni eyiti o ba jẹ aburu ẹsan rẹ yoo jẹ aburu, dajudaju Ọlọhun Ọba Allah jẹ onimimọ amọtan yan an yan lori oun ti wọn nse, nkankan ko pamọ si nibi gbogbo isẹ wọn.
فَٱسۡتَقِمۡ كَمَآ أُمِرۡتَ وَمَن تَابَ مَعَكَ وَلَا تَطۡغَوۡاْۚ إِنَّهُۥ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرٞ 112
Dunni mọ sise deedee ni oju ọna ti o duro tọ - irẹ ojisẹ - gẹgẹ bi Ọlọhun Ọba Allah se pa ọ lasẹ, ki o si maa tẹle awọn asẹ rẹ, ki o tun jinna si awọn nkan ti O kọ, ki awọn ti wọn ronu piwada pẹlu rẹ ninu awọn olugbagbọ ododo naa duro deedee, ki ẹ mase kọja ẹnu aala pẹlu dida ẹsẹ toripe ẹniti O ri gbogbo nkan ti ẹ nse nisẹ nii se, nkankan ko pamọ fun Un nibi isẹ yin, yoo san yin lẹsan le lori.
وَلَا تَرۡكَنُوٓاْ إِلَى ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ فَتَمَسَّكُمُ ٱلنَّارُ وَمَا لَكُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ مِنۡ أَوۡلِيَآءَ ثُمَّ لَا تُنصَرُونَ 113
Ẹ mase fi si ọdọ awọn keferi alabosi pẹlu mima pọ nkan ti wọn nse tabi fifẹ han ki ina o ma ba kan yin lati ara ifara ti si wọn, ko si alatilẹyin kan fun yatọ si Allah ti o le layin nibẹ, lẹyin naa ẹ ko nii ri ẹniti yoo ran yin se.
وَأَقِمِ ٱلصَّلَوٰةَ طَرَفَيِ ٱلنَّهَارِ وَزُلَفٗا مِّنَ ٱلَّيۡلِۚ إِنَّ ٱلۡحَسَنَٰتِ يُذۡهِبۡنَ ٱلسَّئَِّاتِۚ ذَٰلِكَ ذِكۡرَىٰ لِلذَّٰكِرِينَ 114
Gbe duro - irẹ ojisẹ - irun ni ojupọnna ti o dara ni abala ọsan meji, awọn mejeeji naa ni akọkọ ọsan ati igbẹyin wọn, ki o si gbe duro ni awọn asiko kan loru, dajudaju awọn isẹẹre ma npa awọn ẹsẹ keekeke rẹ, eleyi ti a sọ yi jẹ isiti fun awọn ti wọn ngba isiti, o si tun jẹ oriwoye fun awọn ti wọn ngba iwoye.
وَٱصۡبِرۡ فَإِنَّ ٱللَّهَ لَا يُضِيعُ أَجۡرَ ٱلۡمُحۡسِنِينَ 115
Se suuru lori sise ohun ti a pa ọ lasẹ lori gẹgẹ bi iduro sinsin ati ohun ti o yatọ si ati lori gbigbe ohun ti a kọ fun ọ ju silẹ gẹgẹ bi ikọja ẹnu aala ati ifara ti abosi dajudaju Allah ko nii ba ẹsan awọn oluse daadaa jẹ bikose wipe yoo gba eyiti o dara ju ninu ohun ti wọn se wọle, yoo si san wọn lẹsan ju nkan ti o dara ju ohun ti wọn se nisẹ lọ.
فَلَوۡلَا كَانَ مِنَ ٱلۡقُرُونِ مِن قَبۡلِكُمۡ أُوْلُواْ بَقِيَّةٖ يَنۡهَوۡنَ عَنِ ٱلۡفَسَادِ فِي ٱلۡأَرۡضِ إِلَّا قَلِيلٗا مِّمَّنۡ أَنجَيۡنَا مِنۡهُمۡۗ وَٱتَّبَعَ ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ مَآ أُتۡرِفُواْ فِيهِ وَكَانُواْ مُجۡرِمِينَ 116
Ori kinni awọn ijọ ti a fi iya jẹ yii siwaju yin ti o jẹ asẹkubọ ninu awọn ọlọla ẹniire nkọ fun awọn ijọ naa nibi keferi ati kuro nibi ibajẹ lori pẹlu dida ẹsẹ asẹkubọ yii ko si pẹlu wọn ayaafi diẹ ninju wọn ni wọn ma nkọ ibajẹ, awa la wọn nigbati a pa ijọ wọn ti o jẹ alabosi run, bẹẹ ni awọn alabosi ninu ijọ wọn tẹle idẹkun ti wọn wa lori rẹ, o si tun jẹ alabosi pẹlu titẹle awọn eniyan yii.
وَمَا كَانَ رَبُّكَ لِيُهۡلِكَ ٱلۡقُرَىٰ بِظُلۡمٖ وَأَهۡلُهَا مُصۡلِحُونَ 117
Ọlọhun Ọba rẹ kii se - irẹ ojisẹ - ẹniti yoo pa abule kan ninu awọn abule nigbati wọn ba jẹ olutunlẹse, sugbọn yoo pa a run nigbati wọn ba jẹ olubalẹjẹ lati ibi keferi tabi abosi tabi awọn ẹsẹ.
O jẹ dandan iduro sinsin lori ẹsin Ọlọhun Ọba Allah ti O ga.
Sise ikilọ kuro nibi fifi ara ti si awọn keferi alabosi lati ibi ẹpọn ati ififẹhan.
Sise alaye isesi Ọlọhun Ọba ti ọla Rẹ ga nibi wipe daadaa sise ma npa aburu rẹ.
Siseni loju kokoro si mimu awọn ijọ ti o lọla, ti wọn yoo maa pasẹ daadaa jade, ti wọn yoo si maa kọ fun ni kuro nibi ibajẹ ati aburu, ati wipe dajudaju awọn idaabobo kuro nibi iya Allah.