وَٱلَّذِينَ ٱتَّخَذُواْ مَسۡجِدٗا ضِرَارٗا وَكُفۡرٗا وَتَفۡرِيقَۢا بَيۡنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ وَإِرۡصَادٗا لِّمَنۡ حَارَبَ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ مِن قَبۡلُۚ وَلَيَحۡلِفُنَّ إِنۡ أَرَدۡنَآ إِلَّا ٱلۡحُسۡنَىٰۖ وَٱللَّهُ يَشۡهَدُ إِنَّهُمۡ لَكَٰذِبُونَ 107
O nbẹ ninu awọn sọbẹ selu bakanna, awọn ti wọn kọ mọsalaasi laifi tẹle asẹ Allah bikose lati fi inira kan awọn olugbafa ati lati se afihan keferi lati le fun awọn onisọbẹ selu ni agbara ati lati se onpinya laarin awọn olugbagbọ ododo ati lati mura silẹ ni rireti awọn ti wọn gbogun ti Allah ati ojisẹ Rẹ siwaju kikọ mọsalaasi naa, awọn sọbẹ selu yii yii si maa bura fun yin: a ko gbero nkankan ju pẹlẹpẹlẹ fun awọn olugbafa lọ, Ọlọhun Ọba Allah si jẹri wipe awọn ni opuirọ nibi apemọra nkan ti wọn nsọ yii.
لَا تَقُمۡ فِيهِ أَبَدٗاۚ لَّمَسۡجِدٌ أُسِّسَ عَلَى ٱلتَّقۡوَىٰ مِنۡ أَوَّلِ يَوۡمٍ أَحَقُّ أَن تَقُومَ فِيهِۚ فِيهِ رِجَالٞ يُحِبُّونَ أَن يَتَطَهَّرُواْۚ وَٱللَّهُ يُحِبُّ ٱلۡمُطَّهِّرِينَ 108
Mọsalaasi yii, iroyin rẹ ni wipe wọn ko nii tẹwọ gba a - irẹ Anọbi - ipepe awọn sọbẹ selu fun ọ nibi irun nibẹ, dajudaju Mọsalaasi kuba eyiti wọn pilẹ lori ipilẹ ipaya Ọlọhun lọla ki wọn kirun nibẹ ju Mọsalasi yii eyiti wọn pilẹ lori keferi lọ, ni inu Mọsalaasi kuba awọn okunrin kan wọ nibẹ, ti wọn nifẹ si ki wọn o maa se imọra kuro nibi ẹgbin keekeeke ati ẹgbin nla, ati kuro nibi awọn ẹsẹ pẹlu ironu piwada ati wiwa aforijin, Ọlọhun Ọba Allah nifẹ awọn olumọra kuro nibi awọn ẹgbin keekeeke ati awọn ẹgbin nla ati awọn ẹsẹ.
أَفَمَنۡ أَسَّسَ بُنۡيَٰنَهُۥ عَلَىٰ تَقۡوَىٰ مِنَ ٱللَّهِ وَرِضۡوَٰنٍ خَيۡرٌ أَم مَّنۡ أَسَّسَ بُنۡيَٰنَهُۥ عَلَىٰ شَفَا جُرُفٍ هَارٖ فَٱنۡهَارَ بِهِۦ فِي نَارِ جَهَنَّمَۗ وَٱللَّهُ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلظَّٰلِمِينَ 109
Se o jẹ ara wọn bi, ẹniti o pilẹ ile tirẹ lori ipaya Allah pẹlu titẹle awọn asẹ Rẹ ati jijinna si awọn ohun ti O kọ, ati iyọnu Allah nibi gbigbaaye nibi awọn isẹẹre pẹlu ẹniti o kọ masalaasi lati fi inira kan awọn olugbafa ati fifun keferi lagbara ati sise onpinya laarin awọn olugbagbọ ododo bi?! Wọn ko dọgbọ lailai, ẹni akọkọ ile tirẹ lagbara, o si gbaramu, ko le paya sisubu le lori, ẹni yii apejuwe rẹ da gẹgẹ bi ẹniti o kọ ile si eti koto, ti o wo, ti o si subu, ti ile rẹ tun waa yẹ si koto jahanamọ, Ọlọhun Ọba Allah ko nii fi ijọ alabosi se kongẹ nitori keferi, sọbẹ selu ati ohun ti o yatọ si eleyi.
لَا يَزَالُ بُنۡيَٰنُهُمُ ٱلَّذِي بَنَوۡاْ رِيبَةٗ فِي قُلُوبِهِمۡ إِلَّآ أَن تَقَطَّعَ قُلُوبُهُمۡۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ 110
Mọsalaasi wọn ti wọn mọ niti inira, ko nii yẹ ko nii gbo ni iyemeji ati ise sọbẹ selu ti o rinlẹ ninu ọkan wọn titi ti iku yoo fi mu titan ba ọkan wọn tabi pa pẹlu ida, Ọlọhun Ọba Allah jẹ onimimọ si awọn isẹ ẹru Rẹ, ọjọgbọn nibi idajọ ti O ba se, bi sise ẹsan lori rere tabi aburu.
Nigbati Ọlọhun Ọba Allah ba salaye idojuti awọn sọbẹ selu oluyapa kuro nibi igbiyanju, O tun wa salaye awọn olugbiyanju si oju ọna Rẹ, O wa sọ wipe:
۞إِنَّ ٱللَّهَ ٱشۡتَرَىٰ مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ أَنفُسَهُمۡ وَأَمۡوَٰلَهُم بِأَنَّ لَهُمُ ٱلۡجَنَّةَۚ يُقَٰتِلُونَ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ فَيَقۡتُلُونَ وَيُقۡتَلُونَۖ وَعۡدًا عَلَيۡهِ حَقّٗا فِي ٱلتَّوۡرَىٰةِ وَٱلۡإِنجِيلِ وَٱلۡقُرۡءَانِۚ وَمَنۡ أَوۡفَىٰ بِعَهۡدِهِۦ مِنَ ٱللَّهِۚ فَٱسۡتَبۡشِرُواْ بِبَيۡعِكُمُ ٱلَّذِي بَايَعۡتُم بِهِۦۚ وَذَٰلِكَ هُوَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡعَظِيمُ 111
Dajudaju Allah ti mimọ nbẹ fun ti ra ẹmin awọn olugbagbọ ododo - pẹlu wipe awọn ni wọn ni; ni sise ọla lati ọdọ Rẹ - pẹlu dukia ti o niye lori ohun naa ni alujannah nigbati wọn ba ti le jagun lati ba keferi ja ki gbolohun Allah jẹ ohun ti o ga, wọn nba keferi ja, awọn keferi naa si nba wọn ja, adehun Allah lori eleyi jẹ adehun ododo ninu taoreeta: tii se iwe Musa ati Injiila: tii se iwe Isa ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa bẹ fun gbogbo wọn ati Alukuraani: tii se iwe Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, ko si ẹnikankan ti o le pe adehun Rẹ bii Allah tin mimọ nbẹ fun; ẹ yaa maa yọ, ki ẹ maa dunnu -ẹyin olugbagbọ ododo- pẹlu owo eyiti ẹ ba Ọlọhun Ọba Allah se, paapaa ẹ ti jere nibẹ ni ere ti o tobi, owo yii jẹ erenjẹ ti o tobi.
Ifẹ Ọlọhun Ọba Allah rinlẹ fun awọn oluse imọra kuro nibi awọn ẹgbin ara ati ti ẹmin.
Ko le jọ ara wọn ẹniti o ba se isẹ ni erongba ojuure Ọlọhun Ọba; isẹ yii ni isẹ ti yoo maa sẹku ti ẹniti o se e yoo si ti ibẹ se oriire, ati ẹnikan ti o gbero aranse keferi pẹlu isẹẹrẹ ati igbogunti awọn olugbafa; isẹ yii ohun ni yoo tan, ti yoo si ko oriibu ba ẹniti o se e
Sise igbiyanju lofin ati siseni loju kokoro si i o wa ninu awọn ẹsin ti o ti wa siwaju Islam bakanna.
Eyikeyi isesi ti o le mu onpinya wa laarin awọn olugbagbọ ododo, dajudaju o wa ninu awọn ẹsẹ eyiti a da soju ki a gbe ju silẹ, ki a si yẹ fun un, gẹgẹ bi o se ga si wipe gbogbo awọn isesi ti yoo ba mu awọn olugbagbọ ododo ko papọ, ti yoo si pa ọkan wọn papọ, a se titẹle ni ohun ti a da soju ati pipasẹ ẹ rẹ ati sise awọn eniyan loju kokoro si i.