وَإِن يَمۡسَسۡكَ ٱللَّهُ بِضُرّٖ فَلَا كَاشِفَ لَهُۥٓ إِلَّا هُوَۖ وَإِن يُرِدۡكَ بِخَيۡرٖ فَلَا رَآدَّ لِفَضۡلِهِۦۚ يُصِيبُ بِهِۦ مَن يَشَآءُ مِنۡ عِبَادِهِۦۚ وَهُوَ ٱلۡغَفُورُ ٱلرَّحِيمُ 107
Ti Ọlọhun ba jẹ ko sẹlẹ si ọ - ire ojise - aluba ti o si nfẹ ki o yi kuro lọdọ rẹ, ko si ẹniti o le yi kuro ayaafi Oun Allah ti mimọ nbẹ fun, ti o ba si ngbero irọra, ko si ẹnikan ti o le kọ ọla Rẹ fun ọ, O ma nfi ọla Rẹ fun ẹniti o ba wu U ninu ẹru Rẹ, ẹnikankan ko le tako, Oun ni olufi ori jinni fun ẹniti o ba ronu piwada ninu ẹru Rẹ ati olukẹ si wọn.
قُلۡ يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ قَدۡ جَآءَكُمُ ٱلۡحَقُّ مِن رَّبِّكُمۡۖ فَمَنِ ٱهۡتَدَىٰ فَإِنَّمَا يَهۡتَدِي لِنَفۡسِهِۦۖ وَمَن ضَلَّ فَإِنَّمَا يَضِلُّ عَلَيۡهَاۖ وَمَآ أَنَا۠ عَلَيۡكُم بِوَكِيلٖ 108
Sọ - irẹ ojisẹ -: ẹyin eniyan, paapaa Alukuraani ti sọkalẹ fun yin lati ọdọ Ọlọhun Ọba yin, ẹniti o ba mọ ọna, ti o si nigbagbọ si I, anfaani eleyi yoo sẹri lọ si ọdọ rẹ; nitori wipe dajudaju Ọlọhun Ọba rọrọ kuro nibi itẹle asẹ ẹru Rẹ, Ọlọhun Ọba Allah jẹ ẹniti ẹsẹ ẹru Rẹ ko le ko inira ba A, emi kii se olusọ le yin lori ti maa mọ sọ isẹ yin tabi se isiro yin.
وَٱتَّبِعۡ مَا يُوحَىٰٓ إِلَيۡكَ وَٱصۡبِرۡ حَتَّىٰ يَحۡكُمَ ٱللَّهُۚ وَهُوَ خَيۡرُ ٱلۡحَٰكِمِينَ 109
Ki o si tẹle - irẹ ojisẹ - imisi Ọlọhun Ọba rẹ si ọ ki o si fi sisẹ, ki o si tun se suuru lori ẹniti o ba yapa asẹ Ọlọhun Ọba rẹ ninu awọn ijọ rẹ, ati lori imudopin ohun ti wọn pa ọ lasẹ wipe ki o mude opin, ki o si tẹsiwaju lori eleyi titi ti Ọlọhun Ọba Allah yoo fi dajọ nipa wọn nibi ki o ran ọ se le wọn lori ni ile aye, ati ki o fi iya jẹ wọn ni ọrun ti wọn ba ku lori keferi wọn.
سورة (MAKIYYAH)
Sise afirinle anabi ati awon olugbagbo ododo pelu itan awon anabi ti wọn ti gbawaju, ati sise adehun iya ti o le koko fun awon opurọ.
الٓرۚ كِتَٰبٌ أُحۡكِمَتۡ ءَايَٰتُهُۥ ثُمَّ فُصِّلَتۡ مِن لَّدُنۡ حَكِيمٍ خَبِيرٍ 1
(الٓر) (Alif Lam Rọọ) ọrọ ti re kọja lori iru rẹ ninu ọgba ọrọ bakọrah, alukuraani jẹ iwe ti awọn amin rẹ daju niti eto ati itumọ, o ko le ri alafo tabi ẹdinku nibẹ, lẹyin naa wọn salaye awọn ẹtọ ati eewọ ati asẹ ati ikọfunni ati adehun daadaa ati adehun iya ati awọn itan ati ohun ti o yatọ si eleyi lati ọdọ ọjọgbọn nibi idari ati isofin rẹ, olufuni niro nipa isesi awọn ẹru Rẹ ati ohun ti yoo se wọn ni anfaani.
أَلَّا تَعۡبُدُوٓاْ إِلَّا ٱللَّهَۚ إِنَّنِي لَكُم مِّنۡهُ نَذِيرٞ وَبَشِيرٞ 2
Ohun ti o wa ninu awọn aayah ti o sọkalẹ fun Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun: kikọ fun awọn ẹru lati sin ẹlomiran ti yatọ si Allah, dajudaju emi - ẹyin eniyan - npaya Ọlọhun Ọba le yin lori nigbati ẹ ba se keferi si I, ti ẹ si sẹ Ẹ, mo si nfun yin niro idunnu ẹsan Rẹ ti ẹ ba nigbagbọ si I, ti ẹ se ofin Rẹ.
وَأَنِ ٱسۡتَغۡفِرُواْ رَبَّكُمۡ ثُمَّ تُوبُوٓاْ إِلَيۡهِ يُمَتِّعۡكُم مَّتَٰعًا حَسَنًا إِلَىٰٓ أَجَلٖ مُّسَمّٗى وَيُؤۡتِ كُلَّ ذِي فَضۡلٖ فَضۡلَهُۥۖ وَإِن تَوَلَّوۡاْ فَإِنِّيٓ أَخَافُ عَلَيۡكُمۡ عَذَابَ يَوۡمٖ كَبِيرٍ 3
Ki ẹ si maa wa - ẹyin eniyan - aforijin ẹsẹ yin lọdọ Ọlọhun Ọba yin, ki ẹ si sẹri lọsi ọdọ Rẹ pẹlu abamọ lori ohun ti o ti bọ mọ yin lọwọ, yoo fun yin ni idẹkun ni isẹmin aye, idẹkun daadaa titi di asiko ti titan yin ti a pebubu fun yin yoo fi de, ti yoo si fun gbogbo ẹniti o ba ni ọla nibi itẹle asẹ ati isẹ ni ẹsan ọla rẹ ni pipe laini si ẹdinku, ti wọn ba si gunri kuro nibi igbagbọ si ohun ti mo mu wa lati ọdọ Ọlọhun Ọba mi, dajudaju emi npaya iya ọjọ ti o le koko ni ibẹru ati ọjọ igbende le yin lori.
إِلَى ٱللَّهِ مَرۡجِعُكُمۡۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٌ 4
Ọdọ Ọlọhun Ọba Allah nikan ni isẹri si yin - ẹyin eniyan - ni ọjọ igbende, Oun nikan ti nmimọ nbẹ fun ni o lagbara lori gbogbo nkan, nkankan ko le ko agara ba A, bẹẹ ni tita yin ati sise isiro yin lẹyin iku yin ati gbigbe yin dide ko le ko agara ba A.
أَلَآ إِنَّهُمۡ يَثۡنُونَ صُدُورَهُمۡ لِيَسۡتَخۡفُواْ مِنۡهُۚ أَلَا حِينَ يَسۡتَغۡشُونَ ثِيَابَهُمۡ يَعۡلَمُ مَا يُسِرُّونَ وَمَا يُعۡلِنُونَۚ إِنَّهُۥ عَلِيمُۢ بِذَاتِ ٱلصُّدُورِ 5
Tẹti ẹ gbọ, dajudaju awọn ẹlẹbọ yii nse aanu ẹmin ara wọn ki wọn le fi ọkan balẹ lori iyemeji nipa Ọlọhun niti aimọkan lati ọdọ wọn si I, ẹ tẹti ẹ gbọ, nigbati wọn ba fi asọ wọn bo ori wọn, Ọlọhun Ọba Allah mọ ohun ti wọn fi pamọ ati eyiti wọn se afihan rẹ, Oun jẹ onimimọ nkan ti o pamọ si inu igbaaya.
Dajudaju rere ati aburu ati anfaani ati inira wa lọwọ Ọlọhun Ọba Allah yatọ si ẹlomiran.
Jijẹ dandan titẹle tira naa ati kikọse Anọbi ati suuru lori suta ati mima reti abayọ lati ọdọ Ọlọhun Ọba Allah.
Awọn aayah alukuraani jẹ ohun ti ọgbọn wa nibẹ, ko si alafo tabi ibajẹ nibẹ, wọn ti salaye awọn ofin ibẹ ni ẹkunrẹrẹ ti o pe.
Jijẹ dandan yiyara lọsi ibi ironu piwada ati kikabamọ lori ẹsẹ ki a le ni ohun ti a nwa, ati ki a le la kuro nibi ohun ti a nsaa fun.