أَلَمۡ تَكُنۡ ءَايَٰتِي تُتۡلَىٰ عَلَيۡكُمۡ فَكُنتُم بِهَا تُكَذِّبُونَ 105
Wọn yoo maa sọ fun wọn niti fifi ọrọ to wọn leti: se kii se wipe awọn aayah Alukuraani jẹ ohun ti nwọn ka fun yin ni ile aye ni, ti ẹ si jẹ ẹniti o npe e nirọ?!
قَالُواْ رَبَّنَا غَلَبَتۡ عَلَيۡنَا شِقۡوَتُنَا وَكُنَّا قَوۡمٗا ضَآلِّينَ 106
Wọn sọ wipe: Ọlọhun wa, eyiti o ti gba waju ninu imọ nipa oriburuku wa ti bori wa, a si jẹ ijọ ti o sọnu kuro nibi ododo.
رَبَّنَآ أَخۡرِجۡنَا مِنۡهَا فَإِنۡ عُدۡنَا فَإِنَّا ظَٰلِمُونَ 107
Ọlọhun wa, mu wa jade ninu ina, ti a ba sẹri sibi ohun ti a wa lori rẹ gẹgẹ bi keferi ati anu, a ti jẹ alabosi lori ẹmin wa, bẹẹni awijare wa si ti tan.
قَالَ ٱخۡسَُٔواْ فِيهَا وَلَا تُكَلِّمُونِ 108
Allah sọpe: ẹ maa gbe ni ẹni yẹpẹrẹ ati ẹni ilẹ ninu ina, ki ẹ mase ba mi sọrọ.
إِنَّهُۥ كَانَ فَرِيقٞ مِّنۡ عِبَادِي يَقُولُونَ رَبَّنَآ ءَامَنَّا فَٱغۡفِرۡ لَنَا وَٱرۡحَمۡنَا وَأَنتَ خَيۡرُ ٱلرَّٰحِمِينَ 109
Dajudaju o jẹ apakan ninu awọn ẹru Mi awọn ti wọn nigbagbọ si Mi, wọn yoo maa sọpe: Ọlọhun wa, a nigbagbọ si Ọ, ki O si fi ori ẹsẹ wa jin wa, ki O si kẹ wa lati ibi ikẹ Rẹ, iwọ ni o loore ju ni oluse ikẹ.
فَٱتَّخَذۡتُمُوهُمۡ سِخۡرِيًّا حَتَّىٰٓ أَنسَوۡكُمۡ ذِكۡرِي وَكُنتُم مِّنۡهُمۡ تَضۡحَكُونَ 110
Ẹ si gba awọn olugbagbọ ododo mu ni olupe Ọlọhun Ọba wọn ni aaye ifinise yẹyẹ, ti ẹ si mu wọn sere, ẹ nse yẹyẹ wọn titi ti ifinise yẹyẹ yin fi mu yin gbagbe iranti Allah, ẹ wa nrẹrin niti ifini se yẹyẹ ati imuni sere.
إِنِّي جَزَيۡتُهُمُ ٱلۡيَوۡمَ بِمَا صَبَرُوٓاْ أَنَّهُمۡ هُمُ ٱلۡفَآئِزُونَ 111
Dajudaju Emi san awọn olugbagbọ ododo wọnyi ni ẹsan erenjẹ ọgba idẹra ni ọjọ igbende; nitori suuru wọn lori itẹle ti Allah ati lori ohun ti wọn ba pade ninu suta lọdọ yin.
Nigbati wọn beere fun isẹri pada si aye lati se atunse ohun ti wọn bajẹ, O wa ran wọn leti ohun ti wọn ti lo nibẹ ninu ohun ti o le to fun wọn lati ronu piwada ti wọn ba gbero eleyi.
قَٰلَ كَمۡ لَبِثۡتُمۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ عَدَدَ سِنِينَ 112
O sọpe: ọdun melo ni ẹ lo ni ori ilẹ? Melo ni ẹ si ra lare ninu asiko.
قَالُواْ لَبِثۡنَا يَوۡمًا أَوۡ بَعۡضَ يَوۡمٖ فَسَۡٔلِ ٱلۡعَآدِّينَ 113
Wọn yoo si fesi pẹlu gbolohun wọn: a lo ọjọ kan tabi ilaji ninu ọjọ, ki o beere lọwọ awọn ti wọn ni ikọbi ara si isiro awọn ọjọ ati osu.
قَٰلَ إِن لَّبِثۡتُمۡ إِلَّا قَلِيلٗاۖ لَّوۡ أَنَّكُمۡ كُنتُمۡ تَعۡلَمُونَ 114
O sọpe: a ko lo ni ile aye ayaafi asiko kekere, ti suuru sise rọrun nibẹ lati tẹle asẹ ti o ba jasi wipe ẹ ma odiwọn ohun ti ẹ lo.
أَفَحَسِبۡتُمۡ أَنَّمَا خَلَقۡنَٰكُمۡ عَبَثٗا وَأَنَّكُمۡ إِلَيۡنَا لَا تُرۡجَعُونَ 115
Se ẹ lero ni - ẹyin eniyan - wipe a da yin niti ere laisi ọgbọn, ti koo nii si ẹsan tabi ijiya gẹgẹ bi awọn ẹranko, atipe dajudaju ẹ ko ni sẹri lọ si ọdọ Wa ni ọjọ igbende fun isiro ati ẹsan?!
فَتَعَٰلَى ٱللَّهُ ٱلۡمَلِكُ ٱلۡحَقُّۖ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ رَبُّ ٱلۡعَرۡشِ ٱلۡكَرِيمِ 116
Ọba Allah Ọlọla Oluse bi O se wu U nipa ẹda Rẹ pẹlu bi O se wu U, mọ kanga eyiti o jẹ ododo, ti adehun si jẹ ododo, ti gbolohun Rẹ naa jẹ ododo, ko si si ẹni ijọsin fun tootọ yatọ si I, Oni aga alaarasi ti o lapọnle eyiti o tobi ju ninu ẹda, ẹnikẹni ti no ba jẹ olukapa ohun ti o tobi ju ninu ẹda, Oujn naa ni yoo jẹ Ọlọhun rẹ lapapọ.
وَمَن يَدۡعُ مَعَ ٱللَّهِ إِلَٰهًا ءَاخَرَ لَا بُرۡهَٰنَ لَهُۥ بِهِۦ فَإِنَّمَا حِسَابُهُۥ عِندَ رَبِّهِۦٓۚ إِنَّهُۥ لَا يُفۡلِحُ ٱلۡكَٰفِرُونَ 117
Ẹniti o ba npe nkan ijọsin miran mọ Allah, ko si awijare fun un lori titọ ijọsin naa, eleyi si ni isesi gbogbo nkan ijọsin ti o yatọ si Allah, bẹẹni ẹsan aburu rẹ wa lọdọ Ọlọhun Ọba rẹ ti mimọ nbẹ fun, Oun ni yoo fi iya san lẹsan, dajudaju keferi ko le la pẹlu ki ọwọ rẹ tẹ ohun ti o nwa, bẹẹni ko le la nibi gbogbo ohujnn ti o nda ẹru bani.
وَقُل رَّبِّ ٱغۡفِرۡ وَٱرۡحَمۡ وَأَنتَ خَيۡرُ ٱلرَّٰحِمِينَ 118
Ki o si sọpe - irẹ ojisẹ -: Ọlọhun Ọba fi ori awọn ẹsẹ mi jin mi, ki O si fi ikẹ Rẹ kẹ mi, Iwọ ni o loore ju ni olukẹ ẹlẹsẹ, ki O si gba ironu piwada rẹ.
Keferi jẹ ẹni yẹpẹrẹ ẹni ilẹ ni ọdọ Allah.
Fifi awọn ẹniire se yẹyẹ jẹ ẹsẹ ti o tobi, ti ẹniti o ba nse yoo lẹtọ si iya.
Rira ọjọ ori lare jẹ nkan dandan ninu isesi keferi.
Yinyin Allah jẹ ihande kan ninu awọn ihande ẹkọ nibi adua.
Nigbati Allah ti mimọ nbẹ fun sise suura naa pẹlu sise iranti awọn iroyin erenjẹ awọn olugbagbọ ododo, o tọ ki o pari suura naa pẹlu ki o sọ ofo awọn keferi ati aikoni jere wọn.