وَبِٱلۡحَقِّ أَنزَلۡنَٰهُ وَبِٱلۡحَقِّ نَزَلَۗ وَمَآ أَرۡسَلۡنَٰكَ إِلَّا مُبَشِّرٗا وَنَذِيرٗا 105
Pẹlu ododo ni A sọ Alukuraani kalẹ fun Muhammad ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, pẹlu ododo naa si ni o fi sọkalẹ fun un laisi iyipada tabi iparẹ, bẹẹni a ko ran ọ nisẹ - irẹ ojisẹ - ayaafi ki o le olufuni niro idunnu fun awọn olupaya pẹlu Alujannah, ki o si tun jẹ oludẹruba awọn ẹni keferi ati ẹsẹ nibi ina.
وَقُرۡءَانٗا فَرَقۡنَٰهُ لِتَقۡرَأَهُۥ عَلَى ٱلنَّاسِ عَلَىٰ مُكۡثٖ وَنَزَّلۡنَٰهُ تَنزِيلٗا 106
A sọ ọ kalẹ ni nkan kika, a si fọ ọ si wẹwẹ, a si se alaye rẹ nitori ki o le ka fun awọn eniyan ni pẹlẹpẹlẹ ati sisẹntẹle nibi kika a; nitoripe o pepe lọsi ibi agbọye ati ironu ju, a si sọ ọ kalẹ niti irawọ ni ọtọọtọ ni ibamun si awọn isẹlẹ ati awọn isesi.
قُلۡ ءَامِنُواْ بِهِۦٓ أَوۡ لَا تُؤۡمِنُوٓاْۚ إِنَّ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡعِلۡمَ مِن قَبۡلِهِۦٓ إِذَا يُتۡلَىٰ عَلَيۡهِمۡ يَخِرُّونَۤ لِلۡأَذۡقَانِۤ سُجَّدٗاۤ 107
Sọ - irẹ ojisẹ - wipe: ki ẹ nigbagbọ si I, igbagbọ yin ko le alekun fun Un, tabi ẹ ko tirẹ nigbagbọ si I, bẹẹni sise keferi yin ko le ko adinku ba A, dajudaju awọn ti o nka awọn tira sanmọ ti o siwaju, ti wọn si mọ imisi ati ijẹ anọbi nigbati wọn ba ka Alaukuraani fun wọn, wọn yoo da oju bolẹ ni ẹniti yoo fi ori kanlẹ fun Allah niti idupẹ.
وَيَقُولُونَ سُبۡحَٰنَ رَبِّنَآ إِن كَانَ وَعۡدُ رَبِّنَا لَمَفۡعُولٗا 108
Wọn yoo sọ nibi iforikanlẹ wọn: Ọlọhun wa mọ kanga kọja yiyapa adehun, ohun ti O se ni adehun nipa yiyipada gbigbe Anọbi Muhammad ki ikẹ ati ọla nbẹ fun dide yoo sẹlẹ, dajudaju adehun Ọlọhun wa pẹlu eleyi ati nkan miran yoo sẹlẹ ti ko si ibuyẹ.
وَيَخِرُّونَ لِلۡأَذۡقَانِ يَبۡكُونَ وَيَزِيدُهُمۡ خُشُوعٗا۩ 109
Wọn da oju wọn bolẹ ni ẹniti o fi ori kanlẹ fun Allah, wọn si nsunkun nitori ipaya rẹ, bẹẹ ni gbigbọ Alukuraani ati rironu nipa itumọ rẹ se alekun itẹriba fun Allah ati ipaya Rẹ.
قُلِ ٱدۡعُواْ ٱللَّهَ أَوِ ٱدۡعُواْ ٱلرَّحۡمَٰنَۖ أَيّٗا مَّا تَدۡعُواْ فَلَهُ ٱلۡأَسۡمَآءُ ٱلۡحُسۡنَىٰۚ وَلَا تَجۡهَرۡ بِصَلَاتِكَ وَلَا تُخَافِتۡ بِهَا وَٱبۡتَغِ بَيۡنَ ذَٰلِكَ سَبِيلٗا 110
Sọ fun - irẹ ojisẹ - ẹniti o tako adeu pẹlu gbolohun rẹ wipe: (irẹ Allah, irẹ Ọba Ajọkẹ aye): Allah ati ajọkẹ aye orukọ mejeeji jẹ tiRẹ ti mimọ nbẹ fun, ki ẹ maa pe E pẹlu eyikeyi ninu wọn tabi awọn miran ninu awọn orukọ Rẹ, Ohun - ti mimọ nbẹ fun - ni O ni awọn orukọ ti o dara ju, awọn mejeeji yii si wa ninu wọn, ki ẹ yaa maa pe E pẹlu mejeeji tabi ohun ti o yatọ si wọn ninu awọn orukọ Rẹ ti o dara, mase maa ka ni ohun oke ninu irun rẹ ki awọn ẹlẹbọ le maa gbọ ọ, masi se ni jẹẹjẹ ti awọn olugbagbọ ododo ko fi nii gbọ ọ, wa oju ọna aarin laarin alamọri mejeeji.
وَقُلِ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ ٱلَّذِي لَمۡ يَتَّخِذۡ وَلَدٗا وَلَمۡ يَكُن لَّهُۥ شَرِيكٞ فِي ٱلۡمُلۡكِ وَلَمۡ يَكُن لَّهُۥ وَلِيّٞ مِّنَ ٱلذُّلِّۖ وَكَبِّرۡهُ تَكۡبِيرَۢا 111
Tun sọ wipe - irẹ ojisẹ -: ọpẹ ni fun Allah Ẹniti o lẹtọ si oniranran ọpẹ, ti O si mọ kuro nibi ọmọ, O tun mọ kuro nibi akẹgbẹ, ko si orogun fun Un nibi ọla Rẹ, iyẹpẹrẹ tabi irẹlẹ ko nii kan An, ko ni bukaata si ẹniti yoo ranse tabi fun lagbara, ki o si maa gbe titobi ni titobi ti o pọ, mase fi ọmọ ti si lọdọ, bẹẹ ni akẹgbẹ ninu ọla ko si fun, ko si si olurannise alaanu.
سورة (MAKIYYAH)
Sise alaye ọna amulo pẹlu awọn adanwo.
ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ ٱلَّذِيٓ أَنزَلَ عَلَىٰ عَبۡدِهِ ٱلۡكِتَٰبَ وَلَمۡ يَجۡعَل لَّهُۥ عِوَجَاۜ 1
Ẹyin pẹlu awọn iroyin ti o pe ati eyiti o gbọngbọn ati idẹkun ti o fi oju han ati eyiti o pamọ jẹ ti Allah nnikan soso eyiti O sọ Alukuraani kalẹ fun ẹru Rẹ ati Ojisẹ Rẹ ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, ko si fi iwọgun ati fifi kuro nibi ododo si bi Alukuraani yii.
قَيِّمٗا لِّيُنذِرَ بَأۡسٗا شَدِيدٗا مِّن لَّدُنۡهُ وَيُبَشِّرَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ٱلَّذِينَ يَعۡمَلُونَ ٱلصَّٰلِحَٰتِ أَنَّ لَهُمۡ أَجۡرًا حَسَنٗا 2
Bikosepe O se ni ohun ti o duro tọ ti ko si itako ara wọn tabi iyapa nibẹ; lati dẹruba awọn keferi nibi iya ti o le lati ọdọ Ọlọhun Allah eyiti ti nreti wọn, ko si le fun awọn olugbagbọ ododo ti wọn sisẹẹre ni iru ohun ti yoo dun wọn ninu wipe dajudaju ẹsan daradara ti ẹsan kankan ko lee le ba nbẹ fun wọn.
مَّٰكِثِينَ فِيهِ أَبَدٗا 3
Wọn yoo maa wa gbere ninu ẹsan lọ lailai ko si nii ja kuro ni ọdọ wọn.
وَيُنذِرَ ٱلَّذِينَ قَالُواْ ٱتَّخَذَ ٱللَّهُ وَلَدٗا 4
O si tun ndẹruba yahuudi ati nasọọra ati apakan ẹlẹbọ awọn ti wọn sọpe: Ọlọhun Allah ni ọmọ.
Ọlọhun Allah sọ Alukuraani kalẹ ti o kun fun ododo, deede, ofin ati idajọ ti o dara.
Titọ ẹkun sisun ninu irun nitori ipaya Allah ti O ga
Adua tabi nkan kika ninu irun gbọdọ jẹ ojupọnna laarin igbohun soke ati isẹrẹ jẹẹjẹ.
Alukuraani Alapọnle jẹ ohun ti o kun fun isẹ rere eyiti o nmu ni de nkan ti yoo dun ẹmin ninu, ti awọn ẹmin yoo si maa yọ pẹlu rẹ.