وَإِذَا قِيلَ لَهُمۡ تَعَالَوۡاْ إِلَىٰ مَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ وَإِلَى ٱلرَّسُولِ قَالُواْ حَسۡبُنَا مَا وَجَدۡنَا عَلَيۡهِ ءَابَآءَنَآۚ أَوَلَوۡ كَانَ ءَابَآؤُهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ شَيۡٔٗا وَلَا يَهۡتَدُونَ 104
Ti wọn ba sọ fuin awọn eniyan ti wọn nda adapa irọ mọ Ọlọhun Ọba Allah, lori sise awọn ẹran kan ni eewọ: ẹ wa sibi nkan ti Ọlọhun Ọba Allah sọkalẹ ninu Alukuraani ati sibi ikọse ojisẹ naa ti ikẹ ati ọla nbẹ fun, ki ẹ le mọ ẹtọ yatọ si eewọ, wọn wa sọ wipe: awọn nkan ti a gba, ati eyiti a jogun ni ọdọ awọn eni isiwaju wa ninu adisọkan ati ọrọ ati ise, ti to wa, bawo ni yoo se to wọn, ti o si ja si wipe awọn ẹni isiwaju wọn ko mọ nkankan, bẹẹ ni wọn ko mọ ọna ododo? ! ẹnikan ko nii tẹle wọn ayaafi ẹniti o ba jẹ alaimọkan ju wọn lọ, ti o si ti sina, alaimọkan ẹni anu ni wọn nse.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ عَلَيۡكُمۡ أَنفُسَكُمۡۖ لَا يَضُرُّكُم مَّن ضَلَّ إِذَا ٱهۡتَدَيۡتُمۡۚ إِلَى ٱللَّهِ مَرۡجِعُكُمۡ جَمِيعٗا فَيُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ 105
Ẹyin olugbagbọ ododo, ẹ sọ ara yin ki ẹ si mojuto ohun ti yoo mu anfaani ba a, ẹniti o sọnu ninu awọn eniyan, ti ko si jẹ ipe yin, ko le ko inira ba yin nigbati ẹyin ba ti mọ ọna, ninu itọ wọn sọna yin niki ẹ pa wọn lasẹ daadaa, ati ki ẹ kọ kuro nibi ibajẹ, ọdọ Ọlọhun Ọba Allah nikan ni olusẹri si yin ni ọjọ igbende, Yoo fun yin niro ohun ti ẹ se ni ile aye, Yoo si san yin lẹsan le lori.
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ شَهَٰدَةُ بَيۡنِكُمۡ إِذَا حَضَرَ أَحَدَكُمُ ٱلۡمَوۡتُ حِينَ ٱلۡوَصِيَّةِ ٱثۡنَانِ ذَوَا عَدۡلٖ مِّنكُمۡ أَوۡ ءَاخَرَانِ مِنۡ غَيۡرِكُمۡ إِنۡ أَنتُمۡ ضَرَبۡتُمۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَأَصَٰبَتۡكُم مُّصِيبَةُ ٱلۡمَوۡتِۚ تَحۡبِسُونَهُمَا مِنۢ بَعۡدِ ٱلصَّلَوٰةِ فَيُقۡسِمَانِ بِٱللَّهِ إِنِ ٱرۡتَبۡتُمۡ لَا نَشۡتَرِي بِهِۦ ثَمَنٗا وَلَوۡ كَانَ ذَا قُرۡبَىٰ وَلَا نَكۡتُمُ شَهَٰدَةَ ٱللَّهِ إِنَّآ إِذٗا لَّمِنَ ٱلۡأٓثِمِينَ 106
Ẹyin olugbagbọ ododo, ti iku ba sun mọ ẹnikan ninu yin pẹlu sise afihan amin kan ninu amin iku, ki o fi ẹlẹri meji ti o jẹ onideede ninu awọn olugbagbọ ododo, ki o fi han lori asọtẹlẹ rẹ, tabi ọkunrin meji ninu awọn keferi nigbati o ba ni bukaata si wọn pẹlu wipe o se afẹku awọn olugbagbọ ododo, ti ẹ ba se irin-ajo, ti iku waa de, tabi ẹ nse iyemeji nipa ẹri awọn mejeeji, ki ẹ da awọn mejeeji duro lẹyin ọkan ninu awọn irun ọranyan, ki awọn mejeeji fi Ọlọhun Ọba Allah bura: wọn ko gbọdọ ta ipin wọn ni ọdọ Ọlọhun Ọba Allah pẹlu ohunkihun, wọn gbọdọ fi di si ọdọ alasunmọ wọn, wọn si ko gbọdọ fi ẹri Ọlọhun Ọba Allah ti nẹb ni ọdọ wọn pamọ, dajudaju ti awọn mejeeji ba se bẹẹ, wọn ti wa ninu ẹlẹsẹ ati oluyapa Ọlọhun Ọba Allah.
فَإِنۡ عُثِرَ عَلَىٰٓ أَنَّهُمَا ٱسۡتَحَقَّآ إِثۡمٗا فََٔاخَرَانِ يَقُومَانِ مَقَامَهُمَا مِنَ ٱلَّذِينَ ٱسۡتَحَقَّ عَلَيۡهِمُ ٱلۡأَوۡلَيَٰنِ فَيُقۡسِمَانِ بِٱللَّهِ لَشَهَٰدَتُنَآ أَحَقُّ مِن شَهَٰدَتِهِمَا وَمَا ٱعۡتَدَيۡنَآ إِنَّآ إِذٗا لَّمِنَ ٱلظَّٰلِمِينَ 107
Ti o han de lẹyin igba ti wọn ti bura pẹlu irọ tabi ijẹri tabi ijanba wọn han; ki eeyan meji jẹri tabi bura ni ipo awọn mejeeji ninu awọn ti wọn sun mọ oku ju lori ohun ti o jẹ ododo, awọn mejeeji yoo fi Ọlọhun Ọba Allah bura lati jẹri wipe irọ ati ijanba awọn mejeeji ko daju bi ẹri awọn, ibura ti wa kii se irọ, ti awa ba jẹri irọ, ninu alabosi ni a wa ati ẹniti o kọja ti ẹnu aala ti Ọlọhun Ọba Allah.
ذَٰلِكَ أَدۡنَىٰٓ أَن يَأۡتُواْ بِٱلشَّهَٰدَةِ عَلَىٰ وَجۡهِهَآ أَوۡ يَخَافُوٓاْ أَن تُرَدَّ أَيۡمَٰنُۢ بَعۡدَ أَيۡمَٰنِهِمۡۗ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَٱسۡمَعُواْۗ وَٱللَّهُ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلۡفَٰسِقِينَ 108
Ibura ẹlẹri meji ti a sọ yii, yoo waye lẹyin irun ọranyan nigbati iyemeji ba wa nibi ijẹri awọn meji akọkọ tabi nibi ifesi pada ẹri awọn mejeeji, eleyi ni o sun mọ lati mu ẹri wa ni ojupọnna ofin ti Ọlọhun Ọba Allah gbe kalẹ, wọn ko gbọdọ yi ẹri jijẹ tabi paarọ rẹ, tabi se ijanba rẹ, bakanna eleyi ni o sun mọ lati da esi ẹri awọn ti yoo jẹ ogun pada lẹyin ibura wọn, ti wọn ko fi nii bura lori ohun ti o yatọ si nkan ti wọn fi oju ri, ti wọn yoo fi waa di ẹni yẹyẹ, ẹ paya Ọlọhun Ọba Allah pẹlu ki ẹ gbe irọ ju silẹ ati ijanba nibi ẹri jijẹ ati ibura, ki ẹ tẹti gbọ nkan ti wọn pa yin lasẹ, ni gbigbọ ti itẹwọgbọ yoo tẹle, Ọlọhun Ọba Allah ko nii fi awọn ti wọn jade kuro nibi itẹle asẹ se kongẹ.
Ti ẹru ba dunni mọ itẹle asẹ Ọlọhun Ọba Allah ati mima pasẹ daadaa, ati kikọ kuro nibi ibajẹ ni ibamun si ikapani Rẹ, isina ẹnikẹni ko lee ko inira ba A, wọn ko si nii bi leere nipa ẹlomiran, paapaa julọ awọn ẹni anu ninu wọn.
Sise ni loju kokoro nibi kikọ asọtẹlẹ ati didaabo boo pẹlu wiwa ẹlẹri onideede le lori.
Sise alaye bi ofin ẹsin se yaworan bibeere ẹlẹri lori asọtẹlẹ.