وَمَا تَسَۡٔلُهُمۡ عَلَيۡهِ مِنۡ أَجۡرٍۚ إِنۡ هُوَ إِلَّا ذِكۡرٞ لِّلۡعَٰلَمِينَ 104
Ti wọn ba se laakaye ni wọn ko ba nigbagbọ si ọ; toripe o ko beere lọdọ wọn - irẹ ojisẹ - ẹsan kankan lori Alukuraani ati lori ohun ti o npe wọn si, Alukuraani ko jẹ nkankan ju isekilọ fun gbogbo awọn eniyan lọ.
وَكَأَيِّن مِّنۡ ءَايَةٖ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ يَمُرُّونَ عَلَيۡهَا وَهُمۡ عَنۡهَا مُعۡرِضُونَ 105
Ni ọpọ oun si jẹ awọn aayah ti o ntọka lori ijọkan soso rẹ ti mimọ nbẹ fun, ti o si rinlẹ ni gbogbo sanmọ ati ilẹ, ti wọn nrekọja lori rẹ sugbọn wọn jẹ ẹniti o gunri kuro nibi rironu ati iwoye nipa rẹ, wọn kii gboju wobẹ.
وَمَا يُؤۡمِنُ أَكۡثَرُهُم بِٱللَّهِ إِلَّا وَهُم مُّشۡرِكُونَ 106
Ọpọ awọn eniyan ko nigbagbọ ninu Allah wipe Oun ni adẹda olusaranse, olujinni, olupani bikose wipe wọn ka nsin ẹlomiran pẹlu Rẹ ninu awọn oosa ati ẹbọ ni, wọn sin npe apemọra wipe O ni ọmọ, mimọ Rẹ.
أَفَأَمِنُوٓاْ أَن تَأۡتِيَهُمۡ غَٰشِيَةٞ مِّنۡ عَذَابِ ٱللَّهِ أَوۡ تَأۡتِيَهُمُ ٱلسَّاعَةُ بَغۡتَةٗ وَهُمۡ لَا يَشۡعُرُونَ 107
Se awọn ẹlẹbọ yiii fi ọkan balẹ ni ki iya ile aye waa ba wọn tii yoo bo wọn daru, ti yoo si mokunkun ba wọn, wọn ko nikapa lati tii danu tabi ki ọjọ igbende wa ba wọn lojiji, ti wọn ko nii fura mọ wiwa rẹ, debi wipe wọn yoo mura silẹ fun un, tori eleyi ni wọn ko fi gbagbọ?!
قُلۡ هَٰذِهِۦ سَبِيلِيٓ أَدۡعُوٓاْ إِلَى ٱللَّهِۚ عَلَىٰ بَصِيرَةٍ أَنَا۠ وَمَنِ ٱتَّبَعَنِيۖ وَسُبۡحَٰنَ ٱللَّهِ وَمَآ أَنَا۠ مِنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ 108
Sọ - irẹ ojisẹ - fun awọn ti o npe: eleyi ni oju ọna mi eyiti mo npe awọn eniyan si lori awijare ti o han ni emi npepe si, oun ni ẹniti o tẹle mi na npepe si, ti o nkọse mi, ti o si ntẹle oju ọna mi, mimọ fun Allah kuro nibi ohun ti wọn nse afiti si ọdọ Rẹ ti kosi lẹtọ si, emi kosi ninu awọn ẹlẹbọ pẹlu Allah bikose wipe mo jẹ ọkan ninu awọn olumu Ọlọhun Ọba lọkan soso ti mimọ nbẹ fun.
وَمَآ أَرۡسَلۡنَا مِن قَبۡلِكَ إِلَّا رِجَالٗا نُّوحِيٓ إِلَيۡهِم مِّنۡ أَهۡلِ ٱلۡقُرَىٰٓۗ أَفَلَمۡ يَسِيرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَيَنظُرُواْ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۗ وَلَدَارُ ٱلۡأٓخِرَةِ خَيۡرٞ لِّلَّذِينَ ٱتَّقَوۡاْۚ أَفَلَا تَعۡقِلُونَ 109
A ko gbe dide siwaju rẹ - irẹ ojisẹ - ayaafi awọn ọkunrin abara tii ki se Malaika, a ransẹ imisi si wọn gẹgẹ bi a se ransẹ imisi si ọ, ninu awọn ara ilu kii se ninu awọn ara oko, awọn ijọ wọn pe wọn nirọ, a si pa wọn run, se awọn opurọ yii ko wa rin pẹlu rẹ ni ori ilẹ ni, ki wọn le ronu si bawi ni igbẹyin awọn oluporu siwaju ti wọn se ri, ki wọn si woye pẹlu wọn?! Ati idẹkun ti nbẹ ni ile ọrun o loore fun awọn ti npaya ni ile aye, se ẹ ko se laakaye wipe eleyi loore ni, ki ẹ wa paya Allah pẹlu titẹle awọn asẹ Rẹ - eyiti ti o tobi ju u rẹ ni igbagbọ - ati jijinna si nkan ti O kọ eyiti ti o tobi ju ninu rẹ ni sise ẹbọ pẹlu Allah.
حَتَّىٰٓ إِذَا ٱسۡتَيَۡٔسَ ٱلرُّسُلُ وَظَنُّوٓاْ أَنَّهُمۡ قَدۡ كُذِبُواْ جَآءَهُمۡ نَصۡرُنَا فَنُجِّيَ مَن نَّشَآءُۖ وَلَا يُرَدُّ بَأۡسُنَا عَنِ ٱلۡقَوۡمِ ٱلۡمُجۡرِمِينَ 110
Awọn ojisẹ ti a ransẹ si yii, a nlọ awọn ọta wọn lara, ako ni kanju iya fun niti didẹwọn lẹkẹ titi ti iparun wọn yoo fi lọra, ti awọn ojisẹ naa yoo fi jakan kuro nibi iparun wọn ati ti awọn keferi yoo fi lero wipe awọn ojisẹ wọn parọ fun lori ohun ti wọn se ni adehun fun wọn ninu iya ti o wa fun awọn opurọ ati lila awọn olugbagbọ ododo; aranse wa de fun awọn ojisẹ wa, a si la awọn ojisẹ ati awọn olugbagbọ ododo kuro nibi iparun ti o sẹlẹ si awọn opurọ, ko si ohun ti yoo da iya Wa pada kuro fun awọn ijọ ẹlẹsẹ nigbati a ba sọọkalẹ fun wọn.
لَقَدۡ كَانَ فِي قَصَصِهِمۡ عِبۡرَةٞ لِّأُوْلِي ٱلۡأَلۡبَٰبِۗ مَا كَانَ حَدِيثٗا يُفۡتَرَىٰ وَلَٰكِن تَصۡدِيقَ ٱلَّذِي بَيۡنَ يَدَيۡهِ وَتَفۡصِيلَ كُلِّ شَيۡءٖ وَهُدٗى وَرَحۡمَةٗ لِّقَوۡمٖ يُؤۡمِنُونَ 111
Paapaa o ti wa ninu itan awọn ojisẹ ati itan awọn ijọ wọn ati nibi itan Yuusuf ati awọn ọmọ baba rẹ, isiti eyiti awọn onilaakaye mimọ yoo maa gba, alukuraani ko kun fun awọn ọrọ ahunjọ mọ Ọlọhun Ọba Allah sugbọn o jẹ ohun ti npe awọn iwe sanmọ ti a sọkalẹ lati ọdọ Ọlọhun Ọba lododo, o si jẹ alaye fun gbogbo ohun ti eniyan le ni bukaata si ifọsiyẹyẹ rẹ ninu awọn idajọ ati awọn ofin, o si jẹ itọsọna lọsi ibi gbogbo daadaa, o tun jẹ ikẹ fun awọn ijọ ti o nigbagbọ pẹlu rẹ, awọn ẹniti yoo se anfaani pẹlu ohun ti nbẹ ninu rẹ.
Ninu ọla Ọlọhun Ọba ti O ga julọ ni ki Ọlọhun Ọba Allah mu awọn anọbi ri apakan awọn ọrọ kọkọ nitori awọn idi pataki ati awọn ọgbọn.
Dajudaju olupepe ko nikapa yiyi ọkan awọn ẹru pada tabi gbigbe lọ si ibi itẹle asẹ ati wipe dajudaju ọpọlọpọ ẹda wọn kii se ẹni imọna.
Aayah yii kun fun ...قُلۡ هَٰذِهِۦ سَبِيلِيٓ (sọ wipe oju ọna mi ni eleyi...) iranti apakan awọn origun ipepe ninu rẹ ni: A- bibẹ ojupọnna: ((أَدۡعُوٓاْ) إِلَى ٱللَّهِ) (mu npepe lọ si ọdọ Allah) B- ojupọnna naa yoo wa lori imọ: (عَلَىٰ بَصِيرَةٍ) (lori imọ) D- bibẹ olupepe: (أَدۡعُوٓاْ)s(أَنَا۠) (mo npepe) (emi) E- bibẹ ẹniti a npe: (وَمَنِ ٱتَّبَعَنِي) (ati ẹniti o ba tẹle mi).